< Numbers 4 >

1 Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni pé,
Y él Señor dijo a Moisés y a Aarón:
2 “Ka iye àwọn ọmọ Kohati láàrín àwọn ọmọ Lefi nípa ilé baba wọn àti ìdílé wọn.
Los hijos de Coat, de entre los hijos de Leví, sean contados por sus familias, por orden de las casas de sus padres;
3 Ka gbogbo ọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta ọdún gbogbo àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé.
Todos aquellos de treinta a cincuenta años que puedan hacer el trabajo de la Tienda de reunión.
4 “Wọ̀nyí ni iṣẹ́ ìsìn àwọn ọmọ Kohati nínú àgọ́ àjọ, láti tọ́jú àwọn ohun èlò mímọ́ jùlọ.
Y esta es la obra de los hijos de Coat en conexión con las cosas del lugar santísimo.
5 Nígbà tí àgọ́ yóò bá tẹ̀síwájú, Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò wọ inú rẹ̀, wọn yóò sí aṣọ ìbòrí rẹ̀, wọn yóò sì fi bo àpótí ẹ̀rí.
Cuando toda la gente avanza, Aarón debe ir con sus hijos y quitarán el velo de la cortina, cubriendo con él cofre del pacto del testimonio;
6 Wọn yóò sì fi awọ ewúrẹ́ bò ó, lórí awọ ewúrẹ́ yìí ni wọn ó tẹ̀ bọ ààyè rẹ̀.
Y poniendo sobre ella la cubierta de cuero y sobre eso un paño azul; y poniendo sus varillas en su lugar.
7 “Lórí tábìlì àkàrà ìfihàn ni kí wọn ó na aṣọ aláró kan sí, kí wọn kí ó sì fi àwopọ̀kọ́ sórí rẹ̀, àti ṣíbí àti àwokòtò àti ìgò fún ọrẹ ohun mímu; àti àkàrà ìgbà gbogbo ní kí ó wà lórí rẹ̀.
Y sobre la mesa del pan santo deben poner un paño azul, y sobre ella todas las vasijas, las cucharas y los recipientes y las copas; y el pan santo con ellos;
8 Lórí gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni wọn yóò da, wọn ó tún fi awọ ewúrẹ́ bò ó, wọn ó sì fi òpó rẹ̀ bọ ààyè rẹ̀.
Y sobre ellos deben poner un paño rojo, cubrirlo con una cubierta de cuero, y poner sus varillas en sus lugares.
9 “Kí wọn kí ó sì mú aṣọ aláwọ̀ aláró kan, kí wọn kí ó sì fi bo ọ̀pá fìtílà àti fìtílà rẹ̀, àti alumagaji rẹ̀, àti àwo alumagaji rẹ̀, àti gbogbo ohun èlò òróró rẹ̀, èyí tí wọ́n fi ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀.
Y deben llevar una tela azul, cubriendo con ella el candelabro con sus luces y sus instrumentos y sus bandejas y todos los recipientes de aceite que se utilizan para ello:
10 Kí wọn ó fi awọ ẹran yí fìtílà àti gbogbo ohun èlò rẹ, kí wọn kí ó sì gbé e lé orí férémù tí wọn yóò fi gbé e.
Todos estos son para poner en una cubierta de cuero, y ponerlo en una charola.
11 “Ní orí pẹpẹ wúrà ni kí wọn ó tẹ́ aṣọ aláró kan sí, wọn yóò sì fi awọ seali bò ó, kí wọ́n sì fi òpó rẹ̀ bọ ààyè rẹ̀.
Sobre el altar de oro deben poner un paño azul, cubriéndolo con una cubierta de cuero; y han de poner sus varas en sus lugares.
12 “Kí wọn kó gbogbo ohun èlò tí wọ́n ń lò fún iṣẹ́ ìsìn ní ibi mímọ́, kí wọn ó fi aṣọ aláwọ̀ búlúù yìí, kí wọn ó sì fi awọ seali bò ó, kí wọn ó sì fi gbé wọn ka orí férémù.
Todas las vasijas que se usan en el lugar santo deben ponerse en un paño azul, cubrirlas con una cubierta de cuero y colocarlas en la charola.
13 “Kí wọn ó kó eérú kúrò lórí pẹpẹ idẹ, kí wọn ó sì tẹ́ aṣọ aláwọ̀ àlùkò lé e lórí.
Y quitarán los restos quemados del altar, y pondrán sobre ellos un paño púrpura;
14 Nígbà náà ni kí wọn ó kó gbogbo ohun èlò fún iṣẹ́ ìsìn níbi pẹpẹ, títí dórí àwo iná, fọ́ọ̀kì ẹran, ọkọ́ eérú àti àwokòtò. Kí wọn ó fi awọ ewúrẹ́ bo gbogbo rẹ̀, kí wọn ó sì fi òpó rẹ̀ bọ ààyè rẹ̀.
Colocando encima la tela todas sus vasijas, las cestas de fuego, los ganchos de carne, las espadas y las cubetas; todos los vasos del altar; Deben poner una cubierta de cuero sobre todos estos, y poner sus varillas en sus lugares.
15 “Lẹ́yìn tí Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ ti parí bíbo ibi mímọ́ àti gbogbo ohun èlò ibi mímọ́, nígbà tí àgọ́ bá sì ṣetán láti tẹ̀síwájú, kí àwọn ọmọ Kohati bọ́ síwájú láti gbé e, ṣùgbọ́n wọn kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan ohun mímọ́ kankan, bí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀ wọn ó kú. Àwọn ọmọ Kohati ni yóò gbé gbogbo ohun tó wà nínú àgọ́ ìpàdé.
Y después de que el lugar santo y todas sus vasijas hayan sido tapadas por Aarón y sus hijos, cuando las tiendas del pueblo avancen, los hijos de Coat vendrán y lo recogerán; pero las cosas santas no pueden ser tocadas por temor a la muerte.
16 “Iṣẹ́ Eleasari ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà ni ṣíṣe àbojútó òróró fìtílà, tùràrí dídùn, ẹbọ ohun jíjẹ ìgbà gbogbo àti òróró ìtasórí. Kí ó jẹ́ alábojútó gbogbo ohun tó jẹ mọ́ àgọ́ àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀, pẹ̀lú gbogbo ohun èlò ibi mímọ́.”
Y Eleazar, el hijo del sacerdote Aarón, será el responsable del aceite para la luz, y los perfumes aromáticos para el fuego, y la ofrenda de la comida regular, y el aceite santo; La tienda de reunión el lugar santo y todo lo que hay en ella estará bajo su cuidado.
17 Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni pé,
Y él Señor Dijo a Moisés y a Aarón:
18 “Rí i pé a kò gé ẹ̀yà Kohati kúrò lára àwọn ọmọ Lefi.
No dejes que la familia de los Coatitas sea separada de entre los levitas;
19 Nítorí kí wọ́n lè yè, kí wọ́n má ba à kú nígbà tí wọ́n bá súnmọ́ tòsí àwọn ohun mímọ́ jùlọ: Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ ni kí ó wọ ibi mímọ́ láti pín iṣẹ́ oníkálùkù àti àwọn ohun tí wọn yóò gbé.
Pero háganles esto, para que la vida, y no la muerte, sean suyas cuando se acerquen a las cosas más santas; Deja que Aarón y sus hijos entren y entreguen a cada uno su trabajo y lo que debe asumir;
20 Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Kohati kò gbọdọ̀ wọlé láti wo àwọn ohun mímọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ ìṣẹ́jú kan, bí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, wọn yóò kú.”
Pero ellos mismos no deben entrar para ver el lugar santo, ni siquiera por un minuto, por temor a la muerte.
21 Olúwa sọ fún Mose pé,
Y él Señor dijo a Moisés:
22 “Tún ka iye àwọn ọmọ Gerṣoni nípa ilé baba wọn àti ìdílé wọn.
Que los hijos de Gersón sean contados por familias, por orden de las casas de sus padres;
23 Ka gbogbo ọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta ọdún, gbogbo àwọn tó ń wá ṣiṣẹ́ ní àgọ́ ìpàdé.
Todos aquellos de treinta a cincuenta años que pueden hacer el trabajo de la Tienda de reunión.
24 “Èyí ni iṣẹ́ ìsìn ìdílé àwọn ọmọ Gerṣoni, bí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ àti ní ẹrù rírù.
Esta es la obra de los gersonitas, las cosas que deben hacer y asumir.
25 Àwọn ni yóò máa ru àwọn aṣọ títa ti àgọ́, ti àgọ́ ìpàdé àti ìbòrí rẹ̀, àti awọ ewúrẹ́ tí a fi bò ó, aṣọ títa ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé,
Deben tomar las cortinas del santuario, y la Tienda de reunión con su tapa y la cubierta de cuero sobre ella, y las cortinas para la puerta de la Tienda de reunión;
26 aṣọ títa ti àgbàlá tó yí àgọ́ àti pẹpẹ ká, aṣọ títa ti ẹnu-ọ̀nà àbáwọlé sí àgbàlá, okùn àti àwọn ohun èlò iṣẹ́ ìsìn, àti ohun gbogbo tí à ń lò fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn ó máa sìn. Àwọn ọmọ Gerṣoni ni yóò ṣe gbogbo ohun tó bá yẹ pẹ̀lú àwọn nǹkan wọ̀nyí.
Y las cortinas para el atrio y alrededor de la Tienda y él altar y la cortina para su entrada, con las cuerdas y todas las cosas que se usaron para ellos; Lo que sea necesario, para su oficio y trabajo.
27 Gbogbo iṣẹ́ ìsìn àwọn ọmọ Gerṣoni yálà ni iṣẹ́ ṣíṣe tàbí ní ẹrù rírù ni, Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ ni yóò máa darí wọn; ìwọ ni kí o sì yàn ẹrù tí oníkálùkù yóò rù fún un.
De la boca de Aarón y de sus hijos, los gersonitas tendrán noticias acerca de todas las cosas que deben hacer y tomar; Tú debes darles sus órdenes de lo que deben de hacer.
28 Èyí ni iṣẹ́ ìdílé àwọn Gerṣoni ni àgọ́ ìpàdé Itamari, ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà ni yóò sì jẹ alábojútó iṣẹ́ wọn.
Esta es la obra de la familia de los gersonitas en la Tienda de reunión, y estarán bajo la dirección de Itamar, el hijo del sacerdote Aarón.
29 “Ka iye àwọn ọmọ Merari nípa ilé baba wọn àti ìdílé wọn.
Los hijos de Merari serán contados por familias, en el orden de las casas de sus padres;
30 Ka gbogbo ọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta ọdún, gbogbo àwọn tó ń wá ṣiṣẹ́ ní àgọ́ ìpàdé.
Cada uno de treinta a cincuenta años que pueda hacer el trabajo de la Tienda de reunión.
31 Iṣẹ́ tí wọn yóò sì máa ṣe nínú àgọ́ ìpàdé nìyìí: gbígbẹ́ àwọn férémù àgọ́, pákó ìdábùú rẹ̀, òpó àti ihò òpó rẹ̀,
Y esta es su parte en el trabajo de la Tienda de reunión: el transporte de las tablas y las varillas de la tienda, con los pilares y sus basas;
32 pẹ̀lú gbogbo òpó tó yí àgbàlá ká àti ohun èlò tó jẹ mọ́ lílò wọn, kí o sì yan ohun tí oníkálùkù yóò rù fún un.
Y los pilares del atrio fuera de él, con sus basas y sus estacas y cuerdas y todos los instrumentos utilizados, y todo lo que debe hacerse allí; todos los instrumentos de los que son responsables deben ser numerados por su nombre.
33 Èyí ni iṣẹ́ ìsìn ìdílé àwọn ọmọ Merari, bí wọn yóò ti máa ṣiṣẹ́ ní àgọ́ ìpàdé lábẹ́ àkóso Itamari ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà.”
Este es el trabajo que los hijos de Merari deben hacer en relación con la Tienda de reunión, bajo la dirección de Itamar, el hijo de Aarón el sacerdote.
34 Mose àti Aaroni pẹ̀lú àwọn olórí ìjọ ènìyàn ka àwọn ọmọ Kohati nípa ìdílé àti ilé baba wọn.
Entonces Moisés, Aarón y los jefes del pueblo tomaron en sus manos la numeración de los hijos de los Coatitas, por familias, por orden de las casas de sus padres;
35 Gbogbo ọmọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta ọdún gbogbo àwọn tó ń wá ṣiṣẹ́ ní Àgọ́ ìpàdé.
Numerar a todos aquellos de treinta a cincuenta años que pudieron hacer el trabajo en la Tienda de reunión;
36 Iye wọn nípa ìdílé jẹ́ ẹgbẹ̀rìnlá ó dín làádọ́ta.
Y el número de todos estos fue dos mil setecientos cincuenta.
37 Èyí ni àpapọ̀ iye àwọn ọmọ Kohati tó ń ṣiṣẹ́ ní àgọ́ ìpàdé; tí Mose àti Aaroni kà gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún Mose.
Este es el número de aquellos de Coat que hicieron el trabajo en la Tienda de la reunión, ya que fueron contados por Moisés y Aarón por orden del Señor.
38 Wọ́n ka àwọn ọmọ Gerṣoni nípa ìdílé àti ilé baba wọn.
Y los de los hijos de Gersón, que fueron contados por familias,
39 Gbogbo ọmọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta, gbogbo àwọn tó lè ṣiṣẹ́ ní àgọ́ ìpàdé.
Todos aquellos de treinta a cincuenta años que pudieron hacer el trabajo en la Tienda de reunión,
40 Iye wọn nípa ìdílé àti ilé baba wọn jẹ́ ẹgbẹ̀tàlá ó lé ọgbọ̀n.
Los que fueron contados por familias en el orden de las casas de sus padres, fueron dos mil seiscientos treinta.
41 Èyí jẹ́ àpapọ̀ iye àwọn ọmọ Gerṣoni, àwọn tó ṣiṣẹ́ ní àgọ́ ìpàdé. Mose àti Aaroni ṣe bí àṣẹ Olúwa.
Este es el número de los hijos de Gersón que hicieron el trabajo en la Tienda de reunión, ya que fueron contados por Moisés y Aarón por orden del Señor.
42 Wọ́n ka àwọn ọmọ Merari nípa ìdílé àti ilé baba wọn.
Y los de los hijos de Merari, que fueron contados por familias, por orden de las casas de sus padres,
43 Gbogbo ọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta ọdún, àwọn tó ṣiṣẹ́ ní àgọ́ ìpàdé.
Todos los de treinta a cincuenta años que hicieron el trabajo en la Tienda de reunión,
44 Iye wọn nípa ìdílé àti ilé baba wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rìndínlógún.
Que fueron contados por familias, eran tres mil doscientos.
45 Èyí ni àpapọ̀ iye àwọn ọmọ Merari. Mose àti Aaroni kà wọ́n gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa láti ẹnu Mose.
Este es el número de los hijos de Merari, numerados por Moisés y Aarón por orden del Señor.
46 Gbogbo àwọn tí a kà nínú àwọn ọmọ Lefi, ti Mose àti Aaroni àti àwọn olórí Israẹli kà, nípa ìdílé wọn àti gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn.
Y todos los levitas que fueron contados por Moisés y Aarón, y los jefes del pueblo, por familias, por orden de las casas de sus padres,
47 Gbogbo ọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta, àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ìsìn tó sì ń ru àwọn ẹrù inú Àgọ́ ìpàdé.
Los de treinta a cincuenta años que pudieron hacer el trabajo de la Tienda de reunión y de su transporte.
48 Àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ẹgbẹ̀tàlá lé lẹ́gbàarin ó dín ogún.
Llegó a ocho mil quinientos ochenta.
49 Wọ́n yan iṣẹ́ àti àwọn ohun tí ẹni kọ̀ọ̀kan yóò máa gbé fún un gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ láti ẹnu Mose. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe kà wọ́n gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.
Por orden del Señor fueron contados por Moisés, cada uno en relación con su trabajo y con su parte en el transporte; así fueron contados por Moisés por orden del Señor.

< Numbers 4 >