< Proverbs 7 >
1 Ọmọ mi, pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, sì fi àwọn òfin mi pamọ́ sínú ọkàn rẹ.
My son, keep my words. Lay up my commandments within you.
2 Pa òfin mi mọ́, ìwọ yóò sì yè tọ́jú ẹ̀kọ́ mi bí ẹyinlójú rẹ.
Keep my commandments and live! Guard my teaching as the apple of your eye.
3 Kọ wọ́n sí ọwọ́ òsì rẹ, má ṣe fi jẹun kọ wọ́n sí inú wàláà àyà rẹ.
Bind them on your fingers. Write them on the tablet of your heart.
4 Wí fún ọgbọ́n pé, “Ìwọ ni arábìnrin mi,” sì pe òye ní ìbátan rẹ.
Tell wisdom, “You are my sister.” Call understanding your relative,
5 Wọn yóò pa ó mọ́ kúrò lọ́wọ́ obìnrin alágbèrè, kúrò lọ́wọ́ àjèjì obìnrin àti ọ̀rọ̀ ìtànjẹ rẹ̀.
that they may keep you from the strange woman, from the foreigner who flatters with her words.
6 Ní ojú fèrèsé ilé è mi mo wo ìta láti ojú fèrèsé.
For at the window of my house, I looked out through my lattice.
7 Mo rí i láàrín àwọn aláìmọ̀kan mo sì kíyèsi láàrín àwọn ọ̀dọ́kùnrin, ọ̀dọ́ kan tí ó ṣe aláìgbọ́n.
I saw among the simple ones. I discerned among the youths a young man void of understanding,
8 Ó ń lọ ní pópónà ní tòsí i ilé alágbèrè obìnrin náà, ó ń rìn lọ sí ọ̀nà ilé e rẹ̀.
passing through the street near her corner, he went the way to her house,
9 Ní ìrọ̀lẹ́ bí oòrùn ṣe ń wọ̀, bí òkùnkùn ṣe ń bo ni lára.
in the twilight, in the evening of the day, in the middle of the night and in the darkness.
10 Bẹ́ẹ̀ ni obìnrin kan jáde wá láti pàdé rẹ̀, ó múra bí panṣágà pẹ̀lú ètè búburú.
Behold, there a woman met him with the attire of a prostitute, and with crafty intent.
11 (Ó jẹ́ aláriwo àti alágídí, ìdí rẹ̀ kì í jókòó nílé;
She is loud and defiant. Her feet don’t stay in her house.
12 bí ó ti ń já níhìn-ín ní ó ń já lọ́hùn ún gbogbo orígun ni ó ti ń ba ní ibùba.)
Now she is in the streets, now in the squares, and lurking at every corner.
13 Ó dìímú, ó sì fẹnukò ó ní ẹnu pẹ̀lú ojú díndín ó wí pé,
So she caught him, and kissed him. With an impudent face she said to him:
14 “Mo ní ọrẹ àlàáfíà ní ilé; lónìí ni mo san ẹ̀jẹ́ mi.
“Sacrifices of peace offerings are with me. Today I have paid my vows.
15 Nítorí náà ni n o ṣe jáde wá pàdé è rẹ; mo wá ọ káàkiri mo sì ti rí ọ!
Therefore I came out to meet you, to diligently seek your face, and I have found you.
16 Mo ti tẹ́ ibùsùn mi pẹ̀lú aṣọ aláràbarà láti ilẹ̀ Ejibiti.
I have spread my couch with carpets of tapestry, with striped cloths of the yarn of Egypt.
17 Mo ti fi nǹkan olóòórùn dídùn sí ibùsùn mi bí i òjìá, aloe àti kinamoni.
I have perfumed my bed with myrrh, aloes, and cinnamon.
18 Wá, jẹ́ kí a lo ìfẹ́ papọ̀ ní kíkún títí di àárọ̀; jẹ́ kí a gbádùn ara wa pẹ̀lú ìfẹ́!
Come, let’s take our fill of loving until the morning. Let’s solace ourselves with loving.
19 Ọkọ ọ̀ mi ò sí nílé; ó ti lọ sí ìrìnàjò jíjìn.
For my husband isn’t at home. He has gone on a long journey.
20 Ó mú owó púpọ̀ lọ́wọ́ kò sì ní darí dé kí ó tó di ọ̀sán.”
He has taken a bag of money with him. He will come home at the full moon.”
21 Pẹ̀lú ọ̀rọ̀ dídùn ó sì í lọ́nà; ó tàn án jẹ pẹ̀lú ẹnu dídùn.
With persuasive words, she led him astray. With the flattering of her lips, she seduced him.
22 Òun sì tọ̀ ọ́ lọ lẹsẹ̀ kan náà, bí i màlúù tí ń lọ sí ibi pípa, tàbí bí àgbọ̀nrín tí ń lọ sí ibi okùn ìso.
He followed her immediately, as an ox goes to the slaughter, as a fool stepping into a noose.
23 Títí tí ọ̀kọ̀ fi gún un ní ẹ̀dọ̀, bí ẹyẹ ṣe ń fẹ́ wọ inú okùn, láìmọ̀ pé yóò gba ẹ̀mí òun.
Until an arrow strikes through his liver, as a bird hurries to the snare, and doesn’t know that it will cost his life.
24 Nítorí náà báyìí ẹ̀yin ọmọ mi, tẹ́tí sí mi fọkàn sí nǹkan tí mo sọ.
Now therefore, sons, listen to me. Pay attention to the words of my mouth.
25 Má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ kí ó yà sí ọ̀nà rẹ̀, tàbí kí ó rìn lọ sí ipa ọ̀nà rẹ̀.
Don’t let your heart turn to her ways. Don’t go astray in her paths,
26 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn tí ó ti fà lulẹ̀. Ogunlọ́gọ̀ àwọn alágbára ni ó ti pa.
for she has thrown down many wounded. Yes, all her slain are a mighty army.
27 Ilé e rẹ̀ ni ọ̀nà tààrà sí isà òkú, tí ó lọ tààrà sí àgbàlá ikú. (Sheol )
Her house is the way to Sheol, going down to the rooms of death. (Sheol )