< Psalms 104 >

1 Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi. Olúwa Ọlọ́run mi, ìwọ tóbi jọjọ; ọlá àti ọláńlá ni ìwọ wọ̀ ní aṣọ.
Bless the Lord, O my soul. O Lord my God, you are very great, clad in awful splendor,
2 Ìwọ fi ìmọ́lẹ̀ bo ara rẹ gẹ́gẹ́ bí aṣọ; ó tẹ ọ̀run bí títẹ́ ẹní,
covered with robe of light. You stretch out the heavens like the cloth of a tent.
3 ìwọ tí ó fi omi ṣe ìtì igi àjà ìyẹ̀wù rẹ. Ìwọ tí o ṣe àwọsánmọ̀ ní kẹ̀kẹ́ ogun rẹ ìwọ tí ó ń rìn lórí apá ìyẹ́ afẹ́fẹ́.
He lays the beams of his chambers on water. He takes dark clouds for his chariot, and rides on the wings of the wind.
4 Ó fi ẹ̀fúùfù ṣe àwọn ìránṣẹ́ rẹ, ọ̀wọ́-iná ni àwọn olùránṣẹ́ rẹ.
He takes the winds for his messengers, the fire and the flame for his servants.
5 O fi ayé gúnlẹ̀ lórí àwọn ìpìlẹ̀; tí a kò le è mì láéláé.
He founded the earth upon pillars, to sustain it unshaken forever.
6 Ìwọ fi ibú omi bò ó mọ́lẹ̀ bí aṣọ; àwọn omi sì dúró lórí àwọn òkè ńlá.
With the garment of ocean he covered it, waters towered over the mountains.
7 Ṣùgbọ́n nípa ìbáwí rẹ ni àwọn omi lọ, nípa ohùn àrá rẹ ni wọ́n sálọ.
But at your rebuke they fled, scared by the roar of your thunder,
8 wọ́n sàn kọjá lórí àwọn òkè, wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ sí àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀, sí ibi tí ìwọ ti yàn fún wọn.
mountains rose, valleys sank down to the place appointed for them.
9 Ìwọ gbé òpin tí wọn kò lè kọjá rẹ̀ kálẹ̀; láéláé ni wọ́n kò ní lè bo ayé mọ́lẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i.
They dared not pass the bounds set for them, or cover the earth any more.
10 Ìwọ mú kí ìsun da omi sí àwọn àfonífojì; tí ó ń sàn láàrín àwọn òkè.
He sent brooks into the valleys, they meander between the mountains.
11 Wọ́n fún gbogbo àwọn ẹranko igbó ní omi àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ń pa òǹgbẹ wọn.
The wild beasts all drink from them, and the wild asses quench their thirst.
12 Àwọn ẹyẹ ojú òfúrufú tẹ́ ìtẹ́ wọn lẹ́gbẹ̀ẹ́ omi wọ́n ń kọrin láàrín àwọn ẹ̀ka.
The birds have their home by the banks, and sing in the branches.
13 Ó bu omi rin àwọn òkè láti ìyẹ̀wù rẹ̀ wá; a tẹ́ ayé lọ́rùn nípa èso iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
From his chambers above he gives drink to the mountains, and satisfies earth with the vials of heaven.
14 Ó mú kí koríko hù jáde fún àwọn ẹranko láti jẹ àti àwọn ewébẹ̀ fún ènìyàn láti lò, kí ó lè mú oúnjẹ jáde láti ilẹ̀ wá.
He makes grass grow for the cattle, and herbs for people. He brings bread out of the earth;
15 Ọtí wáìnì tí ó ń mú ọkàn ènìyàn yọ̀, òróró láti mú ojú rẹ̀ tan, àti àkàrà láti ra ọkàn rẹ̀ padà.
wine, to gladden hearts; oil, to make faces shine; bread, to strengthen hearts.
16 Àwọn igi Olúwa ni a bu omi rin dáradára, kedari ti Lebanoni tí ó gbìn.
The trees of the Lord drink their fill the cedars he planted on Lebanon,
17 Níbẹ̀ ní àwọn ẹyẹ ṣe ìtẹ́ wọn bí ó ṣe tí àkọ̀ ni, orí igi gíga ni ilé rẹ̀.
where the little birds build their nest, and the stork whose home is the cypress.
18 Àwọn òkè gíga ni ààbò fún àwọn ewúrẹ́ igbó; àti àwọn àlàpà jẹ́ ààbò fún àwọn ehoro.
The high hills are for the wild goats, and the rocks are for coneys to hide in.
19 Òṣùpá jẹ́ àmì fún àkókò oòrùn sì mọ ìgbà tí yóò wọ̀.
He created the moon to mark seasons, and told the sun when to set.
20 Ìwọ mú òkùnkùn wá, ó sì di òru, nínú èyí tí gbogbo ẹranko igbó ń rìn kiri.
You make it dark: night comes, when all the wild beasts creep out.
21 Kìnnìún ń bú ramúramù fún ohun ọdẹ wọn wọ́n sì ń wá oúnjẹ wọn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.
Young lions that roar for their prey, seeking their meat from God.
22 Oòrùn ràn, wọ́n sì kó ara wọn jọ, wọn padà lọ dùbúlẹ̀ sí ihò wọn.
At sunrise they slink away, and lie down in their dens.
23 Ọkùnrin jáde lọ sí iṣẹ́ wọn, àti sí làálàá rẹ̀ títí di àṣálẹ́.
Then people go forth to their work, and toil till evening.
24 Iṣẹ́ rẹ ti pọ̀ tó, Olúwa! Nínú ọgbọ́n ni ìwọ ṣe gbogbo wọn: ayé kún fún àwọn ìṣẹ̀dá á rẹ.
How many, O Lord, are your works, all of them made in wisdom! The earth is filled with your creatures.
25 Bẹ́ẹ̀ ni Òkun yìí tí ó tóbi, tí ó sì ni ìbú, tí ó kún fún àwọn ẹ̀dá alààyè ní ìsàlẹ̀ láìníye ohun alààyè tí tóbi àti kékeré.
And there is the great broad sea, where are countless things in motion, living creatures, both great and small.
26 Níbẹ̀ ni ọkọ̀ ń lọ síwá sẹ́yìn, àti Lefitani, tí ìwọ dá láti ṣe àríyá nínú rẹ̀.
There go the ships, and the Leviathan you made to play there.
27 Àwọn wọ̀nyí ń wò ọ́ láti fún wọn ní oúnjẹ wọn lákòókò rẹ̀.
They all look in hope to you, to give them their food in due season.
28 Nígbà tí ìwọ bá fi fún wọn, wọn yóò kó jọ; nígbà tí ìwọ bá la ọwọ́ rẹ̀, a tẹ́ wọn lọ́rùn pẹ̀lú ohun rere.
And you give with open hand; they gather and eat to their heart’s desire.
29 Nígbà tí ìwọ bá pa ojú rẹ mọ́ ara kò rọ̀ wọ́n nígbà tí ìwọ bá mú ẹ̀mí wọn lọ, wọn ó kú, wọn ó sì padà sí erùpẹ̀.
When you hide your face, they are terrified; when you take their breath away, they die and go back to their dust.
30 Nígbà tí ìwọ rán ẹ̀mí rẹ, ni a dá wọn, ìwọ sì tún ojú ayé ṣe.
But a breath from your lips creates them, and renews the face of the earth.
31 Jẹ́ kí ògo Olúwa wà pẹ́ títí láé; kí inú Olúwa kí ó dùn ní ti iṣẹ́ rẹ̀,
May the glory of the Lord be forever, may the Lord rejoice in his works.
32 ẹni tí ó wo ayé, tí ó sì wárìrì, ẹni tí ó fọwọ́ tọ́ àwọn òkè, tí wọ́n yọ èéfín.
A glance of his makes the earth tremble, a touch of his makes the hills smoke.
33 Ní gbogbo ayé mi ní n ó kọrin sí Olúwa: èmi ó kọrin ìyìn sí Olúwa níwọ̀n ìgbà tí mo wà láààyè.
I will sing to the Lord while I live, I will play to my God while I am.
34 Jẹ́ kí ẹ̀kọ́ mi kí ó tẹ́ ọ lọ́rùn bí mo ti ń yọ̀ nínú Olúwa.
May my musing be sweet to him, for I rejoice in the Lord.
35 Ṣùgbọ́n kí ẹlẹ́ṣẹ̀ kúrò láyé kí ènìyàn búburú má sì sí mọ́. Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi. Yin Olúwa.
But may sinners be swept from the earth, and the wicked vanish forever. O my soul, bless the Lord. Hallelujah.

< Psalms 104 >