< Numbers 17 >
1 Olúwa sì sọ fún Mose pé,
Jehovah spoke to Moses, saying,
2 “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli kí o sì gba ọ̀pá méjìlá lọ́wọ́ wọn, ọ̀kọ̀ọ̀kan lọ́wọ́ olórí ìdílé ẹ̀yà ìran wọn, kọ orúkọ ènìyàn kọ̀ọ̀kan sí ara ọ̀pá rẹ̀.
"Speak to the children of Israel, and take of them rods, one for each fathers' house, of all their princes according to their fathers' houses, twelve rods: write every man's name on his rod.
3 Lórí ọ̀pá Lefi kọ orúkọ Aaroni, nítorí ọ̀pá kọ̀ọ̀kan gbọdọ̀ wà fún olórí ìdílé kọ̀ọ̀kan tí yóò jẹ́ orí fún ẹ̀yà ìran kọ̀ọ̀kan.
You shall write Aaron's name on the rod of Levi; for there shall be one rod for each head of their fathers' houses.
4 Kó wọn sí àgọ́ ìpàdé níwájú ẹ̀rí níbi tí èmi ti ń pàdé yín.
You shall lay them up in the Tent of Meeting before the testimony, where I meet with you.
5 Ọ̀pá tí ó bá yí jẹ́ ti ẹni tí èmi bá yàn yóò rúwé, èmi yóò sì dá kíkùn gbogbo ìgbà àwọn ọmọ Israẹli sí yín dúró.”
It shall happen, that the rod of the man whom I shall choose shall bud: and I will make to cease from me the murmurings of the children of Israel, which they murmur against you."
6 Nígbà náà Mose bá àwọn ọmọ Israẹli sọ̀rọ̀, àwọn olórí wọn sì fún un ní ọ̀pá méjìlá, ọ̀pá kan fún olórí kọ̀ọ̀kan ẹ̀yà ìran wọn, ọ̀pá Aaroni sì wà lára àwọn ọ̀pá náà.
Moses spoke to the children of Israel; and all their leaders gave him rods, one for each leader, according to their ancestral houses, even twelve rods: and the rod of Aaron was among their rods.
7 Mose sì fi ọ̀pá wọ̀nyí lélẹ̀ níwájú Olúwa nínú àgọ́ ẹ̀rí.
Moses laid up the rods before Jehovah in the tent of the testimony.
8 Ó sì ṣe ní ọjọ́ kejì Mose wọ inú àgọ́ ẹ̀rí lọ, ó sì rí ọ̀pá Aaroni, tí ó dúró fún ẹ̀yà Lefi, kì í ṣe wí pé ó hù nìkan, ṣùgbọ́n ó rúwé, ó yọ ìtànná, ó sì so èso almondi.
It happened on the next day, that Moses went into the tent of the testimony; and look, the rod of Aaron for the house of Levi was budded, and put forth buds, and produced blossoms, and bore ripe almonds.
9 Nígbà náà ni Mose kó gbogbo àwọn ọ̀pá jáde láti iwájú Olúwa wá fún àwọn ọmọ Israẹli. Wọ́n wò wọ́n, ẹnìkọ̀ọ̀kan sì mú ọ̀pá tirẹ̀.
Moses brought out all the rods from before Jehovah to all the children of Israel: and they looked, and took every man his rod.
10 Olúwa sọ fún Mose pé, “Mú ọ̀pá Aaroni padà wá síwájú ẹ̀rí, láti fi pamọ́ gẹ́gẹ́ bí àmì fún àwọn ọlọ̀tẹ̀. Èyí ó sì mú òpin bá kíkùn sínú wọn sí mi, kí wọn kí ó má ba à kú.”
Jehovah said to Moses, "Put back the rod of Aaron before the testimony, to be kept for a token against the rebels; that you may make an end of their murmurings against me, that they not die."
11 Mose sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti páláṣẹ fún un.
Moses did so. As Jehovah commanded him, so he did.
12 Àwọn ọmọ Israẹli sọ fún Mose pé, “Àwa yóò kú! A ti sọnù, gbogbo wa ti sọnù!
The children of Israel spoke to Moses, saying, "Look, we perish. We are undone. We are all undone.
13 Ẹnikẹ́ni tí ó bá súnmọ́ tabanaku Olúwa yóò kú. Ṣé gbogbo wa ni yóò kú?”
Everyone who comes near, who comes near to the tabernacle of Jehovah, dies. Will we all perish?"