< Proverbs 3 >

1 Ọmọ mi, má ṣe gbàgbé ẹ̀kọ́ mi. Ṣùgbọ́n pa òfin mi mọ́ sí ọkàn rẹ.
בני תורתי אל תשכח ומצותי יצר לבך׃
2 Nítorí ọjọ́ gígùn, ẹ̀mí gígùn, àti àlàáfíà, ni wọn yóò fi kùn un fún ọ.
כי ארך ימים ושנות חיים ושלום יוסיפו לך׃
3 Má ṣe jẹ́ kí ìfẹ́ àti òtítọ́ ṣíṣe fi ọ́ sílẹ̀ láéláé so wọ́n mọ́ ọrùn rẹ, kọ wọ́n sí wàláà àyà rẹ.
חסד ואמת אל יעזבך קשרם על גרגרותיך כתבם על לוח לבך׃
4 Nígbà náà ni ìwọ yóò rí ojúrere àti orúkọ rere ní ojú Ọlọ́run àti lójú ènìyàn.
ומצא חן ושכל טוב בעיני אלהים ואדם׃
5 Gbẹ́kẹ̀lé Olúwa pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ má ṣe sinmi lé òye ara à rẹ.
בטח אל יהוה בכל לבך ואל בינתך אל תשען׃
6 Mọ̀ ọ́n ní gbogbo ọ̀nà rẹ òun yóò sì máa tọ́ ipa ọ̀nà rẹ.
בכל דרכיך דעהו והוא יישר ארחתיך׃
7 Má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n lójú ara à rẹ bẹ̀rù Olúwa kí o sì kórìíra ibi.
אל תהי חכם בעיניך ירא את יהוה וסור מרע׃
8 Èyí yóò mú ìlera fún ara rẹ àti okun fún àwọn egungun rẹ.
רפאות תהי לשרך ושקוי לעצמותיך׃
9 Fi ọrọ̀ rẹ bọ̀wọ̀ fún Olúwa, pẹ̀lú àkọ́so oko rẹ,
כבד את יהוה מהונך ומראשית כל תבואתך׃
10 nígbà náà ni àká rẹ yóò kún àkúnya àgbá rẹ yóò kún àkúnwọ́sílẹ̀ fún wáìnì tuntun.
וימלאו אסמיך שבע ותירוש יקביך יפרצו׃
11 Ọmọ mi, má ṣe kẹ́gàn ìbáwí Olúwa má sì ṣe bínú nígbà tí ó bá ń bá ọ wí,
מוסר יהוה בני אל תמאס ואל תקץ בתוכחתו׃
12 nítorí Olúwa a máa bá àwọn tí ó fẹ́ràn wí bí baba ti í bá ọmọ tí ó bá nínú dídùn sí wí.
כי את אשר יאהב יהוה יוכיח וכאב את בן ירצה׃
13 Ìbùkún ni fún ẹni tí ó ní ìmọ̀, ẹni tí ó tún ní òye sí i,
אשרי אדם מצא חכמה ואדם יפיק תבונה׃
14 nítorí ó ṣe èrè ju fàdákà lọ ó sì ní èrè lórí ju wúrà lọ.
כי טוב סחרה מסחר כסף ומחרוץ תבואתה׃
15 Ó ṣe iyebíye ju iyùn lọ; kò sí ohunkóhun tí a lè fiwé e nínú ohun gbogbo tí ìwọ fẹ́.
יקרה היא מפניים וכל חפציך לא ישוו בה׃
16 Ẹ̀mí gígùn ń bẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀; ní ọwọ́ òsì rẹ sì ni ọrọ̀ àti ọlá.
ארך ימים בימינה בשמאולה עשר וכבוד׃
17 Àwọn ọ̀nà rẹ jẹ́ ọ̀nà ìtura, òpópónà rẹ sì jẹ́ ti àlàáfíà.
דרכיה דרכי נעם וכל נתיבותיה שלום׃
18 Igi ìyè ni ó jẹ́ fún gbogbo ẹni tí ó bá gbà á; àwọn tí ó bá sì dìímú yóò rí ìbùkún gbà.
עץ חיים היא למחזיקים בה ותמכיה מאשר׃
19 Nípa ọgbọ́n, Olúwa fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé sọlẹ̀; nípa òye, ó fi àwọn ọ̀run sí ipò wọn;
יהוה בחכמה יסד ארץ כונן שמים בתבונה׃
20 nípa ìmọ̀ rẹ̀ ó pín ibú omi ní yà, àwọsánmọ̀ sì ń sẹ ìrì.
בדעתו תהומות נבקעו ושחקים ירעפו טל׃
21 Ọmọ mi, pa ọgbọ́n tí ó yè kooro àti ìmòye mọ́, má jẹ́ kí wọn lọ kúrò ní ibi tí ojú rẹ ti le tó wọn.
בני אל ילזו מעיניך נצר תשיה ומזמה׃
22 Wọn yóò jẹ́ ìyè fún ọ, àti ẹ̀ṣọ́ fún ọrùn rẹ.
ויהיו חיים לנפשך וחן לגרגרתיך׃
23 Nígbà náà ni ìwọ yóò bá ọ̀nà rẹ lọ ní àìléwu, ìwọ kì yóò sì kọsẹ̀.
אז תלך לבטח דרכך ורגלך לא תגוף׃
24 Nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀, ìwọ kì yóò bẹ̀rù, nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀, oorun rẹ yóò jẹ́ oorun ayọ̀.
אם תשכב לא תפחד ושכבת וערבה שנתך׃
25 Má ṣe bẹ̀rù ìdààmú òjijì, tàbí ti ìparun tí ó ń dé bá àwọn ènìyàn búburú.
אל תירא מפחד פתאם ומשאת רשעים כי תבא׃
26 Nítorí Olúwa yóò jẹ́ ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ, kì yóò sì jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ bọ́ sínú pàkúté.
כי יהוה יהיה בכסלך ושמר רגלך מלכד׃
27 Má ṣe fa ọwọ́ ìre sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ àwọn tí ṣe tìrẹ, nígbà tí ó bá wà ní ìkápá rẹ láti ṣe ohun kan.
אל תמנע טוב מבעליו בהיות לאל ידיך לעשות׃
28 Má ṣe wí fún aládùúgbò rẹ pé, “Padà wá nígbà tó ṣe díẹ̀; èmi yóò fi fún ọ ní ọ̀la,” nígbà tí o ní i pẹ̀lú rẹ nísinsin yìí.
אל תאמר לרעיך לך ושוב ומחר אתן ויש אתך׃
29 Má ṣe pète ohun búburú fún aládùúgbò rẹ, ti o gbé nítòsí rẹ, tí ó sì fọkàn tán ọ.
אל תחרש על רעך רעה והוא יושב לבטח אתך׃
30 Má ṣe fẹ̀sùn kan ènìyàn láìnídìí, nígbà tí kò ṣe ọ́ ní ibi kankan rárá.
אל תרוב עם אדם חנם אם לא גמלך רעה׃
31 Má ṣe ṣe ìlara ènìyàn jàgídíjàgan tàbí kí o yàn láti rìn ní ọ̀nà rẹ̀.
אל תקנא באיש חמס ואל תבחר בכל דרכיו׃
32 Nítorí Olúwa kórìíra ènìyàn aláyídáyidà ṣùgbọ́n a máa fọkàn tán ẹni dídúró ṣinṣin.
כי תועבת יהוה נלוז ואת ישרים סודו׃
33 Ègún Olúwa ń bẹ lórí ilé ènìyàn búburú, ṣùgbọ́n ó bùkún fún ilé olódodo.
מארת יהוה בבית רשע ונוה צדיקים יברך׃
34 Ó fi àwọn ẹlẹ́yà ṣe yẹ̀yẹ́, ṣùgbọ́n ó fi oore-ọ̀fẹ́ fún onírẹ̀lẹ̀.
אם ללצים הוא יליץ ולעניים יתן חן׃
35 Ọlọ́gbọ́n jogún iyì, ṣùgbọ́n àwọn aṣiwèrè ni yóò ru ìtìjú wọn.
כבוד חכמים ינחלו וכסילים מרים קלון׃

< Proverbs 3 >