< Proverbs 28 >

1 Ènìyàn búburú ń sá bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹnìkan kò lé e ṣùgbọ́n olódodo láyà bí i kìnnìún.
악인은 쫓아 오는 자가 없어도 도망하나 의인은 사자 같이 담대하니라
2 Nígbà tí orílẹ̀-èdè bá ní orí kunkun, àwọn ọba rẹ̀ a máa pọ̀, ṣùgbọ́n olóye àti onímọ̀ a máa pa òfin mọ́.
나라는 죄가 있으면 주관자가 많아져도 명철과 지식 있는 사람으로 말미암아 장구하게 되느니라
3 Ọba tí ó ni àwọn tálákà lára dàbí àgbàrá òjò tí ó ń gbá gbogbo ọ̀gbìn lọ.
가난한 자를 학대하는 가난한 자는 곡식을 남기지 아니하는 폭우같으니라
4 Àwọn tí ó kọ òfin sílẹ̀ a máa gbóríyìn fún ènìyàn búburú ṣùgbọ́n àwọn tí ó pa òfin mọ́ kọjú ìjà sí ènìyàn búburú.
율법을 버린 자는 악인을 칭찬하나 율법을 지키는 자는 악인을 대적하느니라
5 Òye ìdájọ́ òdodo kò yé àwọn ẹni ibi ṣùgbọ́n ó yé àwọn tí ń wá Olúwa dáradára.
악인은 공의를 깨닫지 못하나 여호와를 찾는 자는 모든 것을 깨닫느니라
6 Ó sàn láti jẹ́ tálákà tí ìrìn rẹ̀ jẹ́ aláìlábùkù ju ọlọ́rọ̀ tí ọ̀nà rẹ̀ rí pálapàla.
성실히 행하는 가난한 자는 사곡히 행하는 부자보다 나으니라
7 Ẹni tí ó pa òfin mọ́ jẹ́ olóye ọmọ ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ẹ́ jẹgúdújẹrá kẹ́gbẹ́ dójútì baba rẹ̀.
율법을 지키는 자는 지혜로운 아들이요 탐식자를 사귀는 자는 아비를 욕되게 하는 자니라
8 Ẹni tí ó mú ọrọ̀ rẹ̀ di púpọ̀ nípa èrè àjẹjù ń kó jọ fún ẹlòmíràn, tí yóò ní àánú àwọn tálákà.
중한 변리로 자기 재산을 많아지게 하는 것은 가난한 사람 불쌍히 여기는 자를 위하여 그 재산을 저축하는 것이니라
9 Bí ẹnikẹ́ni bá kọ etí ikún sí òfin, kódà àdúrà rẹ̀ jẹ́ ìríra.
사람이 귀를 돌이키고 율법을 듣지 아니하면 그의 기도도 가증하니라
10 Ẹni tí ó mú olódodo rìn ọ̀nà búburú yóò bọ́ sínú pàkúté ara rẹ̀ ṣùgbọ́n aláìlẹ́gàn yóò gba ogún rere.
정직한 자를 악한 길로 유인하는 자는 스스로 자기 함정에 빠져도 성실한 자는 복을 얻느니라
11 Ọlọ́rọ̀ ènìyàn le è gbọ́n lójú ara rẹ̀ ṣùgbọ́n tálákà tí ó ní òye rí ìdí, rẹ̀.
부자는 자기를 지혜롭게 여겨도 명철한 가난한 자는 그를 살펴 아느니라
12 Nígbà tí olódodo ń lékè ariwo ayọ̀ ta; ṣùgbọ́n nígbà tí ènìyàn búburú gorí òye, àwọn ènìyàn a na pápá bora.
의인이 득의하면 큰 영화가 있고 악인이 일어나면 사람이 숨느니라
13 Ẹni tí ó bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀ kì yóò ṣe rere, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá jẹ́wọ́ tí ó sì kọ̀ wọ́n sílẹ̀ máa ń rí àánú gbà.
자기의 죄를 숨기는 자는 형통치 못하나 죄를 자복하고 버리는 자는 불쌍히 여김을 받으리라
14 Ìbùkún ni fún ènìyàn náà tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run nígbà gbogbo ṣùgbọ́n ẹni tí ó sé ọkàn rẹ̀ le bọ́ sínú wàhálà.
항상 경외하는 자는 복되거니와 마음을 강퍅하게 하는 자는 재앙에 빠지리라
15 Bí kìnnìún tí ń ké tàbí Beari tí ń halẹ̀ ni ènìyàn búburú tí ń jẹ ọba lórí àwọn aláìlágbára.
가난한 백성을 압제하는 악한 관원은 부르짖는 사자와 주린 곰 같으니라
16 Ọmọ-aládé tí ó ṣe aláìmòye púpọ̀ ní ń ṣe ìwà ìkà púpọ̀ pẹ̀lú, ṣùgbọ́n èyí tí ó kórìíra ojúkòkòrò yóò mú ọjọ́ rẹ̀ pẹ́.
무지한 치리자는 포학을 크게 행하거니와 탐욕을 미워하는 자는 장수하리라
17 Ẹni tí ọkàn rẹ̀ kò balẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ìpànìyàn yóò máa joró rẹ̀ títí ikú má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ràn án lọ́wọ́.
사람의 피를 흘린 자는 함정으로 달려갈 것이니 그를 막지 말지니라
18 Ẹni tí ń rìn déédéé ní yóò là, ṣùgbọ́n ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ àyídáyidà ni yóò ṣubú lójijì.
성실히 행하는 자는 구원을 얻을 것이나 사곡히 행하는 자는 곧 넘어지리라
19 Ẹni tí ó bá ro ilẹ̀ rẹ̀ yóò ní oúnjẹ lọ́pọ̀lọ́pọ̀ ṣùgbọ́n ẹni tí ń lé ohun asán yóò kún fún òsì.
자기의 토지를 경작하는 자는 먹을 것이 많으려니와 방탕을 좇는 자는 궁핍함이 많으리라
20 Olóòtítọ́ ènìyàn yóò rí ìbùkún gbà gan an ṣùgbọ́n ẹni tí ojú ń kán láti di ọlọ́rọ̀ kì yóò lọ láìjìyà.
충성된 자는 복이 많아도 속히 부하고자 하는 자는 형벌을 면치 못하리라
21 Ojúsàájú ṣíṣe kò dára, síbẹ̀ ènìyàn kan ń ṣẹ̀ nítorí òkèlè oúnjẹ kan.
사람의 낯을 보아주는 것이 좋지 못하고 한 조각 떡을 인하여 범법하는 것도 그러하니라
22 Ahun ń sáré àti là kò sì funra pé òsì dúró de òun.
악한 눈이 있는 자는 재물을 얻기에만 급하고 빈궁이 자기에게로 임할 줄은 알지 못하느니라
23 Ẹni tí ó bá ènìyàn kan wí yóò rí ojúrere ni nígbẹ̀yìn ju ẹni tí ó ní ètè ẹ̀tàn lọ.
사람을 경책하는 자는 혀로 아첨하는 자보다 나중에 더욱 사랑을 받느니라
24 Ẹni tí ó ja baba tàbí ìyá rẹ̀ lólè tí ó sì wí pé, “Kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀,” irú kan ni òun àti ẹni tí ń pa ni run.
부모의 물건을 도적질하고 죄가 아니라 하는 자는 멸망케 하는 자의 동류니라
25 Ọ̀kánjúwà ènìyàn a máa dá ìjà sílẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé Olúwa yóò gbilẹ̀.
마음이 탐하는 자는 다툼을 일으키나 여호와를 의지하는 자는 풍족하게 되느니라
26 Ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀lé ara rẹ̀ jẹ́ aláìgbọ́n ṣùgbọ́n ẹni tí ń rìn nínú ọgbọ́n wà láìléwu.
자기의 마음을 믿는 자는 미련한 자요 지혜롭게 행하는 자는 구원을 얻을 자니라
27 Ẹni tí ó ń fi fún tálákà kì yóò ṣe aláìní ohunkóhun, ṣùgbọ́n ẹni tí ó di ojú rẹ̀ sí wọn gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ègún.
가난한 자를 구제하는 자는 궁핍하지 아니 하려니와 못본체 하는 자에게는 저주가 많으리라
28 Nígbà tí ènìyàn búburú bá dórí ìjọba, àwọn ènìyàn a na pápá bora; ṣùgbọ́n nígbà tí ènìyàn búburú bá ṣègbé, àwọn olódodo ń gbilẹ̀ sí i.
악인이 일어나면 사람이 숨고 그가 멸망하면 의인이 많아지느니라

< Proverbs 28 >