< Numbers 19 >
1 Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni pé,
Yahweh spoke to Moses and Aaron. He said,
2 “Èyí ni ohun tí òfin Olúwa pàṣẹ béèrè lọ́wọ́ yín. Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli, kí wọn mú ẹgbọrọ ọ̀dọ́ màlúù pupa tí kò lábùkù tàbí àbàwọ́n, lára èyí tí a kò tí ì di àjàgà mọ́.
“This is a statute, a law which I am commanding you: Say to the people of Israel that they must bring to you a red heifer without flaw or blemish, and which has never carried a yoke.
3 Ẹ mú fún Eleasari àlùfáà, yóò sì mu jáde lọ sí ẹ̀yìn ibùdó kí ó sì pa á ní ojú rẹ.
Give the heifer to Eleazar the priest. He must bring it outside the camp, and someone must kill it in front of him.
4 Nígbà náà ni Eleasari àlùfáà yóò mú lára ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sórí ìka ọwọ́ rẹ̀ yóò sì wọn lẹ́ẹ̀méje ní ọ̀kánkán iwájú àgọ́ ìpàdé.
Eleazar the priest must take some of its blood with his finger and sprinkle it seven times toward the front of the tent of meeting.
5 Ní ojú rẹ̀ ni àlùfáà yóò ti sun ọ̀dọ́ abo màlúù yìí: awọ ara rẹ̀, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ẹran-ara àti ìgbẹ́ rẹ̀.
Another priest must burn the heifer in his sight. He must burn its hide, flesh, and its blood with its dung.
6 Àlùfáà yóò mú igi kedari, hísópù àti òwú òdòdó yóò sì jù wọ́n sí àárín ọ̀dọ́ abo màlúù tí a ń sun.
The priest must take cedarwood, hyssop, and scarlet wool, and throw it all into the middle of the burning heifer.
7 Lẹ́yìn náà, àlùfáà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ ara rẹ̀ pẹ̀lú omi lẹ́yìn náà ó lè wá sínú àgọ́. Ṣùgbọ́n yóò jẹ́ aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.
Then he must wash his clothes and bathe in water. Then he may come into the camp, where he will remain unclean until the evening.
8 Ẹni tí ó sun ún náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ kí ó sì wẹ̀ pẹ̀lú omi, òun náà yóò jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.
The one who has burned the heifer must wash his clothes in water and bathe in water. He will remain unclean until the evening.
9 “Ẹni tó wà ní mímọ́ ni yóò kó eérú ọ̀dọ́ màlúù náà lọ sí ibi tí a yà sí mímọ́ lẹ́yìn ibùdó. Kí gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli kó o pamọ́ fún lílò fún omi ìwẹ̀nùmọ́. Ó jẹ́ ìwẹ̀nùmọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀.
Someone who is clean must gather up the heifer's ashes and put them outside the camp in a clean place. These ashes must be kept for the community of the people of Israel. They will mix the ashes with water for purification from sin, since the ashes were from a sin offering.
10 Ọkùnrin tí ó kó eérú ọ̀dọ́ abo màlúù náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, òun náà yóò sì jẹ́ aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́. Èyí ni yóò jẹ́ ìlànà láéláé fún àwọn ọmọ Israẹli àti fún àwọn àjèjì tí ó ń gbé láàrín wọn.
The one who gathered the heifer's ashes must wash his clothes. He will remain unclean until the evening. This will be a permanent law for the people of Israel and the foreigners who stay with them.
11 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan òkú ẹnikẹ́ni, yóò jẹ́ aláìmọ́ fún ọjọ́ méje.
Whoever touches the dead body of any man will be unclean for seven days.
12 Ó gbọdọ̀ wẹ ara rẹ̀ pẹ̀lú omi ní ọjọ́ kẹta àti ní ọjọ́ keje; nígbà náà ni yóò jẹ́ mímọ́. Ṣùgbọ́n tí ó bá jẹ́ pé kò wẹ ara rẹ̀ mọ́ ní ọjọ́ kẹta àti ní ọjọ́ keje yóò jẹ́ aláìmọ́.
Such a person must purify himself on the third day and on the seventh day. Then he will be clean. But if he does not purify himself the third day, then he will not be clean on the seventh day.
13 Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan òkú ẹnìkan tí kò sì wẹ ara rẹ̀ mọ́, ó ba àgọ́ Olúwa jẹ́. A ó ké irú ẹni bẹ́ẹ̀ kúrò lára àwọn ọmọ Israẹli. Nítorí pé a kò tí ì wọ́n omi ìwẹ̀nùmọ́ lé e lórí, ó jẹ́ aláìmọ́, àìmọ́ rẹ̀ sì wà lára rẹ̀.
Whoever touches a dead person, the body of a man who has died, and does not purify himself—this person defiles Yahweh's tabernacle. That person must be cut off from Israel because the water for impurity was not sprinkled on him. He will remain unclean; his uncleanness will remain on him.
14 “Èyí ni òfin tí ó jẹ mọ́ bí ènìyàn bá kú nínú àgọ́, ẹnikẹ́ni tí ó bá wọ inú àgọ́ àti ẹni tí ó wà nínú àgọ́ yóò di aláìmọ́ fún ọjọ́ méje,
This is the law for when someone dies in a tent. Everyone who goes into the tent and everyone who is already in the tent will be unclean for seven days.
15 gbogbo ohun èlò tí a kò bá fi omọrí dé ni yóò jẹ́ aláìmọ́.
Every open container with no cover becomes unclean.
16 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá wà ní ìta tí ó sì fi ọwọ́ kan ẹni tí a fi idà pa tàbí ẹni tí ó kú ikú àtọ̀runwá, tàbí bí ẹnìkan bá fi ọwọ́ kan egungun òkú ènìyàn tàbí isà òkú, yóò jẹ́ aláìmọ́ fún ọjọ́ méje.
Similarly, anyone outside a tent who touches someone who has been killed with a sword, any other dead body, a human bone, or a grave—that person will be unclean for seven days.
17 “Fún aláìmọ́ ènìyàn, mú eérú díẹ̀ lára eérú ọrẹ ìwẹ̀nùmọ́ sínú ìgò, kí o sì da omi tó ń sàn lé e lórí.
Do this for the unclean person: Take some ashes from the burnt sin offering and mix them in a jar with fresh water.
18 Nígbà náà, ọkùnrin tí a yà sí mímọ́ yóò mú hísópù díẹ̀ yóò rì í sínú omi yóò sì fi wọ́n àgọ́ àti gbogbo ohun èlò tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ àti àwọn ènìyàn tí ó wà níbẹ̀. O gbọdọ̀ tún fi wọ́n ẹnikẹ́ni tí ó fi ọwọ́ kan egungun òkú ènìyàn tàbí isà òkú, tàbí ẹni tí ó kú ikú ara rẹ̀, tàbí ẹni tí ó kú ikú àti ọ̀run wá.
Someone who is clean must then take hyssop, dip it in the water, and sprinkle it on the tent, on all the containers inside the tent, on the persons who were there, and on anyone who touched the bone, the one who was killed, the one who died, or the grave.
19 Ọkùnrin tí ó mọ́ ni kí ó bu omi wọ́n àwọn ènìyàn aláìmọ́ ní ọjọ́ kẹta àti ọjọ́ keje, ní ọjọ́ keje ó gbọdọ̀ wẹ ara rẹ̀ mọ́. Ẹni tí a wẹ̀mọ́ gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ kí ó sì wẹ̀ pẹ̀lú omi, ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà yóò mọ́.
On the third day and on the seventh day, the clean person must sprinkle the unclean person. On the seventh day the unclean person must purify himself. He must wash his clothes and bathe in water. At evening he will become clean.
20 Ṣùgbọ́n bí ẹni tí ó bá jẹ́ aláìmọ́ kò bá wẹ ara rẹ̀ mọ́, a gbọdọ̀ gé e kúrò nínú ìjọ ènìyàn, nítorí wí pé ó ti ba àgọ́ Olúwa jẹ́. A kò tí ì fi omi ìwẹ̀nùmọ́ sí ara rẹ̀, ó sì jẹ́ aláìmọ́.
But anyone who remains unclean, who refuses to purify himself—that person will be cut off from the community, because he has defiled Yahweh's sanctuary. The water for impurity has not been sprinkled on him; he remains unclean.
21 Èyí jẹ́ ìlànà láéláé fún wọn. “Ọkùnrin tí ó wọ́n omi ìwẹ̀nùmọ́ náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ àti ẹnikẹ́ni tí ó fi ọwọ́ kan omi ìwẹ̀nùmọ́ yóò di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.
This will be an ongoing law concerning these situations. The one who sprinkles the water for impurity must wash his clothes. The one who touches the water for impurity will become unclean until evening.
22 Gbogbo ohun tí ẹni tí ó jẹ́ aláìmọ́ bá fi ọwọ́ kàn yóò di àìmọ́, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fi ọwọ́ kàn án yóò jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.”
Whatever the unclean person touches will become unclean. The person who touches it will become unclean until evening.”