< Nehemiah 7 >

1 Lẹ́yìn ìgbà tí a tún odi mọ tán tí mo sì ri àwọn ìlẹ̀kùn sí ààyè wọn, a sì yan àwọn aṣọ́bodè, àwọn akọrin àti àwọn Lefi.
Now it happened, when the wall was built, and I had set up the doors, and the gatekeepers and the singers and the Levites were appointed,
2 Mo fún Hanani arákùnrin mi pẹ̀lú Hananiah olórí ilé ìṣọ́ ní àṣẹ lórí Jerusalẹmu, nítorí tí ó jẹ́ ènìyàn olóòtítọ́, ó sì bẹ̀rù Ọlọ́run jù bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ti ṣe lọ.
that I put my brother Hanani, and Hananiah the commander of the fortress, in charge of Jerusalem; for he was a faithful man, and feared God above many.
3 Mo sọ fún wọn pé, “A kò gbọdọ̀ ṣí ìlẹ̀kùn Jerusalẹmu títí oòrùn yóò fi mú. Nígbà tí àwọn aṣọ́bodè bá sì wà lẹ́nu iṣẹ́, jẹ́ kí wọn ti ìlẹ̀kùn kí wọn sì há wọn. Bákan náà, yàn nínú àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́. Àwọn mìíràn níbi tí a pín wọn sí àti àwọn mìíràn ní tòsí ilé e wọn.”
I said to them, "Do not let the gates of Jerusalem be opened until the sun is hot; and while they stand guard, let them shut the doors, and you bar them: and appoint watches of the inhabitants of Jerusalem, everyone in his watch, with everyone near his house."
4 Ìlú náà tóbi ó sì ní ààyè, ṣùgbọ́n ènìyàn inú rẹ̀ kéré, a kò sì tí ì tún àwọn ilé inú rẹ̀ kọ́.
Now the city was wide and large; but the people were few in it, and the houses were not built.
5 Nígbà náà ni Ọlọ́run mi fi sí mi ní ọkàn láti kó àwọn ọlọ́lá, àwọn ìjòyè, àti àwọn ènìyàn jọ fún ìforúkọsílẹ̀ ní ìdílé ìdílé. Mo rí ìwé àkọsílẹ̀ ìtàn ìran àwọn tí ó kọ́ gòkè padà wá láti ìgbèkùn. Èyí ni ohun tí mo rí tí a kọ sínú ìwé náà.
My God put into my heart to gather together the nobles, and the rulers, and the people, that they might be reckoned by genealogy. I found the book of the genealogy of those who came up at the first, and I found written in it:
6 Èyí ni àwọn ènìyàn agbègbè náà tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ wá láti ìgbèkùn, àwọn tí Nebukadnessari ọba Babeli ti kó ní ìgbèkùn (wọ́n padà sí Jerusalẹmu àti Juda, olúkúlùkù sí ìlú u rẹ̀.
These are the people of the province, who went up out of the captivity of those who had been carried away, whom Nebuchadnezzar the king of Babylon had carried away, and who returned to Jerusalem and to Judah, everyone to his city;
7 Wọ́n jọ rìn wá pẹ̀lú u Serubbabeli, Jeṣua, Nehemiah, Asariah, Raamiah, Nahamani, Mordekai, Bilṣani, Misperi, Bigfai, Nehumu, àti Baanah). Àkọsílẹ̀ orúkọ àwọn ọkùnrin Israẹli,
who came with Zerubbabel, Jeshua, Nehemiah, Seraiah, Reelaiah, Nahamani, Mordecai, Bilshan, Mispar, Bigvai, Rehum, Baanah. The number of the men of the people of Israel:
8 àwọn ọmọ Paroṣi jẹ́ ẹgbàá ó lé méjìléláàádọ́sàn-án
The descendants of Parosh, two thousand one hundred seventy-two.
9 Ṣefatia jẹ́ òjìdínnírinwó ó lé méjìlá
The descendants of Shephatiah, three hundred seventy-two.
10 Arah jẹ́ ẹgbẹ̀tàléláàádọ́ta ó lé méjì
The descendants of Arah, six hundred fifty-two.
11 Pahati-Moabu (láti ipasẹ̀ ọmọ Jeṣua àti Joabu) jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìnlá ó lé méjìdínlógún
The descendants of Pahath-Moab, of the descendants of Jeshua and Joab, two thousand eight hundred eighteen.
12 Elamu jẹ́ àádọ́ta lé lẹ́gbẹ̀fà ó lé mẹ́rin
The descendants of Elam, one thousand two hundred fifty-four.
13 Sattu jẹ́ òjìlélẹ́gbẹ̀rin ó lé márùn-ún
The descendants of Zattu, eight hundred forty-five.
14 Sakkai jẹ́ òjìdínlẹ́gbẹ̀rin
The descendants of Zaccai, seven hundred sixty.
15 Binnui jẹ́ òjìlélẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́jọ
The descendants of Bani, six hundred forty-eight.
16 Bebai jẹ́ ẹgbẹ̀ta ó lé méjìdínlọ́gbọ̀n
The descendants of Bebai, six hundred twenty-eight.
17 Asgadi jẹ́ ẹgbẹ̀ta ó dín méjìdínlọ́gọ́rin
The descendants of Azgad, two thousand three hundred twenty-two.
18 Adonikami jẹ́ ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀ta ó lé méje
The descendants of Adonikam, six hundred sixty-seven.
19 Bigfai jẹ́ ẹgbàá ó lé mẹ́tàdínláàádọ́rin
The descendants of Bigvai, two thousand sixty-seven.
20 Adini jẹ́ àádọ́ta lé lẹ́gbẹ̀ta ó lé márùn-ún
The descendants of Adin, six hundred fifty-five.
21 Ateri (láti ipasẹ̀ Hesekiah) jẹ́ méjìdínlọ́gọ́rùn-ún
The descendants of Ater, of Hezekiah, ninety-eight.
22 Haṣumu jẹ́ ọ̀rìndínnírinwó ó lé mẹ́jọ
The descendants of Hashum, three hundred Twenty-eight.
23 Besai jẹ́ ọ̀rìndínnírinwó ó lé mẹ́rin
The descendants of Bezai, three hundred twenty-four.
24 Harifu jẹ́ méjìléláàádọ́fà
The descendants of Jorah, one hundred twelve.
25 Gibeoni jẹ́ márùndínlọ́gọ́rùn.
The descendants of Gibbar, ninety-five.
26 Àwọn ọmọ Bẹtilẹhẹmu àti Netofa jẹ́ igba ó dín méjìlélógún
The men of Bethlehem and Netophah, one hundred eighty-eight.
27 Anatoti jẹ́ méjìdínláàádóje
The men of Anathoth, one hundred twenty-eight.
28 Beti-Asmafeti jẹ́ méjìlélógójì
The men of Beth Azmaveth, forty-two.
29 Kiriati-Jearimu, Kefira, àti Beeroti jẹ́ ọ̀tàdínlẹ́gbẹ̀rin ó lé mẹ́ta
The men of Kiriath Jearim, Kephirah, and Beeroth, seven hundred forty-three.
30 Rama àti Geba jẹ́ ẹgbẹ̀ta ó lé mọ́kànlélógún
The men of Ramah and Geba, six hundred twenty-one.
31 Mikmasi jẹ́ méjìlélọ́gọ́fà
The men of Michmas, one hundred and twenty-two.
32 Beteli àti Ai jẹ́ mẹ́tàlélọ́gọ́fà
The men of Bethel and Ai, a hundred twenty-three.
33 Nebo mìíràn jẹ́ méjìléláàádọ́ta
The men of the other Nebo, fifty-two.
34 Elamu mìíràn jẹ́ ẹgbẹ̀fà ó lé mẹ́rìnléláàádọ́ta
The descendants of the other Elam, one thousand two hundred fifty-four.
35 Harimu jẹ́ ọ̀rìndínnírinwó
The descendants of Harim, three hundred twenty.
36 Jeriko jẹ́ ọ̀tàdínnírinwó ó lé márùn-ún.
The descendants of Jericho, three hundred forty-five.
37 Lodi, Hadidi, àti Ono jẹ́ ọ̀rìndínlẹ́gbẹ̀rin ó lé ọ̀kan
The descendants of Lod, Hadid, and Ono, seven hundred twenty-one.
38 Senaa jẹ́ ẹgbàajì ó dín àádọ́rin.
The descendants of Senaah, three thousand nine hundred thirty.
39 Àwọn àlùfáà: àwọn ọmọ Jedaiah (láti ipasẹ̀ ìdílé Jeṣua) jẹ́ ogún dín lẹ́gbẹ̀rin ó dín méje
The priests: The descendants of Jedaiah, of the house of Jeshua, nine hundred seventy-three.
40 Immeri jẹ́ àádọ́ta lé lẹ́gbẹ̀rún ó lé méjì
The descendants of Immer, one thousand fifty-two.
41 Paṣuri jẹ́ ẹgbẹ̀fà ó lé mẹ́tàdínláàádọ́ta
The descendants of Pashhur, one thousand two hundred forty-seven.
42 Harimu jẹ́ ẹgbẹ̀rún ó lé mẹ́tàdínlógún.
The descendants of Harim, one thousand seventeen.
43 Àwọn ọmọ Lefi: àwọn ọmọ Jeṣua (láti ipasẹ̀ Kadmieli, láti ipasẹ̀ Hodafiah) jẹ́ mẹ́rìnléláàádọ́rin.
The Levites: the descendants of Jeshua, of Kadmiel, of the descendants of Hodaviah, seventy-four.
44 Àwọn akọrin: àwọn ọmọ Asafu jẹ́ méjìdínláàádọ́jọ.
The singers: the descendants of Asaph, one hundred forty-eight.
45 Àwọn aṣọ́nà: àwọn ọmọ Ṣallumu, Ateri, Talmoni, Akkubu, Hatita, àti Ṣobai jẹ́ méjìdínlógóje.
The gatekeepers: the descendants of Shallum, the descendants of Ater, the descendants of Talmon, the descendants of Akkub, the descendants of Hatita, the descendants of Shobai, one hundred thirty-eight.
46 Àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili. Àwọn ọmọ Siha, Hasufa, Tabboati,
The Nethinim: the descendants of Ziha, the descendants of Hasupha, the descendants of Tabbaoth,
47 Kerosi, Sia, Padoni,
the descendants of Keros, the descendants of Siaha, the descendants of Padon,
48 Lebana, Hagaba, Ṣalmai,
the descendants of Lebana, the descendants of Hagaba, the descendants of Salmai,
49 Hanani, Giddeli, Gahari,
the descendants of Hanan, the descendants of Giddel, the descendants of Gahar,
50 Reaiah, Resini, Nekoda,
the descendants of Reaiah, the descendants of Rezin, the descendants of Nekoda,
51 Gassamu, Ussa, Pasea,
the descendants of Gazzam, the descendants of Uzza, the descendants of Paseah.
52 Besai, Mehuni, Nefisimu,
The descendants of Besai, the descendants of Meunim, the descendants of Nephusim,
53 Bakbu, Hakufa, Harhuri,
the descendants of Bakbuk, the descendants of Hakupha, the descendants of Harhur,
54 Basluti, Mehida, Harṣa,
the descendants of Bazluth, the descendants of Mehida, the descendants of Harsha,
55 Barkosi, Sisera, Tema,
the descendants of Barkos, the descendants of Sisera, the descendants of Temah,
56 Nesia, àti Hatifa.
the descendants of Neziah, the descendants of Hatipha.
57 Àwọn ọmọ àwọn ìránṣẹ́ Solomoni: àwọn ọmọ Sotai, Sofereti; Perida,
The descendants of Solomon's servants: the descendants of Sotai, the descendants of Hassophereth, the descendants of Peruda,
58 Jaala, Darkoni, Giddeli,
the descendants of Jaalah, the descendants of Darkon, the descendants of Giddel,
59 Ṣefatia, Hattili, Pokereti-Haṣṣebaimu, àti Amoni.
the descendants of Shephatiah, the descendants of Hattil, the descendants of Pokereth Hazzebaim, the descendants of Amon.
60 Àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili àti àwọn ọmọ ìránṣẹ́ Solomoni jẹ́ irinwó ó dín mẹ́jọ.
All the Nethinim, and the descendants of Solomon's servants, were three hundred ninety-two.
61 Àwọn wọ̀nyí gòkè wá láti àwọn ìlú ti Teli-Mela, Teli-Harṣa, Kerubu, Addoni àti Immeri, ṣùgbọ́n wọn kò lè sọ pẹ̀lú ìdánilójú pé ìdílé àwọn wá láti ara ìran ẹ̀yà Israẹli.
These were those who went up from Tel Melah, Tel Harsha, Cherub, Addan, and Immer; but they could not prove their ancestral houses, nor their descent, whether they were of Israel:
62 Àwọn ọmọ Delaiah, Tobiah àti Nekoda jẹ́ òjìlélẹ́gbẹ̀ta ó lé méjì.
The descendants of Delaiah, the descendants of Tobiah, the descendants of Nekoda, six hundred forty-two.
63 Lára àwọn àlùfáà ni: àwọn ọmọ Hobaiah, Hakosi àti Barsillai (ọkùnrin tí ó fẹ́ ọmọbìnrin Barsillai ará Gileadi, ẹni tí a ń fi orúkọ yìí pè).
Of the priests: the descendants of Hobaiah, the descendants of Hakkoz, the descendants of Barzillai, who took a wife of the daughters of Barzillai the Gileadite, and was called after their name.
64 Àwọn wọ̀nyí wá àkọsílẹ̀ orúkọ ìran wọn, ṣùgbọ́n wọn kò rí í níbẹ̀, fún ìdí èyí, a yọ wọ́n kúrò nínú àwọn tí ń ṣiṣẹ́ àlùfáà gẹ́gẹ́ bí aláìmọ́.
These searched for their genealogical records, but couldn't find them. Therefore were they deemed polluted and put from the priesthood.
65 Baálẹ̀ sọ fún wọn nítorí náà pé wọn kò gbọdọ̀ kópa nínú jíjẹ oúnjẹ mímọ́ títí tí àlùfáà tí yóò wá tí ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ pẹ̀lú Urimu àti Tumimu yóò fi dé.
The governor said to them, that they should not eat of the most holy things, until there stood up a priest with Urim and Thummim.
66 Gbogbo ìjọ ènìyàn náà jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlélógún ó lé òjìdínnírinwó,
The whole assembly together was forty-two thousand three hundred sixty,
67 yàtọ̀ sí àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin tí wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀ta dín lẹ́gbàárin ó dín ẹ̀tàlélọ́gọ́ta; wọ́n sì tún ní àwọn akọrin ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n jẹ́ òjìlúgba ó lé márùn-ún.
besides their male servants and their female servants, of whom there were seven thousand three hundred thirty-seven: and they had two hundred forty-five singing men and singing women.
68 Ẹṣin wọn jẹ́ ọ̀tàdínlẹ́gbẹ̀rin ó dín mẹ́rin, ìbákasẹ wọn jẹ́ òjìlúgba ó dín márùn-ún;
Their horses were seven hundred thirty-six; their mules, two hundred forty-five;
69 ìbákasẹ wọn jẹ́ òjìlénírinwó ó dín márùn-ún; kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀rìnlélọ́gbọ̀n ó dín ọgọ́rin.
their camels, four hundred thirty-five; their donkeys, six thousand seven hundred twenty.
70 Díẹ̀ lára àwọn olórí ìdílé náà kópa nínú ṣíṣe iṣẹ́ náà. Baálẹ̀ fún ilé ìṣúra ní ẹgbẹ̀rún dariki wúrà, àádọ́ta àwo koto àti ọ̀rìndínlẹ́gbẹ̀ta lé mẹ́wàá ẹ̀wù fún àwọn àlùfáà.
Some from among the heads of ancestral houses gave to the work. The governor gave to the treasury one thousand darics of gold, fifty basins, and five hundred thirty priests' garments.
71 Díẹ̀ lára àwọn olórí ìdílé fún ilé ìṣúra ní ogún ẹgbẹ̀rún dariki wúrà àti ẹgbọ̀kànlá mina fàdákà.
Some of the heads of ancestral houses gave into the treasury of the work twenty thousand darics of gold, and two thousand two hundred minas of silver.
72 Àròpọ̀ gbogbo ohun tí àwọn ènìyàn tókù fi sílẹ̀ jẹ́ ogún ẹgbẹ̀rún dariki wúrà, ẹgbẹ̀rún méjì mina fàdákà àti ẹẹ́tàdínláàdọ́rin ẹ̀wù fún àwọn àlùfáà.
That which the rest of the people gave was twenty thousand darics of gold, and two thousand minas of silver, and sixty-seven priests' garments.
73 Àwọn àlùfáà, àwọn Lefi, àwọn aṣọ́bodè, àwọn akọrin, àwọn ènìyàn díẹ̀, àwọn ìránṣẹ́ ilé Ọlọ́run, àti gbogbo ènìyàn Israẹli wà ní ìlú wọn. Nígbà tí ó di oṣù keje, tí àwọn ọmọ Israẹli sì ti wà nínú ìlú u wọn,
So the priests, and the Levites, and the gatekeepers, and the singers, and some of the people, and the Nethinim, and all Israel, lived in their cities. When the seventh month had come, the children of Israel were in their cities.

< Nehemiah 7 >