< Numbers 28 >

1 Olúwa sọ fún Mose pé,
Yahweh spoke to Moses and said,
2 “Fún àwọn ọmọ Israẹli ní òfin yìí kí o sì wí fún wọn pé: ‘Ẹ rí i wí pé ẹ gbé e wá sí iwájú mi ní àkókò tí a ti yàn, oúnjẹ ọrẹ ẹbọ mi tí a fi iná ṣe sí mi, gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn sí mi.’
“Command the people of Israel and say to them, 'You must offer sacrifices to me at the appointed times, the food of my offerings made by fire to produce a sweet aroma for me.'
3 Sọ fún wọn, ‘Èyí ní ọrẹ ẹbọ tí a fi iná sun tí ẹ gbọdọ̀ mú wá fún Olúwa: akọ ọ̀dọ́-àgùntàn méjì ọlọ́dún kan aláìlábàwọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sísun ní ojoojúmọ́.
You must also say to them, 'This is the offering made by fire that you must offer to Yahweh—male lambs a year old without blemish, two each day, as a regular burnt offering.
4 Pèsè ọ̀dọ́-àgùntàn kan ní òwúrọ̀ àti òmíràn ní àfẹ̀mọ́júmọ́.
One lamb you must offer in the morning, and the other lamb you must offer in the evening.
5 Pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ tí ó jẹ́ ìdámẹ́wàá efa ìyẹ̀fun dáradára tí a pò mọ́ ìdámẹ́rin hínì òróró tí a yọ lára Olifi.
You must offer a tenth of an ephah of fine flour as a grain offering, mixed with one-fourth of a hin of beaten oil.
6 Èyí ni ẹbọ sísun gbogbo ìgbà tí a fi lélẹ̀ ní òkè Sinai gẹ́gẹ́ bí olóòórùn dídùn ẹbọ tí a fi iná sun fún Olúwa pẹ̀lú iná.
This is the regular burnt offering that was commanded at Mount Sinai to produce a sweet aroma, an offering made by fire to Yahweh.
7 Àfikún ọrẹ ohun mímu rẹ gbọdọ̀ jẹ́ ìdámẹ́rin ti hínì dídé omi mímu tí ó kan pẹ̀lú ọ̀kọ̀ọ̀kan ọ̀dọ́-àgùntàn. Da ẹbọ mímu náà síta sí Olúwa ní ibi mímọ́.
The drink offering with it must be one-fourth of a hin for one of the lambs. You must pour out in the holy place a drink offering of strong drink to Yahweh.
8 Pèsè ọ̀dọ́-àgùntàn kejì ní àfẹ̀mọ́júmọ́, pẹ̀lú oríṣìí ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu èyí tí ó pèsè ní òwúrọ̀, èyí ni ẹbọ tí a fi iná ṣe, olóòórùn dídùn sí Olúwa.
The other lamb you must offer in the evening along with another grain offering like the one offered in the morning. You must also offer another drink offering with it, an offering made by fire, to produce a sweet aroma for Yahweh.
9 “‘Ní ọjọ́ ìsinmi, pèsè akọ ọ̀dọ́-àgùntàn méjì ọlọ́dún kan tí kò lábùkù, pẹ̀lú ẹbọ ohun mímu àti ẹbọ ohun jíjẹ tí i ṣe ìdá méjì nínú ìdámẹ́wàá òsùwọ̀n ìyẹ̀fun tí a fi òróró pò.
On the Sabbath day you must offer two male lambs, each a year old without blemish, and two-tenths of an ephah of fine flour as a grain offering, mixed with oil, and the drink offering with it.
10 Èyí ni ẹbọ sísun fún gbogbo ọjọ́ ìsinmi kọ̀ọ̀kan, ní àfikún pẹ̀lú ẹbọ sísun àti ẹbọ ohun mímu.
This is to be the burnt offering for every Sabbath, in addition to the regular burnt offering and the drink offering with it.
11 “‘Àti ní ọjọ́ tí o bẹ̀rẹ̀ oṣù kọ̀ọ̀kan, kí ẹ̀yin kí ó gbé ẹbọ sísun fún Olúwa pẹ̀lú ọ̀dọ́ akọ màlúù méjì, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn méje ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan, kí gbogbo rẹ̀ sì jẹ́ aláìlábùkù.
At the beginning of each month, you must offer a burnt offering to Yahweh. You must offer two young bulls, one ram, and seven male lambs a year old without blemish.
12 Pẹ̀lú akọ màlúù kọ̀ọ̀kan ni kí wọn ó rú ẹbọ ohun jíjẹ ẹbọ ìdámẹ́ta nínú mẹ́wàá ìyẹ̀fun tí a pòpọ̀ pẹ̀lú òróró; pẹ̀lú àgbò, ni kí wọn ó rú ẹbọ ohun jíjẹ tí í ṣe ìdá méjì nínú mẹ́wàá òsùwọ̀n ìyẹ̀fun tí a pòpọ̀ mọ́ òróró;
You must also offer three-tenths of an ephah of fine flour as a grain offering mixed with oil for each bull, and two-tenths of fine flour as a grain offering mixed with oil for the one ram.
13 pẹ̀lú ọ̀kọ̀ọ̀kan ọ̀dọ́-àgùntàn, ni kí ẹ rú ẹbọ ìyẹ̀fun ìyẹ̀fun kíkúnná tí a pò mọ́ òróró. Èyí ni ẹbọ sísun, òórùn dídùn, àti ẹbọ tí a ṣe fún Olúwa pẹ̀lú iná.
You must also offer a tenth of an ephah of fine flour mixed with oil as a grain offering for each lamb. This is to be the burnt offering, to produce a sweet aroma, an offering made by fire to Yahweh.
14 Kí ẹbọ ohun mímu wọn jẹ́ ààbọ̀ òsùwọ̀n hínì ti ọtí wáìnì, fún akọ màlúù kan, àti ìdámẹ́wàá òsùwọ̀n hínì fún àgbò kan àti ìdámẹ́rin òsùwọ̀n hínì fún ọ̀dọ́-àgùntàn kan. Èyí ni ẹbọ sísun tí wọn ó máa rú ní oṣù kọ̀ọ̀kan nínú ọdún.
The people's drink offerings must be half a hin of wine for a bull, a third of a hin for a ram, and one-fourth of a hin for a lamb. This is to be the burnt offering for every month throughout the months of the year.
15 Yàtọ̀ sí ẹbọ sísun pẹ̀lú ẹbọ ohun mímu, ẹ gbọdọ̀ fi akọ ewúrẹ́ kọ̀ọ̀kan fún Olúwa gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.
One male goat as a sin offering to Yahweh must be offered. This will be in addition to the regular burnt offering and the drink offering with it.
16 “‘Ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìn-ín-ní ni ìrékọjá Olúwa gbọdọ̀ wáyé.
During the first month, on the fourteenth day of the month, comes Yahweh's Passover.
17 Ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù yìí ẹ gbọdọ̀ ṣiṣẹ́ àjọ̀dún fún ọjọ́ méje kí ó jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà.
On the fifteenth day of this month a feast is to be held. For seven days, bread without yeast must be eaten.
18 Ní ọjọ́ kìn-ín-ní kí àpéjọ mímọ́ kí ó wà; ẹ́yin kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ agbára kankan.
On the first day, there must be a holy assembly to honor Yahweh. You must not do regular work on that day.
19 Ẹ rú ẹbọ sísun sí Olúwa, ẹ rú u pẹ̀lú ọ̀dọ́ màlúù méjì akọ, ẹbọ sísun pẹ̀lú iná àgbò kan àti ọ̀dọ́-àgùntàn méje ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan kí wọn kí ó jẹ́ aláìlábùkù.
However, you must offer a sacrifice made by fire, a burnt offering to Yahweh. You must offer two young bulls, one ram, and seven male lambs a year old, without blemish.
20 Pẹ̀lú akọ màlúù kọ̀ọ̀kan ni kí ẹ pèsè ẹbọ ohun mímu pẹ̀lú ìdámẹ́ta nínú mẹ́wàá ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò; pẹ̀lú àgbò, ìdá méjì nínú mẹ́wàá;
Along with the bull, you must offer a grain offering of three-tenths of an ephah of fine flour mixed with oil, and along with the ram, two-tenths.
21 pẹ̀lú ọ̀dọ́-àgùntàn kọ̀ọ̀kan ìdákan nínú mẹ́wàá.
With each of the seven lambs, you must offer a tenth of an ephah of fine flour mixed with oil,
22 Pẹ̀lú òbúkọ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣètùtù fún un yín.
and one male goat as a sin offering to make atonement for yourselves.
23 Ṣe eléyìí ní àfikún sí ẹbọ sísun àràárọ̀.
You must offer these in addition to the regular burnt offering required each morning.
24 Báyìí ní kí ẹ̀yin rúbọ ní ọjọọjọ́, jálẹ̀ ní ọjọ́ méjèèje, oúnjẹ ẹbọ tí a fi iná ṣe, tí olóòórùn dídùn sí Olúwa; ó rú u pẹ̀lú ẹbọ sísun ìgbà gbogbo, àti ẹbọ ohun mímu.
As described here, you must offer these sacrifices daily, for the seven days of the Passover, the food of the offering made by fire, a sweet aroma for Yahweh. It must be offered in addition to the regular burnt offering and the drink offering with it.
25 Ní ọjọ́ keje kí ẹ̀yin kí ó ní àpéjọ mímọ́, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan.
On the seventh day you must have a holy assembly to honor Yahweh, and you must not do regular work on that day.
26 “‘Ní ọjọ́ àkọ́so pẹ̀lú, nígbà tí ẹ̀yin bá mú ẹbọ ohun jíjẹ tuntun wá fún Olúwa lẹ́yìn àsìkò àjọ̀dún, kí ẹ̀yin kí ó ní àpéjọ mímọ́, ẹ̀yin kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan.
Also on the day of the firstfruits, when you offer a new grain offering to Yahweh in your Festival of Weeks, you must have a holy assembly to honor Yahweh, and you must not do regular work on that day.
27 Kí ẹ mú ẹbọ sísun ẹgbọrọ màlúù méjì, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn méje ọlọ́dún kan gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn fún Olúwa.
You must offer a burnt offering to produce a sweet aroma for Yahweh. You must offer two young bulls, one ram, and seven male lambs a year old.
28 Pẹ̀lú ọ̀kọ̀ọ̀kan akọ màlúù ní kí ẹ rú ẹbọ ohun mímu ìdámẹ́ta pẹ̀lú òsùwọ̀n ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò pẹ̀lú àgbò kan.
Offer also grain offering to go with them: Fine flour mixed with oil, three-tenths of an ephah of fine flour mixed with oil for each bull and two-tenths for the one ram.
29 Àti pẹ̀lú ọ̀kọ̀ọ̀kan ọ̀dọ́-àgùntàn méje, kí ó jẹ́ ìdákan nínú mẹ́wàá.
Offer a tenth of an ephah of fine flour mixed with oil for each of the seven lambs,
30 Ẹ fi òbúkọ kan ṣe ètùtù fún ara yín.
and one male goat to make atonement for yourselves.
31 Kí ẹ̀yin kí ó rú wọn pẹ̀lú ẹbọ sísun ìgbà gbogbo, àti ẹbọ ohun mímu yín àti ẹbọ ohun jíjẹ yín. Kí ẹ sì ri dájú pé àwọn ẹranko náà jẹ́ aláìlábùkù.
When you offer those animals without blemish, along with their drink offerings, this must be in addition to the regular burnt offering and the grain offering with it.'”

< Numbers 28 >