< Psalms 101 >
1 Ti Dafidi. Saamu. Èmi yóò kọrin ìfẹ́ àti òdodo; sí ọ Olúwa, èmi yóò máa kọrin ìyìn.
A Psalm of David. I will sing of mercy and justice; unto Thee, O LORD, will I sing praises.
2 Èmi yóò máa rin ìrìn mi pẹ̀lú ọgbọ́n láìlẹ́ṣẹ̀, ìgbà wo ni ìwọ yóò wá sí ọ̀dọ̀ mi? Èmi yóò máa rìn ní ilé mi pẹ̀lú àyà pípé.
I will give heed unto the way of integrity; Oh when wilt Thou come unto me? I will walk within my house in the integrity of my heart.
3 Èmi kì yóò gbé ohun búburú sí iwájú mi: iṣẹ́ àwọn tí ó yapa ni èmi kórìíra. Wọn kì yóò rọ̀ mọ́ mi.
I will set no base thing before mine eyes; I hate the doing of things crooked; it shall not cleave unto me.
4 Agídí ọkàn yóò kúrò lọ́dọ̀ mi; èmi kì yóò mọ ènìyàn búburú.
A perverse heart shall depart from me; I will know no evil thing.
5 Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń sọ̀rọ̀ ẹnìkejì rẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀, òun ní èmi yóò gé kúrò ẹni tí ó bá gbé ojú rẹ̀ ga tí ó sì ní ìgbéraga àyà, òun ní èmi kì yóò faradà fún.
Whoso slandereth his neighbour in secret, him will I destroy; whoso is haughty of eye and proud of heart, him will I not suffer.
6 Ojú mi yóò wà lára àwọn olóòtítọ́ lórí ilẹ̀, kí wọn kí ó lè máa bá mi gbé; ẹni tí ó bá n rin ọ̀nà pípé òun ni yóò máa sìn mí.
Mine eyes are upon the faithful of the land, that they may dwell with me; he that walketh in a way of integrity, he shall minister unto me.
7 Ẹni tí ó bá ń ṣe ẹ̀tàn, kì yóò gbé ilé mi, kò sí ẹni tí ń ṣèké tí yóò dúró ní iwájú mi.
He that worketh deceit shall not dwell within my house; he that speaketh falsehood shall not be established before mine eyes.
8 Ní ojoojúmọ́ ní èmi yóò wá máa pa a lẹ́nu mọ gbogbo àwọn ènìyàn búburú ilẹ̀ náà; èmi yóò gé àwọn olùṣe búburú kúrò ní ìlú Olúwa.
Morning by morning will I destroy all the wicked of the land; to cut off all the workers of iniquity from the city of the LORD.