< Proverbs 31 >

1 Àwọn ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ ti Lemueli ọba, ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ìyá rẹ̀ kọ́ ọ,
דברי למואל מלך משא אשר יסרתו אמו׃
2 “Gbọ́ ìwọ ọmọ mi, gbọ́ ìwọ ọmọ inú mi! Gbọ́ ìwọ ọmọ ẹ̀jẹ́ mi.
מה ברי ומה בר בטני ומה בר נדרי׃
3 Má ṣe lo agbára rẹ lórí obìnrin, okun rẹ lórí àwọn tí ó pa àwọn ọba run.
אל תתן לנשים חילך ודרכיך למחות מלכין׃
4 “Kì í ṣe fún àwọn ọba, ìwọ Lemueli, kì í ṣe fún ọba láti mu ọtí wáìnì, kì í ṣe fún alákòóso láti máa wá ọtí líle,
אל למלכים למואל אל למלכים שתו יין ולרוזנים או שכר׃
5 kí wọn má ba à mu ọtí yó kí wọn sì gbàgbé ohun tí òfin wí, kí wọn sì fi ẹ̀tọ́ àwọn tí ara ń ni dù wọ́n.
פן ישתה וישכח מחקק וישנה דין כל בני עני׃
6 Fi ọtí líle fún àwọn tí ń ṣègbé wáìnì fún àwọn tí ó wà nínú ìrora.
תנו שכר לאובד ויין למרי נפש׃
7 Jẹ́ kí wọn mu ọtí kí wọn sì gbàgbé òsì wọn kí wọn má sì rántí òsì wọn mọ́.
ישתה וישכח רישו ועמלו לא יזכר עוד׃
8 “Sọ̀rọ̀ lórúkọ àwọn tí kò le sọ̀rọ̀ fúnra wọn fún ẹ̀tọ́ àwọn ẹni tí ń parun.
פתח פיך לאלם אל דין כל בני חלוף׃
9 Sọ̀rọ̀ kí o sì ṣe ìdájọ́ àìṣègbè jà fún ẹ̀tọ́ àwọn tálákà àti aláìní.”
פתח פיך שפט צדק ודין עני ואביון׃
10 Ta ni ó le rí aya oníwà rere? Ó níye lórí ju iyùn lọ.
אשת חיל מי ימצא ורחק מפנינים מכרה׃
11 Ọkọ rẹ̀ ní ìgbẹ́kẹ̀lé púpọ̀ nínú rẹ̀ kò sì ṣí ìwà rere tí kò pé lọ́wọ́ rẹ̀.
בטח בה לב בעלה ושלל לא יחסר׃
12 Ire ní ó ń ṣe fún un, kì í ṣe ibi ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.
גמלתהו טוב ולא רע כל ימי חייה׃
13 Ó sa aṣọ irun àgùntàn olówùú àti ọ̀gbọ̀ Ó sì ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìyárí.
דרשה צמר ופשתים ותעש בחפץ כפיה׃
14 Ó dàbí ọkọ̀ ojú omi tí àwọn oníṣòwò; ó ń gbé oúnjẹ rẹ̀ wá láti ọ̀nà jíjìn.
היתה כאניות סוחר ממרחק תביא לחמה׃
15 Ó dìde nígbà tí òkùnkùn sì kùn; ó ṣe oúnjẹ fún ìdílé rẹ̀ àti ìpín oúnjẹ fún àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀.
ותקם בעוד לילה ותתן טרף לביתה וחק לנערתיה׃
16 Ó kíyèsi oko kan, ó sì rà á; nínú ohun tí ó ń wọlé fún un ó gbin ọgbà àjàrà rẹ̀.
זממה שדה ותקחהו מפרי כפיה נטע כרם׃
17 Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ tagbára tagbára apá rẹ̀ le koko fún iṣẹ́.
חגרה בעוז מתניה ותאמץ זרעותיה׃
18 Ó rí i pé òwò òun pé fìtílà rẹ̀ kì í sì í kú ní òru.
טעמה כי טוב סחרה לא יכבה בליל נרה׃
19 Ní ọwọ́ rẹ̀, ó di kẹ̀kẹ́ òwú mú ó sì na ọwọ́ rẹ̀ di ìrànwú mú.
ידיה שלחה בכישור וכפיה תמכו פלך׃
20 O la ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn tálákà ó sì na ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn aláìní.
כפה פרשה לעני וידיה שלחה לאביון׃
21 Nígbà tí òjò-dídì rọ̀, kò bẹ̀rù nítorí ìdílé rẹ̀ nítorí gbogbo wọn ni ó wọ aṣọ tí ó nípọn.
לא תירא לביתה משלג כי כל ביתה לבש שנים׃
22 Ó ṣe aṣọ títẹ́ fún ibùsùn rẹ̀; ẹ̀wù dáradára àti elése àlùkò ni aṣọ rẹ̀.
מרבדים עשתה לה שש וארגמן לבושה׃
23 A bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀ ní ẹnu ibodè ìlú níbi tí ó ń jókòó láàrín àwọn àgbàgbà ìlú.
נודע בשערים בעלה בשבתו עם זקני ארץ׃
24 Ó ń ṣe àwọn aṣọ dáradára ó sì ń tà wọ́n ó sì ń kó ọjà fún àwọn oníṣòwò.
סדין עשתה ותמכר וחגור נתנה לכנעני׃
25 Agbára àti ọlá ni ó wò ọ́ láṣọ ó le fi ọjọ́ iwájú rẹ́rìn-ín.
עז והדר לבושה ותשחק ליום אחרון׃
26 A sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọgbọ́n ìkọ́ni òtítọ́ sì ń bẹ létè e rẹ̀
פיה פתחה בחכמה ותורת חסד על לשונה׃
27 Ó ń bojútó gbogbo ètò ilé rẹ̀ kì í sì í jẹ oúnjẹ ìmẹ́lẹ́.
צופיה הליכות ביתה ולחם עצלות לא תאכל׃
28 Àwọn ọmọ rẹ̀ dìde wọ́n sì pè é ní alábùkún ọkọ rẹ̀ pẹ̀lú ń gbóríyìn fún un.
קמו בניה ויאשרוה בעלה ויהללה׃
29 “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ obìnrin ní ń ṣe nǹkan ọlọ́lá ṣùgbọ́n ìwọ ju gbogbo wọn lọ.”
רבות בנות עשו חיל ואת עלית על כלנה׃
30 Ojú dáradára a máa tan ni, ẹwà sì jẹ́ asán nítorí obìnrin tí ó bẹ̀rù Olúwa yẹ kí ó gba oríyìn.
שקר החן והבל היפי אשה יראת יהוה היא תתהלל׃
31 Sì fún un ní èrè tí ó tọ́ sí i kí o sì jẹ́ kí iṣẹ́ rẹ̀ fún un ní ìyìn ní ẹnu ibodè ìlú.
תנו לה מפרי ידיה ויהללוה בשערים מעשיה׃

< Proverbs 31 >