< Psalms 108 >
1 Orin. Saamu ti Dafidi. Ọlọ́run, ọkàn mi dúró ṣinṣin èmi ó máa kọrin, èmi ó máa fi ọkàn mi kọrin.
A Song, a Psalm of David. Prepared is my heart, O God, I sing, yea, I sing praise, also my honour.
2 Jí ohun èlò orin àti haapu! Èmi ó jí ní kùtùkùtù,
Awake, psaltery and harp, I awake the dawn.
3 èmi ó yìn ọ́, Olúwa, nínú àwọn orílẹ̀-èdè, èmi ó kọrin rẹ nínú àwọn ènìyàn.
I thank Thee among peoples, O Jehovah, And I praise Thee among the nations.
4 Nítorí tí o tóbi ní àánú rẹ ju àwọn ọ̀run lọ àti òdodo rẹ dé àwọsánmọ̀.
For great above the heavens [is] Thy kindness, And unto the clouds Thy truth.
5 Gbé ara rẹ ga, Ọlọ́run, lórí àwọn ọ̀run, àti ògo rẹ lórí gbogbo ayé.
Be Thou exalted above the heavens, O God, And above all the earth Thy honour.
6 Kí a sì lè gba àwọn olùfẹ́ rẹ là; fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ ṣe ìgbàlà, kí o sì dá mi lóhùn
That Thy beloved ones may be delivered, Save [with] Thy right hand, and answer us.
7 Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ láti ibi mímọ́ rẹ̀ pé, “Èmi yóò yọ̀, èmi yóò pín Ṣekemu, èmi yóò sì wọn àfonífojì Sukkoti kúrò.
God hath spoken in His holiness: I exult, I apportion Shechem, And the valley of Succoth I measure,
8 Gileadi ni tèmi, Manase ni tèmi, Efraimu ni ìbòrí mi, Juda ni olófin mi,
Mine [is] Gilead, mine [is] Manasseh, And Ephraim [is] the strength of my head, Judah [is] my lawgiver,
9 Moabu sì ni ìkòkò ìwẹsẹ̀ mi, lórí Edomu ni èmi ó bọ́ bàtà mi sí, lórí òkè Filistia ni èmi yóò hó ìhó ayọ̀.”
Moab [is] a pot for my washing, Upon Edom I cast my shoe, Over Philistia I shout habitually.
10 Ta ni yóò mú mi wá sí ìlú olódi? Ta ni yóò sìn mí wá sí Edomu?
Who doth bring me in to the fenced city? Who hath led me unto Edom?
11 Ìwọ Ọlọ́run ha kọ́, ìwọ tí ó ti kọ̀ wá sílẹ̀. Ọlọ́run ìwọ kì yóò bá àwọn jagunjagun wa jáde mọ́.
Hast not Thou, O God, cast us off? And Thou goest not out, O God, with our hosts!
12 Fún wa ní ìrànlọ́wọ́ nínú ìpọ́njú, nítorí ìrànlọ́wọ́ ènìyàn asán ni.
Give to us help from adversity, And vain is the salvation of man.
13 Nípasẹ̀ Ọlọ́run ni àwa ó ṣe akin nítorí òun ó tẹ àwọn ọ̀tá wa mọ́lẹ̀.
In God we do mightily, And He doth tread down our adversaries!