< Numbers 2 >

1 Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni pé,
The Lord told Moses and Aaron,
2 “Kí àwọn ọmọ Israẹli pa àgọ́ wọn yí àgọ́ ìpàdé ká, kí wọ́n jẹ́ kí àgọ́ wọn jìnnà sí i díẹ̀, oníkálùkù lábẹ́ ọ̀págun pẹ̀lú àsíá ìdílé wọn.”
“The Israelites are to set up their camp around the Tent of Meeting but some distance from it. Every member of each tribe will camp under their own flag and family banner.
3 Ní ìlà-oòrùn, ní ìdojúkọ àtiyọ oòrùn: ni kí ìpín ti Juda pa ibùdó wọn sí lábẹ́ ọ̀págun wọn. Olórí Juda ni Nahiṣoni ọmọ Amminadabu.
The tribal division of Judah is to camp under their flag on the east side. Their leader is Nahshon, son of Amminadab,
4 Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàdínlógójì ó lé ẹgbẹ̀ta.
and he has 74,600 men.
5 Ẹ̀yà Isakari ni yóò pa ibùdó tẹ̀lé wọn. Olórí Isakari ni Netaneli ọmọ Suari.
The tribe of Issachar will camp next to them. Their leader is Nethanel, son of Zuar,
6 Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ó lé irinwó.
and he has 54,400 men.
7 Ẹ̀yà Sebuluni ni yóò tẹ̀lé e. Olórí Sebuluni ni Eliabu ọmọ Heloni.
Next is the tribe of Zebulun. Their leader is Eliab, son of Helon,
8 Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá méjìdínlọ́gbọ̀n ó lé egbèje.
and he has 57,400 men.
9 Gbogbo àwọn tí a yàn sí ibùdó Juda, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàléláàdọ́rùn-ún ó lé irinwó. Àwọn ni yóò kọ́kọ́ ṣáájú.
So the total number of men in the area of the camp of Judah is 186,400. When it's time to march out, they are the ones who will lead.
10 Ní ìhà gúúsù: ni ìpín ti Reubeni pa ibùdó sí lábẹ́ ọ̀págun wọn. Olórí Reubeni ni Elisuri ọmọ Ṣedeuri.
The tribal division of Reuben is to camp under their flag on the south side. Their leader is Elizur, son of Shedeur,
11 Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàlélógún ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta.
and he has 46,500 men.
12 Ẹ̀yà Simeoni ni yóò pa ibùdó tẹ̀lé wọn. Olórí Simoni ni Ṣelumieli ọmọ Suriṣaddai.
The tribe of Simeon will camp next to them. Their leader is Shelumiel, son of Zurishaddai,
13 Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá mọ́kàndínlọ́gbọ̀n ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbéje.
and he has 59,300 men.
14 Ẹ̀yà Gadi ló tẹ̀lé wọn. Olórí Gadi ni Eliasafu ọmọ Deueli.
Next is the tribe of Gad. Their leader is Eliasaph, son of Deuel,
15 Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá méjìlélógún ó lé àádọ́talélẹ́gbẹ̀jọ.
and he has 45,650 men.
16 Gbogbo ènìyàn tí a yàn sí ibùdó Reubeni, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ẹgbàá márùndínlọ́gọ́rin ó lé àádọ́talélégbèje. Àwọn ni yóò jáde sìkéjì.
So the total number of men in the area of the camp of Reuben is 151,450. They shall march out in second place.
17 Nígbà náà ni àwọn ọmọ Lefi àti àgọ́ ìpàdé yóò tẹ̀síwájú láàrín ibùdó àwọn ènìyàn, wọn yóò tẹ̀síwájú ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé gẹ́gẹ́ bí wọn ṣe pa ibùdó, olúkúlùkù láààyè rẹ̀, àti lábẹ́ ọ̀págun rẹ̀.
The Tent of Meeting which is stands at the center of the camp is to accompany the Levites. They are to march out in the same order as they set up camp, each in their rightful place under their flag.
18 Ní ìhà ìlà-oòrùn: ni ìpín Efraimu yóò pa ibùdó rẹ̀ sí lábẹ́ ọ̀págun rẹ̀. Olórí Efraimu ni Eliṣama ọmọ Ammihudu.
The tribal division of Ephraim is to camp under their flag on the west side. Their leader is Elishama, son of Ammihud,
19 Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì lé ó lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta.
and he has 40,500 men.
20 Ẹ̀yà Manase ni yóò tẹ̀lé wọn. Olórí Manase ni Gamalieli ọmọ Pedasuri.
The tribe of Manasseh will camp next to them. Their leader is Gamaliel, son of Pedahzur,
21 Iye ìpín rẹ̀ ni ẹgbàá mẹ́rìndínlógún ó lé igba.
and he has 32,200 men.
22 Ẹ̀yà Benjamini ni yóò tẹ̀lé e. Olórí Benjamini ni Abidani ọmọ Gideoni.
Next is the tribe of Benjamin. Their leader is Abidan, son of Gideoni,
23 Iye ìpín rẹ̀ ni ẹgbàá mẹ́tàdínlógún ó lé egbèje.
and he has 35,400 men.
24 Gbogbo ènìyàn tí a yàn sí ibùdó Efraimu, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn, àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìnléláàádọ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún. Àwọn ni yóò jáde sìkẹ́ta.
So the total number of men in the area of the camp of Ephraim is 108,100. They shall march out in third place
25 Ní ìhà àríwá: ni ìpín Dani yóò pa ibùdó sí lábẹ́ ọ̀págun wọn. Olórí Dani ni Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai.
The tribal division of Dan is to camp under their flag on the north side. Their leader is Ahiezer, son of Ammishaddai,
26 Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlélọ́gbọ̀n ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin.
and he has 62,700 men.
27 Ẹ̀yà Aṣeri ni yóò pa ibùdó tẹ̀lé wọn. Olórí Aṣeri ni Pagieli ọmọ Okanri.
The tribe of Asher will camp next to them. Their leader is Pagiel, son of Ocran,
28 Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ.
and he has 41,500 men.
29 Ẹ̀yà Naftali ni yóò kàn lẹ́yìn wọn. Olórí Naftali ni Ahira ọmọ Enani.
Next is the tribe of Naphtali. Their leader is Ahira son of Enan,
30 Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìndínlógún ó lé egbèje.
and he has 53,400 men.
31 Gbogbo ènìyàn tí a yàn sí ibùdó Dani jẹ́ ẹgbàá méjìdínlọ́gọ̀rin ó lé ẹgbẹ̀jọ. Àwọn ni yóò jáde kẹ́yìn lábẹ́ ọ̀págun wọn.
So the total number of men in the area of the camp of Dan is 157,600; They shall march out in last, with their flags.”
32 Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n kà nípa ìdílé wọn. Gbogbo àwọn tó wà ní ibùdó, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn, wọ́n jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó lé egbèjìdínlógún dín làádọ́ta.
This is sums up the registration of the Israelites, carried out by family. The final total of those counted in the camps by their tribal division was 603,550.
33 Ṣùgbọ́n a kò ka àwọn ọmọ Lefi papọ̀ mọ́ àwọn Israẹli gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún Mose.
However, the Levites were not counted among the other Israelites, following the Lord's instructions to Moses.
34 Àwọn ọmọ Israẹli ṣe gbogbo ohun tí Olúwa pàṣẹ fún Mose, báyìí ni wọ́n ṣe pa ibùdó lábẹ́ ọ̀págun wọn, bẹ́ẹ̀ náà sì ni wọ́n ṣe jáde, oníkálùkù pẹ̀lú ẹbí àti ìdílé rẹ̀.
The Israelites did everything the Lord had ordered Moses. They set up their camps under their flags in their assigned positions, and marched out in the same order, each with their own tribe and family.

< Numbers 2 >