< Proverbs 15 >
1 Ìdáhùn pẹ̀lẹ́ yí ìbínú padà ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ líle máa ń ru ìbínú sókè.
A gentle answer turns away wrath, but a harsh word stirs up anger.
2 Ahọ́n ọlọ́gbọ́n a máa gbé ìmọ̀ jáde ṣùgbọ́n ẹnu aláìgbọ́n ń tú ọ̀rọ̀ ọ òmùgọ̀ jáde.
The tongue of the wise commends knowledge, but the mouth of fools gush out folly.
3 Ojú Olúwa wà níbi gbogbo, Ó ń wo àwọn ẹni búburú àti àwọn ẹni rere.
The eyes of YHWH are everywhere, keeping watch on the evil and the good.
4 Ahọ́n tí ń mú ìtura wá jẹ́ igi ìyè ṣùgbọ́n ahọ́n ẹ̀tàn ń pa ẹ̀mí run.
A gentle tongue is a tree of life, but deceit in it crushes the spirit.
5 Aláìgbọ́n ọmọ kọ ìbáwí baba rẹ̀ ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí jẹ́ ọlọ́gbọ́n.
A fool despises his father's correction, but he who heeds reproof shows prudence.
6 Ilé olódodo kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ìṣúra, ṣùgbọ́n èrè àwọn ènìyàn búburú ń mú ìyọnu wá fún wọn.
In the house of the righteous is much treasure, but the income of the wicked brings trouble.
7 Ètè olódodo ń tan ìmọ̀ kalẹ̀; ṣùgbọ́n kò rí bẹ́ẹ̀ fún ọkàn aláìgbọ́n.
The lips of the wise spread knowledge; not so with the heart of fools.
8 Olúwa kórìíra ìrúbọ àwọn ènìyàn búburú ṣùgbọ́n àdúrà olódodo tẹ́ ẹ lọ́rùn.
The sacrifice made by the wicked is an abomination to YHWH, but the prayer of the upright is his delight.
9 Olúwa kórìíra ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú, ṣùgbọ́n ó fẹ́ràn àwọn tí ń lépa òdodo.
The way of the wicked is an abomination to YHWH, but he loves him who follows after righteousness.
10 Ẹni tí ó kúrò lójú ọ̀nà yóò rí ìbáwí gan an, ẹni tí ó kórìíra ìbáwí yóò kú.
There is stern discipline for one who forsakes the way: whoever hates reproof shall die.
11 Ikú àti ìparun ṣí sílẹ̀ níwájú Olúwa, mélòó mélòó ní nínú ọkàn àwọn ènìyàn. (Sheol )
Sheol and Abaddon are before YHWH—how much more then the hearts of human beings. (Sheol )
12 Ẹlẹ́gàn kò fẹ́ ẹni tí ń ba wí: kò ní gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ ọlọ́gbọ́n.
A scoffer doesn't love to be reproved; he will not go to the wise.
13 Inú dídùn máa ń mú kí ojú túká ṣùgbọ́n ìbànújẹ́ ọkàn máa ń pa ẹ̀mí run.
A glad heart makes a cheerful face; but an aching heart breaks the spirit.
14 Ọkàn olóye ń wá ìmọ̀ ṣùgbọ́n ẹnu aláìgbọ́n ń fẹ́ ìwà òmùgọ̀ bí ẹní jẹun.
The heart of one who has understanding seeks knowledge, but the mouths of fools feed on folly.
15 Gbogbo ọjọ́ àwọn olùpọ́njú jẹ́ ibi, ṣùgbọ́n onínúdídùn ń jẹ àlàáfíà ní ìgbà gbogbo.
All the days of the afflicted are wretched, but one who has a cheerful heart enjoys a continual feast.
16 Ó sàn kí ó má pọ̀, kí ìbẹ̀rù Olúwa sì wà ju ọrọ̀ púpọ̀ pẹ̀lú ìyọnu.
Better is little, with the fear of YHWH, than great treasure with trouble.
17 Oúnjẹ ewébẹ̀ níbi tí ìfẹ́ wà sàn ju àbọ́pa màlúù tòun ti ìríra.
Better is a dinner of herbs, where love is, than a fattened calf with hatred.
18 Ènìyàn onínú ríru dá ìjà sílẹ̀ ṣùgbọ́n onísùúrù paná ìjà.
A wrathful man stirs up contention, but one who is slow to anger appeases strife.
19 Ọ̀nà ọ̀lẹ ni ẹ̀gún dí, ṣùgbọ́n ọ̀nà olódodo já geerege ni.
The way of the sluggard is like a thorn patch, but the path of the upright is a highway.
20 Ọlọ́gbọ́n ọmọ mú inú baba rẹ̀ dùn, ṣùgbọ́n aṣiwèrè ènìyàn kẹ́gàn ìyá rẹ̀.
A wise son makes a father glad, but a foolish man despises his mother.
21 Inú ènìyàn aláìlóye a máa dùn sí ìwà òmùgọ̀; ṣùgbọ́n olóye ènìyàn a máa rin ọ̀nà tààrà.
Folly is joy to one who is void of wisdom, but a man of understanding keeps his way straight.
22 Ìgbèrò a máa dasán níbi tí kò sí ìmọ̀ràn; ṣùgbọ́n a máa yege níbi tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùbádámọ̀ràn wà.
Where there is no counsel, plans fail; but in a multitude of counselors they are established.
23 Inú ènìyàn a máa dùn nígbà tí ó bá fèsì tó yẹ ọ̀rọ̀ tí ó bá sì wá lásìkò tó yẹ dára púpọ̀!
Joy comes to a man with the reply of his mouth. How good is a word at the right time.
24 Ọ̀nà ìyè ń lọ sókè fún ọlọ́gbọ́n láti sọ kí ó má bá à sọ̀kalẹ̀ lọ sí ipò òkú. (Sheol )
The path of life leads upward for the wise, to keep him from going downward to Sheol. (Sheol )
25 Olúwa fa ilé onígbèéraga ya lulẹ̀, ṣùgbọ́n ó pa ààlà opó onírẹ̀lẹ̀ mọ́ láìyẹ̀.
YHWH will uproot the house of the proud, but he will keep the widow's borders intact.
26 Olúwa kórìíra èrò ènìyàn búburú, ṣùgbọ́n mímọ́ ni ọ̀rọ̀ ẹni pípé.
YHWH detests the thoughts of the wicked, but the thoughts of the pure are pleasing.
27 Ọ̀kánjúwà ènìyàn mú ìyọnu bá ilé rẹ̀ ṣùgbọ́n ẹni tí ó kórìíra àbẹ̀tẹ́lẹ̀ yóò yè.
He who is greedy for gain troubles his own house, but he who hates bribes will live.
28 Ọkàn olódodo ń wọn ìdáhùn wò ṣùgbọ́n ẹnu ènìyàn búburú ń tú ibi jáde.
The heart of the righteous weighs answers, but the mouth of the wicked gushes out evil.
29 Olúwa jìnnà sí ènìyàn búburú ṣùgbọ́n ó ń gbọ́ àdúrà olódodo.
YHWH is far from the wicked, but he hears the prayer of the righteous.
30 Ojú tó túká máa ń mú ayọ̀ wá fún ọkàn, ìròyìn ayọ̀ sì ń mú ìlera wá sínú egungun.
The light of the eyes rejoices the heart. Good news gives health to the bones.
31 Ẹni tí ó fetí sí ìbáwí tí ń fún ni ní ìyè, yóò wà ní àpéjọpọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n.
The ear that listens to reproof lives, and will be at home among the wise.
32 Ẹni tí ó kọ̀ ìbáwí kẹ́gàn ara rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí yóò ní ìmọ̀ sí i.
He who refuses correction despises his own soul, but he who listens to reproof gets understanding.
33 Ìbẹ̀rù Olúwa kọ́ ènìyàn ní ọgbọ́n, ìrẹ̀lẹ̀ sì ni ó máa ń ṣáájú ọlá.
The fear of YHWH teaches wisdom. Before honor is humility.