< Psalms 116 >

1 Èmi fẹ́ràn Olúwa, nítorí ó gbọ́ ohùn mi; ó gbọ́ ẹkún mi fún àánú.
I love the Lord, for he hears my voice, my pleas for mercy.
2 Nítorí ó yí etí rẹ̀ padà sí mi, èmi yóò máa pè é ni wọ́n ìgbà tí mo wà láààyè.
For he has inclined his ear to me: I will call upon him as long as I live.
3 Okùn ikú yí mi ká, ìrora isà òkú wá sórí mi; ìyọnu àti ìbànújẹ́ borí mi. (Sheol h7585)
About me were snares of death, the anguish of Sheol was upon me: distress and sorrow were mine. (Sheol h7585)
4 Nígbà náà ni mo ké pe orúkọ Olúwa: “Olúwa, èmi bẹ̀ ọ́, gba ọkàn mi!”
Then I called on the name of the Lord: “I beseech you, O Lord, deliver me.”
5 Olúwa ní oore-ọ̀fẹ́, ó sì ní òdodo; Ọlọ́run wa kún fún àánú.
Gracious and just is the Lord, compassionate is our God.
6 Olúwa pa àwọn ọlọ́kàn fífúyẹ́ mọ́ nígbà tí mo wà nínú àìní ńlá, ó gbà mí.
The Lord preserves the simple; when I was drooping, he saved me.
7 Padà, ìwọ ọkàn mi, sí ibi ìsinmi rẹ, nítorí Olúwa ṣe dáradára sí ọ.
Be at peace, my heart, once more, for the Lord has been good to you.
8 Nítorí ìwọ, Olúwa, ti gba ọkàn mi kúrò lọ́wọ́ ikú, ojú mi kúrò lọ́wọ́ omijé, àti ẹsẹ̀ mi kúrò lọ́wọ́ ìṣubú,
You have rescued me from death, my eyes from tears, my feet from stumbling.
9 nítorí èmi yóò máa rìn níwájú Olúwa ní ilẹ̀ alààyè.
Before the Lord I will walk in the land of the living.
10 Èmi gbàgbọ́; nítorí náà mo wí pé, “èmi rí ìpọ́njú púpọ̀”.
I held fast my faith, though I said, “Ah me! I am sore afflicted,”
11 Àti nínú ìdààmú mi mo wí pé, “Èké ni gbogbo ènìyàn”.
though in my alarm I said, “Everyone is a liar.”
12 Kí ni èmi yóò san fún Olúwa nítorí gbogbo rere rẹ̀ sí mi?
What shall I render the Lord for all his bounty to me?
13 Èmi yóò gbé ago ìgbàlà sókè èmi yóò sì máa ké pe orúkọ Olúwa.
I will lift up the cup of salvation, and call on the name of the Lord.
14 Èmi yóò mú ìlérí mi ṣẹ sí Olúwa ní ojú àwọn ènìyàn rẹ̀.
I will pay my vows to the Lord in the presence of all his people.
15 Iyebíye ní ojú Olúwa àti ikú àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀.
Grave in the eyes of the Lord is the death of his loyal and loved ones.
16 Olúwa, nítòótọ́ ìránṣẹ́ rẹ ni mo jẹ́; èmi ni ìránṣẹ́ rẹ, ọmọ ìránṣẹ́bìnrin rẹ; ó ti tú mi sílẹ̀ nínú ìdè mi.
Ah, Lord! I am your servant, your servant, child of your handmaid. You have loosened my bonds.
17 Èmi yóò rú ẹbọ ọpẹ́ sí ọ èmi yóò sì ké pe orúkọ Olúwa.
I will offer to you a thank-offering, and call on the name of the Lord.
18 Èmi yóò mú ìlérí mi sẹ sí Olúwa ní ojú gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀,
I will pay my vows to the Lord in the presence of all his people,
19 nínú àgbàlá ilé Olúwa ní àárín rẹ̀, ìwọ Jerusalẹmu. Ẹ yin Olúwa.
in the courts of the house of the Lord, in the midst of you, O Jerusalem. Hallelujah.

< Psalms 116 >