< Proverbs 14 >
1 Ọlọ́gbọ́n obìnrin kọ́ ilé e rẹ̀, ṣùgbọ́n aṣiwèrè obìnrin fi ọwọ́ ara rẹ̀ fà á lulẹ̀.
Every wise woman builds her house, but a foolish one tears it down with her own hands.
2 Ẹni tí ń rìn déédé bẹ̀rù Olúwa, ṣùgbọ́n ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ kò tọ́ kẹ́gàn Olúwa.
He who walks in uprightness fears the LORD, but the one who is devious in his ways despises Him.
3 Ọ̀rọ̀ aṣiwèrè a máa ṣokùnfà pàṣán fún ẹ̀yìn rẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ètè ọlọ́gbọ́n a máa dáàbò bò ó.
The proud speech of a fool brings a rod to his back, but the lips of the wise protect them.
4 Níbi tí kò sí ẹran, ibùjẹ ẹran a máa mọ́ tónítóní, ṣùgbọ́n, nípa agbára akọ màlúù ni ọ̀pọ̀ ìkórè ti ń wá.
Where there are no oxen, the manger is empty, but an abundant harvest comes through the strength of the ox.
5 Ẹlẹ́rìí tí ń ṣọ òtítọ́ kì í tan ni ṣùgbọ́n ẹlẹ́rìí èké a máa tú irọ́ jáde.
An honest witness does not deceive, but a dishonest witness pours forth lies.
6 Ẹlẹ́gàn ń wá ọgbọ́n kò sì rí rárá, ṣùgbọ́n ìmọ̀ máa ń wà fún olóye.
A mocker seeks wisdom and finds none, but knowledge comes easily to the discerning.
7 Má ṣe súnmọ́ aláìgbọ́n ènìyàn, nítorí ìwọ kì yóò rí ìmọ̀ ní ètè rẹ̀.
Stay away from a foolish man; you will gain no knowledge from his speech.
8 Ọgbọ́n olóye ni láti ronú jinlẹ̀ nípa ọ̀nà wọn ṣùgbọ́n ìwà òmùgọ̀ aṣiwèrè ni ìtànjẹ.
The wisdom of the prudent is to discern his way, but the folly of fools deceives them.
9 Aláìgbọ́n ń dẹ́ṣẹ̀ nígbà tí ó yẹ kí ó ṣe àtúnṣe ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ṣùgbọ́n láàrín àwọn olódodo ni a ti rí ojúrere.
Fools mock the making of amends, but goodwill is found among the upright.
10 Ọkàn kọ̀ọ̀kan ló mọ ẹ̀dùn ọkàn tirẹ̀ kò sì ṣí ẹnìkan tó le è bá ọkàn mìíràn pín ayọ̀ rẹ̀.
The heart knows its own bitterness, and no stranger shares in its joy.
11 A ó pa ilé ènìyàn búburú run, ṣùgbọ́n àgọ́ olódodo yóò máa gbèrú sí i.
The house of the wicked will be destroyed, but the tent of the upright will flourish.
12 Ọ̀nà kan wà tí ó dàbí i pé ó dára lójú ènìyàn, ṣùgbọ́n ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín, a máa jásí ikú.
There is a way that seems right to a man, but its end is the way of death.
13 Kódà nígbà tí a ń rẹ́rìn-ín, ọkàn le è máa kérora; ayọ̀ sì le è yọrí sí ìbànújẹ́.
Even in laughter the heart may ache, and joy may end in sorrow.
14 A ó san án lẹ́kùnrẹ́rẹ́ fún aláìgbàgbọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀, ènìyàn rere yóò sì gba èrè fún tirẹ̀.
The backslider in heart receives the fill of his own ways, but a good man is rewarded for his ways.
15 Òpè ènìyàn gba ohun gbogbo gbọ́ ṣùgbọ́n olóye ènìyàn ronú lórí àwọn ìgbésẹ̀ rẹ̀.
The simple man believes every word, but the prudent man watches his steps.
16 Ọlọ́gbọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run ó sì kórìíra ibi ṣùgbọ́n aláìgbọ́n jẹ́ alágídí àti aláìṣọ́ra.
A wise man fears and turns from evil, but a fool is careless and reckless.
17 Ẹni tí ó máa ń tètè bínú máa ń hùwà aṣiwèrè, a sì kórìíra eléte ènìyàn.
A quick-tempered man acts foolishly, and a devious man is hated.
18 Òpè jogún ìwà òmùgọ̀ ṣùgbọ́n a dé ọlọ́gbọ́n ní adé ìmọ̀.
The simple inherit folly, but the prudent are crowned with knowledge.
19 Ènìyàn ìkà yóò tẹríba níwájú àwọn ènìyàn rere àti ènìyàn búburú níbi ìlẹ̀kùn àwọn olódodo.
The evil bow before the good, and the wicked at the gates of the righteous.
20 Kódà àwọn aládùúgbò tálákà kò fẹ́ràn rẹ̀, ṣùgbọ́n, ọlọ́rọ̀ ní ọ̀rẹ́ púpọ̀.
The poor man is hated even by his neighbor, but many are those who love the rich.
21 Ẹni tí ó kẹ́gàn aládùúgbò o rẹ̀ ti dẹ́ṣẹ̀ ṣùgbọ́n ìbùkún ni fún ẹni tí ó ṣàánú àwọn aláìní.
He who despises his neighbor sins, but blessed is he who shows kindness to the poor.
22 Ǹjẹ́ àwọn tí ń pète ibi kì í ṣìnà bí? Ṣùgbọ́n àwọn tí ń gbèrò ohun rere ń rí ìfẹ́ àti òtítọ́.
Do not those who contrive evil go astray? But those who plan goodness find loving devotion and faithfulness.
23 Gbogbo iṣẹ́ àṣekára ló máa ń mú èrè wá, ṣùgbọ́n ẹjọ́ rírò lásán máa ń ta ni lósì ni.
There is profit in all labor, but mere talk leads only to poverty.
24 Ọrọ̀ ọlọ́gbọ́n ènìyàn ni adé orí wọn ṣùgbọ́n ìwà aláìgbọ́n ń mú ìwà òmùgọ̀ wá.
The crown of the wise is their wealth, but the effort of fools is folly.
25 Ẹlẹ́rìí tí ó ṣọ òtítọ́ gba ẹ̀mí là ṣùgbọ́n ẹlẹ́rìí èké jẹ́ ẹlẹ́tàn.
A truthful witness saves lives, but one who utters lies is deceitful.
26 Nínú ìbẹ̀rù Olúwa ni ìgbẹ́kẹ̀lé tí ó lágbára, yóò sì tún jẹ́ ibi ààbò fún àwọn ọmọ rẹ̀.
He who fears the LORD is secure in confidence, and his children shall have a place of refuge.
27 Ìbẹ̀rù Olúwa jẹ́ orísun ìyè, tí ń yí ènìyàn padà kúrò nínú ìkẹ́kùn ikú.
The fear of the LORD is a fountain of life, turning a man from the snares of death.
28 Ènìyàn púpọ̀ ní ìlú jẹ́ ògo ọba, ṣùgbọ́n láìsí ìjòyè, ọba á parun.
A large population is a king’s splendor, but a lack of subjects is a prince’s ruin.
29 Onísùúrù ènìyàn ní òye tí ó pọ̀, ṣùgbọ́n onínú-fùfù ènìyàn máa ń fi ìwà aṣiwèrè hàn.
A patient man has great understanding, but a quick-tempered man promotes folly.
30 Ọkàn tí ó lálàáfíà fi ìyè mú kí ọjọ́ ayé gùn fún ara, ṣùgbọ́n ìlara mú kí egungun jẹrà.
A tranquil heart is life to the body, but envy rots the bones.
31 Ẹni tí ó fi ìyà jẹ aláìní ń fi ìkórìíra hàn ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó ṣoore fún aláìní bu ọlá fún Ọlọ́run.
Whoever oppresses the poor taunts their Maker, but whoever is kind to the needy honors Him.
32 Nígbà tí ìyọnu bá dé, a fa àwọn búburú lulẹ̀, kódà nínú ikú àwọn olódodo ni ààbò.
The wicked man is thrown down by his own sin, but the righteous man has a refuge even in death.
33 Ọgbọ́n wà nínú ọkàn olóye kódà láàrín àwọn aláìlóye, ó jẹ́ kí wọn mọ òun.
Wisdom rests in the heart of the discerning; even among fools she is known.
34 Òdodo a máa gbé orílẹ̀-èdè lékè, ṣùgbọ́n ìtìjú ni ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ fún àwùjọ káwùjọ.
Righteousness exalts a nation, but sin is a disgrace to any people.
35 Ọba a máa ní inú dídùn sí ìránṣẹ́ tí ó gbọ́n ṣùgbọ́n ìbínú rẹ̀ wá sórí ìránṣẹ́ adójútini.
A king delights in a wise servant, but his anger falls on the shameful.