< Proverbs 5 >

1 Ọmọ mi, fiyèsí ọgbọ́n mi, kí o sì dẹtí rẹ sí òye mi,
HIJO mío, está atento á mi sabiduría, y á mi inteligencia inclina tu oído;
2 kí ìwọ sì lè ní ìṣọ́ra kí ètè rẹ sì le pa ìmọ̀ mọ́.
Para que guardes consejo, y tus labios conserven la ciencia.
3 Nítorí ètè àwọn àjèjì obìnrin a máa sun bi oyin, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì kúnná ju òróró lọ.
Porque los labios de la extraña destilan miel, y su paladar es más blando que el aceite:
4 Ṣùgbọ́n ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín, ó korò ju òróǹró lọ, ó mú bí idà olójú méjì.
Mas su fin es amargo como el ajenjo, agudo como cuchillo de dos filos.
5 Ẹsẹ̀ rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí ọ̀nà ikú ìgbésẹ̀ rẹ̀ lọ tààrà sí ibojì òkú. (Sheol h7585)
Sus pies descienden á la muerte; sus pasos sustentan el sepulcro: (Sheol h7585)
6 Kí ìwọ má ba à já ipa ọ̀nà ìyè; ọ̀nà rẹ̀ rí pálapàla, ṣùgbọ́n kò tilẹ̀ mọ́.
Sus caminos son instables; no [los] conocerás, si no considerares el camino de vida.
7 Nítorí náà, ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ dẹtí sí mi, kí ẹ̀yin kí ó má ṣe yàgò kúrò nínú ọ̀rọ̀ tí mo sọ.
Ahora pues, hijos, oidme, y no os apartéis de las razones de mi boca.
8 Rìn ní ọ̀nà tí ó jìnnà sí ti rẹ̀, má ṣe súnmọ́ ẹnu-ọ̀nà ilé rẹ̀,
Aleja de ella tu camino, y no te acerques á la puerta de su casa;
9 àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ yóò gbé gbogbo ọlá rẹ lé ẹlòmíràn lọ́wọ́ àti ọjọ́ ayé rẹ fún ìkà ènìyàn.
Porque no des á los extraños tu honor, y tus años á cruel;
10 Kí a má ba à fi ọrọ̀ rẹ fún àjèjì ènìyàn, kí làálàá rẹ sì sọ ilé ẹlòmíràn di ọlọ́rọ̀.
Porque no se harten los extraños de tu fuerza, y tus trabajos [estén] en casa del extraño;
11 Ní ìgbẹ̀yìn ayé rẹ ìwọ yóò kérora, nígbà tí agbára rẹ àti ara rẹ bá ti joro tán.
Y gimas en tus postrimerías, cuando se consumiere tu carne y tu cuerpo,
12 Ìwọ yóò wí pé, “Mo ti kórìíra ẹ̀kọ́ tó! Ọkàn mi ṣe wá kórìíra ìbáwí!
Y digas: ¡Cómo aborrecí el consejo, y mi corazón menospreció la reprensión;
13 N kò gbọ́rọ̀ sí àwọn olùkọ́ mi lẹ́nu, tàbí kí n fetí sí àwọn tí ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́.
Y no oí la voz de los que me adoctrinaban, y á los que me enseñaban no incliné mi oído!
14 Mo ti bẹ̀rẹ̀ ìparun pátápátá ní àárín gbogbo àwùjọ ènìyàn.”
Casi en todo mal he estado, en medio de la sociedad y de la congregación.
15 Mu omi láti inú kànga tìrẹ, omi tí ń sàn láti inú kànga rẹ.
Bebe el agua de tu cisterna, y los raudales de tu pozo.
16 Ó ha yẹ kí omi ìsun rẹ kún àkúnya sí ojú ọ̀nà àti odò tí ń sàn lọ sí àárín ọjà?
Derrámense por de fuera tus fuentes, en las plazas los ríos de aguas.
17 Jẹ́ kí wọn jẹ́ tìrẹ nìkan, má ṣe ṣe àjọpín wọn pẹ̀lú àjèjì láéláé.
Sean para ti solo, y no para los extraños contigo.
18 Jẹ́ kí orísun rẹ kí ó ní ìbùkún; kí ìwọ ó sì máa yọ nínú aya ìgbà èwe rẹ.
Sea bendito tu manantial; y alégrate con la mujer de tu mocedad.
19 Abo àgbọ̀nrín tó dára, ìgalà tí ó wu ni jọjọ, jẹ́ kí ọmú rẹ̀ kí ó máa fi ayọ̀ fún ọ nígbà gbogbo, kí o sì máa yọ̀ nínú ìfẹ́ rẹ̀ nígbàkígbà.
[Como] cierva amada y graciosa corza, sus pechos te satisfagan en todo tiempo; y en su amor recréate siempre.
20 Ọmọ mi, èéṣe tí ìwọ ó fi máa yọ̀ nínú ìfẹ́ obìnrin panṣágà, tí ìwọ ó sì fi dì mọ́ ìyàwó ẹlòmíràn?
¿Y por qué, hijo mío, andarás ciego con la ajena, y abrazarás el seno de la extraña?
21 Nítorí ọ̀nà ènìyàn kò fi ara sin rárá fún Olúwa Ó sì ń gbé gbogbo ọ̀nà rẹ̀ yẹ̀ wò.
Pues que los caminos del hombre están ante los ojos de Jehová, y él considera todas sus veredas.
22 Ìwà búburú ènìyàn búburú ni yóò mú kó bọ́ sínú okùn; okùn ẹ̀ṣẹ̀ ara rẹ̀ yóò sì dìímú.
Prenderán al impío sus propias iniquidades, y detenido será con las cuerdas de su pecado.
23 Yóò kú ní àìgba ẹ̀kọ́ ìwà òmùgọ̀ ara rẹ̀ yóò sì mú kí ó máa ṣìnà kiri.
El morirá por falta de corrección; y errará por la grandeza de su locura.

< Proverbs 5 >