< Psalms 10 >

1 Èéha ti ṣe, Olúwa, tí ìwọ fi dúró ní òkè réré? Èéha ti ṣe, tí ìwọ fi ara rẹ pamọ́ ní ìgbà ìpọ́njú?
לָמָ֣ה יְ֭הוָה תַּעֲמֹ֣ד בְּרָח֑וֹק תַּ֝עְלִ֗ים לְעִתּ֥וֹת בַּצָּרָֽה׃
2 Nínú àrékérekè ni ènìyàn búburú tí mu aláìlera, ẹni ti ó mú nínú ìdẹ̀kùn àrékérekè rẹ̀.
בְּגַאֲוַ֣ת רָ֭שָׁע יִדְלַ֣ק עָנִ֑י יִתָּפְשׂ֓וּ ׀ בִּמְזִמּ֖וֹת ז֣וּ חָשָֽׁבוּ׃
3 Nítorí ènìyàn búburú ń ṣògo ìfẹ́ inú ọkàn rẹ̀; Ó bùkún olójúkòkòrò, ó sì ń kẹ́gàn Olúwa.
כִּֽי־הִלֵּ֣ל רָ֭שָׁע עַל־תַּאֲוַ֣ת נַפְשׁ֑וֹ וּבֹצֵ֥עַ בֵּ֝רֵ֗ךְ נִ֘אֵ֥ץ ׀ יְהוָֽה׃
4 Ènìyàn búburú kò lè rí nínú ìgbéraga rẹ̀; kò sí ààyè fún Ọlọ́run nínú gbogbo èrò rẹ̀.
רָשָׁ֗ע כְּגֹ֣בַהּ אַ֭פּוֹ בַּל־יִדְרֹ֑שׁ אֵ֥ין אֱ֝לֹהִ֗ים כָּל־מְזִמּוֹתָֽיו׃
5 Ọ̀nà rẹ̀ ń gún régé nígbà gbogbo; òun ń gbéraga, òfin rẹ̀ sì jìnnà sí i; òun kẹ́gàn àwọn ọ̀tá rẹ̀.
יָ֘חִ֤ילוּ דרכו ׀ בְּכָל־עֵ֗ת מָר֣וֹם מִ֭שְׁפָּטֶיךָ מִנֶּגְדּ֑וֹ כָּל־צ֝וֹרְרָ֗יו יָפִ֥יחַ בָּהֶֽם׃
6 O wí fún ara rẹ̀, “Kò sí ohun tí ó lè mì mí. Inú mi yóò máa dùn nígbà gbogbo, èmi kò sì ní ní wàhálà.”
אָמַ֣ר בְּ֭לִבּוֹ בַּל־אֶמּ֑וֹט לְדֹ֥ר וָ֝דֹ֗ר אֲשֶׁ֣ר לֹֽא־בְרָֽע׃
7 Ẹnu rẹ̀ kún fún ègún àti irọ́ àti ìtànjẹ; wàhálà àti ohun búburú wà lábẹ́ ahọ́n rẹ̀.
אָלָ֤ה פִּ֣יהוּ מָ֭לֵא וּמִרְמ֣וֹת וָתֹ֑ךְ תַּ֥חַת לְ֝שׁוֹנ֗וֹ עָמָ֥ל וָאָֽוֶן׃
8 Ó lúgọ ní bùba nítòsí ìletò. Ò gọ níbi ìkọ̀kọ̀ láti pa aláìṣẹ̀. Ojú rẹ̀ ń ṣọ́ àwọn tálákà ní ìkọ̀kọ̀.
יֵשֵׁ֤ב ׀ בְּמַאְרַ֬ב חֲצֵרִ֗ים בַּֽ֭מִּסְתָּרִים יַהֲרֹ֣ג נָקִ֑י עֵ֝ינָ֗יו לְֽחֵלְכָ֥ה יִצְפֹּֽנוּ׃
9 Ó ba ní ní bùba bí i kìnnìún nínú pàǹtí; Ó ba ní bùba láti mú àwọn aláìní ìrànwọ́; ó mú àwọn aláìlólùrànlọ́wọ́, ó sì wọ́ wọn lọ sínú àwọ̀n rẹ̀.
יֶאֱרֹ֬ב בַּמִּסְתָּ֨ר ׀ כְּאַרְיֵ֬ה בְסֻכֹּ֗ה יֶ֭אֱרֹב לַחֲט֣וֹף עָנִ֑י יַחְטֹ֥ף עָ֝נִ֗י בְּמָשְׁכ֥וֹ בְרִשְׁתּֽוֹ׃
10 Ó ba, ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀; kí tálákà ba à le bọ́ sí ọwọ́ agbára rẹ̀.
ודכה יָשֹׁ֑חַ וְנָפַ֥ל בַּ֝עֲצוּמָ֗יו חלכאים ׃
11 Ó wí fún ara rẹ̀, “Ọlọ́run ti gbàgbé; Ó pa ojú rẹ̀ mọ́, òun kì yóò rí i láéláé.”
אָמַ֣ר בְּ֭לִבּוֹ שָׁ֣כַֽח אֵ֑ל הִסְתִּ֥יר פָּ֝נָ֗יו בַּל־רָאָ֥ה לָנֶֽצַח׃
12 Dìde, Olúwa! Gbé ọwọ́ rẹ sókè, Ọlọ́run. Má ṣe gbàgbé àwọn olùpọ́njú.
קוּמָ֤ה יְהוָ֗ה אֵ֭ל נְשָׂ֣א יָדֶ֑ךָ אַל־תִּשְׁכַּ֥ח עניים׃
13 Èéṣe tí ènìyàn búburú ṣe ń kẹ́gàn Ọlọ́run? Èéṣe tí o fi wí nínú ọkàn ara rẹ̀, “Kò ní pè mí láti ṣe ìṣirò”?
עַל־מֶ֤ה ׀ נִאֵ֖ץ רָשָׁ֥ע ׀ אֱלֹהִ֑ים אָמַ֥ר בְּ֝לִבּ֗וֹ לֹ֣א תִּדְרֹֽשׁ׃
14 Ṣùgbọ́n ìwọ, Ọlọ́run, ni ó rí wàhálà àti ìrora; Ìwọ rò láti fi sí ọwọ́ rẹ. Tálákà fi ara rẹ̀ jì fún ọ; Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ àwọn aláìní baba.
רָאִ֡תָה כִּֽי־אַתָּ֤ה ׀ עָ֘מָ֤ל וָכַ֨עַס ׀ תַּבִּיט֮ לָתֵ֪ת בְּיָ֫דֶ֥ךָ עָ֭לֶיךָ יַעֲזֹ֣ב חֵלֶ֑כָה יָ֝ת֗וֹם אַתָּ֤ה ׀ הָיִ֬יתָ עוֹזֵֽר׃
15 Ṣẹ́ apá àwọn ènìyàn búburú àti ènìyàn ibi; pè é láti wá ṣírò fún ìwà ìkà rẹ̀ tí a kò le è rí.
שְׁ֭בֹר זְר֣וֹעַ רָשָׁ֑ע וָ֝רָ֗ע תִּֽדְרוֹשׁ־רִשְׁע֥וֹ בַל־תִּמְצָֽא׃
16 Olúwa ń jẹ ọba láé àti láéláé; àwọn orílẹ̀-èdè yóò ṣègbé lórí ilé rẹ.
יְהוָ֣ה מֶ֭לֶךְ עוֹלָ֣ם וָעֶ֑ד אָבְד֥וּ ג֝וֹיִ֗ם מֵֽאַרְצֽוֹ׃
17 Ìwọ́ gbọ́, Olúwa, ìfẹ́ àwọn tí a ni lára; Ìwọ gbà wọ́n níyànjú, ó sì gbọ́ igbe wọn,
תַּאֲוַ֬ת עֲנָוִ֣ים שָׁמַ֣עְתָּ יְהוָ֑ה תָּכִ֥ין לִ֝בָּ֗ם תַּקְשִׁ֥יב אָזְנֶֽךָ׃
18 láti ṣe ìdájọ́ àwọn aláìní baba àti àwọn ti a ni lára, kí ọkùnrin, tí ó wà ní ayé, kí ó má ṣe dẹ́rùbà ni mọ́.
לִשְׁפֹּ֥ט יָת֗וֹם וָ֫דָ֥ךְ בַּל־יוֹסִ֥יף ע֑וֹד לַעֲרֹ֥ץ אֱ֝נ֗וֹשׁ מִן־הָאָֽרֶץ׃

< Psalms 10 >