< Numbers 26 >

1 Lẹ́yìn àjàkálẹ̀-ààrùn Olúwa sọ fún Mose àti Eleasari ọmọ Aaroni, àlùfáà pé,
It came about after the plague that Yahweh spoke to Moses and Eleazar son of Aaron the priest. He said,
2 “Ka iye gbogbo àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọ́n; láti ẹni ogun ọdún àti jù bẹ́ẹ̀ lọ tí ó lè jà lójú ogun ní Israẹli.”
“Count all the community of the people of Israel, from twenty years old and up, by their ancestor's families, all who are able to go to war for Israel.”
3 Lórí pẹ̀tẹ́lẹ̀ ti Moabu pẹ̀lú Jordani tí ó kọjá Jeriko, Mose àti Eleasari àlùfáà sọ̀rọ̀ pẹ̀lú wọn ó wí pé,
So Moses and Eleazar the priest spoke to them in the plains of Moab by the Jordan at Jericho and said,
4 “Ka iye àwọn ọkùnrin tí ó jẹ́ ọmọ-ogun ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.” Èyí ni àwọn ọmọ Israẹli tí ó jáde láti Ejibiti wá.
“Count the people, from twenty years old and up, as Yahweh commanded Moses and the people of Israel, who came out of the land of Egypt.”
5 Àwọn ọmọ Reubeni, àkọ́bí ọmọkùnrin Israẹli, láti ẹni ti ìdílé Hanoku, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ìdílé Hanoku ti jáde wá, láti ìdílé Pallu, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ìdílé àwọn ọmọ Pallu ti jáde wá;
Reuben was the firstborn of Israel. From his son Hanok came the clan of the Hanokites. From Pallu came the clan of the Palluites.
6 ti Hesroni, ìdílé àwọn ọmọ Hesroni; ti Karmi, ìdílé àwọn ọmọ Karmi.
From Hezron came the clan of the Hezronites. From Karmi came the clan of the Karmites.
7 Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Reubeni; àwọn tí a sì kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlélógún ó lé lẹ́gbẹ̀sán ó dín àádọ́rin.
These were the clans of Reuben, who numbered 43,730 men.
8 Àwọn ọmọkùnrin Pallu ni Eliabu,
Eliab was a son of Pallu.
9 àwọn ọmọkùnrin Elifelehu ni Nemueli àti Eliabu, Datani àti Abiramu. Èyí ni Datani àti Abiramu náà tí wọ́n ní òkìkí nínú ìjọ tí ó jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ sí Mose àti Aaroni tí ó sì wà lára àwọn ẹgbẹ́ Kora nígbà tí wọ́n bá Olúwa jà.
Eliab's sons were Nemuel, Dathan, and Abiram. These were the same Dathan and Abiram who followed Korah when they challenged Moses and Aaron and rebelled against Yahweh.
10 Ilẹ̀ sì la ẹnu rẹ̀, ó sì gbé wọn mì pọ̀ pẹ̀lú Kora, nígbà tí ẹgbẹ́ rẹ̀ kú níbi tí iná ti run àwọn àádọ́ta lé nígba ọkùnrin. Tí wọ́n sì di àmì ìkìlọ̀.
The earth opened its mouth and swallowed them up together with Korah when all his followers died. At that time, fire devoured 250 men, who became a warning sign.
11 Àwọn ọmọ Kora, bí ó ti wù kí ó rí, wọn kò kú.
But Korah's line did not die out.
12 Àwọn ọmọ ìran Simeoni bí ìdílé wọn: ti Nemueli, ìdílé Nemueli; ti Jamini, ìdílé Jamini; ti Jakini, ìdílé Jakini;
The clans of Simeon's descendants were these: Through Nemuel, the clan of the Nemuelites, through Jamin, the clan of the Jaminites, through Jakin, the clan of the Jakinites,
13 ti Sera, ìdílé Sera; tí Saulu, ìdílé Saulu.
through Zerah, the clan of the Zerahites, through Shaul, the clan of the Shaulites.
14 Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Simeoni, ẹgbẹ̀rún méjìlélógún ó lé igba ọkùnrin.
These were the clans of Simeon's descendants, who numbered 22,200 men.
15 Àwọn ọmọ Gadi bí ìdílé wọn: ti Sefoni, ìdílé Sefoni; ti Haggi, ìdílé Haggi; ti Ṣuni, ìdílé Ṣuni;
The clans of Gad's descendants were these: Through Zephon, the clan of the Zephonites, through Haggi, the clan of the Haggites, through Shuni, the clan of the Shunites,
16 ti Osni, ìdílé Osni; ti Eri, ìdílé Eri;
through Ozni, the clan of the Oznites, through Eri, the clan of the Erites,
17 ti Arodi, ìdílé Arodi; ti Areli, ìdílé Areli.
through Arod, the clan of the Arodites, through Areli, the clan of the Arelites.
18 Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Gadi tí iye wọn sì jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ó lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta.
These were the clans of Gad's descendants, who numbered 40,500 men.
19 Àwọn ọmọ Juda ni Eri àti Onani, ṣùgbọ́n Eri àti Onani kú ní ilẹ̀ Kenaani.
Judah's sons were Er and Onan, but these men died in the land of Canaan.
20 Àti àwọn ọmọ Juda gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn: ti Ṣela, ìdílé Ṣela; ti Peresi, ìdílé Peresi; ti Sera, ìdílé Sera.
The clans of Judah's other descendants were these: through Shelah, the clan of the Shelanites, through Perez, the clan of the Perezites, and through Zerah, the clan of the Zerahites.
21 Àwọn ọmọ Peresi: ti Hesroni, ìdílé Hesroni; ti Hamulu, ìdílé Hamulu.
The descendants of Perez were these: Through Hezron, the clan of the Hezronites, through Hamul, the clan of the Hamulites.
22 Wọ̀nyí ni ìdílé Juda; gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn tí iye wọn sì jẹ́ ẹgbàá méjìdínlógójì ó lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta.
These were the clans of Judah's descendants, who numbered 76,500 men.
23 Àwọn ọmọ Isakari gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn: ti Tola, ìdílé Tola; ti Pufa, ìdílé Pufa;
The clans of Issachar's descendants were these: Through Tola, the clan of the Tolaites, through Puah, the clan of the Puites,
24 ti Jaṣubu, ìdílé Jaṣubu; ti Ṣimroni, ìdílé Ṣimroni.
through Jashub, the clan of the Jashubites, through Shimron, the clan of the Shimronites.
25 Wọ̀nyí ni ìdílé Isakari gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn tí iye wọn sì jẹ́ ẹgbàá méjìlélọ́gbọ̀n ó lé ọ̀ọ́dúnrún.
These were the clans of Issachar, who numbered 64,300 men.
26 Àwọn ọmọ Sebuluni gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn: ti Seredi, ìdílé Seredi; ti Eloni, ìdílé Eloni; ti Jaleeli, ìdílé Jaleeli.
The clans of Zebulun's descendants were these: Through Sered, the clan of the Seredites, through Elon, the clan of the Elonites, through Jahleel, the clan of the Jahleelites.
27 Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Sebuluni gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn tí iye wọn sì jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́ta ó lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta.
These were the clans of the Zebulunites, who numbered 60,500 men.
28 Àwọn ọmọ Josẹfu gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn; Manase àti Efraimu.
The clans of Joseph's descendants were Manasseh and Ephraim.
29 Àwọn ọmọ Manase: ti Makiri, ìdílé Makiri (Makiri sì bí Gileadi); ti Gileadi, ìdílé àwọn ọmọ Gileadi.
The descendants of Manasseh were these: through Makir, the clan of the Makirites (Makir was Gilead's father), through Gilead, the clan of the Gileadites.
30 Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Gileadi: ti Ieseri, ìdílé Ieseri; ti Heleki, ìdílé Heleki
Gilead's descendants were these: Through Iezer, the clan of the Iezerites, through Helek, the clan of the Helekites,
31 àti ti Asrieli, ìdílé Asrieli; àti ti Ṣekemu, ìdílé Ṣekemu;
through Asriel, the clan of the Asrielites, through Shechem, the clan of the Shechemites,
32 àti Ṣemida, ìdílé àwọn ọmọ Ṣemida; àti ti Heferi, ìdílé àwọn ọmọ Heferi.
through Shemida, the clan of the Shemidaites, through Hepher, the clan of the Hepherites.
33 (Selofehadi ọmọ Heferi kò sì ni ọmọkùnrin, bí kò ṣe ọmọbìnrin; orúkọ àwọn ọmọbìnrin ni Mahila, Noa, àti Hogla, Milka àti Tirsa).
Zelophehad son of Hepher had no sons, but only daughters. The names of his daughters were Mahlah, Noah, Hoglah, Milkah, and Tirzah.
34 Wọ̀nyí ni ìdílé Manase tí iye wọn sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ó lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin.
These were the clans of Manasseh, who numbered 52,700 men.
35 Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Efraimu gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn: láti ọ̀dọ̀ Ṣutelahi, ìdílé àwọn ọmọ Ṣutelahi; ti Bekeri, ìdílé àwọn ọmọ Bekeri; ti Tahani, ìdílé àwọn ọmọ Tahani.
The clans of Ephraim's descendants were these: Through Shuthelah, the clan of the Shuthelahites, through Beker, the clan of the Bekerites, through Tahan, the clan of the Tahanites.
36 Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Ṣutelahi: ti Erani, ìdílé àwọn ọmọ Erani.
The descendants of Shuthelah were, by Eran, the clan of the Eranites.
37 Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Efraimu, àwọn tí a kà nínú wọn sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìndínlógún ó lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Josẹfu gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn.
These were the clans of Ephraim's descendants, who numbered 32,500 men. These were Joseph's descendants, counted in each of their clans.
38 Àwọn ọmọ Benjamini gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn nìyìí: tí Bela, ìdílé àwọn ọmọ Bela; ti Aṣbeli, ìdílé àwọn ọmọ Aṣbeli; ti Ahiramu, ìdílé àwọn ọmọ Ahiramu;
The clans of Benjamin's descendants were these: Through Bela, the clan of the Belaites, through Ashbel, the clan of the Ashbelites, through Ahiram, the clan of the Ahiramites,
39 ti Ṣufamu, ìdílé àwọn ọmọ Ṣufamu; ti Hufamu, ìdílé àwọn ọmọ Hufamu.
through Shephupham, the clan of the Shuphamites, through Hupham, the clan of the Huphamites.
40 Àwọn ọmọ Bela ní ipasẹ̀ Ardi àti Naamani nìyìí: ti Ardi, ìdílé àwọn ọmọ Ardi; ti Naamani, ìdílé àwọn ọmọ Naamani.
Bela's sons were Ard and Naaman. From Ard came the clan of the Ardites, and from Naaman came the clan of the Naamites.
41 Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Benjamini; gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn; àti àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá méjìlélógún ó lé ẹgbẹ̀jọ.
These were the clans of Benjamin's descendants. They numbered 45,600 men.
42 Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Dani gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn: ti Ṣuhamu, ìdílé àwọn ọmọ Ṣuhamu. Wọ̀nyí ni ìdílé Dani gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn.
The clans of Dan's descendants were, by Shuham, the clans of the Shuhamites. These were the clans of Dan's descendants.
43 Gbogbo ìdílé àwọn ọmọ Ṣuhamu, gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá méjìlélọ́gbọ̀n ó lé irinwó.
All the clans of the Shuhamites numbered 64,400 men.
44 Ti àwọn ọmọ Aṣeri gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn: ti Imina, ìdílé àwọn ọmọ Imina; ti Iṣfi, ìdílé àwọn ọmọ Iṣfi; ti Beriah, ìdílé àwọn ọmọ Berii.
The clans of Asher's descendants were these: Through Imnah, the clan of the Imnites, through Ishvi, the clan of the Ishvites, through Beriah, the clan of the Beriites.
45 Ti àwọn ọmọ Beriah: ti Heberi, ìdílé àwọn ọmọ Heberi; ti Malkieli, ìdílé àwọn ọmọ Malkieli.
The descendants of Beriah were these: Through Heber, the clan of the Heberites, through Malkiel, the clan of the Malkielites.
46 (Orúkọ ọmọ Aṣeri obìnrin nì jẹ́ Sera.)
The name of Asher's daughter was Serah.
47 Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Aṣeri gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ó lé egbèje.
These were the clans of Asher's descendants, who numbered 53,400 men.
48 Ti àwọn ọmọ Naftali gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn: ti Jasieli, ìdílé àwọn ọmọ Jaseeli: ti Guni, ìdílé àwọn ọmọ Guni;
The clans of Naphtali's descendants were these: Through Jahzeel, the clan of the Jahzeelites, through Guni, the clan of the Gunites,
49 ti Jeseri, ìdílé àwọn ọmọ Jeṣeri; ti Ṣillemu, ìdílé àwọn ọmọ Ṣillemu.
through Jezer, the clan of the Jezerites, through Shillem, the clan of the Shillemites.
50 Wọ̀nyí ni ìdílé ti Naftali gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn, àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá méjìlélógún ó lé egbèje.
These were the clans of Naphtali's descendants, who numbered 45,400 men.
51 Àpapọ̀ iye tí a kà nínú àwọn ọmọ Israẹli jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó lé ẹgbẹ̀sán dín làádọ́rin.
This was the complete count of men among the people of Israel: 601,730.
52 Olúwa sọ fún Mose pé,
Yahweh spoke to Moses and said,
53 “Ilẹ̀ náà gbọdọ̀ jẹ́ pínpín fún wọn gẹ́gẹ́ bí ogún wọn gẹ́gẹ́ bí iye orúkọ wọn.
“The land must be divided among these men as an inheritance according to the number of their names.
54 Fún àwọn ọ̀pọ̀ ni kí ìwọ ó fún ní ogún ìlú púpọ̀ àti fún àwọn tí ó kéré ni kí ìwọ ó fi kékeré fún, ẹnìkọ̀ọ̀kan gbọdọ̀ gba ogún ìbí tirẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí a kọ.
To the larger clans you must give more inheritance, and to the smaller clans you must give less inheritance. To every family you must give an inheritance according to the number of men who were counted.
55 Rí dájú pé ilẹ̀ yìí gbọdọ̀ jẹ́ fífi ìbò pín gẹ́gẹ́ bí wọn sì ti pọ̀ tó. Gẹ́gẹ́ bí orúkọ ẹ̀yà àwọn baba wọn ni kí wọn kí ó ni í.
However, the land must be divided by random lots. They must inherit the land as it will be divided among their ancestors' tribes.
56 Olúkúlùkù ogún ìní ni a gbọdọ̀ fi ìbò pín gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti pọ̀ tó láàrín ńlá àti kékeré.”
Their inheritance must be divided among the larger and the smaller clans, distributed to them by random lot.”
57 Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Lefi tí a kà nínú wọn gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn: ti Gerṣoni, ìdílé àwọn ọmọ Gerṣoni; ti Kohati, ìdílé àwọn ọmọ Kohati; ti Merari, ìdílé àwọn ọmọ Merari.
The Levite clans, counted clan by clan, were these: Through Gershon, the clan of the Gershonites, through Kohath, the clan of the Kohathites, through Merari, the clan of the Merarites.
58 Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Lefi; ìdílé àwọn ọmọ Libni, ìdílé àwọn ọmọ Hebroni, ìdílé àwọn ọmọ Mahili, ìdílé àwọn ọmọ Muṣi, ìdílé àwọn ọmọ Kora. (Kohati ni baba Amramu,
The clans of Levi were these: the clan of the Libnites, the clan of the Hebronites, the clan of the Mahlites, the clan of the Mushites, and the clan of the Korahites. Kohath was the Amram's ancestor.
59 orúkọ aya Amramu sì ń jẹ́ Jokebedi, ọmọbìnrin Lefi, tí ìyá rẹ̀ bí fún Lefi ní Ejibiti. Òun sì bí Aaroni, Mose, àti Miriamu arábìnrin wọn fún Amramu.
The name of Amram's wife was Jochebed, a descendant of Levi, who was born to Levites in Egypt. She bore to Amram their children, who were Aaron, Moses, and Miriam their sister.
60 Aaroni ni baba Nadabu àti Abihu, Eleasari àti Itamari.
To Aaron were born Nadab and Abihu, Eleazar and Ithamar.
61 Ṣùgbọ́n Nadabu àti Abihu kú, nígbà tí wọ́n rú ẹbọ níwájú Olúwa nígbà tí wọ́n mú iná àjèjì wá.)
Nadab and Abihu died when they offered before Yahweh unacceptable fire.
62 Gbogbo àwọn ọmọkùnrin Lefi láti oṣù kan àti ju bẹ́ẹ̀ lọ ẹgbẹ̀rún méjìlélógún ó lé lẹ́gbẹ̀rún. Wọn kò ka wọ́n mọ́ àwọn ọmọ Israẹli tókù nítorí tí wọ́n kò gba ogún ìní lára wọn.
The males who were counted among them numbered twenty-three thousand, all males one month old and up. But they were not counted among Israel's descendants because no inheritance was given to them among the people of Israel.
63 Àwọn wọ̀nyí ni Mose àti Eleasari àlùfáà kà nígbà tí wọ́n ka àwọn ọmọ Israẹli ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu lẹ́bàá odò Jordani létí Jeriko.
These are the ones who were counted by Moses and Eleazar the priest. They counted the people of Israel in the plains of Moab by the Jordan at Jericho.
64 Kò sí ẹnìkan nínú àwọn tí Mose àti Aaroni àlùfáà kà nígbà tí wọ́n ka àwọn ọmọ Israẹli ní aginjù Sinai.
But among these there was no man who had been counted by Moses and Aaron the priest when the descendants of Israel were counted in the wilderness of Sinai.
65 Nítorí Olúwa ti sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kíkú ni wọn yóò kú sí aginjù, kò sì sí ẹnìkankan nínú wọn tí kò kú àfi Kalebu ọmọ Jefunne, àti Joṣua ọmọ Nuni.
For Yahweh had said that all of those people would certainly die in the wilderness. There was not a man left among them, except Caleb son of Jephunneh and Joshua son of Nun.

< Numbers 26 >