< Proverbs 22 >

1 Yíyan orúkọ rere sàn ju púpọ̀ ọrọ̀ lọ, àti ojúrere dára ju fàdákà àti wúrà lọ.
נבחר שם מעשר רב מכסף ומזהב חן טוב
2 Ọlọ́rọ̀ àti tálákà péjọpọ̀: Olúwa ni ẹlẹ́dàá gbogbo wọn.
עשיר ורש נפגשו עשה כלם יהוה
3 Ọlọ́gbọ́n ènìyàn ti rí ibi tẹ́lẹ̀, ó ṣé ara rẹ̀ mọ́: ṣùgbọ́n àwọn òpè tẹ̀síwájú, a sì jẹ wọ́n ní yà.
ערום ראה רעה ויסתר (ונסתר) ופתיים עברו ונענשו
4 Èrè ìrẹ̀lẹ̀ àti ìbẹ̀rù Olúwa ni ọrọ̀ ọlá, àti ìyè.
עקב ענוה יראת יהוה עשר וכבוד וחיים
5 Ègún àti ìdẹ̀kùn ń bẹ ní ọ̀nà aláyídáyidà: ẹni tí ó bá pa ọkàn rẹ̀ mọ́ yóò jìnnà sí wọn.
צנים פחים בדרך עקש שומר נפשו ירחק מהם
6 Tọ́ ọmọdé ní ọ̀nà tí yóò tọ̀: nígbà tí ó bá dàgbà, kì yóò kúrò nínú rẹ̀.
חנך לנער על-פי דרכו-- גם כי-יזקין לא-יסור ממנה
7 Ọlọ́rọ̀ ṣe olórí olùpọ́njú, ajigbèsè sì ṣe ìránṣẹ́ fún ẹni tí a jẹ ní gbèsè.
עשיר ברשים ימשול ועבד לוה לאיש מלוה
8 Ẹni tí ó bá fúnrúgbìn ẹ̀ṣẹ̀, yóò ká asán: ọ̀pá ìbínú rẹ̀ yóò kùnà.
זורע עולה יקצור- (יקצר-) און ושבט עברתו יכלה
9 Ẹni tí ó ní ojú àánú ni a ó bùkún fún; nítorí tí ó fi nínú oúnjẹ rẹ̀ fún olùpọ́njú.
טוב-עין הוא יברך כי-נתן מלחמו לדל
10 Lé ẹlẹ́gàn sí ìta, ìjà yóò sì jáde; nítòótọ́ ìjà àti ẹ̀gàn yóò dẹ́kun.
גרש לץ ויצא מדון וישבת דין וקלון
11 Ẹni tí ó fẹ́ ìwà funfun ti àyà, tí ó sì ń sọ̀rọ̀ iyì jáde, ọba yóò ṣe ọ̀rẹ́ rẹ̀.
אהב טהור- (טהר-) לב-- חן שפתיו רעהו מלך
12 Ojú Olúwa pa ìmọ̀ mọ́, ó sì yí ọ̀rọ̀ olùrékọjá pò.
עיני יהוה נצרו דעת ויסלף דברי בגד
13 Ọ̀lẹ wí pé, “Kìnnìún ń bẹ lóde! Yóò pa mí ní ìgboro!”
אמר עצל ארי בחוץ בתוך רחבות ארצח
14 Ẹnu àwọn àjèjì obìnrin, ihò jíjìn ni; ẹni tí a ń bínú sí láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá ni yóò ṣubú sínú rẹ̀.
שוחה עמקה פי זרות זעום יהוה יפול- (יפל-) שם
15 Àyà ọmọdé ni ìwà wèrè dì sí; ṣùgbọ́n pàṣán ìtọ́ni ni yóò lé e jìnnà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.
אולת קשורה בלב-נער שבט מוסר ירחיקנה ממנו
16 Ẹni tó ń ni tálákà lára láti ní ọrọ̀, tí ó sì ń ta ọlọ́rọ̀ lọ́rẹ, yóò di aláìní bí ó ti wù kó rí. Gbọ́ ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n ènìyàn.
עשק דל להרבות לו-- נתן לעשיר אך-למחסור
17 Dẹtí rẹ sílẹ̀, kí o gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n, kí o sì fi àyà rẹ sí ẹ̀kọ́ mi.
הט אזנך--ושמע דברי חכמים ולבך תשית לדעתי
18 Nítorí ohun dídùn ni bí ìwọ bá pa wọ́n mọ́ ní inú rẹ; nígbà tí a sì pèsè wọn tán ní ètè rẹ.
כי-נעים כי-תשמרם בבטנך יכנו יחדו על-שפתיך
19 Kí ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ lè wà ní ti Olúwa, èmi fihàn ọ́ lónìí, àní fún ọ.
להיות ביהוה מבטחך-- הודעתיך היום אף-אתה
20 Èmi kò ha ti kọ̀wé ohun dáradára sí ọ ní ti ìmọ̀ràn àti ní ti ẹ̀kọ́,
הלא כתבתי לך שלשום (שלשים)-- במעצות ודעת
21 kí ó lè mú ọ mọ ìdájú ọ̀rọ̀ òtítọ́; kí ìwọ le máa fi ìdáhùn òtítọ́ fún àwọn tí ó rán ọ?
להודיעך--קשט אמרי אמת להשיב אמרים אמת לשלחיך
22 Má ṣe ja tálákà ní olè, nítorí tí ó jẹ́ tálákà: bẹ́ẹ̀ ni kí o má sì ṣe ni olùpọ́njú lára ní ibodè,
אל-תגזל-דל כי דל-הוא ואל-תדכא עני בשער
23 nítorí Olúwa yóò gbèjà wọn, yóò sì gba ọkàn àwọn tí ń gba tiwọn náà.
כי-יהוה יריב ריבם וקבע את-קבעיהם נפש
24 Má ṣe bá oníbìínú ènìyàn ṣe ọ̀rẹ́; má sì ṣe bá ọkùnrin onínú-fùfù rìn.
אל-תתרע את-בעל אף ואת-איש חמות לא תבוא
25 Kí ìwọ má ba à kọ́ ìwà rẹ̀, ìwọ a sì gba ìkẹ́kùn fún ara rẹ.
פן-תאלף ארחתו ולקחת מוקש לנפשך
26 Má ṣe wà nínú àwọn tí ń ṣe ìgbọ̀nwọ́, tàbí nínú àwọn tí ó dúró fún gbèsè.
אל-תהי בתקעי-כף בערבים משאות
27 Bí ìwọ kò bá ní nǹkan tí ìwọ ó fi san, nítorí kín ni yóò ṣe gba ẹni rẹ kúrò lábẹ́ rẹ?
אם-אין-לך לשלם-- למה יקח משכבך מתחתיך
28 Má ṣe yẹ ààlà ilẹ̀ ìgbàanì, tí àwọn baba rẹ ti pa.
אל-תסג גבול עולם-- אשר עשו אבותיך
29 Ìwọ ha rí ènìyàn tí ó ń fi àìṣe ìmẹ́lẹ́ ṣe iṣẹ́ rẹ̀? Òun yóò dúró níwájú àwọn ọba; òun kì yóò dúró níwájú àwọn ènìyàn lásán.
חזית איש מהיר במלאכתו-- לפני-מלכים יתיצב בל-יתיצב לפני חשכים

< Proverbs 22 >