< Proverbs 4 >
1 Tẹ́tí, ẹ̀yin ọmọ mi, sí ẹ̀kọ́ baba; fetísílẹ̀ kí o sì ní òye sí i.
2 Mo fún ọ ní ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro, nítorí náà, má ṣe kọ ẹ̀kọ́ mi sílẹ̀.
3 Nígbà tí mo jẹ́ ọ̀dọ́mọkùnrin ní ilé baba à mí, mo jẹ́ èwe, tí mo sì jẹ́ ọ̀kan ṣoṣo lọ́wọ́ ìyá mi.
4 Ó kọ́ mi ó sì wí pé, “Jẹ́ kí àyà rẹ kí ó gba ọ̀rọ̀ mi dúró, pa òfin mi mọ́, kí ìwọ kí ó sì yè.
5 Gba ọgbọ́n, gba òye, má ṣe gbàgbé ọ̀rọ̀ mi tàbí kí o yẹsẹ̀ kúrò nínú rẹ̀.
6 Má ṣe kọ ọgbọ́n sílẹ̀, yóò sì dáàbò bò ọ́, fẹ́ràn rẹ̀, yóò sì bojútó ọ.
7 Ọgbọ́n ni ó ga jù; nítorí náà gba ọgbọ́n. Bí ó tilẹ̀ ná gbogbo ohun tí o ní, gba òye.
8 Gbé e ga, yóò sì gbé ọ ga dìrọ̀ mọ́ ọn, yóò sì bu iyì fún ọ.
9 Yóò fi òdòdó ọ̀ṣọ́ ẹwà sí orí rẹ yóò sì fi adé ẹlẹ́wà fún ọ.”
10 Tẹ́tí, ọmọ mi, gba ohun tí mo sọ, ọjọ́ ayé è rẹ yóò sì gùn.
11 Mo tọ́ ọ ṣọ́nà ní ọ̀nà ti ọgbọ́n mo sì mú ọ lọ ní ọ̀nà ti tààrà.
12 Nígbà tí o rìn, ìgbésẹ̀ rẹ kò ní ní ìdíwọ́ nígbà tí o bá sáré, ìwọ kì yóò kọsẹ̀.
13 Di ẹ̀kọ́ mú, má ṣe jẹ́ kí ó lọ; tọ́jú u rẹ̀ dáradára nítorí òun ni ìyè rẹ.
14 Má ṣe gbé ẹsẹ̀ rẹ sí ojú ọnà àwọn ènìyàn búburú tàbí kí o rìn ní ọ̀nà àwọn ẹni ibi.
15 Yẹra fún un, má ṣe rìn níbẹ̀; yàgò fún un kí o sì bá ọ̀nà tìrẹ lọ.
16 Nítorí wọn kò le sùn àyàfi tí wọ́n bá ṣe ibi, wọn kò ní tòògbé àyàfi tí wọ́n bá gbé ẹlòmíràn ṣubú.
17 Wọ́n ń jẹ oúnjẹ ìwà búburú wọ́n sì ń mu wáìnì ìwà ìkà.
18 Ipa ọ̀nà olódodo dàbí àṣẹ̀ṣẹ̀yọ oòrùn tí ń tànmọ́lẹ̀ sí i títí ọjọ́ fi kanrí
19 ṣùgbọ́n ọ̀nà ènìyàn búburú dàbí òkùnkùn biribiri; wọn kò mọ ohun tí ó ń mú wọn kọsẹ̀.
20 Ọmọ mi, tẹ́tí sí ohun tí mo sọ; fetísílẹ̀ dáradára sí ọ̀rọ̀ mi.
21 Má ṣe jẹ́ kí wọ́n rá mọ́ ọ lójú pa wọ́n mọ́ sínú ọkàn rẹ,
22 nítorí ìyè ni wọ́n jẹ́ fún gbogbo ẹni tí ó rí wọn àti ìlera fún gbogbo ara ènìyàn.
23 Ju gbogbo nǹkan tókù lọ, pa ọkàn rẹ mọ́, nítorí òun ni orísun ìyè.
24 Mú àrékérekè kúrò ní ẹnu rẹ; sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìsọkúsọ jìnnà réré sí ẹnu rẹ.
25 Jẹ́ kí ojú rẹ máa wo iwájú, jẹ́ kí ìwo ojú rẹ máa wo ọ̀kánkán iwájú rẹ sá á.
26 Kíyèsi ìrìn ẹsẹ̀ rẹ sì rìn ní àwọn ọ̀nà tí ó dára nìkan.
27 Má ṣe yà sọ́tùn ún tàbí sósì; pa ẹsẹ̀ rẹ mọ́ kúrò nínú ibi.