< Proverbs 2 >

1 Ọmọ mi, bí ìwọ bá gba ọ̀rọ̀ mi, tí ìwọ sì pa òfin mi mọ́ sí inú rẹ,
My son, if you accept my words and hide my commandments within you,
2 tí ìwọ dẹtí rẹ sílẹ̀ sí ọgbọ́n tí ìwọ sì fi ọkàn rẹ sí òye,
if you incline your ear to wisdom and direct your heart to understanding,
3 àní, bí ìwọ bá ké tọ ìmọ̀ lẹ́yìn, tí ìwọ sì gbé ohùn rẹ sókè fún òye
if you truly call out to insight and lift your voice to understanding,
4 bí ìwọ bá ṣàfẹ́rí rẹ̀ bí i fàdákà tí ìwọ sì wa kiri bí ìṣúra tí a fi pamọ́.
if you seek it like silver and search it out like hidden treasure,
5 Nígbà náà ni ìwọ yóò bẹ̀rù Olúwa, ìwọ yóò sì rí ìmọ̀ Ọlọ́run.
then you will discern the fear of the LORD and discover the knowledge of God.
6 Nítorí Olúwa ni ó ń fún ni ní ọgbọ́n, láti ẹnu rẹ̀ sì ni ìmọ̀ àti òye ti ń wá.
For the LORD gives wisdom; from His mouth come knowledge and understanding.
7 Ó to ìgbàlà fún àwọn olódodo, Òun ni asà fún àwọn tí ń rìn déédé,
He stores up sound wisdom for the upright; He is a shield to those who walk with integrity,
8 Ó pa ipa ọ̀nà ìdájọ́ mọ́ Ó sì ń pa ọ̀nà àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ mọ́.
to guard the paths of justice and protect the way of His saints.
9 Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ òdodo àti ìdájọ́, àti àìṣègbè—gbogbo ipa ọ̀nà rere.
Then you will discern righteousness and justice and equity—every good path.
10 Nítorí ọgbọ́n yóò wọ inú ọkàn rẹ ìmọ̀ yóò sì jẹ́ ìtura fún ọkàn rẹ.
For wisdom will enter your heart, and knowledge will delight your soul.
11 Ìmòye yóò pa ọ mọ́ òye yóò sì máa ṣọ́ ọ.
Discretion will watch over you, and understanding will guard you,
12 Ọgbọ́n yóò gbà ọ́ là kúrò ní ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú, lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn tí ọrọ̀ ọ wọn jẹ́ àyídáyidà,
to deliver you from the way of evil, from the man who speaks perversity,
13 ẹni tí ó kúrò ní ọ̀nà ìdúró ṣinṣin láti rìn ní ọ̀nà tí ó ṣókùnkùn,
from those who leave the straight paths to walk in the ways of darkness,
14 ẹni tí ó yọ̀ nínú ṣíṣe búburú, tí ó ṣe inú dídùn sí àyídáyidà àwọn ènìyàn ibi,
from those who enjoy doing evil and rejoice in the twistedness of evil,
15 ọ̀nà ẹni tí ó wọ́ tí wọ́n sì jẹ́ alárékérekè ní ọ̀nà wọn.
whose paths are crooked and whose ways are devious.
16 Yóò gba ìwọ pẹ̀lú là kúrò lọ́wọ́ àwọn àjèjì obìnrin, àní, lọ́wọ́ obìnrin àjèjì tí ń fi ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ tannijẹ,
It will rescue you from the forbidden woman, from the stranger with seductive words
17 ẹni tí ó ti kọ ọkọ àkọ́fẹ́ ìgbà èwe rẹ̀ sílẹ̀ tí ó sì gbàgbé májẹ̀mú tí ó ti dá níwájú Ọlọ́run rẹ̀.
who abandons the partner of her youth and forgets the covenant of her God.
18 Nítorí ilé rẹ̀ jẹ́ ọ̀nà sí ikú ipa ọ̀nà rẹ̀ sọ́dọ̀ àwọn òkú.
For her house sinks down to death, and her tracks to the departed spirits.
19 Kò sẹ́ni tó lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ tí ó padà bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í dé ọ̀nà ìyè.
None who go to her return or negotiate the paths of life.
20 Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ yóò rìn ní ọ̀nà àwọn ènìyàn rere kí ìwọ kí ó sì pa ọ̀nà àwọn olódodo mọ́.
So you will follow in the ways of the good, and keep to the paths of the righteous.
21 Nítorí ẹni dídúró ṣinṣin yóò gbé ní ilé náà àwọn aláìlẹ́gàn sì ni yóò máa wà nínú rẹ̀.
For the upright will inhabit the land, and the blameless will remain in it;
22 Ṣùgbọ́n a ó ké ènìyàn búburú kúrò lórí ilẹ̀ náà a ó sì fa àwọn aláìṣòótọ́ tu kúrò lórí rẹ̀.
but the wicked will be cut off from the land, and the unfaithful will be uprooted.

< Proverbs 2 >