< Proverbs 26 >
1 Bí òjò-dídì tàbí òjò ní ìgbà ìkórè ọlá kò yẹ aláìgbọ́n ènìyàn.
As snow in summer, and as rain in harvest, so honor is not seemly for a fool.
2 Bí ológoṣẹ́ tí ń ṣí kiri tàbí alápáǹdẹ̀dẹ̀ tí ń rábàbà èpè kò le è mọ́ ẹni tí kò ṣiṣẹ́ èpè èpè kì í jani bí a kò bá ṣiṣẹ́ èpè.
As the sparrow in her wandering, as the swallow in her flying, so the curse that is causeless does not alight.
3 Ẹgba fún ẹṣin, ìjánu fún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti pàṣán fún ẹ̀yìn aṣiwèrè.
A whip for the horse, a bridle for the donkey, and a rod for the back of fools.
4 Má ṣe dá aláìgbọ́n lóhùn gẹ́gẹ́ bí ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ pẹ̀lú yóò dàbí i rẹ̀.
Answer not a fool according to his folly, lest thou also be like to him.
5 Dá aláìgbọ́n lóhùn gẹ́gẹ́ bí ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ àìṣe bẹ́ẹ̀ yóò dàbí ọlọ́gbọ́n lójú ara rẹ̀.
Answer a fool according to his folly, lest he be wise in his own conceit.
6 Bí ìgbà tí ènìyàn gé ẹsẹ̀ ara rẹ̀ tàbí mú ìwà ipá ni kí a ránṣẹ́ nípasẹ̀ aṣiwèrè.
He who sends a message by the hand of a fool cuts off the feet, and drinks injury.
7 Bí ẹsẹ̀ arọ tí ó ń mi dirodiro ni òwe lẹ́nu aṣiwèrè.
The legs of a lame man hang loose. So is a proverb in the mouth of fools.
8 Bí ìgbà tí a so òkúta mọ́ okùn títa ni fífún aláìgbọ́n ní ọlá.
As he who binds a stone in a sling, so is he who gives honor to a fool.
9 Bí ẹ̀gún èṣùṣú lọ́wọ́ ọ̀mùtí ni òwe lẹ́nu aláìgbọ́n.
As a thorn that goes up into the hand of a drunkard, so is a proverb in the mouth of fools.
10 Bí tafàtafà ti ń ṣe ni léṣe lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan ni ẹni tí ó gba aṣiwèrè ṣíṣẹ́ tàbí ẹni tí ń kọjá lọ.
As an archer who wounds all, so is he who hires a fool, and he who hires those who pass by.
11 Bí ajá ti í padà sí èébì rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni aṣiwèrè tún ń hu ìwà òmùgọ̀ rẹ̀.
As a dog who returns to his vomit, is a fool who repeats his folly.
12 Ǹjẹ́ o rí ènìyàn tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní ojú ara rẹ̀? Ìrètí ń bẹ fún aláìgbọ́n ènìyàn jù ú lọ.
See thou a man wise in his own conceit? There is more hope for a fool than of him.
13 Ọ̀lẹ wí pé, “Kìnnìún wà lójú ọ̀nà kìnnìún búburú ń ké ní ojú ọ̀nà.”
The sluggard says, There is a lion in the way; a lion is in the streets.
14 Bí ìlẹ̀kùn ti ń yí lórí ìsolẹ̀kùn rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀lẹ ń yí lórí ibùsùn rẹ̀.
The door turns upon its hinges, so does the sluggard upon his bed.
15 Ọ̀lẹ ki ọwọ́ rẹ̀ bọ inú àwo oúnjẹ, ó lẹ dé bi pé kò le è mú u padà wá sí ẹnu rẹ̀.
The sluggard buries his hand in the dish. It wearies him to bring it again to his mouth.
16 Ọ̀lẹ gbọ́n ní ojú ara rẹ̀, ju ènìyàn méje tí wọ́n le è fún un ní ìdáhùn ọlọ́gbọ́n.
The sluggard is wiser in his own conceit than seven men who can render a reason.
17 Bí ènìyàn tí ó di ajá ní etí mú ni ẹni tí ń kọjá lọ tí ó dá sí ọ̀rọ̀ ìjà tí kì í ṣe tirẹ̀.
He who passes by, and meddles with strife not his, is like he who takes a dog by the ears.
18 Bí i asínwín ti ń ju ọfà àti ọfà tí ń ṣe kú pa ni
As a madman who casts firebrands, arrows, and death,
19 ni ènìyàn tí ń tan aládùúgbò rẹ̀ jẹ tí ó sì wí pé, “Àwàdà lásán ni mo ń ṣe.”
so is the man who deceives his neighbor, and says, Am I not in sport?
20 Láìsí igi, iná yóò kú láìsí ọ̀rọ̀ ẹ̀yìn, ìjà máa ń parí.
For lack of wood the fire goes out, and where there is no whisperer, contention ceases.
21 Bí èédú ti rí sí ẹyin iná, igi fún iná, bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn oníjà fún ìjà dídá sílẹ̀.
As coals are to hot embers, and wood to fire, so is a contentious man to inflame strife.
22 Ọ̀rọ̀ ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ẹ̀yìn dàbí àṣàyàn òkèlè wọ́n a sì wọ ìsàlẹ̀ inú lọ.
The words of a whisperer are as dainty morsels, and they go down into the innermost parts.
23 Ètè jíjóni, àti àyà búburú, dà bí ìdàrọ́ fàdákà tí a fi bo ìkòkò.
Fervent lips and a wicked heart are an earthen vessel overlaid with silver dross.
24 Ènìyàn tí ó kórìíra máa ń fi ètè rẹ̀ bo àṣírí ara rẹ̀ ṣùgbọ́n nínú ọkàn rẹ̀ ni ìtànjẹ wà.
He who hates masquerades with his lips, but he lays up deceit within him.
25 Bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tilẹ̀ fanimọ́ra, má ṣe gbà á gbọ́ nítorí ìríra méje ni ó kún inú ọkàn rẹ̀.
When he speaks graciously, believe him not, for there are seven abominations in his heart.
26 Ìkórìíra rẹ le è fi ara sin nípa ẹ̀tàn ṣùgbọ́n àṣírí ìwà búburú rẹ̀ yóò tú ní gbangba.
Though his hatred cover itself with guile, his wickedness shall be openly shown before the assembly.
27 Bí ènìyàn kan bá gbẹ́ kòtò, yóò ṣubú sínú rẹ̀. Bí ẹnìkan bá ju òkúta, yóò padà sọ́dọ̀ òun tìkára rẹ̀.
He who digs a pit shall fall in it, and he who rolls a stone, it shall return upon him.
28 Ahọ́n ẹ̀tàn máa ń kórìíra àwọn tí ó ṣe ní ìkà, ẹnu ìtànjẹ sì máa ń pa ni run.
A lying tongue hates those whom it has wounded, and a flattering mouth works ruin.