< Proverbs 9 >

1 Ọgbọ́n ti kọ́ ilé rẹ̀, ó ti gbẹ́ òpó o rẹ̀ méjèèjì,
חכמות בנתה ביתה חצבה עמודיה שבעה
2 ó ti fi ilé pọn tí, ó ti fọ̀nà rokà. Ó sì ti ṣètò o tábìlì oúnjẹ rẹ̀
טבחה טבחה מסכה יינה אף ערכה שלחנה
3 ó ti rán àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ jáde, ó sì ń pè, láti ibi tí ó ga jù láàrín ìlú.
שלחה נערתיה תקרא-- על-גפי מרמי קרת
4 “Jẹ́ kí gbogbo àwọn aláìgbọ́n wọ ibí wá!” Ó ń wí fún àwọn tí kò lọ́gbọ́n pé,
מי-פתי יסר הנה חסר-לב אמרה לו
5 “Wá, ẹ wá jẹ́ oúnjẹ mi sì mu wáìnì tí mo ti pò.
לכו לחמו בלחמי ושתו ביין מסכתי
6 Fi ìwà àìmọ̀kan rẹ sílẹ̀ ìwọ yóò sì yè; rìn ní ọ̀nà òye.
עזבו פתאים וחיו ואשרו בדרך בינה
7 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ẹlẹ́gàn wí, kọ lẹ́tà sí àbùkù ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ẹni búburú wí kọ lẹ́tà sí èébú.
יסר לץ--לקח לו קלון ומוכיח לרשע מומו
8 Má ṣe bá ẹlẹ́gàn wí, àìṣe bẹ́ẹ̀ yóò kórìíra rẹ. Bá ọlọ́gbọ́n wí yóò sì fẹ́ràn rẹ;
אל-תוכח לץ פן-ישנאך הוכח לחכם ויאהבך
9 kọ́ ọlọ́gbọ́n ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́, yóò sì gbọ́n sí i kọ́ olódodo ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́, yóò sì fi kún ìmọ̀ rẹ̀.
תן לחכם ויחכם-עוד הודע לצדיק ויוסף לקח
10 “Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ́n, ìmọ̀ nípa Ẹni Mímọ́ ni òye.
תחלת חכמה יראת יהוה ודעת קדשים בינה
11 Nítorí nípasẹ̀ mi ọjọ́ rẹ yóò gùn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún yóò sì kún ọjọ́ ayé rẹ.
כי-בי ירבו ימיך ויוסיפו לך שנות חיים
12 Bí ìwọ bá gbọ́n, ọgbọ́n rẹ yóò fún ọ ní èrè: bí ìwọ bá jẹ́ ẹlẹ́gàn, ìwọ nìkan ni yóò jìyà.”
אם-חכמת חכמת לך ולצת לבדך תשא
13 Òmùgọ̀ obìnrin jẹ́ aláriwo; ó jẹ́ aláìlẹ́kọ̀ọ́ àti aláìní ìmọ̀.
אשת כסילות המיה פתיות ובל-ידעה מה
14 Ó jókòó ní ẹnu-ọ̀nà ilé rẹ̀ lórí ìjókòó níbi tí ó ga jù láàrín ìlú,
וישבה לפתח ביתה-- על-כסא מרמי קרת
15 ó ń pe àwọn tí ó ń kọjá lọ, tí wọn ń lọ tààrà ní ọ̀nà wọn.
לקרא לעברי-דרך המישרים ארחותם
16 “Jẹ́ kí gbogbo ẹni tí ó jẹ́ aláìlóye súnmọ́ bí!” Ni ó wí fún ẹni tí òye kù díẹ̀ ká à tó fún.
מי-פתי יסר הנה וחסר-לב ואמרה לו
17 “Omi tí a jí mu dùn oúnjẹ tí a jẹ ní ìkọ̀kọ̀ a máa ládùn!”
מים-גנובים ימתקו ולחם סתרים ינעם
18 Ṣùgbọ́n wọn ò funra pé àwọn òkú wà níbẹ̀, pé àwọn àlejò rẹ̀ wà ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀ isà òkú. (Sheol h7585)
ולא-ידע כי-רפאים שם בעמקי שאול קראיה (Sheol h7585)

< Proverbs 9 >