< Proverbs 24 >
1 Má ṣe ṣe ìlara àwọn ènìyàn búburú má ṣe jẹ́ kí àwùjọ wọn wù ọ́;
2 nítorí ọkàn wọn ń gbèrò ohun búburú, ètè wọn sì ń sọ̀rọ̀ nípa dídá rúgúdù sílẹ̀.
3 Nípa ọgbọ́n ni ilé di kíkọ́ nípa òye sì ni ó ti fìdímúlẹ̀;
4 nípa ìmọ̀ ni àwọn yàrá rẹ̀ kún pẹ̀lú àwọn ohun ọ̀ṣọ́ tí ó lẹ́wà tí ó sì ṣọ̀wọ́n.
5 Ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní agbára púpọ̀, ènìyàn tí ó ní ìmọ̀ sì ń ní agbára sí i.
6 Láti jagun, ó nílò ìtọ́sọ́nà: nínú ìṣẹ́gun ni ọ̀pọ̀ onígbìmọ̀.
7 Ọgbọ́n ga ju fún aṣiwèrè àti gbọ̀ngàn ìlú níbi ibodè kò ní ohun tí yóò wí.
8 Ẹni tí ń pète ibi ni a ó mọ̀ bí ènìyàn ibi.
9 Ète òmùgọ̀ ènìyàn jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, àwọn ènìyàn sì kórìíra ẹlẹ́gàn.
10 Bí ìwọ bá dákú lásìkò ìdààmú báwo ni agbára rẹ ha ti kéré tó!
11 Gba àwọn tí a ń wọ́ lọ sí ibi ikú là; fa àwọn tó ń ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n lọ sí ibi ìparun padà.
12 Bí ìwọ bá wí pé, “Ṣùgbọ́n a kò mọ nǹkan kan nípa èyí,” ǹjẹ́ ẹni tí ń díwọ̀n ọkàn kò kíyèsi i? Ǹjẹ́ ẹni tí ń ṣọ́ ẹ̀mí rẹ kò mọ̀ ọ́n? Ǹjẹ́ kò ní san án fún ẹnìkọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó ti ṣe?
13 Jẹ oyin, ìwọ ọmọ mi, nítorí tí ó dára, oyin láti inú afárá oyin dùn lẹ́nu.
14 Mọ̀ pẹ̀lú pé ọgbọ́n pẹ̀lú dùn fún ọkàn rẹ bí ìwọ bá rí i ìrètí ọjọ́ iwájú wà fún ọ ìrètí rẹ kì yóò sì já ṣófo.
15 Má ṣe ba ní ibùba bí ènìyàn búburú láti gba ibùjókòó olódodo, má ṣe fi ibi ìsinmi rẹ̀ ṣe ìjẹ;
16 nítorí bí olódodo ènìyàn bá tilẹ̀ ṣubú ní ìgbà méje, yóò tún padà dìde sá á ni, ṣùgbọ́n ìdààmú yóò fa ènìyàn búburú lulẹ̀.
17 Má ṣe yọ̀ nígbà tí ọ̀tá rẹ bá ṣubú; nígbà tí ó bá kọsẹ̀, má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ kí ó yọ̀.
18 Àìṣe bẹ́ẹ̀ Olúwa yóò rí i yóò sì bínú yóò sì yí ìbínú rẹ̀ padà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.
19 Má ṣe fòyà nítorí àwọn ènìyàn ibi tàbí jowú àwọn ènìyàn búburú,
20 nítorí ẹni ibi kò ní ìrètí ọjọ́ iwájú a ó sì pa fìtílà àwọn ènìyàn búburú kú.
21 Bẹ̀rù Olúwa àti ọba, ọmọ mi, má sì ṣe darapọ̀ pẹ̀lú àwọn olórí kunkun.
22 Nítorí àwọn méjèèjì yóò rán ìparun òjijì sórí wọn, ta ni ó sì mọ irú ìyọnu tí wọ́n lè mú wá?
23 Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú tún jẹ́ ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n: láti ṣe ojúsàájú níbi ìdájọ́ kò dára rárá.
24 Ẹnikẹ́ni tí ó wí fún ẹlẹ́bi pé, “Ìwọ lo jàre,” àwọn ènìyàn yóò ṣẹ́ èpè fún un àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì kọ̀ ọ́.
25 Ṣùgbọ́n yóò dára fún àwọn tí ń dá ẹlẹ́bi lẹ́bi, ọ̀pọ̀ ìbùkún yóò sì wá sórí wọn.
26 Ìdáhùn òtítọ́ dàbí ìfẹnukoni ní ẹnu.
27 Parí gbogbo iṣẹ́ ajé rẹ sì rí i pé oko rẹ ti ṣe dáradára; lẹ́yìn náà kọ́ ilé rẹ.
28 Má ṣe rojọ́ èké mọ́ aládùúgbò rẹ láìnídìí, tàbí kí o fi ètè rẹ tannijẹ.
29 Má ṣe wí pé, “Èmi yóò ṣe é fún un gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe fún mi; Èmi yóò san ohun tí ó ṣe fún mi padà fún un.”
30 Mo kọjá níbi oko ọ̀lẹ, mo kọjá níbi ọgbà àjàrà aláìgbọ́n ènìyàn;
31 ẹ̀gún ti hù ní ibi gbogbo, koríko ti gba gbogbo oko náà.
32 Mo fi ọkàn mi sí nǹkan tí mo kíyèsi mo sì kẹ́kọ̀ọ́ lára ohun tí mo rí;
33 oorun díẹ̀, òògbé díẹ̀, ìkáwọ́gbera díẹ̀ láti sinmi,
34 òsì yóò sì dé bá ọ bí adigunjalè àti àìní bí olè.