< Proverbs 25 >

1 Wọ̀nyí ni àwọn òwe mìíràn tí Solomoni pa, tí àwọn ọkùnrin Hesekiah ọba Juda dà kọ.
גם אלה משלי שלמה אשר העתיקו אנשי חזקיה מלך יהודה׃
2 Ògo Ọlọ́run ní láti fi ọ̀rọ̀ kan pamọ́; láti rí ìdí ọ̀rọ̀ kan ni ògo àwọn ọba.
כבד אלהים הסתר דבר וכבד מלכים חקר דבר׃
3 Bí ọ̀run ṣe ga tó tí ayé sì jì bẹ́ẹ̀ ni ó ṣòro láti mọ èrò ọkàn ọba.
שמים לרום וארץ לעמק ולב מלכים אין חקר׃
4 Mú ìdàrọ́ kúrò lára fàdákà ohun èlò yóò sì jáde fún alágbẹ̀dẹ fàdákà.
הגו סיגים מכסף ויצא לצרף כלי׃
5 Mú ènìyàn búburú kúrò níwájú ọba a ó sì fìdí ìtẹ́ rẹ múlẹ̀ nípasẹ̀ òdodo.
הגו רשע לפני מלך ויכון בצדק כסאו׃
6 Má ṣe gbé ara rẹ ga níwájú ọba, má sì ṣe jìjàdù ààyè láàrín àwọn ènìyàn pàtàkì,
אל תתהדר לפני מלך ובמקום גדלים אל תעמד׃
7 ó sàn kí ó wí fún ọ pé, “Gòkè wá síyìn-ín,” ju wí pé kí ó dójútì ọ́ níwájú ènìyàn pàtàkì.
כי טוב אמר לך עלה הנה מהשפילך לפני נדיב אשר ראו עיניך׃
8 Ohun tí o ti fi ojú ara rẹ rí má ṣe kánjú gbé e lọ sílé ẹjọ́ nítorí kí ni ìwọ yóò ṣe ní ìgbẹ̀yìn bí aládùúgbò rẹ bá dójútì ọ́?
אל תצא לרב מהר פן מה תעשה באחריתה בהכלים אתך רעך׃
9 Bí o bá ń ṣe àwíjàre rẹ níwájú aládùúgbò rẹ, má ṣe tú àṣírí tí ẹlòmíràn ní lọ́dọ̀ rẹ,
ריבך ריב את רעך וסוד אחר אל תגל׃
10 àìṣe bẹ́ẹ̀ ẹni tí ó gbọ́ ọ le dójútì ọ́ orúkọ búburú tí ìwọ bá sì gba kì yóò tán láéláé.
פן יחסדך שמע ודבתך לא תשוב׃
11 Ọ̀rọ̀ tí a sọ ní àkókò tí ó yẹ ó dàbí èso wúrà nínú àpẹẹrẹ fàdákà.
תפוחי זהב במשכיות כסף דבר דבר על אפניו׃
12 Bí i yẹtí wúrà tàbí ohun ọ̀ṣọ́ ti wúrà dáradára ni ìbáwí ọlọ́gbọ́n fún etí tí ó bá fetísílẹ̀.
נזם זהב וחלי כתם מוכיח חכם על אזן שמעת׃
13 Bí títutù òjò yìnyín ní àsìkò ìkórè ni ìránṣẹ́ tí ó jẹ́ olóòtítọ́ sí àwọn tí ó rán an ó ń tu ọ̀gá rẹ̀ nínú.
כצנת שלג ביום קציר ציר נאמן לשלחיו ונפש אדניו ישיב׃
14 Bí ojú ṣíṣú àti afẹ́fẹ́ láìsí òjò ni ènìyàn tí ń yangàn nípa ẹ̀bùn tí kò fún ni.
נשיאים ורוח וגשם אין איש מתהלל במתת שקר׃
15 Nípa sùúrù a lè yí ọba lọ́kàn padà ahọ́n tí ń sọ̀rọ̀ rírọ̀ sí egungun.
בארך אפים יפתה קצין ולשון רכה תשבר גרם׃
16 Bí ìwọ bá rí oyin, jẹ ẹ́ ní ìwọ̀nba bí o bá jẹ ẹ́ jù, ìwọ yóò sì bì í.
דבש מצאת אכל דיך פן תשבענו והקאתו׃
17 Má ṣe máa lọ sí ilé aládùúgbò rẹ nígbà gbogbo tàbí kí ó máa lọ síbẹ̀ lálọ jù, yóò sì kórìíra rẹ.
הקר רגלך מבית רעך פן ישבעך ושנאך׃
18 Bí ọ̀pá, idà tàbí ọ̀kọ̀ tí ó mú ni ènìyàn tí ó jẹ́rìí èké lòdì sí aládùúgbò rẹ̀.
מפיץ וחרב וחץ שנון איש ענה ברעהו עד שקר׃
19 Bí eyín tí ó bàjẹ́ tàbí ẹsẹ̀ tí ó rọ ni ìgbẹ́kẹ̀lé lórí aláìṣòótọ́ ní àsìkò ìdààmú.
שן רעה ורגל מועדת מבטח בוגד ביום צרה׃
20 Bí ẹni tí ó bọ́ra kalẹ̀ ní ọjọ́ tí òtútù mú, tàbí, bí ọtí kíkan tí a dà sí ojú ọgbẹ́, ní ẹni tí ń kọ orin fún ẹni tí ọkàn rẹ̀ bàjẹ́.
מעדה בגד ביום קרה חמץ על נתר ושר בשרים על לב רע׃
21 Bí ebi bá ń pa ọ̀tá rẹ, fún un ní oúnjẹ jẹ; bí òǹgbẹ bá ń gbẹ ẹ́, fún un ní omi mú.
אם רעב שנאך האכלהו לחם ואם צמא השקהו מים׃
22 Nípa ṣíṣe báyìí, ìwọ yóò wa ẹ̀yín iná lé e lórí Olúwa yóò sì san ọ ní ẹ̀san rẹ̀ fún ọ.
כי גחלים אתה חתה על ראשו ויהוה ישלם לך׃
23 Bí afẹ́fẹ́ gúúsù ti í mú òjò wá, bí ahọ́n tí ń sọ̀rọ̀ ẹ̀yìn ṣe ń mú ojú ìbínú wá.
רוח צפון תחולל גשם ופנים נזעמים לשון סתר׃
24 Ó sàn láti gbé ní ibi igun kan lórí òrùlé ju láti bá aya oníjà gbé ilé pọ̀.
טוב שבת על פנת גג מאשת מדונים ובית חבר׃
25 Bí omi tútù sí ọkàn tí ń ṣe àárẹ̀ ni ìròyìn ayọ̀ láti ọ̀nà jíjìn.
מים קרים על נפש עיפה ושמועה טובה מארץ מרחק׃
26 Bí ìsun tí ó di àbàtà tàbí kànga tí omi rẹ̀ bàjẹ́ ni olódodo tí ó fi ààyè gba ènìyàn búburú.
מעין נרפש ומקור משחת צדיק מט לפני רשע׃
27 Kò dára láti jẹ oyin àjẹjù, bẹ́ẹ̀ ni kò pọ́n ni lé láti máa wá ọlá fún ara ẹni.
אכל דבש הרבות לא טוב וחקר כבדם כבוד׃
28 Bí ìlú tí odi rẹ̀ ti wó lulẹ̀ ni ènìyàn tí kò le kó ara rẹ̀ ní ìjánu.
עיר פרוצה אין חומה איש אשר אין מעצר לרוחו׃

< Proverbs 25 >