< Proverbs 29 >
1 Ẹni tí ó sì ń ṣorí kunkun lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbáwí yóò parun lójijì láìsí àtúnṣe.
A man who remains stiff-necked after much reproof will suddenly be shattered beyond recovery.
2 Nígbà tí olódodo bá ń gbilẹ̀, àwọn ènìyàn a yọ̀ nígbà tí ènìyàn búburú ń ṣàkóso, àwọn ènìyàn ń kórìíra.
When the righteous flourish, the people rejoice, but when the wicked rule, the people groan.
3 Ènìyàn tí ó fẹ́ràn ọgbọ́n mú kí baba rẹ̀ láyọ̀ ṣùgbọ́n ẹni ti ń bá panṣágà kẹ́gbẹ́ ba ọrọ̀ ọ rẹ̀ jẹ́.
A man who loves wisdom brings joy to his father, but a companion of prostitutes squanders his wealth.
4 Nípa ìdájọ́ òdodo ni ọba fi í mú ìlú tòrò nini, ṣùgbọ́n èyí tí ń ṣe ojúkòkòrò àbẹ̀tẹ́lẹ̀ fà á lulẹ̀.
By justice a king brings stability to the land, but a man who exacts tribute demolishes it.
5 Ẹnikẹ́ni tí ó bá tan aládùúgbò rẹ̀ ó ń dẹ àwọ̀n de ẹsẹ̀ ẹ rẹ̀.
A man who flatters his neighbor spreads a net for his feet.
6 Ẹ̀ṣẹ̀ ènìyàn ibi ni ó jẹ́ ìdẹ̀kùn rẹ̀ ṣùgbọ́n olódodo le è kọrin kí ó sì máa yọ̀.
An evil man is caught by his own sin, but a righteous one sings and rejoices.
7 Olódodo ń máa ro ọ̀rọ̀ tálákà, ṣùgbọ́n ènìyàn búburú kò sú sí i láti rò ó.
The righteous consider the cause of the poor, but the wicked have no regard for such concerns.
8 Àwọn ẹlẹ́yà a máa ru ìlú sókè, ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn máa ń mú ìbínú kúrò.
Mockers inflame a city, but the wise turn away anger.
9 Bí ọlọ́gbọ́n ènìyàn bá lọ sí ilé ẹjọ́ pẹ̀lú aláìgbọ́n aláìgbọ́n a máa bínú a sì máa jà, kò sì ní sí àlàáfíà.
If a wise man goes to court with a fool, there will be raving and laughing with no resolution.
10 Àwọn tí ó ń tàjẹ̀ sílẹ̀ kò rí ẹni dídúró ṣinṣin wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti pa olódodo.
Men of bloodshed hate a blameless man, but the upright care for his life.
11 Aláìgbọ́n ènìyàn fi gbogbo ẹnu rẹ̀ bínú ṣùgbọ́n ọlọ́gbọ́n ènìyàn a máa kó ìbínú rẹ̀ ní ìjánu.
A fool vents all his anger, but a wise man holds it back.
12 Bí olórí bá fetí sí irọ́, gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀ a di ènìyàn búburú lójú rẹ̀.
If a ruler listens to lies, all his officials will be wicked.
13 Tálákà ènìyàn àti aninilára jọ ní àbùdá yìí, Olúwa jẹ́ kí ojú àwọn méjèèjì máa ríran.
The poor man and the oppressor have this in common: The LORD gives light to the eyes of both.
14 Bí ọba kan bá ń ṣe ìdájọ́ tálákà pẹ̀lú òtítọ́ ìtẹ́ ìjọba rẹ yóò fìdímúlẹ̀ nígbà gbogbo.
A king who judges the poor with fairness— his throne will be established forever.
15 Ọ̀pá ìbániwí ń fún ni ní ọgbọ́n ṣùgbọ́n ọmọ tí a fi sílẹ̀ fúnra rẹ̀ a dójútì ìyá rẹ̀.
A rod of correction imparts wisdom, but a child left to himself disgraces his mother.
16 Nígbà tí ènìyàn búburú ń gbilẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀ṣẹ̀ ń gbilẹ̀ ṣùgbọ́n olódodo yóò rí ìṣubú wọn.
When the wicked thrive, rebellion increases; but the righteous will see their downfall.
17 Bá ọmọ rẹ wí, yóò sì fún ọ ní àlàáfíà yóò sì mú inú dídùn wá sí inú ọkàn rẹ.
Discipline your son, and he will give you rest; he will bring delight to your soul.
18 Níbi tí kò ti sí ìfihàn, àwọn ènìyàn a gbé ìgbé ayé àìbìkítà, ṣùgbọ́n ìbùkún ní fún àwọn tí ń pa òfin mọ́.
Where there is no vision, the people cast off restraint; but blessed is he who keeps the Law.
19 A kò le fi ọ̀rọ̀ lásán kìlọ̀ fún ìránṣẹ́ bí ó tilẹ̀ yé e, kò ní kọbi ara sí i.
A servant cannot be corrected by words alone; though he understands, he will not respond.
20 Ǹjẹ́ ó rí ènìyàn tí ń kánjú sọ̀rọ̀? Ìrètí wà fún aláìgbọ́n jù ú lọ.
Do you see a man who speaks in haste? There is more hope for a fool than for him.
21 Bí ènìyàn kan bá kẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ lákẹ̀ẹ́jù láti kékeré yóò mú ìbànújẹ́ wá ní ìgbẹ̀yìn.
A servant pampered from his youth will bring grief in the end.
22 Oníbìínú ènìyàn a ru ìjà sókè, onínú-fùfù ènìyàn a sì máa dá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀.
An angry man stirs up dissension, and a hot-tempered man abounds in transgression.
23 Ìgbéraga ènìyàn a máa sọ ọ́ di ẹni ilẹ̀ ṣùgbọ́n onírẹ̀lẹ̀ ènìyàn a máa gba iyì kún iyì.
A man’s pride will bring him low, but a humble spirit will obtain honor.
24 Ẹni tí ó ń kó ẹgbẹ́, olè kórìíra ọkàn ara rẹ̀, ó ń gbọ́ èpè olóhun kò sì le è fọhùn.
A partner to a thief hates his own soul; he receives the oath, but does not testify.
25 Ìbẹ̀rù ènìyàn kan yóò sì di ìdẹ̀kùn ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bẹ̀rù Olúwa wà láìléwu.
The fear of man is a snare, but whoever trusts in the LORD is set securely on high.
26 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ń wá ojúrere alákòóso, ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni ènìyàn tí ń gba ìdájọ́ òdodo.
Many seek the ruler’s favor, but a man receives justice from the LORD.
27 Olódodo kórìíra àwọn aláìṣòótọ́: ènìyàn búburú kórìíra olódodo.
An unjust man is detestable to the righteous, and one whose way is upright is detestable to the wicked.