< Obadiah 1 >

1 Ìran ti Obadiah. Èyí ni Olúwa Olódùmarè wí nípa Edomu. Àwa ti gbọ́ ohùn kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá, a sì ti rán ikọ̀ kan sí gbogbo kèfèrí láti sọ pé, “Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a dìde ogun sí i.”
חֲזוֹן עֹֽבַדְיָה כֹּֽה־אָמַר אֲדֹנָי יֱהֹוִה לֶאֱדוֹם שְׁמוּעָה שָׁמַעְנוּ מֵאֵת יְהֹוָה וְצִיר בַּגּוֹיִם שֻׁלָּח קוּמוּ וְנָקוּמָה עָלֶיהָ לַמִּלְחָמָֽה׃
2 “Kíyèsi i, Èmi yóò sọ ọ́ di kékeré láàrín àwọn kèfèrí; ìwọ yóò sì di gígàn lọ́pọ̀lọ́pọ̀.
הִנֵּה קָטֹן נְתַתִּיךָ בַּגּוֹיִם בָּזוּי אַתָּה מְאֹֽד׃
3 Ìgbéraga àyà rẹ ti tàn ọ́ jẹ, ìwọ tí ń gbé inú pálapàla àpáta, tí o sì kọ́ ibùgbé rẹ sí ibi gíga, ìwọ wí nínú ọkàn rẹ pé, ‘Ta ni yóò mú mi sọ̀kalẹ̀?’
זְדוֹן לִבְּךָ הִשִּׁיאֶךָ שֹׁכְנִי בְחַגְוֵי־סֶלַע מְרוֹם שִׁבְתּוֹ אֹמֵר בְּלִבּוֹ מִי יוֹרִדֵנִי אָֽרֶץ׃
4 Bí ìwọ tilẹ̀ gbé ara rẹ ga bí ẹyẹ idì, bí ìwọ tilẹ̀ tẹ́ ìtẹ́ rẹ sí àárín àwọn ìràwọ̀, láti ibẹ̀ ni èmi yóò ti sọ̀ ọ kalẹ̀,” ni Olúwa wí.
אִם־תַּגְבִּיהַּ כַּנֶּשֶׁר וְאִם־בֵּין כּֽוֹכָבִים שִׂים קִנֶּךָ מִשָּׁם אוֹרִֽידְךָ נְאֻם־יְהֹוָֽה׃
5 “Bí àwọn olè tọ̀ ọ́ wá, bí àwọn ọlọ́ṣà ní òru, Háà! Irú ìparun wo ló dúró dè ọ́, wọn kò ha jalè tó bí wọ́n ti fẹ́? Bí àwọn tí ń ká èso àjàrà tọ̀ ọ́ wá, wọn kò ha ni fi èso àjàrà díẹ̀ sílẹ̀?
אִם־גַּנָּבִים בָּאֽוּ־לְךָ אִם־שׁוֹדְדֵי לַיְלָה אֵיךְ נִדְמֵיתָה הֲלוֹא יִגְנְבוּ דַּיָּם אִם־בֹּֽצְרִים בָּאוּ לָךְ הֲלוֹא יַשְׁאִירוּ עֹלֵלֽוֹת׃
6 Báwo ni a ṣe ṣe àwárí nǹkan Esau, tí a sì wá ohun ìní ìkọ̀kọ̀ rẹ̀ jáde.
אֵיךְ נֶחְפְּשׂוּ עֵשָׂו נִבְעוּ מַצְפֻּנָֽיו׃
7 Gbogbo àwọn ẹni ìmùlẹ̀ rẹ ti mú ọ dé ìpẹ̀kun ilẹ̀ rẹ, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ ti tàn ọ́ jẹ, wọ́n sì ti borí rẹ; àwọn tó jẹ oúnjẹ rẹ dẹ pàkúté dè ọ́, ṣùgbọ́n ìwọ kò ní ní òye rẹ̀.”
עַֽד־הַגְּבוּל שִׁלְּחוּךָ כֹּל אַנְשֵׁי בְרִיתֶךָ הִשִּׁיאוּךָ יָכְלוּ לְךָ אַנְשֵׁי שְׁלֹמֶךָ לַחְמְךָ יָשִׂימוּ מָזוֹר תַּחְתֶּיךָ אֵין תְּבוּנָה בּֽוֹ׃
8 Olúwa wí pé, “Ní ọjọ́ náà, Èmi kì yóò ha pa àwọn ọlọ́gbọ́n Edomu run, àti àwọn amòye run kúrò ní òkè Esau?
הֲלוֹא בַּיּוֹם הַהוּא נְאֻם־יְהֹוָה וְהַאֲבַדְתִּי חֲכָמִים מֵֽאֱדוֹם וּתְבוּנָה מֵהַר עֵשָֽׂו׃
9 A ó ṣe ẹ̀rù ba àwọn jagunjagun rẹ, ìwọ Temani, gbogbo àwọn tó wà ní orí òkè Esau ní a ó gé kúrò nínú ìpànìyàn náà.
וְחַתּוּ גִבּוֹרֶיךָ תֵּימָן לְמַעַן יִכָּֽרֶת־אִישׁ מֵהַר עֵשָׂו מִקָּֽטֶל׃
10 Nítorí ìwà ipá sí Jakọbu arákùnrin rẹ, ìtìjú yóò bò ọ, a ó sì pa ọ run títí láé.
מֵחֲמַס אָחִיךָ יַעֲקֹב תְּכַסְּךָ בוּשָׁה וְנִכְרַתָּ לְעוֹלָֽם׃
11 Ní ọjọ́ tí ìwọ dúró ní apá kan, ní ọjọ́ tí àlejò kó ogún rẹ lọ, tí àwọn àjèjì sì wọ ibodè rẹ, tí wọ́n sì sẹ́ kèké lórí Jerusalẹmu, ìwọ náà wà bí ọ̀kan nínú wọn.
בְּיוֹם עֲמׇֽדְךָ מִנֶּגֶד בְּיוֹם שְׁבוֹת זָרִים חֵילוֹ וְנׇכְרִים בָּאוּ שְׁעָרָו וְעַל־יְרוּשָׁלַ͏ִם יַדּוּ גוֹרָל גַּם־אַתָּה כְּאַחַד מֵהֶֽם׃
12 Ìwọ kì bá tí fi ojú kéré arákùnrin rẹ, ní àkókò ìbànújẹ́ rẹ̀ ìwọ kì bá tí yọ̀ lórí àwọn ọmọ Juda, ní ọjọ́ ìparun wọn ìwọ kì bá tí gbéraga púpọ̀ ní ọjọ́ wàhálà wọn.
וְאַל־תֵּרֶא בְיוֹם־אָחִיךָ בְּיוֹם נׇכְרוֹ וְאַל־תִּשְׂמַח לִבְנֵֽי־יְהוּדָה בְּיוֹם אׇבְדָם וְאַל־תַּגְדֵּל פִּיךָ בְּיוֹם צָרָֽה׃
13 Ìwọ kì bá tí wọ inú ibodè àwọn ènìyàn mi lọ, ní ọjọ́ àjálù wọn. Ìwọ kì bá tí fojú kó wọn mọ́lẹ̀ nínú ìdààmú wọn, ní ọjọ́ àjálù wọn. Ìwọ kì bá tí jí ẹrù wọn kó, ní ọjọ́ ìpọ́njú wọn.
אַל־תָּבוֹא בְשַֽׁעַר־עַמִּי בְּיוֹם אֵידָם אַל־תֵּרֶא גַם־אַתָּה בְּרָעָתוֹ בְּיוֹם אֵידוֹ וְאַל־תִּשְׁלַחְנָה בְחֵילוֹ בְּיוֹם אֵידֽוֹ׃
14 Ìwọ kì bá tí dúró ní ìkóríta ọ̀nà láti ké àwọn tirẹ̀ tó ti sálà kúrò. Ìwọ kì bá tí fa àwọn tó ṣẹ́kù nínú wọn lélẹ̀ ní ọjọ́ wàhálà wọn.
וְאַֽל־תַּעֲמֹד עַל־הַפֶּרֶק לְהַכְרִית אֶת־פְּלִיטָיו וְאַל־תַּסְגֵּר שְׂרִידָיו בְּיוֹם צָרָֽה׃
15 “Nítorí ọjọ́ Olúwa súnmọ́ etílé lórí gbogbo àwọn kèfèrí. Bí ìwọ ti ṣe, bẹ́ẹ̀ ni a ó ṣe sí ìwọ náà; ẹ̀san rẹ yóò sì yípadà sí orí ara rẹ.
כִּֽי־קָרוֹב יוֹם־יְהֹוָה עַל־כׇּל־הַגּוֹיִם כַּאֲשֶׁר עָשִׂיתָ יֵעָשֶׂה לָּךְ גְּמֻלְךָ יָשׁוּב בְּרֹאשֶֽׁךָ׃
16 Gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀ ṣe mu lórí òkè mímọ́ mi, bẹ́ẹ̀ ni gbogbo kèfèrí yóò máa mu títí; wọn yóò mu ún ní àmutẹ́rùn wọn yóò sì wà bí ẹni pé wọn kò mu ún rí.
כִּי כַּֽאֲשֶׁר שְׁתִיתֶם עַל־הַר קׇדְשִׁי יִשְׁתּוּ כׇֽל־הַגּוֹיִם תָּמִיד וְשָׁתוּ וְלָעוּ וְהָיוּ כְּלוֹא הָיֽוּ׃
17 Ṣùgbọ́n ìgbàlà yóò wà lórí òkè Sioni, wọn yóò sì jẹ́ mímọ́, àti ilé Jakọbu yóò sì ní ìní wọn.
וּבְהַר צִיּוֹן תִּהְיֶה פְלֵיטָה וְהָיָה קֹדֶשׁ וְיָֽרְשׁוּ בֵּית יַֽעֲקֹב אֵת מוֹרָֽשֵׁיהֶֽם׃
18 Ilé Jakọbu yóò sì jẹ́ iná àti ilé Josẹfu ọwọ́ iná ilé Esau yóò jẹ àgékù koríko wọn yóò fi iná sí i, wọn yóò jo run. Kì yóò sí ẹni tí yóò kù ní ilé Esau.” Nítorí Olúwa ti sọ̀rọ̀.
וְהָיָה בֵית־יַעֲקֹב אֵשׁ וּבֵית יוֹסֵף לֶהָבָה וּבֵית עֵשָׂו לְקַשׁ וְדָלְקוּ בָהֶם וַאֲכָלוּם וְלֹֽא־יִֽהְיֶה שָׂרִיד לְבֵית עֵשָׂו כִּי יְהֹוָה דִּבֵּֽר׃
19 Àwọn ará gúúsù yóò ni òkè Esau, àwọn ará ẹsẹ̀ òkè yóò ni ilẹ̀ àwọn ará Filistini ní ìní. Wọn yóò sì ni oko Efraimu àti Samaria; Benjamini yóò ní Gileadi ní ìní.
וְיָרְשׁוּ הַנֶּגֶב אֶת־הַר עֵשָׂו וְהַשְּׁפֵלָה אֶת־פְּלִשְׁתִּים וְיָרְשׁוּ אֶת־שְׂדֵה אֶפְרַיִם וְאֵת שְׂדֵה שֹׁמְרוֹן וּבִנְיָמִן אֶת־הַגִּלְעָֽד׃
20 Àwọn ìgbèkùn Israẹli tí ó wà ní Kenaani yóò ni ilẹ̀ títí dé Sarefati; àwọn ìgbèkùn láti Jerusalẹmu tí ó wà ní Sefaredi yóò ni àwọn ìlú gúúsù ní ìní.
וְגָלֻת הַֽחֵל־הַזֶּה לִבְנֵי יִשְׂרָאֵל אֲשֶֽׁר־כְּנַעֲנִים עַד־צָרְפַת וְגָלֻת יְרוּשָׁלַ͏ִם אֲשֶׁר בִּסְפָרַד יִֽרְשׁוּ אֵת עָרֵי הַנֶּֽגֶב׃
21 Àwọn tó ń gba ni là yóò sì gòkè Sioni wá láti jẹ ọba lé orí àwọn òkè Esau. Ìjọba náà yóò sì jẹ́ ti Olúwa.
וְעָלוּ מֽוֹשִׁעִים בְּהַר צִיּוֹן לִשְׁפֹּט אֶת־הַר עֵשָׂו וְהָיְתָה לַֽיהֹוָה הַמְּלוּכָֽה׃

< Obadiah 1 >