< Psalms 100 >

1 Saamu. Fún ọpẹ́. Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Olúwa, gbogbo ayé.
(감사의 시) 온 땅이여, 여호와께 즐거이 부를지어다
2 Ẹ fi ayọ̀ sin Olúwa, ẹ wá síwájú rẹ̀ pẹ̀lú orin dídùn
기쁨으로 여호와를 섬기며 노래하면서 그 앞에 나아갈지어다
3 Olúwa Ọlọ́run ni ó dá wa, kí ẹ̀yin kí ó mọ̀ pé tirẹ̀ ni àwa, àwa ní ènìyàn rẹ̀ àti àgùntàn pápá rẹ̀.
여호와가 우리 하나님이신 줄 너희는 알지어다! 그는 우리를 지으신 자시요 우리는 그의 것이니 그의 백성이요 그의 기르시는 양이로다
4 Ẹ lọ sí ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́ àti sí àgbàlá rẹ̀ pẹ̀lú ìyìn; ẹ fi ọpẹ́ àti ìyìn fún orúkọ rẹ̀.
감사함으로 그 문에 들어가며 찬송함으로 그 궁정에 들어가서 그에게 감사하며 그 이름을 송축할지어다
5 Nítorí tí Olúwa pọ̀ ní oore ìfẹ́ rẹ̀ sì wà títí láé; àti òtítọ́ rẹ̀ láti ìran de ìran.
대저 여호와는 선하시니 그 인자하심이 영원하고 그 성실하심이 대대에 미치리로다

< Psalms 100 >