< Nehemiah 3 >

1 Eliaṣibu olórí àlùfáà àti àwọn àlùfáà arákùnrin rẹ̀ lọ ṣiṣẹ́, wọ́n sì tún ibodè Àgùntàn mọ. Wọ́n yà á sí mímọ́, wọ́n sì gbé ìlẹ̀kùn dúró sí ibi tí ó yẹ, wọ́n mọ ọ́n títí dé ilé ìṣọ́ ọgọ́rùn-ún, èyí tí wọ́n yà sí mímọ́ títí dé ilé ìṣọ́ gíga Hananeli.
Entonces el sumo sacerdote Eliasib se levantó con sus hermanos sacerdotes. Reedificaron la puerta de las Ovejas, pusieron las hojas de la puerta y la consagraron. Reedificaron la torre de los Cien y consagraron [el muro] hasta la torre Hanan-ʼEl.
2 Àwọn ọkùnrin Jeriko sì mọ ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, Sakkuri ọmọ Imri sì mọ ní ẹ̀gbẹ́ àwọn ọkùnrin Jeriko.
Junto a ellos los varones de Jericó reedificaron, y a su lado Zacur, hijo de Imri, también reedificó.
3 Àwọn ọkùnrin Senaa ni wọ́n mọ ibodè ẹja. Wọ́n kún ọ̀pọ̀ ìgbéró rẹ̀, wọ́n sì gbé ìlẹ̀kùn rẹ̀, ìdábùú ìlẹ̀kùn àti àwọn ìdè e rẹ̀ sí ààyè e wọn.
Los hijos de Senaa reedificaron la puerta de los Peces. Ellos la enmaderaron y pusieron las hojas de su puerta, con sus cerraduras y cerrojos.
4 Meremoti ọmọ Uriah, ọmọ Hakosi tún èyí tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ ẹ wọn mọ. Ẹni tí ó tún wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ni Meṣullamu ọmọ Berekiah, ọmọ Meṣesabeli tún èyí ti ó wà ní ẹ̀gbẹ́ wọn mọ. Bákan náà ni ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, Sadoku ọmọ Baanah náà tún odi mọ.
Junto a ellos Meremot, hijo de Urías, hijo de Cos, reedificó. Junto a él restauró Mesulam, hijo de Berequías, hijo de Mesezabeel, y a su lado reparó Sadoc, hijo de Baana.
5 Èyí tí ó tún wà ní ẹ̀gbẹ́ wọn ni àwọn ọkùnrin Tekoa tún mọ, ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́lá kò ṣe àtìlẹ́yìn fún iṣẹ́ náà lábẹ́ àwọn olórí wọn.
Los tecoítas repararon junto a ellos, pero sus nobles no apoyaron el trabajo de sus señores.
6 Jehoida ọmọ Pasea àti Meṣullamu ọmọ Besodeiah ni wọ́n tún ẹnu ibodè àtijọ́ ṣe. Wọ́n kún bíìmù rẹ̀, wọ́n ri àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀, àwọn ìdábùú ìlẹ̀kùn àti àwọn ìdè rẹ̀ sí ààyè wọn.
La puerta Antigua fue reparada por Joiada, hijo de Pasea, y Mesulam, hijo de Besodías. Ellos mismos la enmaderaron, pusieron las hojas de su puerta, sus cerraduras y sus cerrojos.
7 Lẹ́yìn in wọn ni àtúnṣe tún wà láti ọ̀dọ̀ àwọn ọkùnrin Gibeoni àti Mispa; Melatiah ti Gibeoni àti Jadoni ti Meronoti; àwọn ibi tí ó wà lábẹ́ àṣẹ baálẹ̀ agbègbè Eufurate.
Junto a ellos repararon Melatías gabaonita y Jadón meronotita, hombres de Gabaón y Mizpa, según la autoridad del gobernador de Más Allá del Río.
8 Usieli ọmọ Harhiah, ọ̀kan lára àwọn alágbẹ̀dẹ wúrà, túnṣe àtúnṣe èyí tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀; àti Hananiah, ọ̀kan lára àwọn tí ó ń ṣe tùràrí, túnṣe àtúnṣe èyí tí ó tún tẹ̀lé e. Wọ́n mú Jerusalẹmu padà bọ̀ sípò títí dé Odi gbígbòòrò.
Al lado de ellos reparó Uziel, hijo de Harhaía, uno de los que trabajaban con objetos de metales preciosos. Junto a él restauró Hananías, hijo de un perfumista. Así restauraron [el muro de] Jerusalén hasta el muro ancho.
9 Refaiah ọmọ Huri, alákòóso ìdajì agbègbè Jerusalẹmu, tún èyí tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ ṣe.
Junto a ellos reparó Refaías, hijo de Hur, jefe de la mitad del distrito Jerusalén.
10 Ní ẹ̀gbẹ́ èyí Jedaiah ọmọ Haramafu tún èyí tí ó wà ní ọ̀ọ́kán ilé rẹ̀ mọ, Hattusi ọmọ Haṣbneiah sì tún tí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ mọ.
Y junto a él Jedaías, hijo de Harumaf, reparó al frente de su casa. A su lado reparó Hatús, hijo de Hasabnías.
11 Malkiah ọmọ Harimu àti Haṣubu ọmọ Pahati-Moabu tún ẹ̀gbẹ́ kejì ṣe àti ilé ìṣọ́ ìléru.
Malquías, hijo de Harim, y Hasub, hijo de Pajat-moab, repararon el otro tramo y la torre de los Hornos.
12 Ṣallumu ọmọ Halloheṣi, alákòóso ìdajì agbègbè Jerusalẹmu tún ti ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ mọ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ọmọbìnrin rẹ̀.
Junto a ellos reparó Salum, hijo de Halohes, jefe de la otra mitad del distrito Jerusalén, él con sus hijas.
13 Ibodè àfonífojì ni Hanuni àti àwọn ará Sanoa tún mọ. Wọ́n tún un kọ́, wọ́n ri àwọn ìlẹ̀kùn àti àwọn ìdè rẹ̀ sí ààyè rẹ̀. Wọ́n sì tún tún ẹgbẹ̀rún kan ìgbọ̀nwọ́ odi mọ títí dé ẹnu ibodè ààtàn.
Hanún reparó la puerta del Valle con los habitantes de Zanoa. Ellos la reedificaron y pusieron las hojas de su puerta, sus cerraduras y sus cerrojos, y además 450 metros del muro hasta la puerta del Muladar.
14 Ẹnu ibodè Ààtàn ni Malkiah ọmọ Rekabu, alákòóso agbègbè Beti-Hakeremu tún mọ. Ó tún un mọ, ó sì gbé àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀, àwọn ìdábùú ìlẹ̀kùn àti àwọn ìdè rẹ̀ sí ààyè wọn.
Malquías, hijo de Recab, jefe del distrito Bet-haquerem, reparó la puerta del Muladar. Él mismo la reedificó y puso las hojas de su puerta, sus cerraduras y sus cerrojos.
15 Ẹnu ibodè orísun ni Ṣalluni Koli-Hose, alákòóso agbègbè Mispa tún mọ. Ó tún ún mọ, ó kan òrùlé e rẹ̀ yíká, ó gbé àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀ àwọn ìdábùú ìlẹ̀kùn àti àwọn idẹ rẹ̀ ró sí ààyè wọn. Ó tún tún odi adágún Siloamu mọ, ní ẹ̀gbẹ́ ọgbà ọba, títí dé àwọn àtẹ̀gùn tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ láti ìlú Dafidi.
Salum, hijo de Colhoze, jefe de la región de Mizpa, reparó la puerta de la Fuente. Él la reedificó, la enmaderó y puso sus hojas, sus cerraduras y sus cerrojos. También edificó el muro junto al estanque de Siloé, hacia el jardín del Rey, hasta las gradas que descienden de la Ciudad de David.
16 Lẹ́yìn in rẹ̀ ni, Nehemiah ọmọ Asbuku, alákòóso ìdajì agbègbè Beti-Suri ṣe àtúnmọ dé ibi ọ̀ọ́kán òdìkejì ibojì Dafidi, títí dé adágún omi àtọwọ́dá àti títí dé ilé àwọn alágbára.
Después de él, Nehemías, hijo de Azbuc, jefe de la mitad del distrito Bet-sur, reparó hasta frente a los Sepulcros de David, el estanque artificial y la casa de los Valientes.
17 Lẹ́yìn rẹ̀ ni àwọn ará a Lefi, ní abẹ́ ẹ Rehumu ọmọ Bani. Lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ ni Haṣabiah, alákòóso ìdajì agbègbè Keila ṣe àtúnṣe fún agbègbè tirẹ̀.
Tras él repararon los levitas [dirigidos por] Reum, hijo de Bani, junto al cual reparó Hasabías, jefe de la mitad del distrito Queila, por cuenta de su distrito.
18 Lẹ́yìn rẹ̀ ni àwọn Lefi arákùnrin wọn ní abẹ́ àkóso Binnui ṣe àtúnṣe, Bafai ọmọ Henadadi, ìjòyè àwọn ìdajì agbègbè Keila.
Después de él repararon sus hermanos y Bavay, hijo de Henadad, jefe de la otra mitad del distrito Queila.
19 Lẹ́yìn rẹ̀ ni Eseri ọmọ Jeṣua, alákòóso Mispa, tún ìbò mìíràn ṣe, láti ibìkan tí ó kojú sí ibi gíga sí ilé-ìhámọ́ra títí dé orígun.
Junto a él, Ezer, hijo de Jesuá, jefe de Mizpa, reparó el otro tramo, frente a la subida del Arsenal del ángulo.
20 Lẹ́yìn rẹ̀ ni Baruku ọmọ Sakkai fi ìtara tún apá mìíràn ṣe, láti orígun dé ẹnu-ọ̀nà ilé Eliaṣibu olórí àlùfáà.
Después de él, Baruc, hijo de Zaba, reparó con gran fervor el tramo que va desde este ángulo hasta la puerta de la casa de Eliasib, el sumo sacerdote.
21 Lẹ́yìn rẹ̀ ni, Meremoti ọmọ Uriah, ọmọ Hakosi tún apá mìíràn ṣe, láti ẹnu-ọ̀nà ilé Eliaṣibu títí dé òpin rẹ̀.
Después de él, Meremot, hijo de Urías, hijo de Cos, reparó otro tramo desde la entrada hasta el extremo de la casa de Eliasib.
22 Àtúnṣe tí a tún túnṣe lẹ́yìn rẹ̀ ní àwọn àlùfáà ní àyíká agbègbè túnṣe.
Detrás de él repararon los sacerdotes procedentes de la llanura.
23 Lẹ́yìn wọn ni Benjamini àti Haṣubu tún èyí ti iwájú ilé wọn ṣe; lẹ́yìn wọn ni, Asariah ọmọ Maaseiah ọmọ Ananiah tún ti ẹ̀gbẹ́ ilé rẹ̀ ṣe.
A continuación de ellos, Benjamín y Jasub repararon frente a su casa, y después de éstos, Azarías, hijo de Maasías, hijo de Ananías, reparó junto a su casa.
24 Lẹ́yìn rẹ̀ ni Binnui ọmọ Henadadi tún apá mìíràn ṣe, láti ilé Asariah dé orígun àti kọ̀rọ̀,
A continuación, Binúi, hijo de Henadad, reparó otro tramo desde la casa de Azarías hasta el ángulo y la esquina.
25 àti Palali ọmọ Usai tún òdìkejì orígun ṣe àti ilé ìṣọ́ tí ó yọ sóde láti ibi gíga ní ẹ̀gbẹ́ ààfin ọba ti òkè lẹ́gbẹ̀ẹ́ agbègbè àwọn olùṣọ́. Lẹ́yìn rẹ̀ ni, Pedaiah ọmọ Paroṣi
Palal, hijo de Uzay, reparó frente a la esquina y la torre elevada que sobresale de la casa del Rey, que está en el patio de la cárcel, y después de él, Pedaías, hijo de Faros.
26 àti àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili tí ó ń gbé ní òkè Ofeli ṣe àtúnṣe títí dé ibi ọ̀kánkán òdìkejì ibodè omi sí ìhà ìlà-oòrùn àti ilé ìṣọ́ tí ó yọ sóde.
También los servidores establecidos en Ofel repararon hasta enfrente de la puerta de las Aguas, al oriente de la torre que sobresale.
27 Lẹ́yìn wọn ni àwọn ènìyàn Tekoa tún apá mìíràn ṣe, láti ilé ìṣọ́ ńlá tí ó yọ sóde títí dé ògiri Ofeli.
Después de ellos los tecoítas repararon otro tramo, desde frente a la torre grande que sobresale hasta el muro de Ofel.
28 Àwọn àlùfáà ni ó ṣe àtúnṣe òkè ibodè ẹṣin ṣe, ẹnìkọ̀ọ̀kan ní iwájú ilé e rẹ̀.
Los sacerdotes repararon adelante de la puerta de los Caballos, cada uno frente a su casa.
29 Lẹ́yìn wọn, Sadoku ọmọ Immeri tún ọ̀kánkán òdìkejì ilé rẹ̀ ṣe. Lẹ́yìn rẹ̀ ni Ṣemaiah ọmọ Ṣekaniah, olùṣọ́ ibodè ìhà ìlà-oòrùn ṣe àtúnṣe.
Detrás de ellos Sadoc, hijo de Imer, reparó frente a su casa, y después de él reparó Semaías, hijo de Secanías, guarda de la puerta Oriental.
30 Lẹ́yìn rẹ̀ ni, Hananiah ọmọ Ṣelemiah, àti Hanuni ọmọ ẹ̀kẹfà Salafi, tún apá ibòmíràn ṣe. Lẹ́yìn wọn ni, Meṣullamu ọmọ Berekiah tún ọ̀kánkán òdìkejì ibùgbé ẹ̀ ṣe.
En seguida de él, Hananías, hijo de Selemías, reparó otro tramo junto con Hanún, sexto hijo de Salaf. Tras éste Mesulam, hijo de Berequías, reparó frente a su casa.
31 Lẹ́yìn in rẹ̀ ni Malkiah, ọ̀kan nínú àwọn alágbẹ̀dẹ wúrà ṣe àtúnṣe títí dé ilé àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili àti àwọn oníṣòwò, ní ọ̀kánkán òdìkejì ibodè àyẹ̀wò títí dé yàrá òkè kọ̀rọ̀;
Tras él, Malquías, hijo del platero, reparó hasta las casas de los servidores del Templo y los mercaderes, enfrente de la puerta del Juicio y hasta el aposento alto de la esquina.
32 àti láàrín yàrá òkè kọ̀rọ̀ àti ibodè àgùntàn ni àwọn alágbẹ̀dẹ wúrà àti àwọn oníṣòwò túnṣe.
Los orífices y los mercaderes repararon entre el aposento alto de la esquina y la puerta de las Ovejas.

< Nehemiah 3 >