< Numbers 25 >

1 Nígbà tí àwọn Israẹli dúró ní Ṣittimu, àwọn ènìyàn sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àgbèrè pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin Moabu,
وَأَقَامَ إِسْرَائِيلُ فِي شِطِّيمَ، وَٱبْتَدَأَ ٱلشَّعْبُ يَزْنُونَ مَعَ بَنَاتِ مُوآبَ.١
2 tí ó pè wọ́n sí ibi ẹbọ òrìṣà wọn. Àwọn ènìyàn náà jẹun wọ́n sì foríbalẹ̀ níwájú òrìṣà wọn.
فَدَعَوْنَ ٱلشَّعْبَ إِلَى ذَبَائِحِ آلِهَتِهِنَّ، فَأَكَلَ ٱلشَّعْبُ وَسَجَدُوا لِآلِهَتِهِنَّ.٢
3 Báyìí ni Israẹli ṣe darapọ̀ mọ́ wọn tí wọ́n sì jọ ń sin Baali-Peori. Ìbínú Olúwa sì ru sí wọn.
وَتَعَلَّقَ إِسْرَائِيلُ بِبَعْلِ فَغُورَ. فَحَمِيَ غَضَبُ ٱلرَّبِّ عَلَى إِسْرَائِيلَ.٣
4 Olúwa sọ fún Mose pé, “Mú gbogbo àwọn olórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí, pa wọ́n kí o sì fi wọ́n kọ́ sórí igi ní gbangba nínú oòrùn níwájú Olúwa, kí ìbínú Olúwa lè kúrò ní ọ̀dọ̀ Israẹli.”
فَقَالَ ٱلرَّبُّ لِمُوسَى: «خُذْ جَمِيعَ رُؤُوسِ ٱلشَّعْبِ وَعَلِّقْهُمْ لِلرَّبِّ مُقَابِلَ ٱلشَّمْسِ، فَيَرْتَدَّ حُمُوُّ غَضَبِ ٱلرَّبِّ عَنْ إِسْرَائِيلَ».٤
5 Mose sọ fún àwọn onídàájọ́ Israẹli, “Ẹnìkọ̀ọ̀kan yín gbọdọ̀ pa arákùnrin rẹ̀ èyí tí ó darapọ̀ ní fífi orí balẹ̀ fún Baali-Peori.”
فَقَالَ مُوسَى لِقُضَاةِ إِسْرَائِيلَ: «ٱقْتُلُوا كُلُّ وَاحِدٍ قَوْمَهُ ٱلْمُتَعَلِّقِينَ بِبَعْلِ فَغُورَ».٥
6 Nítòótọ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin Israẹli sì mú obìnrin Midiani wá síwájú ojú Mose àti gbogbo ìjọ ti Israẹli wọ́n sì ń sọkún ní àbáwọlé àgọ́ ìpàdé.
وَإِذَا رَجُلٌ مِنْ بَنِي إِسْرَائِيلَ جَاءَ وَقَدَّمَ إِلَى إِخْوَتِهِ ٱلْمِدْيَانِيَّةَ، أَمَامَ عَيْنَيْ مُوسَى وَأَعْيُنِ كُلِّ جَمَاعَةِ بَنِي إِسْرَائِيلَ، وَهُمْ بَاكُونَ لَدَى بَابِ خَيْمَةِ ٱلِٱجْتِمَاعِ.٦
7 Nígbà tí Finehasi, ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni, àlùfáà, rí èyí, ó fi ìjọ sílẹ̀, pẹ̀lú ọ̀kọ̀ ní ọwọ́ rẹ̀.
فَلَمَّا رَأَى ذَلِكَ فِينْحَاسُ بْنُ أَلِعَازَارَ بْنِ هَارُونَ ٱلْكَاهِنِ، قَامَ مِنْ وَسَطِ ٱلْجَمَاعَةِ وَأَخَذَ رُمْحًا بِيَدِهِ،٧
8 Ó sì tẹ̀lé arákùnrin Israẹli yìí lọ sínú àgọ́. Ó sì fi ọ̀kọ̀ gún àwọn méjèèjì ní àgúnyọ láti ara ọkùnrin Israẹli àti sí ara obìnrin náà. Nígbà náà ni àjàkálẹ̀-ààrùn lórí àwọn ọmọ Israẹli sì dúró;
وَدَخَلَ وَرَاءَ ٱلرَّجُلِ ٱلْإِسْرَائِيلِيِّ إِلَى ٱلْقُبَّةِ وَطَعَنَ كِلَيْهِمَا، ٱلرَّجُلَ ٱلْإِسْرَائِيلِيَّ وَٱلْمَرْأَةَ فِي بَطْنِهَا. فَٱمْتَنَعَ ٱلْوَبَأُ عَنْ بَنِي إِسْرَائِيلَ.٨
9 ṣùgbọ́n gbogbo àwọn tí ó kú nínú àjàkálẹ̀-ààrùn náà jẹ́ ẹgbàá méjìlá.
وَكَانَ ٱلَّذِينَ مَاتُوا بِٱلْوَبَإِ أَرْبَعَةً وَعِشْرِينَ أَلْفًا.٩
10 Olúwa sì tún sọ fún Mose pé,
فَكَلَّمَ ٱلرَّبُّ مُوسَى قَائِلًا:١٠
11 “Finehasi ọmọ Eleasari ọmọ Aaroni, àlùfáà, ti yí ìbínú mi padà kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli, nítorí tí ó ní ìtara bí èmi náà ti ní ìtara fún iyì mi láàrín wọn, kí ó lè jẹ́ pé èmi ló pa wọ́n run nínú ìtara mi sí wọn.
«فِينْحَاسُ بْنُ أَلِعَازَارَ بْنِ هَارُونَ ٱلْكَاهِنِ قَدْ رَدَّ سَخَطِي عَنْ بَنِي إِسْرَائِيلَ بِكَوْنِهِ غَارَ غَيْرَتِي فِي وَسَطِهِمْ حَتَّى لَمْ أُفْنِ بَنِي إِسْرَائِيلَ بِغَيْرَتِي.١١
12 Nítorí náà sọ fún un pé èmi ṣe májẹ̀mú àlàáfíà mi pẹ̀lú rẹ̀.
لِذَلِكَ قُلْ: هَأَنَذَا أُعْطِيهِ مِيثَاقِي مِيثَاقَ ٱلسَّلَامِ،١٢
13 Òun àti irú-ọmọ rẹ̀ yóò ní májẹ̀mú láéláé fún iṣẹ́ àlùfáà, nítorí pé ó ní ìtara fún Ọlọ́run rẹ̀ láti fi yẹ́ Ọlọ́run sí, ó sì ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Israẹli.”
فَيَكُونُ لَهُ وَلِنَسْلِهِ مِنْ بَعْدِهِ مِيثَاقَ كَهَنُوتٍ أَبَدِيٍّ، لِأَجْلِ أَنَّهُ غَارَ لِلهِ وَكَفَّرَ عَنْ بَنِي إِسْرَائِيلَ».١٣
14 Orúkọ ọmọ Israẹli tí a pa pẹ̀lú obìnrin Midiani náà ni Simri, ọmọ Salu, olórí ilé kan nínú àwọn ọmọ Simeoni.
وَكَانَ ٱسْمُ ٱلرَّجُلِ ٱلْإِسْرَائِيلِيِّ ٱلْمَقْتُولِ ٱلَّذِي قُتِلَ مَعَ ٱلْمِدْيَانِيَّةِ، زِمْرِيَ بْنَ سَالُو، رَئِيسَ بَيْتِ أَبٍ مِنَ ٱلشِّمْعُونِيِّينَ.١٤
15 Orúkọ ọmọbìnrin Midiani náà tí a pa ní Kosbi ọmọbìnrin Suri, tí ṣe olóyè àwọn ẹ̀yà kan nínú ìdílé kan ní Midiani.
وَٱسْمُ ٱلْمَرْأَةِ ٱلْمِدْيَانِيَّةِ ٱلْمَقْتُولَةِ كُزْبِيَ بِنْتَ صُورٍ، هُوَ رَئِيسُ قَبَائِلِ بَيْتِ أَبٍ فِي مِدْيَانَ.١٥
16 Olúwa sì tún sọ fún Mose pé,
ثُمَّ كَلَّمَ ٱلرَّبُّ مُوسَى قَائِلًا:١٦
17 “Ka àwọn ará Midiani sí ọ̀tá, kí o sì pa wọ́n,
«ضَايِقُوا ٱلْمِدْيَانِيِّينَ وَٱضْرِبُوهُمْ،١٧
18 nítorí pé wọ́n ṣe sí yín gẹ́gẹ́ bí ọ̀tá nígbà tí wọ́n tàn yín nípa ìṣẹ̀lẹ̀ Peori, àti arábìnrin wọn Kosbi ọmọbìnrin ìjòyè Midiani kan, obìnrin tí a pa nígbà tí àjàkálẹ̀-ààrùn ṣẹlẹ̀ nítorí Peori.”
لِأَنَّهُمْ ضَايَقُوكُمْ بِمَكَايِدِهِمِ ٱلَّتِي كَادُوكُمْ بِهَا فِي أَمْرِ فَغُورَ وَأَمْرِ كُزْبِي أُخْتِهِمْ بِنْتِ رَئِيسٍ لِمِدْيَانَ، ٱلَّتِي قُتِلَتْ يَوْمَ ٱلْوَبَإِ بِسَبَبِ فَغُورَ».١٨

< Numbers 25 >