< Proverbs 12 >

1 Ẹnikẹ́ni tí ó fẹ́ ẹ̀kọ́ fẹ́ ìmọ̀, ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó kórìíra ìbáwí jẹ́ aláìgbọ́n.
אהב מוסר אהב דעת ושנא תוכחת בער׃
2 Ènìyàn rere gba ojúrere lọ́dọ̀ Olúwa ṣùgbọ́n ènìyàn ètè búburú ni yóò dá lẹ́bi.
טוב יפיק רצון מיהוה ואיש מזמות ירשיע׃
3 A kò lè fi ẹsẹ̀ ènìyàn múlẹ̀ nípa ìwà búburú ṣùgbọ́n a kò le è fa olódodo tu.
לא יכון אדם ברשע ושרש צדיקים בל ימוט׃
4 Aya oníwà rere ni adé ọkọ rẹ̀ ṣùgbọ́n aya adójútini dàbí inú egungun rẹ̀ jẹrà.
אשת חיל עטרת בעלה וכרקב בעצמותיו מבישה׃
5 Èrò àwọn olódodo tọ́, ṣùgbọ́n ìgbìmọ̀ ènìyàn búburú jẹ́ ẹ̀tàn.
מחשבות צדיקים משפט תחבלות רשעים מרמה׃
6 Ọ̀rọ̀ ènìyàn búburú lúgọ de ẹ̀jẹ̀ ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ àwọn olódodo gbà wọ́n là.
דברי רשעים ארב דם ופי ישרים יצילם׃
7 A ṣí àwọn ènìyàn búburú ní ìdí, wọn kò sì sí mọ́; ṣùgbọ́n ilé olódodo dúró ṣinṣin.
הפוך רשעים ואינם ובית צדיקים יעמד׃
8 A ń yín ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ọgbọ́n rẹ̀ ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ọlọ́pọlọ wúruwùru ni a kẹ́gàn.
לפי שכלו יהלל איש ונעוה לב יהיה לבוז׃
9 Ó sàn kí a má jẹ́ ènìyàn pàtàkì kí a sì ní ìránṣẹ́ ju kí a díbọ́n pé a jẹ́ ẹni pàtàkì láìní oúnjẹ.
טוב נקלה ועבד לו ממתכבד וחסר לחם׃
10 Olódodo ènìyàn ń ṣe aájò ohun tí àwọn ohun ọ̀sìn rẹ̀ nílò, ṣùgbọ́n ìyọ́nú àwọn ènìyàn búburú, ìkà ni.
יודע צדיק נפש בהמתו ורחמי רשעים אכזרי׃
11 Ẹni tí ó bá dá oko yóò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ, ṣùgbọ́n ẹni tí ń lépa òjìji lásán làsàn kò gbọ́n.
עבד אדמתו ישבע לחם ומרדף ריקים חסר לב׃
12 Ènìyàn búburú ń fẹ́ ìkógun àwọn ènìyàn ìkà ṣùgbọ́n gbòǹgbò olódodo ń gbilẹ̀.
חמד רשע מצוד רעים ושרש צדיקים יתן׃
13 A mú ènìyàn búburú nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ṣùgbọ́n olódodo bọ́ kúrò lọ́wọ́ ìdààmú.
בפשע שפתים מוקש רע ויצא מצרה צדיק׃
14 Láti inú èso rẹ̀, ènìyàn kún fún onírúurú ohun rere bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ti ń pín in lérè dájúdájú.
מפרי פי איש ישבע טוב וגמול ידי אדם ישוב לו׃
15 Ọ̀nà aláìgbọ́n dára lójú ara rẹ̀ ṣùgbọ́n ọlọ́gbọ́n ènìyàn a máa gba ìmọ̀ràn.
דרך אויל ישר בעיניו ושמע לעצה חכם׃
16 Aláìgbọ́n ènìyàn fi ìbínú un rẹ̀ hàn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ṣùgbọ́n olóye ènìyàn fojú fo ìyànjẹ.
אויל ביום יודע כעסו וכסה קלון ערום׃
17 Ẹni tí ó jẹ́ ajẹ́rìí òtítọ́ jẹ́rìí ohun tí ojú rẹ̀ rí ṣùgbọ́n ajẹ́rìí èké máa ń parọ́.
יפיח אמונה יגיד צדק ועד שקרים מרמה׃
18 Ọ̀rọ̀ tí a kò rò jinlẹ̀ máa ń gún ni bí ọ̀kọ̀ ṣùgbọ́n ahọ́n ọlọ́gbọ́n ń mú ìwòsàn wá.
יש בוטה כמדקרות חרב ולשון חכמים מרפא׃
19 Ètè tí ń ṣọ òtítọ́ yóò wà láéláé ṣùgbọ́n ahọ́n tí ń parọ́ kì í tọ́jọ́.
שפת אמת תכון לעד ועד ארגיעה לשון שקר׃
20 Ẹ̀tàn wà nínú ọkàn àwọn tí ń pète búburú ṣùgbọ́n ayọ̀ wà fún àwọn tí ń mú kí àlàáfíà gbilẹ̀.
מרמה בלב חרשי רע וליעצי שלום שמחה׃
21 Ibi kì í ṣubú lu olódodo rárá ṣùgbọ́n ènìyàn búburú gba ìpín ìyọnu tiwọn.
לא יאנה לצדיק כל און ורשעים מלאו רע׃
22 Olúwa kórìíra ètè tí ń parọ́ ṣùgbọ́n ó ní inú dídùn sí àwọn olóòtítọ́.
תועבת יהוה שפתי שקר ועשי אמונה רצונו׃
23 Ènìyàn olóye fi ìmọ̀ rẹ̀ pamọ́ sínú ara rẹ̀ ṣùgbọ́n ọkàn ènìyàn búburú ń gbé ìwà òmùgọ̀ jáde.
אדם ערום כסה דעת ולב כסילים יקרא אולת׃
24 Ọwọ́ àìṣọ̀lẹ yóò jẹ ọba ṣùgbọ́n ọ̀lẹ ṣíṣe a máa yọrí sí ẹrú ṣíṣe.
יד חרוצים תמשול ורמיה תהיה למס׃
25 Ìbànújẹ́ ní ọkàn ènìyàn ní dorí rẹ̀ kodò ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ rere a máa mú kó yọ̀.
דאגה בלב איש ישחנה ודבר טוב ישמחנה׃
26 Olódodo ènìyàn máa ń ṣọ́ra láti dọ́rẹ̀ẹ́ ṣùgbọ́n ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú ń mú wọn ṣìnà.
יתר מרעהו צדיק ודרך רשעים תתעם׃
27 Ọ̀lẹ ènìyàn kò sun ẹran tí ó pa lóko ọdẹ ṣùgbọ́n ẹni tí kì í ṣe ọ̀lẹ máa ń díwọ̀n ohun ìní rẹ̀.
לא יחרך רמיה צידו והון אדם יקר חרוץ׃
28 Ní ọ̀nà àwọn olódodo ni ìyè wà ní ọ̀nà náà ni àìkú wà.
בארח צדקה חיים ודרך נתיבה אל מות׃

< Proverbs 12 >