< Proverbs 8 >

1 Ǹjẹ́ ọgbọ́n kò ha ń kígbe síta? Òye kò ha ń gbé ohùn rẹ sókè?
הלא חכמה תקרא ותבונה תתן קולה׃
2 Ní ibi gíga ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà, ní ìkóríta, ní ó dúró;
בראש מרומים עלי דרך בית נתיבות נצבה׃
3 ní ẹgbẹ́ ibodè tí ó wọ ìlú, ní ẹnu ibodè ni ó ń kígbe sókè:
ליד שערים לפי קרת מבוא פתחים תרנה׃
4 “Sí i yín ẹ̀yin ènìyàn, ní mo ń kígbe pè; mo gbé ohun mi sókè sí gbogbo ènìyàn.
אליכם אישים אקרא וקולי אל בני אדם׃
5 Ẹ̀yin aláìmọ̀kan, ẹ kọ́gbọ́n; ẹ̀yin aṣiwèrè, ẹ gba òye.
הבינו פתאים ערמה וכסילים הבינו לב׃
6 Ẹ gbọ́, nítorí tí èmi ó sọ̀rọ̀ ohun iyebíye; Èmí ṣí ètè mi láti sọ ohun tí ó tọ́,
שמעו כי נגידים אדבר ומפתח שפתי מישרים׃
7 ẹnu mi ń sọ ohun tí í ṣe òtítọ́, nítorí ètè mi kórìíra ibi.
כי אמת יהגה חכי ותועבת שפתי רשע׃
8 Gbogbo ọ̀rọ̀ ẹnu mi ni ó tọ́, kò sí èyí tí ó jẹ́ ẹ̀tàn tàbí àyídáyidà níbẹ̀.
בצדק כל אמרי פי אין בהם נפתל ועקש׃
9 Fún olóye gbogbo rẹ̀ ni ó tọ̀nà; wọ́n jẹ́ aláìlẹ́gàn fún gbogbo ẹni tí ó ní ìmọ̀.
כלם נכחים למבין וישרים למצאי דעת׃
10 Yan ẹ̀kọ́ mi dípò fàdákà, ìmọ̀ dípò o wúrà àṣàyàn,
קחו מוסרי ואל כסף ודעת מחרוץ נבחר׃
11 nítorí ọgbọ́n ṣe iyebíye jù iyùn lọ, kò sí ohun tí ọkàn rẹ̀ fẹ́ tí a sì le fiwé e.
כי טובה חכמה מפנינים וכל חפצים לא ישוו בה׃
12 “Èmi, ọgbọ́n ń gbé pẹ̀lú òye; mo ní ìmọ̀ àti ọgbọ́n-inú.
אני חכמה שכנתי ערמה ודעת מזמות אמצא׃
13 Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìkórìíra ibi mo kórìíra ìgbéraga àti agídí, ìwà ibi àti ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.
יראת יהוה שנאת רע גאה וגאון ודרך רע ופי תהפכות שנאתי׃
14 Ìmọ̀ràn àti ọgbọ́n tí ó yè kooro jẹ́ tèmi mo ní òye àti agbára.
לי עצה ותושיה אני בינה לי גבורה׃
15 Nípasẹ̀ mi ni ọba ń ṣàkóso tí àwọn aláṣẹ sì ń ṣe òfin tí ó dára.
בי מלכים ימלכו ורוזנים יחקקו צדק׃
16 Nípasẹ̀ mi àwọn ọmọ-aládé ń ṣàkóso, àti gbogbo ọlọ́lá tí ń ṣàkóso ilẹ̀ ayé.
בי שרים ישרו ונדיבים כל שפטי צדק׃
17 Mo fẹ́ràn àwọn tí ó fẹ́ràn mi, àwọn tí ó sì wá mi rí mi.
אני אהביה אהב ומשחרי ימצאנני׃
18 Lọ́dọ̀ mi ni ọrọ̀ àti ọlá wà, ọrọ̀ tí í tọ́jọ́ àti ìgbéga rere.
עשר וכבוד אתי הון עתק וצדקה׃
19 Èso mi dára ju wúrà dáradára lọ; ohun tí mò ń mú wá ju àṣàyàn fàdákà lọ.
טוב פריי מחרוץ ומפז ותבואתי מכסף נבחר׃
20 Mò ń rìn ní ọ̀nà òdodo, ní ojú ọ̀nà òtítọ́,
בארח צדקה אהלך בתוך נתיבות משפט׃
21 mò ń fi ọrọ̀ fún gbogbo àwọn tí ó fẹ́ràn mi mo sì ń mú kí ilé ìṣúra wọn kún.
להנחיל אהבי יש ואצרתיהם אמלא׃
22 “Èmi ni Olúwa kọ́kọ́ dá nínú iṣẹ́ rẹ̀. Ṣáájú àwọn iṣẹ́ rẹ̀ àtijọ́;
יהוה קנני ראשית דרכו קדם מפעליו מאז׃
23 a ti yàn mí láti ayérayé, láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, kí ayé tó bẹ̀rẹ̀.
מעולם נסכתי מראש מקדמי ארץ׃
24 Nígbà tí kò tí ì sí Òkun, ni a ti bí mi, nígbà tí kò tí ì sí ìsun tí ó ní omi nínú;
באין תהמות חוללתי באין מעינות נכבדי מים׃
25 kí a tó fi àwọn òkè sí ipò wọn, ṣáájú àwọn òkè ni a ti bí mi,
בטרם הרים הטבעו לפני גבעות חוללתי׃
26 kí ó tó dá ilẹ̀ ayé tàbí àwọn oko rẹ̀ tàbí èyíkéyìí nínú eruku ayé.
עד לא עשה ארץ וחוצות וראש עפרות תבל׃
27 Mo wà níbẹ̀ nígbà tí ó fi àwọn ọ̀run sí ipò wọn, nígbà tí ó fi òsùwọ̀n àyíká sórí ibú omi,
בהכינו שמים שם אני בחוקו חוג על פני תהום׃
28 nígbà tí ó ṣẹ̀dá òfúrufú lókè tí ó sì fi orísun ibú omi sí ipò rẹ̀ láì le è yẹsẹ̀,
באמצו שחקים ממעל בעזוז עינות תהום׃
29 nígbà tí ó ṣe ààlà fún omi Òkun kí omi má ba à kọjá ààlà àṣẹ rẹ̀, àti nígbà tí ó pààlà ìpìlẹ̀ ayé.
בשומו לים חקו ומים לא יעברו פיו בחוקו מוסדי ארץ׃
30 Nígbà náà èmi ni gbẹ́nàgbẹ́nà ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ mo kún fún inú dídùn lójoojúmọ́, mo ń yọ̀ nígbà gbogbo níwájú rẹ̀.
ואהיה אצלו אמון ואהיה שעשעים יום יום משחקת לפניו בכל עת׃
31 Mo ń yọ̀ nínú gbogbo àgbáyé tí ó dá mo sì ní inú dídùn sí àwọn ọmọ ènìyàn.
משחקת בתבל ארצו ושעשעי את בני אדם׃
32 “Nítorí náà báyìí, ẹ̀yin ọmọ mi, ìbùkún ni fún àwọn tí ó pa ọ̀nà mi mọ́.
ועתה בנים שמעו לי ואשרי דרכי ישמרו׃
33 Fetí sí ìtọ́sọ́nà mi kí o sì gbọ́n; má ṣe pa á tì sápá kan.
שמעו מוסר וחכמו ואל תפרעו׃
34 Ìbùkún ni fún ẹni tí ó fetísílẹ̀ sí mi, tí ń ṣọ́nà ní ẹnu-ọ̀nà mi lójoojúmọ́, tí ń dúró ní ẹnu-ọ̀nà mi.
אשרי אדם שמע לי לשקד על דלתתי יום יום לשמר מזוזת פתחי׃
35 Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá rí mi rí ìyè ó sì rí ojúrere gbà lọ́dọ̀ Olúwa.
כי מצאי מצאי חיים ויפק רצון מיהוה׃
36 Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ̀ láti rí ń pa ara rẹ̀ lára gbogbo ẹni tí ó kórìíra mi fẹ́ ikú.”
וחטאי חמס נפשו כל משנאי אהבו מות׃

< Proverbs 8 >