< Psalms 110 >

1 Ti Dafidi. Saamu. Olúwa sọ fún Olúwa mi pé, “Ìwọ jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi, títí èmi yóò fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.”
大卫的诗。 耶和华对我主说: 你坐在我的右边, 等我使你仇敌作你的脚凳。
2 Olúwa yóò na ọ̀pá agbára rẹ̀ láti Sioni wá, ìwọ jẹ ọba láàrín àwọn ọ̀tá rẹ.
耶和华必使你从锡安伸出能力的杖来; 你要在你仇敌中掌权。
3 Àwọn ènìyàn rẹ jẹ́ ọ̀rẹ́ àtinúwá ní ọjọ́ ìjáde ogun rẹ, nínú ẹwà mímọ́, láti inú òwúrọ̀ wá ìwọ ni ìrì ẹwà rẹ.
当你掌权的日子, 你的民要以圣洁的妆饰为衣, 甘心牺牲自己; 你的民多如清晨的甘露。
4 Olúwa ti búra, kò sì í yí ọkàn padà pé, “Ìwọ ni àlùfáà, ní ipasẹ̀ Melkisedeki.”
耶和华起了誓,决不后悔,说: 你是照着麦基洗德的等次永远为祭司。
5 Olúwa, ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ni yóò lu àwọn ọba bolẹ̀ ni ọjọ́ ìbínú rẹ̀.
在你右边的主, 当他发怒的日子,必打伤列王。
6 Yóò ṣe ìdájọ́ láàrín kèfèrí, yóò kún ibùgbé wọn pẹ̀lú òkú ara; yóò fọ́n àwọn olórí ká sí orí ilẹ̀ ayé tí ó gbòòrò.
他要在列邦中刑罚恶人, 尸首就遍满各处; 他要在许多国中打破仇敌的头。
7 Yóò mu nínú odò ṣíṣàn ní ọ̀nà: nítorí náà ni yóò ṣe gbé orí sókè.
他要喝路旁的河水, 因此必抬起头来。

< Psalms 110 >