< Proverbs 21 >
1 Ọkàn ọba ń bẹ lọ́wọ́ Olúwa; a máa darí rẹ̀ lọ ibi tí ó fẹ́ bí ipa omi.
The king’s heart is in the hand of the LORD, as the rivers of water: he turns it wherever he will.
2 Gbogbo ọ̀nà ènìyàn dàbí i pé ó dára lójú rẹ̀, ṣùgbọ́n, Olúwa ló ń díwọ̀n ọkàn.
Every way of a man is right in his own eyes: but the LORD ponders the hearts.
3 Ṣíṣe ohun tí ó dára tí ó sì tọ̀nà ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà sí Olúwa ju ẹbọ lọ.
To do justice and judgment is more acceptable to the LORD than sacrifice.
4 Ojú tí ó gbéga àti ọkàn ìgbéraga, ìmọ́lẹ̀ àwọn ènìyàn búburú, ẹ̀ṣẹ̀ ni!
An high look, and a proud heart, and the plowing of the wicked, is sin.
5 Ètè àwọn olóye jásí èrè bí ìkánjú ṣe máa ń fa òsì kíákíá.
The thoughts of the diligent tend only to plenty; but of every one that is hasty only to want.
6 Ìṣúra tí a kójọ nípasẹ̀ ahọ́n tí ń parọ́ jẹ́ ìrì lásán àti ìkẹ́kùn ikú.
The getting of treasures by a lying tongue is a vanity tossed to and fro of them that seek death.
7 Ìwà ipá àwọn ènìyàn búburú yóò wọ́ wọn lọ, nítorí wọ́n kọ̀ láti ṣe ohun tí ó tọ́.
The robbery of the wicked shall destroy them; because they refuse to do judgment.
8 Ọ̀nà ẹlẹ́ṣẹ̀ kún fún ìwà ẹ̀ṣẹ̀ ṣùgbọ́n iṣẹ́ onínú funfun jẹ́ títọ́.
The way of man is fraudulent and strange: but as for the pure, his work is right.
9 Ó sàn láti máa gbé ní kọ̀rọ̀ orí òrùlé ju láti ṣe àjọpín ilé pẹ̀lú aya oníjà.
It is better to dwell in a corner of the housetop, than with a brawling woman in a wide house.
10 Ènìyàn búburú ń fẹ́ ibi aládùúgbò rẹ̀ kì í rí àánú kankan gbà lọ́dọ̀ rẹ̀.
The soul of the wicked desires evil: his neighbor finds no favor in his eyes.
11 Nígbà tí a bá ń fìyà jẹ ẹlẹ́gàn, òpè a máa kọ́gbọ́n, nígbà tí a bá sì kọ́ ọlọ́gbọ́n yóò ní ìmọ̀.
When the scorner is punished, the simple is made wise: and when the wise is instructed, he receives knowledge.
12 Olódodo ṣàkíyèsí ilé ènìyàn búburú ó sì mú ènìyàn búburú wá sí ìparun.
The righteous man wisely considers the house of the wicked: but God overthrows the wicked for their wickedness.
13 Ẹnikẹ́ni tí ó bá ti di etí rẹ̀ sí igbe olùpọ́njú, òun tìkára rẹ̀ yóò ké pẹ̀lú; ṣùgbọ́n a kì yóò gbọ́.
Whoever stops his ears at the cry of the poor, he also shall cry himself, but shall not be heard.
14 Ọ̀rẹ́ ìkọ̀kọ̀, mú ìbínú kúrò: àti owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti ibi ìkọ̀kọ̀ wá, dẹ́kun ìbínú líle.
A gift in secret pacifies anger: and a reward in the bosom strong wrath.
15 Ayọ̀ ni fún olódodo láti ṣe ìdájọ́: ṣùgbọ́n ìparun ni fún àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.
It is joy to the just to do judgment: but destruction shall be to the workers of iniquity.
16 Ẹni tí ó bá yà kúrò ní ọ̀nà òye, yóò máa gbé inú ìjọ àwọn òkú.
The man that wanders out of the way of understanding shall remain in the congregation of the dead.
17 Ẹni tí ó bá fẹ́ afẹ́, yóò di tálákà: ẹni tí ó fẹ́ ọtí wáìnì pẹ̀lú òróró kò le lọ́rọ̀.
He that loves pleasure shall be a poor man: he that loves wine and oil shall not be rich.
18 Ènìyàn búburú ni yóò ṣe owó ìràpadà fún olódodo, àti olùrékọjá fún ẹni dídúró ṣinṣin.
The wicked shall be a ransom for the righteous, and the transgressor for the upright.
19 Ó sàn láti jókòó ní aginjù ju pẹ̀lú oníjà obìnrin àti òṣónú lọ.
It is better to dwell in the wilderness, than with a contentious and an angry woman.
20 Ìṣúra iyebíye àti òróró wà ní ibùgbé ọlọ́gbọ́n; ṣùgbọ́n òmùgọ̀ ènìyàn n bà á jẹ́.
There is treasure to be desired and oil in the dwelling of the wise; but a foolish man spends it up.
21 Ẹni tí ó bá tẹ̀lé òdodo àti àánú yóò rí ìyè, òdodo, àti ọlá.
He that follows after righteousness and mercy finds life, righteousness, and honor.
22 Ọlọ́gbọ́n gòkè odi ìlú àwọn alágbára, ó sì bi ibi gíga agbára ìgbẹ́kẹ̀lé wọn ṣubú.
A wise man scales the city of the mighty, and casts down the strength of the confidence thereof.
23 Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ẹnu àti ahọ́n rẹ̀ mọ́, ó pa ọkàn rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ìyọnu.
Whoever keeps his mouth and his tongue keeps his soul from troubles.
24 Agbéraga àti alágídí ènìyàn ń gan orúkọ ara rẹ̀ nítorí ó ń hùwà nínú ìwà ìgbéraga rẹ̀, àti nínú ìbínú púpọ̀púpọ̀.
Proud and haughty scorner is his name, who deals in proud wrath.
25 Ẹlẹ́rìí èké yóò ṣègbé, àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ yóò parun láé; nítorí tí ọwọ́ rẹ̀ kọ iṣẹ́ ṣíṣe.
The desire of the slothful kills him; for his hands refuse to labor.
26 Ó ń fi ìlara ṣe ojúkòkòrò ní gbogbo ọjọ́: ṣùgbọ́n olódodo a máa fi fún ni kì í sì í dáwọ́ dúró.
He covets greedily all the day long: but the righteous gives and spares not.
27 Ẹbọ ènìyàn búburú, ìríra ni: mélòó mélòó ni nígbà tí ó mú un wá pẹ̀lú èrò ìwà ibi?
The sacrifice of the wicked is abomination: how much more, when he brings it with a wicked mind?
28 Ẹlẹ́rìí èké yóò ṣègbé: ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ẹni tí ó gbọ́, yóò dúró.
A false witness shall perish: but the man that hears speaks constantly.
29 Ènìyàn búburú mú ojú ara rẹ̀ le: ṣùgbọ́n ẹni ìdúró ṣinṣin ni ó ń mú ọ̀nà rẹ̀ tọ́.
A wicked man hardens his face: but as for the upright, he directs his way.
30 Kò sí ọgbọ́n, kò sí ìmòye, tàbí ìmọ̀ràn tí ó le mókè níwájú Olúwa.
There is no wisdom nor understanding nor counsel against the LORD.
31 A ń múra ẹṣin sílẹ̀ de ọjọ́ ogun: ṣùgbọ́n ìṣẹ́gun jẹ́ ti Olúwa.
The horse is prepared against the day of battle: but safety is of the LORD.