< Proverbs 20 >
1 Ẹlẹ́yà ni ọtí wáìnì, aláriwo sì ní ọtí líle; ẹnikẹ́ni tí ó bá fi tànjẹ kò gbọ́n.
luxuriosa res vinum et tumultuosa ebrietas quicumque his delectatur non erit sapiens
2 Ìbẹ̀rù ọba dàbí kíké e kìnnìún; ẹnikẹ́ni tí ó bá mú un bínú ba ayé ara rẹ̀ jẹ́.
sicut rugitus leonis ita terror regis qui provocat eum peccat in animam suam
3 Iyì ni ó jẹ́ fún ènìyàn láti sá fún ìjà, ṣùgbọ́n gbogbo aláìgbọ́n a máa tètè wá ìjà.
honor est homini qui separat se a contentionibus omnes autem stulti miscentur contumeliis
4 Ọ̀lẹ kì í ṣiṣẹ́ oko nígbà tí ó yẹ, nítorí náà ní àsìkò ìkórè, yóò wá kò sì ní rì nǹkan.
propter frigus piger arare noluit mendicabit ergo aestate et non dabitur ei
5 Ète ọkàn ènìyàn dàbí omi jíjìn; ṣùgbọ́n ènìyàn olóye á wá wọn jáde.
sicut aqua profunda sic consilium in corde viri sed homo sapiens exhauriet illud
6 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni wọ́n máa ń sọ pe àwọn ní ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn, ṣùgbọ́n kò rọrùn láti rí ènìyàn olóòtítọ́.
multi homines misericordes vocantur virum autem fidelem quis inveniet
7 Olódodo ènìyàn a máa gbé ìgbé ayé àìlábùkù ìbùkún ni fún àwọn ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀.
iustus qui ambulat in simplicitate sua beatos post se filios derelinquet
8 Nígbà tí ọba bá jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀ láti ṣe ìdájọ́ yóò fẹ́ gbogbo ibi dànù pẹ̀lú ojú rẹ̀.
rex qui sedet in solio iudicii dissipat omne malum intuitu suo
9 Ta ni ó le è wí pé, “Mo ti ṣe ọkàn mi ní mímọ́, mo mọ́, n kò sì lẹ́ṣẹ̀”?
quis potest dicere mundum est cor meum purus sum a peccato
10 Ìwọ̀n èké àti òsùwọ̀n ìrẹ́jẹ Olúwa kórìíra méjèèjì.
pondus et pondus mensura et mensura utrumque abominabile est apud Deum
11 Kódà a mọ ọmọdé nípa iṣẹ́ rẹ̀ nípa pe bóyá iṣẹ́ rẹ mọ́ tàbí pé ó tọ̀nà.
ex studiis suis intellegitur puer si munda et si recta sint opera eius
12 Etí tí ó ń gbọ́ àti ojú tí ó ń ríran Olúwa ni ó dá méjèèjì.
aurem audientem et oculum videntem Dominus fecit utrumque
13 Má ṣe fẹ́ràn oorun, àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ yóò di tálákà. Ma ṣe sùn ìwọ yóò sì ní oúnjẹ láti tún fi tọrọ.
noli diligere somnum ne te egestas opprimat aperi oculos tuos et saturare panibus
14 “Kò dára, kò dára!” ní ẹni tó ra ọjà máa ń wí; nígbà tí ó bá kúrò níbẹ̀ tán, yóò máa yangàn bí òun tí ṣe rí rà sí.
malum est malum est dicit omnis emptor et cum recesserit tunc gloriabitur
15 Wúrà wà, iyùn sì wà rẹpẹtẹ, ṣùgbọ́n, ahọ́n tí ń sọ ìmọ̀ gan an ni ọ̀ṣọ́ iyebíye.
est aurum et multitudo gemmarum vas autem pretiosum labia scientiae
16 Gba abọ́ ẹni tí ó ṣe onídùúró fún àlejò; mú un lọ́wọ́ bí ìbúra bí ó bá ṣe é fún obìnrin onírìnkurìn.
tolle vestimentum eius qui fideiussor extitit alieni et pro extraneis aufer pignus ab eo
17 Oúnjẹ tí a fi ọ̀nà èrú rí máa ń dùn lẹ́nu ènìyàn, ṣùgbọ́n, a yọrí sí ibi ẹnu tí ó kún fún erùpẹ̀.
suavis est homini panis mendacii et postea implebitur os eius calculo
18 Pa ètè rẹ mọ́ nípa wíwá ìmọ̀ràn bí o bá ń jagun, gba ìtọ́sọ́nà.
cogitationes consiliis roborantur et gubernaculis tractanda sunt bella
19 Olófòófó a máa tú àṣírí nítorí náà yẹra fún ènìyàn tí ń rojọ́ púpọ̀.
ei qui revelat mysteria et ambulat fraudulenter et dilatat labia sua ne commiscearis
20 Bí ènìyàn kan bá ṣépè fún baba tàbí ìyá rẹ̀, ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ni a ó pa kú nínú òkùnkùn biribiri.
qui maledicit patri suo et matri extinguetur lucerna eius in mediis tenebris
21 Ogún tí a kójọ kíákíá ní ìbẹ̀rẹ̀ kì yóò ní ìbùkún ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín.
hereditas ad quam festinatur in principio in novissimo benedictione carebit
22 Má ṣe wí pé, “N ó sẹ̀san àṣìṣe rẹ yìí fún ọ.” Dúró de Olúwa yóò sì gbà ọ́ là.
ne dicas reddam malum expecta Dominum et liberabit te
23 Olúwa kórìíra òdínwọ̀n èké. Òsùwọ̀n ìrẹ́jẹ kò sì tẹ́ ẹ lọ́rùn.
abominatio est apud Deum pondus et pondus statera dolosa non est bona
24 Olúwa ni ó ń ṣe olùdarí ìgbésẹ̀ ènìyàn. Báwo wá ni òye gbogbo ọ̀nà ènìyàn ṣe le yé ni?
a Domino diriguntur gressus viri quis autem hominum intellegere potest viam suam
25 Ìdẹ̀kùn ni fún ènìyàn láti ṣe ìlérí kíákíá nígbà tí ó bá sì yá kí ó máa ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wò.
ruina est hominis devorare sanctos et post vota tractare
26 Ọlọ́gbọ́n ọba tú ènìyàn búburú ká; Ó sì fi òòlọ ìpakà lọ̀ wọ́n.
dissipat impios rex sapiens et curvat super eos fornicem
27 Àtùpà Olúwa ń ṣe àwárí ẹ̀mí ènìyàn a máa ṣàwárí ibi ìkọ̀kọ̀ inú.
lucerna Domini spiraculum hominis quae investigat omnia secreta ventris
28 Ìfẹ́ àti òdodo pa ọba mọ́, nípa ìfẹ́, ìtẹ́ rẹ̀ wà láìléwu.
misericordia et veritas custodiunt regem et roboratur clementia thronus eius
29 Ògo àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin ni agbára wọn, ewú orí ni iyì arúgbó.
exultatio iuvenum fortitudo eorum et dignitas senum canities
30 Ìgbájú ìgbámú àti ìfarapa máa ń mú ibi lọ, pàṣán sì máa ń ṣe àfọ̀mọ́ ibi ìkọ̀kọ̀ inú.
livor vulneris absterget mala et plagae in secretioribus ventris