< Numbers 1 >

1 Olúwa bá Mose sọ̀rọ̀ ní aginjù Sinai nínú àgọ́ àjọ ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kejì ní ọdún kejì tí àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, ó wí pé,
以色列人出埃及地後,第二年二月初一日,耶和華在西奈的曠野、會幕中曉諭摩西說:
2 “Ka gbogbo àgbájọ ènìyàn Israẹli nípa ẹbí wọn, àti nípa ìdílé baba wọn, to orúkọ wọn olúkúlùkù ọkùnrin ní ọ̀kọ̀ọ̀kan.
「你要按以色列全會眾的家室、宗族、人名的數目計算所有的男丁。
3 Ìwọ àti Aaroni ni kí ẹ kà gbogbo ọmọkùnrin Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn láti ọmọ ogún ọdún sókè, àwọn tí ó tó lọ sójú ogun.
凡以色列中,從二十歲以外,能出去打仗的,你和亞倫要照他們的軍隊數點。
4 Kí ẹ mú ọkùnrin kọ̀ọ̀kan láti inú olúkúlùkù ẹ̀yà kí ó sì wá pẹ̀lú yín, kí olúkúlùkù jẹ́ olórí ilé àwọn baba rẹ̀.
每支派中必有一人作本支派的族長,幫助你們。
5 “Orúkọ àwọn ọkùnrin tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ nìyí: “Láti ọ̀dọ̀ Reubeni, Elisuri ọmọ Ṣedeuri.
他們的名字:屬呂便的,有示丟珥的兒子以利蓿;
6 Láti ọ̀dọ̀ Simeoni, Ṣelumieli ọmọ Suriṣaddai.
屬西緬的,有蘇利沙代的兒子示路蔑;
7 Láti ọ̀dọ̀ Juda, Nahiṣoni ọmọ Amminadabu.
屬猶大的,有亞米拿達的兒子拿順;
8 Láti ọ̀dọ̀ Isakari, Netaneli ọmọ Suari.
屬以薩迦的,有蘇押的兒子拿坦業;
9 Láti ọ̀dọ̀ Sebuluni, Eliabu ọmọ Heloni.
屬西布倫的,有希倫的兒子以利押;
10 Láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Josẹfu: láti ọ̀dọ̀ Efraimu, Eliṣama ọmọ Ammihudu. Láti ọ̀dọ̀ Manase, Gamalieli ọmọ Pedasuri.
約瑟子孫、屬以法蓮的,有亞米忽的兒子以利沙瑪;屬瑪拿西的,有比大蓿的兒子迦瑪列;
11 Láti ọ̀dọ̀ Benjamini, Abidani ọmọ Gideoni.
屬便雅憫的,有基多尼的兒子亞比但;
12 Láti ọ̀dọ̀ Dani, Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai.
屬但的,有亞米沙代的兒子亞希以謝;
13 Láti ọ̀dọ̀ Aṣeri, Pagieli ọmọ Okanri.
屬亞設的,有俄蘭的兒子帕結;
14 Láti ọ̀dọ̀ Gadi, Eliasafu ọmọ Deueli.
屬迦得的,有丟珥的兒子以利雅薩;
15 Láti ọ̀dọ̀ Naftali, Ahira ọmọ Enani.”
屬拿弗他利的,有以南的兒子亞希拉。
16 Àwọn wọ̀nyí ni wọ́n yàn nínú àwùjọ ènìyàn, olórí àwọn ẹ̀yà baba wọn. Àwọn ni olórí àwọn ẹbí Israẹli.
這都是從會中選召的,各作本支派的首領,都是以色列軍中的統領。」
17 Mose àti Aaroni mú àwọn ènìyàn tí a dárúkọ wọ̀nyí
於是,摩西、亞倫帶着這些按名指定的人,
18 wọ́n sì pe gbogbo àwùjọ ènìyàn Israẹli jọ ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kejì. Àwọn ènìyàn sì dárúkọ baba ńlá wọn nípa ẹbí àti ìdílé wọn. Wọ́n sì ṣe àkọsílẹ̀ orúkọ àwọn ọmọkùnrin ní ọ̀kọ̀ọ̀kan láti ọmọ ogún ọdún sókè,
當二月初一日招聚全會眾。會眾就照他們的家室、宗族、人名的數目,從二十歲以外的,都述說自己的家譜。
19 gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose. Bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe kà wọ́n nínú aginjù Sinai.
耶和華怎樣吩咐摩西,他就怎樣在西奈的曠野數點他們。
20 Láti ìran Reubeni tí í ṣe àkọ́bí Israẹli, gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn, lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn.
以色列的長子,呂便子孫的後代,照着家室、宗族、人名的數目,從二十歲以外,凡能出去打仗、被數的男丁,共有四萬六千五百名。
21 Àwọn tí a kà ní ẹ̀yà Reubeni jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàlélógún ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta.
22 Láti ìran Simeoni, gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè, tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n kà, wọ́n sì to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn.
西緬子孫的後代,照着家室、宗族、人名的數目,從二十歲以外,凡能出去打仗、被數的男丁,共有五萬九千三百名。
23 Iye àwọn tí á kà nínú ẹ̀yà Simeoni jẹ́ ẹgbàá mọ́kàndínlọ́gbọ̀n ó lé ọ̀ọ́dúnrún.
24 Láti ìran Gadi, gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí ẹbí àti ìdílé wọn.
迦得子孫的後代,照着家室、宗族、人名的數目,從二十歲以外,凡能出去打仗、被數的,共有四萬五千六百五十名。
25 Iye àwọn tí a kà nínú ẹ̀yà Gadi jẹ́ ẹgbàá méjìlélógún ó lé àádọ́talélẹ́gbẹ̀jọ.
26 Láti ìran Juda, gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè, tí wọ́n le lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn.
猶大子孫的後代,照着家室、宗族、人名的數目,從二十歲以外,凡能出去打仗、被數的,共有七萬四千六百名。
27 Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Juda jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàdínlógójì ó lé ẹgbẹ̀ta.
28 Láti ìran Isakari, gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè tí wọ́n le lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn.
以薩迦子孫的後代,照着家室、宗族、人名的數目,從二十歲以外,凡能出去打仗、被數的,共有五萬四千四百名。
29 Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Isakari jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ó lé irinwó.
30 Láti ìran Sebuluni, gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn.
西布倫子孫的後代,照着家室、宗族、人名的數目,從二十歲以外,凡能出去打仗、被數的,共有五萬七千四百名。
31 Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Sebuluni jẹ́ ẹgbàá méjìdínlọ́gbọ̀n ó lé egbèje.
32 Láti inú àwọn ọmọ Josẹfu. Láti ìran Efraimu, gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọ́n jẹ́ ogún ọdún sókè tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn.
約瑟子孫屬以法蓮子孫的後代,照着家室、宗族、人名的數目,從二十歲以外,凡能出去打仗、被數的,共有四萬零五百名。
33 Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Efraimu jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta.
34 Láti ìran Manase, gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè, tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn.
瑪拿西子孫的後代,照着家室、宗族、人名的數目,從二十歲以外,凡能出去打仗、被數的,共有三萬二千二百名。
35 Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Manase jẹ́ ẹgbàá ẹẹ́rìndínlógún ó lé igba.
36 Láti ìran Benjamini, gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn.
便雅憫子孫的後代,照着家室、宗族、人名的數目,從二十歲以外,凡能出去打仗、被數的,共有三萬五千四百名。
37 Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Benjamini jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàdínlógún ó lé egbèje.
38 Láti ìran Dani, gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ọmọ ogún ọdún sókè, tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn.
但子孫的後代,照着家室、宗族、人名的數目,從二十歲以外,凡能出去打仗、被數的,共有六萬二千七百名。
39 Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Dani jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlélọ́gbọ̀n ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin.
40 Láti ìran Aṣeri, gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè, tí wọ́n le lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn.
亞設子孫的後代,照着家室、宗族、人名的數目,從二十歲以外,凡能出去打仗、被數的,共有四萬一千五百名。
41 Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Aṣeri jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ.
42 Láti ìran Naftali, gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún ó lé, tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn.
拿弗他利子孫的後代,照着家室、宗族、人名的數目,從二十歲以外,凡能出去打仗、被數的,共有五萬三千四百名。
43 Iye àwọn tí a kà nínú ẹ̀yà Naftali jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ó lé egbèje.
44 Wọ̀nyí ni àwọn ènìyàn tí Mose àti Aaroni kà, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn olórí méjìlá fún Israẹli, tí ẹnìkọ̀ọ̀kan ṣojú fún ìdílé rẹ̀.
這些就是被數點的,是摩西、亞倫,和以色列中十二個首領所數點的;這十二個人各作各宗族的代表。
45 Gbogbo ọmọkùnrin Israẹli tó jẹ́ ọmọ ogún ọdún sókè, tó sì lè lọ sójú ogun ni wọ́n kà gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn.
這樣,凡以色列人中被數的,照着宗族,從二十歲以外,能出去打仗、被數的,共有六十萬零三千五百五十名。
46 Àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó lé egbèjìdínlógún dín làádọ́ta.
47 A kò ka àwọn ìdílé ẹ̀yà Lefi mọ́ àwọn ìyókù.
利未人卻沒有按着支派數在其中,
48 Nítorí Olúwa ti sọ fún Mose pé,
因為耶和華曉諭摩西說:
49 “Ìwọ kò gbọdọ̀ ka ẹ̀yà Lefi, tàbí kí o kà wọ́n mọ́ àwọn ọmọ Israẹli.
「惟獨利未支派你不可數點,也不可在以色列人中計算他們的總數。
50 Dípò èyí yan àwọn ọmọ Lefi láti jẹ́ alábojútó àgọ́ ẹ̀rí, lórí gbogbo ohun èlò àti ohun gbogbo tó jẹ́ ti àgọ́ ẹ̀rí. Àwọn ni yóò máa gbé àgọ́ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, wọn ó máa mójútó o, kí wọn ó sì máa pàgọ́ yí i ká.
只要派利未人管法櫃的帳幕和其中的器具,並屬乎帳幕的;他們要抬帳幕和其中的器具,並要辦理帳幕的事,在帳幕的四圍安營。
51 Ìgbàkígbà tí àgọ́ yóò bá tẹ̀síwájú, àwọn ọmọ Lefi ni yóò tú palẹ̀, nígbàkígbà tí a bá sì tún pa àgọ́, àwọn ọmọ Lefi náà ni yóò ṣe é. Àlejò tó bá súnmọ́ tòsí ibẹ̀, pípa ni kí ẹ pa á
帳幕將往前行的時候,利未人要拆卸;將支搭的時候,利未人要豎起。近前來的外人必被治死。
52 kí àwọn ọmọ Israẹli pa àgọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn olúkúlùkù ní ibùdó tirẹ̀ lábẹ́ ọ̀págun tirẹ̀.
以色列人支搭帳棚,要照他們的軍隊,各歸本營,各歸本纛。
53 Àwọn ọmọ Lefi yóò jẹ́ alábojútó àti olùtọ́jú àgọ́ ẹ̀rí náà, kí ìbínú má ba à sí lára ìjọ àwọn ọmọ Israẹli; kí àwọn ọmọ Lefi sì máa ṣe ìtọ́jú àgọ́ ẹ̀rí náà.”
但利未人要在法櫃帳幕的四圍安營,免得忿怒臨到以色列會眾;利未人並要謹守法櫃的帳幕。」
54 Àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.
以色列人就這樣行。凡耶和華所吩咐摩西的,他們就照樣行了。

< Numbers 1 >