< Psalms 109 >

1 Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu. Ọlọ́run, ti èmi ń fi ìyìn fún, má ṣe dákẹ́,
למנצח לדוד מזמור אלהי תהלתי אל-תחרש
2 nítorí àwọn ènìyàn búburú àti ẹlẹ́tàn ti ya ẹnu wọn sí mi wọ́n ti fi ahọ́n èké sọ̀rọ̀ sí mi.
כי פי רשע ופי-מרמה--עלי פתחו דברו אתי לשון שקר
3 Wọ́n fi ọ̀rọ̀ ìríra yí mi káàkiri; wọ́n bá mi jà láìnídìí
ודברי שנאה סבבוני וילחמוני חנם
4 Nípò ìfẹ́ mi, wọn ń ṣe ọ̀tá mi, ṣùgbọ́n èmi ń gba àdúrà.
תחת-אהבתי ישטנוני ואני תפלה
5 Wọ́n sì fi ibi san ìre fún mi àti ìríra fún ìfẹ́ mi.
וישימו עלי רעה תחת טובה ושנאה תחת אהבתי
6 Yan àwọn ènìyàn búburú láti dojúkọ jẹ́ kí àwọn olùfisùn dúró ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀.
הפקד עליו רשע ושטן יעמד על-ימינו
7 Kí a dá a lẹ́bi nígbà tí a bá ṣe ìdájọ́ kí àdúrà rẹ̀ kí ó lè di ìkọ̀sílẹ̀.
בהשפטו יצא רשע ותפלתו תהיה לחטאה
8 Kí ọjọ́ rẹ̀ kí ó kúrú; kí ẹlòmíràn kí ó rọ́pò iṣẹ́ rẹ̀.
יהיו-ימיו מעטים פקדתו יקח אחר
9 Kí àwọn ọmọ rẹ̀ di aláìní baba kí aya rẹ̀ sì di opó.
יהיו-בניו יתומים ואשתו אלמנה
10 Jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ̀ máa ṣagbe kiri kí wọn máa tọrọ oúnjẹ jìnnà sí ibi ahoro wọn.
ונוע ינועו בניו ושאלו ודרשו מחרבותיהם
11 Jẹ́ kí alọ́nilọ́wọ́gbà kí ó mú ohun gbogbo tí ó ní jẹ́ kí àlejò kí o kó èrè iṣẹ́ rẹ̀ lọ.
ינקש נושה לכל-אשר-לו ויבזו זרים יגיעו
12 Má ṣe jẹ́ kí ẹnìkan ṣe àánú fún un tàbí kí wọn káàánú lórí àwọn ọmọ rẹ̀ aláìní baba.
אל-יהי-לו משך חסד ואל-יהי חונן ליתומיו
13 Kí a gé àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ kúrò kí orúkọ wọn kí ó parẹ́ ní ìran tí ń bọ̀.
יהי-אחריתו להכרית בדור אחר ימח שמם
14 Kí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba rẹ̀ kí ó wà ní ìrántí ní ọ̀dọ̀ Olúwa. Má ṣe jẹ́ kí a yọ ẹ̀ṣẹ̀ ìyá wọn kúrò.
יזכר עון אבתיו--אל-יהוה וחטאת אמו אל-תמח
15 Jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ wọn kí ó wà ní ìrántí níwájú Olúwa kí ó lè gé ìrántí wọn kúrò lórí ilẹ̀.
יהיו נגד-יהוה תמיד ויכרת מארץ זכרם
16 Nítorí kò rántí láti ṣàánú, ṣùgbọ́n ó ṣe inúnibíni sí ọkùnrin tálákà àti olùpọ́njú, kí ó lè pa oníròbìnújẹ́ ọkàn.
יען-- אשר לא זכר עשות חסד וירדף איש-עני ואביון--ונכאה לבב למותת
17 Ó fẹ́ràn láti máa mú ègún wá sí orí rẹ̀: bi inú rẹ̀ kò ti dùn si ìre, bẹ́ẹ̀ ni kí ó jìnnà sí.
ויאהב קללה ותבואהו ולא-חפץ בברכה ותרחק ממנו
18 Bí ó ti fi ègún wọ ará rẹ̀ láṣọ bí ẹ̀wù bẹ́ẹ̀ ni kí ó wá sí inú rẹ̀ bí omi.
וילבש קללה כמדו ותבא כמים בקרבו וכשמן בעצמותיו
19 Jẹ́ kí ó rí fún un bí aṣọ tí a dà bò ó ní ara, àti fún àmùrè tí ó fi gba ọ̀já nígbà gbogbo.
תהי-לו כבגד יעטה ולמזח תמיד יחגרה
20 Èyí ni èrè àwọn ọ̀tá mi láti ọwọ́ Olúwa wá; àti ti àwọn tí ń sọ̀rọ̀ ibi sí ọkàn mi.
זאת פעלת שטני מאת יהוה והדברים רע על-נפשי
21 Ṣùgbọ́n ìwọ, ìwọ ṣe fún mi Olúwa Olódùmarè, ṣe rere fún mi nítorí orúkọ rẹ. Nítorí tí àánú rẹ dára, ìwọ gbà mí.
ואתה יהוה אדני-- עשה-אתי למען שמך כי-טוב חסדך הצילני
22 Nítorí pé tálákà àti aláìní ni mí, àyà mi sì gbọgbẹ́ nínú mi.
כי-עני ואביון אנכי ולבי חלל בקרבי
23 Èmi ń kọjá lọ bí òjìji tí àṣálẹ́, mo ń gbọ̀n sókè bí eṣú.
כצל-כנטותו נהלכתי ננערתי כארבה
24 Eékún mi di aláìlera nítorí àwẹ̀ gbígbà ẹran-ara mi sì gbẹ nítorí àìlera mi.
ברכי כשלו מצום ובשרי כחש משמן
25 Mo dàbí ẹ̀gàn fún àwọn olùfisùn mi; nígbà tí wọn wò mí, wọ́n gbọn orí wọn.
ואני הייתי חרפה להם יראוני יניעון ראשם
26 Ràn mí lọ́wọ́, Olúwa Ọlọ́run mi; gbà mí gẹ́gẹ́ bí ìṣeun ìfẹ́ rẹ.
עזרני יהוה אלהי הושיעני כחסדך
27 Jẹ́ kí wọn mọ̀ pé ọwọ́ rẹ ni èyí wí pé ìwọ, Olúwa, ni ó ṣe é.
וידעו כי-ידך זאת אתה יהוה עשיתה
28 Wọ́n ó máa gégùn ún, ṣùgbọ́n ìwọ máa súre, nígbà tí wọn bá dìde kí ojú kí ó tì wọ́n, ṣùgbọ́n ìránṣẹ́ rẹ yóò yọ̀.
יקללו-המה ואתה תברך קמו ויבשו--ועבדך ישמח
29 Jẹ́ kí a wọ àwọn ọ̀tá mi ní aṣọ ìtìjú kí á sì fi ìdàrúdàpọ̀ bọ̀ wọ́n lára bí ẹ̀wù.
ילבשו שוטני כלמה ויעטו כמעיל בשתם
30 Pẹ̀lú ẹnu mi èmi yóò máa yin Olúwa gidigidi ní àárín ọ̀pọ̀ ènìyàn èmi yóò máa yìn ín.
אודה יהוה מאד בפי ובתוך רבים אהללנו
31 Nítorí ó dúró ní apá ọ̀tún aláìní láti gbà á lọ́wọ́ àwọn tí ń dá ọkàn rẹ̀ lẹ́bi.
כי-יעמד לימין אביון-- להושיע משפטי נפשו

< Psalms 109 >