< Proverbs 17 >
1 Òkèlè gbígbẹ tòun tàlàáfíà àti ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ sàn ju ilé tí ó kún fọ́fọ́ fún ẹran àti ìjà.
Bedre er en tør Bid og Ro derhos end et Hus fuldt af slagtet Kvæg med Trætte.
2 Ọlọ́gbọ́n ìránṣẹ́ yóò ṣàkóso adójútini ọmọ, yóò sì pín ogún gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ.
En klog Tjener skal herske over en Søn, som gør Skam, og han skal dele Arv midt iblandt Brødre.
3 Iná ni a fi fọ́ fàdákà àti wúrà, ṣùgbọ́n Olúwa ló ń dán ọkàn wò.
Diglen er til Sølvet og Ovnen til Guldet; men den, som prøver Hjerterne, er Herren.
4 Ènìyàn búburú ń tẹ́tí sí ètè tí ń sọ ibi; òpùrọ́ a máa fetí sí ahọ́n búburú.
Den onde agter paa uretfærdige Læber; Løgneren laaner Øre til den Tunge, der arbejder paa Fordærvelse.
5 Ẹnikẹ́ni tí ó bá sín olùpọ́njú jẹ, ó gan Ẹlẹ́dàá rẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ń yọ̀ sí ìyọnu kò ní lọ láìjìyà.
Hvo som bespotter den fattige, forhaaner hans Skaber; hvo som glæder sig over Ulykke, skal ikke agtes uskyldig.
6 Ọmọ ọmọ ni adé orí arúgbó, ògo àwọn ọmọ sì ni òbí jẹ.
Børnebørn ere de gamles Krone, og Børnenes Pryd er deres Fædre.
7 Ọ̀rọ̀ dídùn kò yẹ aṣiwèrè, bẹ́ẹ̀ ni ètè èké kò yẹ ọmọ-aládé!
Det staar ikke en Daare vel an at tale høje Ord, meget mindre en Fyrste at tale Løgn.
8 Òkúta iyebíye jẹ́ ẹ̀bùn ní ojú ẹni tí ó ni í, ibikíbi tí ó yí sí, á ṣe rere.
Skænk er en yndig Sten i deres Øjne, som modtage den; hvor som helst den vender sig hen, gør den Lykke.
9 Ẹni tí ó fojú fo ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ ẹ́ mú kí ìfẹ́ gbòòrò sí i. Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ń tẹnumọ́ ọ̀rọ̀ yóò pín ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ méjì ní yà.
Hvo som skjuler Overtrædelse, søger Kærlighed; men hvo som ripper op i en Sag, fjerner en fortrolig.
10 Ọ̀rọ̀ ìbáwí dun olóye ènìyàn ju ọgọ́rùn-ún pàṣán lọ lẹ́yìn òmùgọ̀.
Skænd trænger dybere ind hos en forstandig end at slaa en Daare hundrede Gange.
11 Orí kunkun ni ènìyàn ìkà máa ń ṣe, ìjòyè aláìláàánú ni a ó rán sí i.
Den onde søger kun at vise Genstridighed, men et grusomt Bud skal sendes imod ham.
12 Ó sàn kí ènìyàn pàdé beari tí a ti kó lọ́mọ jù aláìgbọ́n nínú ìwà òmùgọ̀ rẹ̀.
Lad en Mand møde en Bjørn, som Ungerne ere fratagne, kun ikke en Daare i hans Taabelighed.
13 Bí ènìyàn kan bá fi ibi san ìre, ibi kì yóò kúrò nílé rẹ̀ láéláé.
Hvo som gengiver godt med ondt, fra hans Hus skal det onde ikke vige.
14 Bíbẹ̀rẹ̀ ìjà dàbí ẹni tí ó dá ojú fún adágún omi; nítorí náà mẹ́nu kúrò nínú ọ̀rọ̀ kí ó tó di ìjà.
Hvo som begynder Trætte, aabner for Vand; opgiv derfor Trætten, førend den vælter sig frem.
15 Gbígbé ẹ̀bi fún aláre àti dídá ẹni jàre lẹ́bi, Olúwa kórìíra méjèèjì.
Den, som frikender den ugudelige, og den, som kender den retfærdige skyldig, ere begge Herren en Vederstyggelighed.
16 Kí ni ìwúlò owó lọ́wọ́ aṣiwèrè, níwọ̀n bí kò ti ní èròǹgbà láti rí ọgbọ́n?
Hvortil skal dog Penge i Daarens Haand? er det for at købe Visdom, da han dog ikke har Forstand?
17 Ọ̀rẹ́ a máa fẹ́ni nígbà gbogbo, arákùnrin sì wà fún ìgbà ìpọ́njú.
En Ven elsker altid, men en Broder fødes til Hjælp i Nød.
18 Ènìyàn aláìgbọ́n ṣe ìbúra, ó sì ṣe onídùúró fún aládùúgbò rẹ̀.
Et Menneske, som fattes Forstand, giver Haandslag og gaar i Borgen hos sin Næste.
19 Ẹni tí ó fẹ́ràn ìjà fẹ́ràn ẹ̀ṣẹ̀; ẹni tí ó kọ́ ibodè gígàn ń wá ìparun.
Hvo der elsker Trætte, elsker Overtrædelse; hvo som søger Undergang, gør sin Dør høj.
20 Ènìyàn aláyídáyidà ọkàn kì í gbèrú, ẹni tí ó ní ahọ́n ẹ̀tàn bọ́ sínú ìyọnu.
Den, som er vanartig i Hjertet, skal ikke finde godt; og den, som taler forvendt med sin Tunge, skal falde i Ulykke.
21 Láti bí aláìgbọ́n lọ́mọ a máa fa ìbànújẹ́ ọkàn, kò sí ayọ̀ fún baba ọmọ tí kò gbọ́n.
Den, som avler en Daare, ham bliver det til Bedrøvelse, og en Daares Fader skal ikke glæde sig.
22 Ọkàn tí ó túká jẹ́ oògùn gidi, ṣùgbọ́n ọkàn tí ó bàjẹ́ a máa mú kí egungun gbẹ.
Et glad Hjerte er en god Lægedom; men et nedslaaet Mod udtørrer Benene.
23 Ènìyàn búburú a gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀ láti yí ìdájọ́ po.
Den ugudelige tager Gave i Smug for at bøje Rettens Stier.
24 Olóye ènìyàn gbójú wo ọgbọ́n níwájú, ṣùgbọ́n ojú aláìgbọ́n ń wò káàkiri ilẹ̀ ayé.
For den forstandiges Ansigt er Visdommen; men en Daares Øjne ere ved Jordens Ende.
25 Aṣiwèrè ọmọ mú ìbànújẹ́ bá baba rẹ̀ àti ìkorò fún ẹni tí ó bí i lọ́mọ.
En daarlig Søn er sin Fader en Harm og sin Moder en Bedrøvelse.
26 Kò dára láti fìyà jẹ ènìyàn tí kò ṣẹ̀, tàbí láti na ìjòyè lórí òtítọ́ inú wọn.
Det er end ikke godt at lægge Bøder paa den retfærdige eller at slaa ædle Mænd tvært imod Ret.
27 Ènìyàn tó ní ìmọ̀ máa ń ṣọ́ra fún àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ, ènìyàn olóye sì máa ń ní sùúrù.
Den, som sparer sine Ord, besidder Kundskab, og en koldsindig Mand er forstandig.
28 Kódà aláìgbọ́n máa ń dàbí ọlọ́gbọ́n bí ó bá dákẹ́, àti bí olóye bí ó bá fètèmétè.
Ogsaa en Daare, om han tav, kunde regnes for viis; den, som holder sine Læber til, er forstandig.