< Numbers 27 >

1 Ọmọbìnrin Selofehadi ọmọ Heferi, ọmọ Gileadi, ọmọ Makiri ọmọ Manase tó jẹ́ ìdílé Manase, ọmọ Josẹfu wá. Orúkọ àwọn ọmọbìnrin náà ni Mahila, Noa, Hogla, Milka àti Tirsa.
Then to Moses came the daughters of Zelophehad son of Hepher son of Gilead son of Machir son of Manasseh, of the clans of Manasseh son of Joseph. These were the names of his daughters: Mahlah, Noah, Hoglah, Milkah, and Tirzah.
2 Wọ́n súnmọ́ ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé wọ́n sì dúró níwájú Mose, àti Eleasari àlùfáà, àti níwájú àwọn olórí àti ìjọ, wọ́n sì wí pé,
They stood before Moses, Eleazar the priest, the leaders, and before all the community at the entrance to the tent of meeting. They said,
3 “Baba wa kú sí aginjù. Kò sí lára àwọn ẹgbẹ́ Kora tí wọ́n kó ara wọn pọ̀ lòdì sí Olúwa, ṣùgbọ́n ó kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ kò sì fi ọmọkùnrin sílẹ̀.
“Our father died in the wilderness. He was not among those who conspired against Yahweh in the company of Korah. He died for his own sin, and he had no sons.
4 Kín ni ó dé tí orúkọ baba wa yóò parẹ́ nínú ìdílé rẹ̀ nítorí pé kò ní ọmọkùnrin? Fún wa ní ilẹ̀ ìní láàrín àwọn arákùnrin baba wa.”
Why should our father's name be taken away from among his clan members because he had no son? Give us land among our father's relatives.”
5 Nígbà náà Mose mú ọ̀rọ̀ wọn wá síwájú Olúwa.
So Moses brought their case before Yahweh.
6 Olúwa sì wí fún un pé,
Yahweh spoke to Moses and said,
7 “Ohun tí àwọn ọmọbìnrin Selofehadi ń sọ tọ̀nà. O gbọdọ̀ fún wọn ní ogún ìní ti baba wọn.
“Zelophehad's daughters are speaking correctly. You must certainly give them land as an inheritance among their father's relatives, and you must ensure that their father's inheritance passes on to them.
8 “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli, ‘Tí ọkùnrin kan bá kú tí kò sì fi ọmọkùnrin sáyé, ẹ fún àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ ní ogún ìní rẹ̀.
You must speak to the people of Israel and say, 'If a man dies and has no son, then you must cause his inheritance to pass to his daughter.
9 Tí kò bá ní ọmọbìnrin, fi ohun ìní rẹ́ fún àwọn arákùnrin rẹ̀.
If he has no daughter, then you must give his inheritance to his brothers.
10 Tí kò bá ní arákùnrin, fi ogún ìní rẹ̀ fún arákùnrin baba rẹ̀.
If he has no brothers, then you must give his inheritance to his father's brothers.
11 Tí baba rẹ̀ kò bá ní arákùnrin, fún ará ilé rẹ̀ tí ó bá súnmọ́ jù ní ìdílé rẹ̀ ní ogún ìní rẹ̀, kí ó lè jogún rẹ̀. Èyí gbọdọ̀ jẹ́ ìlànà ìdájọ́ fún àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.’”
If his father has no brothers, then you must give his inheritance to his nearest relative in his clan, and he must take it for his own. This will be a law established by decree for the people of Israel, as Yahweh has commanded me.'”
12 Nígbà náà Olúwa sọ fún Mose pé, “Lọ sì orí òkè Abarimu yìí, kí o sì lọ wo ilẹ̀ tí mo fún àwọn ọmọ Israẹli.
Yahweh said to Moses, “Go up the mountains of Abarim and look at the land that I have given to the people of Israel.
13 Lẹ́yìn ìgbà tí o bá sì ti rí i, ìwọ náà yóò darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn rẹ gẹ́gẹ́ bí Aaroni arákùnrin rẹ ṣe ṣe,
After you have seen it, you, too, must be gathered to your people, like Aaron your brother.
14 nítorí nígbà tí ìlú ṣọ̀tẹ̀ níbi omi ní aginjù Sini, tí gbogbo yín ṣe àìgbọ́ràn sí mi láti yà mí sí mímọ́ níwájú wọn.” (Èyí ni omi Meriba ní Kadeṣi ní aginjù Sini.)
This will happen because you two rebelled against my command in the wilderness of Zin. There, when the water flowed from the rock, in your anger you failed to honor me as holy before the eyes of the whole community.” These are the waters of Meribah of Kadesh in the wilderness of Zin.
15 Mose sọ fún Olúwa wí pé,
Then Moses spoke to Yahweh and said,
16 “Jẹ́ kí Olúwa, Ọlọ́run ẹ̀mí gbogbo ènìyàn, kí ó yan ọkùnrin kan sí orí ìjọ ènìyàn yìí,
“May you, Yahweh, the God of the spirits of all humanity, appoint a man over the community,
17 láti máa darí wọn, ẹni tí yóò mú wọn jáde, tí yóò sì mú wọn wọlé, gbogbo ènìyàn Olúwa kí yóò dàbí àgùntàn tí kò ní olùṣọ́.”
a man who may go out and come in before them and lead them out and bring them in, so that your community is not like sheep that have no shepherd.”
18 Nígbà náà ní Olúwa sọ fún Mose pé, “Mú Joṣua ọmọ Nuni, ọkùnrin nínú ẹni tí èmi wà, kí o sì gbé ọwọ́ rẹ lé e.
Yahweh said to Moses, “Take Joshua son of Nun, a man in whom my Spirit lives, and lay your hand on him.
19 Jẹ́ kí ó dúró níwájú Eleasari àlùfáà àti ojú gbogbo àwọn ìjọ ènìyàn Israẹli kí o sì fi àṣẹ fún un ní ojú wọn.
Place him before Eleazar the priest and before all the community, and command him before their eyes to lead them.
20 Kí ìwọ kí ó sì fi nínú ọláńlá rẹ sí i lára, kí gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli kí ó lè gbọ́rọ̀ sí i lẹ́nu.
You must put some of your authority on him, so that all the community of the people of Israel may obey him.
21 Kí ó dúró níwájú Eleasari àlùfáà, tí yóò gba ìpinnu fún láti béèrè Urimu níwájú Olúwa. Gẹ́gẹ́ bí òfin yìí ni òun pẹ̀lú gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli yóò jáde lọ, pẹ̀lú òfin rẹ̀ sì ni wọn ó wọlé.”
He will go before Eleazar the priest to seek my will for him by the decisions of the Urim. It will be at his command that the people will go out and come in, both he and all the people of Israel with him, the whole community.”
22 Mose sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ fún un. Ó mú Joṣua ó sì mú kí ó dúró níwájú Eleasari àlùfáà àti níwájú gbogbo ìjọ.
So Moses did as Yahweh had commanded him. He took Joshua and placed him before Eleazar the priest and all the community.
23 Nígbà náà ni ó gbé ọwọ́ rẹ̀ le e, ó sì fi àṣẹ fún un gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.
He laid his hands on him and commanded him to lead, as Yahweh had commanded him to do.

< Numbers 27 >