< Psalms 102 >

1 Àdúrà olùpọ́njú tí àárẹ̀ mú, tí ó sí ọkàn rẹ̀ payá níwájú Olúwa. Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa, jẹ́ kí igbe ẹ̀bẹ̀ mi kí ó wá sí ọ̀dọ̀ rẹ.
The prayer: for a weary and suffering person who pours out their grief to the Lord. Hear my prayer, O Lord; let my cry for help come to you.
2 Má ṣe pa ojú rẹ mọ́ kúrò lọ́dọ̀ mi ní ọjọ́ tí èmi wà nínú ìpọ́njú. Dẹ etí rẹ sí mi; nígbà tí mo bá pè, dá mi lóhùn kíákíá.
Hide not your face from me in the day of my distress. Incline your ear to me: when I call, answer me speedily.
3 Nítorí tí ọjọ́ mi run bí èéfín; egungun mi sì jóná bí ààrò.
For my days pass away like smoke: my bones are burned through as with fire.
4 Àyà mi lù, ó sì rọ bí i koríko; mo gbàgbé láti jẹ oúnjẹ mi.
My heart is scorched, withered like grass; I forget to eat my bread.
5 Nítorí ohùn ìkérora mi, egungun mi lẹ̀ mọ́ ẹran-ara mi.
By reason of my loud groaning, my flesh clings to my bones.
6 Èmi dàbí ẹyẹ igún ní ijù: èmi dàbí òwìwí ibi ahoro.
Like a desert-owl of the wilderness, like an owl among ruins am I.
7 Èmi dìde; èmi dàbí ẹyẹ lórí ilé.
I make my sleepless lament like a bird on the house-top alone.
8 Ní ọjọ́ gbogbo, àwọn ọ̀tá ológoṣẹ́ mi ń gàn mí; àwọn tí ń ṣe ìkanra sí mi ń fi orúkọ mi bú.
All the day wild foes revile me, using my name for a curse.
9 Èmi jẹ eérú gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ mi, èmi sì da ohun mímu mi pọ̀ pẹ̀lú omijé.
For ashes have been my bread, and tears have been mixed with my cup.
10 Nítorí ìbínú ríru rẹ, nítorí ìwọ ti gbé mi sókè, ìwọ sì gbé mi ṣánlẹ̀.
Because of your passionate anger, you did raise me, then hurl me to the ground.
11 Ọjọ́ mi dàbí òjìji àṣálẹ́ èmi sì rọ bí koríko.
My days come to an end, shadows lengthen, I wither like grass.
12 Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa, ni yóò dúró láéláé; ìrántí rẹ láti ìran dé ìran.
But you, O Lord, are enthroned forever, your fame endures to all generations.
13 Ìwọ ó dìde ìwọ ó sì ṣàánú fún Sioni, nítorí ìgbà àti ṣe ojúrere sí i; àkókò náà ti dé.
You will arise and have pity on Zion; it’s time to be gracious; her hour has come.
14 Nítorí tí àwọn òkúta jẹ́ inú dídùn sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ; wọ́n sì káàánú erùpẹ̀ rẹ.
For even her stones are dear to your servants, even the dust of her ruins they look on with love.
15 Àwọn kèfèrí yóò bẹ̀rù orúkọ Olúwa, gbogbo ọba ayé yóò máa bẹ̀rù ògo rẹ.
Then the nations will revere the name of the Lord and all the kings of the earth his glory,
16 Torí tí Olúwa yóò gbé Sioni ró, yóò farahàn nínú ògo rẹ̀.
when the Lord shall have built up Zion, and revealed himself in his glory,
17 Yóò dáhùn àdúrà àwọn aláìní; kì yóò sì gan ẹ̀bẹ̀ wọn.
in response to the prayer of the destitute, whose prayer he will not despise.
18 Jẹ́ kí a kọ èyí fún ìran tí ń bọ̀, àwọn ènìyàn tí a kò tí ì dá yóò yin Olúwa:
Let this be recorded for ages to come, that the Lord may be praised by a people yet unborn.
19 “Olúwa wo ilẹ̀ láti òkè mímọ́ rẹ̀ wá láti ọ̀run wá ni ó bojú wo ayé,
For he shall look down from his holy height, from the heavens the Lord will gaze on the earth,
20 láti gbọ́ ìrora ará túbú, láti tú àwọn tí a yàn sí ikú sílẹ̀.”
to hear the groans of the prisoner, to free those who are doomed to die;
21 Kí a lè sọ orúkọ Olúwa ní Sioni àti ìyìn rẹ̀ ní Jerusalẹmu.
that people may recount the Lord’s fame in Zion, and the praise of him in Jerusalem,
22 Ní ìgbà tí a kó àwọn ènìyàn àti ìjọba pọ̀ láti máa sìn Olúwa.
when the nations are gathered together, and the kingdoms, to worship the Lord.
23 Ní ipa ọ̀nà mi, ó rẹ agbára mi sílẹ̀, ó gé ọjọ́ mi kúrú.
He has broken my strength on the way, he has shortened my days.
24 Èmi sì wí pé: “Ọlọ́run mi, má ṣe mú mi kúrò ní agbede-méjì ọjọ́ mi; ọdún rẹ̀ ń lọ láti ìran dé ìran.
I will say, ‘My God, take me not hence in the midst of my days. ‘Your years endure age after age.
25 Ní ìbẹ̀rẹ̀ ní ìwọ fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀, ọ̀run sì jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
Of old you have founded the earth, and the heavens are the work of your hands.
26 Wọn yóò ṣègbé, wọn yóò parun, ṣùgbọ́n ìwọ yóò wà; gbogbo wọn ni yóò gbó bí aṣọ. Bí ẹ̀wù ni ìwọ yóò pààrọ̀ wọn wọn yóò sì di àpatì.
They shall perish; but you do stand. They shall all wax old like a garment, and change as a robe you will change them.
27 Ṣùgbọ́n ìwọ wà digbí síbẹ̀, ọdún rẹ kò sì ní òpin.
But you are the same, your years are endless.
28 Àwọn ọmọ ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò dúró ní iwájú rẹ pẹ́; a ó sì fi ẹsẹ̀ irú-ọmọ wọn sọlẹ̀ ní iwájú rẹ.”
The children of your servants abide, evermore shall their seed be before you.’

< Psalms 102 >