< Numbers 33 >

1 Wọ̀nyí ni ìrìnàjò àwọn ọmọ Israẹli ní ẹsẹẹsẹ, nígbà tí wọ́n tí ilẹ̀ Ejibiti jáde wá pẹ̀lú àwọn ogun wọn, nípa ọwọ́ Mose àti Aaroni.
This is a record of the journeys made by the Israelites as they left Egypt in their tribal divisions led by Moses and Aaron.
2 Mose sì kọ̀wé ìjáde lọ wọn ní ẹsẹẹsẹ gẹ́gẹ́ bí ìrìnàjò wọn, nípa àṣẹ Olúwa, wọ̀nyí sì ni ìrìnàjò wọn gẹ́gẹ́ bí ìjáde lọ wọn.
Moses recorded the different parts of their journey as instructed by the Lord. These are the journeys they made listed in order from where they started:
3 Àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò láti Ramesesi ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù kìn-ín-ní, ọjọ́ kan lẹ́yìn àjọ ìrékọjá. Wọ́n yan jáde pẹ̀lú ìgboyà níwájú gbogbo àwọn ará Ejibiti.
The Israelites left Rameses on the fifteenth day of the first month, the day after the Passover. They set out in triumph as all the Egyptians watched.
4 Tí wọ́n sì ń sin gbogbo àkọ́bí wọn, ẹni tí Olúwa ti gbé lulẹ̀ láàrín wọn; nítorí tí Olúwa ti mú ẹ̀san wá sórí àwọn òrìṣà wọn.
The Egyptians were burying all their firstborn that the Lord had killed, for the Lord had brought down his judgments on their gods.
5 Àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní Ramesesi wọ́n sì pàgọ́ sí Sukkoti.
The Israelites left Rameses and set up camp at Succoth.
6 Wọ́n kúrò ní Sukkoti, wọ́n sì pàgọ́ sí Etamu, ní ẹ̀bá aginjù.
They moved on from Succoth and set up camp at Etham, on the edge of the desert.
7 Wọ́n kúrò ní Etamu, wọ́n padà sí Pi-Hahirotu sí ìlà-oòrùn Baali-Ṣefoni, wọ́n sì pàgọ́ sí ẹ̀bá Migdoli.
They moved on from Etham, turning back towards Pi-hahiroth, opposite Baal-zephon, and set up camp near Migdol.
8 Wọ́n sì dìde láti lọ kúrò ní iwájú Pi-Hahirotu, wọ́n sì la àárín òkun kọjá lọ sí aginjù. Wọ́n sì rin ìrìn ọjọ́ mẹ́ta ní aginjù Etamu, wọ́n sì pàgọ́ sí Mara.
They moved on from Pi-hahiroth and crossed through the middle of the sea into the desert. They traveled on for three days into the Desert of Etham and set up camp at Marah.
9 Wọ́n kúrò ní Mara wọ́n sì lọ sí Elimu, níbi tí orísun omi méjìlá àti igi ọ̀pẹ àádọ́rin gbé wà, wọ́n sì pàgọ́ níbẹ̀.
They moved on from Marah and arrived at Elim, where there were twelve springs of water and seventy palm trees, and set up camp there.
10 Wọ́n kúrò ní Elimu wọ́n sì pàgọ́ sí ẹ̀bá Òkun Pupa.
They moved on from Elim and set up camp beside the Red Sea.
11 Wọ́n kúrò ní ẹ̀bá Òkun Pupa wọ́n sì pàgọ́ sínú aginjù Sini.
They moved on from the Red Sea and set up camp in the Desert of Sin.
12 Wọ́n kúrò nínú aginjù Sini wọ́n sì pàgọ́ sí aginjù Dofka.
They moved on from the Desert of Sin and set up camp at Dophkah.
13 Wọ́n kúrò ní Dofka wọ́n sì pàgọ́ ní Aluṣi.
They moved on from Dophkah and set up camp at Alush.
14 Wọ́n kúrò ní Aluṣi wọ́n sì pàgọ́ ní Refidimu níbi tí kò sí omi fún àwọn ènìyàn náà láti mu.
They moved on from Alush and set up camp at Rephidim. There wasn't any water there for the people to drink.
15 Wọ́n kúrò ní Refidimu wọ́n sì pàgọ́ ní aginjù Sinai.
They moved on from Rephidim and set up camp in the Sinai Desert.
16 Wọ́n kúrò ní aginjù Sinai wọ́n sì pàgọ́ ní Kibirotu-Hattaafa.
They moved on from the Sinai Desert and set up camp at Kibroth-hattaavah.
17 Wọ́n kúrò ní Kibirotu-Hattaafa wọ́n sì pàgọ́ ní Haserotu.
They moved on from Kibroth-hattaavah and set up camp at Hazeroth.
18 Wọ́n kúrò ní Haserotu wọ́n sì pàgọ́ ní Ritma.
They moved on from Hazeroth and set up camp at Rithmah.
19 Wọ́n kúrò ní Ritma wọ́n sì pàgọ́ ní Rimoni-Peresi.
They moved on from Rithmah and set up camp at Rimmon-perez.
20 Wọ́n kúrò ní Rimoni-Peresi wọ́n sì pàgọ́ ní Libina.
They moved on from Rimmon-perez and set up camp at Libnah.
21 Wọ́n kúrò ní Libina wọ́n sì pàgọ́ ní Rissa.
They moved on from Libnah and set up camp at Rissah.
22 Wọ́n kúrò ní Rissa wọ́n sì pàgọ́ ní Kehelata.
They moved on from Rissah and set up camp at Kehelathah.
23 Wọ́n kúrò ní Kehelata wọ́n sì pàgọ́ ní orí òkè Ṣeferi.
They moved on from Kehelathah and set up camp at Mount Shepher.
24 Wọ́n kúrò lórí òkè Ṣeferi wọ́n sì pàgọ́ ní Harada.
They moved on from Mount Shepher and set up camp at Haradah.
25 Wọ́n kúrò ní Harada wọ́n sì pàgọ́ ní Makhelotu.
They moved on from Haradah and set up camp at Makheloth.
26 Wọ́n kúrò ní Makhelotu wọ́n sì pàgọ́ ní Tahati.
They moved on from Makheloth and set up camp at Tahath.
27 Wọ́n kúrò ní Tahati wọ́n sì pàgọ́ ní Tẹra.
They moved on from Tahath and set up camp at Terah.
28 Wọ́n kúrò ní Tẹra wọ́n sì pàgọ́ ní Mitka.
They moved on from Terah and set up camp at Mithkah.
29 Wọ́n kúrò ní Mitka wọ́n pàgọ́ ní Haṣmona.
They moved on from Mithkah and set up camp at Hashmonah.
30 Wọ́n kúrò ní Haṣmona wọ́n sì pàgọ́ ní Moserotu.
They moved on from Hashmonah and set up camp at Moseroth.
31 Wọ́n kúrò ní Moserotu wọ́n sì pàgọ́ ní Bene-Jaakani.
They moved on from Moseroth and set up camp at Bene-jaakan.
32 Wọ́n kúrò ní Bene-Jaakani wọ́n sì pàgọ́ ní Hori-Haggidgadi.
They moved on from Bene-jaakan and set up camp at Hor-haggidgad.
33 Wọ́n kúrò ní Hori-Haggidgadi wọ́n sí pàgọ́ ní Jotbata.
They moved on from Hor-haggidgad and set up camp at Jotbathah.
34 Wọ́n kúrò ní Jotbata wọ́n sì pàgọ́ ní Abrona.
They moved on from Jotbathah and set up camp at Abronah.
35 Wọ́n kúrò ní Abrona wọ́n sì pàgọ́ ní Esioni-Geberi.
They moved on from Abronah and set up camp at Ezion-geber.
36 Wọ́n kúrò ní Esioni-Geberi wọ́n sì pàgọ́ ní Kadeṣi nínú aginjù Sini.
They moved on from Ezion-geber and set up camp at Kadesh in the Desert of Zin.
37 Wọ́n kúrò ní Kadeṣi wọ́n sì pàgọ́ ní orí òkè Hori, lẹ́bàá Edomu.
They moved on from Kadesh and set up camp at Mount Hor, on the edge of Edom.
38 Nípa àṣẹ Olúwa, Aaroni àlùfáà gùn orí òkè Hori, níbẹ̀ ni ó kú. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù karùn-ún, ọdún ogójì, lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Israẹli ti ilẹ̀ Ejibiti jáde wá.
Aaron the priest climbed Mount Hor as the Lord had directed, and he died there on the first day of the fifth month, in the fortieth year after the Israelites had left Egypt.
39 Aaroni jẹ́ ẹni ọgọ́fà ọdún ó lé mẹ́ta ní ìgbà tí ó kú sí orí òkè Hori.
Aaron was 123 when he died on Mount Hor.
40 Àwọn ará Kenaani, ọba Aradi, tí ń gbé ìhà gúúsù ní ilẹ̀ Kenaani gbọ́ pé àwọn ọmọ Israẹli ń bọ̀.
(The Canaanite king of Arad, who lived in the Negev in the country of Canaan, found out that the Israelites were on their way.)
41 Wọ́n kúrò ní orí òkè Hori, wọ́n sì pàgọ́ ní Salmona.
The Israelites moved on from Mount Hor and set up camp at Zalmonah.
42 Wọ́n kúrò ní Salmona wọ́n sì pàgọ́ ní Punoni.
They moved on from Zalmonah and set up camp at Punon.
43 Wọ́n kúrò ní Punoni wọ́n sì pàgọ́ ní Obotu.
They moved on from Punon and set up camp at Oboth.
44 Wọ́n kúrò ní Obotu wọ́n sì pàgọ́ ní Iye-Abarimu, ní agbègbè Moabu.
They moved on from Oboth and set up camp at Iye-abarim on the border of Moab.
45 Wọ́n kúrò ní Iyimu, wọ́n sì pàgọ́ ní Diboni-Gadi.
They moved on from Iye-abarim and set up camp at Dibon-gad.
46 Wọ́n kúrò ní Diboni-Gadi wọ́n sì pàgọ́ ní Alimon-Diblataimu.
They moved on from Dibon-gad and set up camp at Almon-diblathaim.
47 Wọ́n kúrò ní Alimon-Diblataimu wọ́n sì pàgọ́ sí orí òkè Abarimu lẹ́bàá Nebo.
They moved on from Almon-diblathaim and set up camp in the mountains of Abarim opposite Nebo.
48 Wọ́n kúrò ní orí òkè Abarimu wọ́n sì pàgọ́ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu lẹ́bàá Jordani ní ìkọjá Jeriko.
They moved on from the mountains of Abarim and set up camp on the plains of Moab beside the Jordan opposite Jericho.
49 Níbí ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu wọ́n pàgọ́ lẹ́gbẹ́ Jordani láti Beti-Jeṣimoti títí dé Abeli-Ṣittimu.
There on the plains of Moab they set up camp beside the Jordan, from Beth-jeshimoth to Abel-shittim.
50 Ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu, lẹ́bàá Jordani, létí Jeriko, Olúwa sọ fún Mose pé,
This was where, on the plains of Moab beside the Jordan opposite Jericho, that the Lord told Moses,
51 “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli kí o sì wí fún wọn pé, ‘Ní ìgbà tí ẹ̀yin bá ń rékọjá odò Jordani lọ sí Kenaani,
“Tell the Israelites, ‘Once you cross the Jordan and enter the country of Canaan,
52 lé gbogbo àwọn ará ilẹ̀ náà kúrò níwájú yín. Run gbogbo àwòrán ère wọn àti gbogbo ère dídá wọn, kí ẹ sì wó gbogbo ibi gíga wọn palẹ̀.
you must drive out everyone living in the land, destroy all their carved images and metal idols, and tear down all their pagan temples.
53 Ẹ gba ilẹ̀ náà, kí ẹ̀yin sì máa gbé inú rẹ̀, nítorí èmi ti fi ilẹ̀ náà fún yín gẹ́gẹ́ bí ìní yín.
You are to take over the country and settle there, because I have given you the land and it belongs to you.
54 Ẹ̀yin pín ilẹ̀ náà pẹ̀lú kèké, gẹ́gẹ́ bí ìdílé yín. Fún ọ̀pọ̀ ni kí ẹ̀yin ó fi ilẹ̀ ìní púpọ̀ fún, àti fún díẹ̀, ni kí ẹ̀yin kí ó fi ilẹ̀ ìní díẹ̀ fún. Ohunkóhun tí ó bá bọ́ sí ọ̀dọ̀ wọn nípa kèké yóò jẹ́ tiwọn. Pín wọn gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà ìran wọn.
You are to divide the land and allocate it by lot to the different tribal families. Give a larger portion to a larger family, and a smaller portion to a smaller family. Each one's allocation is decided by lot, and you will all receive an allocation depending on your tribe.
55 “‘Ṣùgbọ́n bí ẹ kò bá lé àwọn ará ilẹ̀ náà kúrò níwájú yín, àwọn tí ẹ bá jẹ́ kí ó kù yóò di ọfà nínú ojú yín, àti ẹ̀gún ní ìhà yín. Wọn yóò fún yín ní wàhálà ní ilẹ̀ náà tí ẹ̀yin yóò gbé.
But if you don't drive out everyone living in the land, the people you allow to remain will be like grit in your eyes and thorns in your sides. They will cause you trouble where you settle in the country.
56 Nígbà náà, èmi yóò ṣe sí yín, ohun tí mo ti rò láti ṣe sí wọn.’”
Eventually the punishment I planned for them I will inflict on you.”

< Numbers 33 >