< Nehemiah 10 >
1 Àwọn tí ó fi èdìdì dì í ni: Nehemiah baálẹ̀, ọmọ Hakaliah. Sedekiah
印を捺る者はハカリヤの子テルシヤタ、ネヘミヤおよびゼデキヤ
2 Seraiah, Asariah, Jeremiah,
セラヤ、アザリヤ、ヱレミヤ
3 Paṣuri, Amariah, Malkiah,
パシユル、アマリヤ、マルキヤ、
4 Hattusi, Ṣebaniah, Malluki,
ハツトシ、シバニヤ、マルク
5 Harimu, Meremoti, Obadiah,
ハリム、メレモテ、オバデヤ
6 Daniẹli, Ginetoni, Baruku,
ダニエル、ギンネトン、バルク
7 Meṣullamu, Abijah, Mijamini,
メシユラム、アビヤ、ミヤミン
8 Maasiah, Bilgai àti Ṣemaiah. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn àlùfáà.
マアジア、ビルガ、シマヤ是等は祭司なり
9 Àwọn ọmọ Lefi: Jeṣua ọmọ Asaniah, Binnui ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Henadadi, Kadmieli,
レビ人は即ちアザニヤの子ヱシユア 、ヘナダデの子ビンヌイ、カデミエル
10 àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn: Ṣebaniah, Hodiah, Kelita, Pelaiah, Hanani,
ならびに其兄弟シバ二ヤ、ホデヤ、ケリタ、ペラヤ、ハナン
11 Mika, Rehobu, Haṣabiah,
ミカ、レホブ、ハシヤビヤ
12 Sakkuri, Ṣerebiah, Ṣebaniah,
ザツクル、セレビヤ、シバ二ヤ
13 Hodiah, Bani àti Beninu.
ホデヤ、バニ、ベニヌ
14 Àwọn olórí àwọn ènìyàn: Paroṣi, Pahati-Moabu, Elamu, Sattu, Bani,
民の長たる者はパロシ、パハテモアブ、エラム、ザツト、バニ
16 Adonijah, Bigfai, Adini,
アドニヤ、ビグワイ、アデン
17 Ateri, Hesekiah, Assuri,
アテル、ヒゼキヤ、アズル
18 Hodiah, Haṣumu, Besai,
ホデヤ、ハシユム、ベザイ
19 Harifu, Anatoti, Nebai,
ハリフ、アナトテ、ノバイ
20 Magpiaṣi, Meṣullamu, Hesiri
マグピアシ、メシユラム、ヘジル
21 Meṣesabeli, Sadoku, Jaddua
メシザベル、ザドク、ヤドア
22 Pelatiah, Hanani, Anaiah,
ペラテヤ、ハナン、アナニヤ
23 Hosea, Hananiah, Haṣubu,
ホセア、ハナニヤ、ハシユブ
24 Halloheṣi, Pileha, Ṣobeki,
ハロヘシ、ピルハ、シヨベク
25 Rehumu, Haṣabna, Maaseiah,
レホム、ハシヤブナ、マアセヤ
26 Ahijah, Hanani, Anani,
アヒヤ、ハナン、アナン
27 Malluki, Harimu, àti Baanah.
マルク、ハリム、バアナ
28 “Àwọn ènìyàn tókù—àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Lefi, àwọn aṣọ́nà, àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili àti gbogbo àwọn tí wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ènìyàn àjèjì nítorí òfin Ọlọ́run, papọ̀ pẹ̀lú ìyàwó wọn, gbogbo ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wọn, tí òye yé
その餘の民祭司レビ人門をまもる者謳歌者ネテニ人ならびに都て國々の民等と離れて神の律法に附る者およびその妻その男子女子など凡そ事を知り辨まふる者は
29 gbogbo wọn fi ara mọ́ àwọn arákùnrin wọn, àwọn ọlọ́lá, wọ́n sì fi ègún àti ìbúra dé ara wọn láti máa tẹ̀lé òfin Ọlọ́run tí a fi fún wọn ní ipasẹ̀ Mose ìránṣẹ́ Ọlọ́run àti láti pa gbogbo àṣẹ, ìlànà àti òfin Olúwa, wa mọ́ dáradára.
皆その兄弟たる貴き人々に附したがひ呪詛に加はり誓を立て云く我ら神の僕モーセによりて傳はりし神の律法に歩み我らの主ヱホバの一切の誡命およびその例規と法度を守り行はん
30 “A ti ṣe ìlérí pé, a kò ní fi àwọn ọmọbìnrin wa fún àwọn tí wọ́n wà ní àyíká wa bí ìyàwó, tàbí fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin wa.
我らは此地の民等に我らの女子を與へじ亦われらの男子のために彼らの女子を娶らじ
31 “Nígbà tí àwọn ènìyàn àdúgbò bá mú ọjà tàbí oúnjẹ wá ní ọjọ́ ìsinmi láti tà, àwa kò ní rà á ní ọwọ́ wọn ní ọjọ́ ìsinmi tàbí ní ọjọ́ mímọ́ kankan. Ní gbogbo ọdún keje àwa kò ní ro ilẹ̀ náà, a ó sì pa gbogbo àwọn gbèsè rẹ́.
比地の民等たとひ貨物あるひは食物を安息日に携へ來りて賣んとするとも安息日または聖日には我儕これを取じ又七年ごとに耕作を廢め一切の負債を免さんと
32 “Àwa gbà ojúṣe láti máa pa àṣẹ mọ́ pé, a ó máa san ìdámẹ́ta ṣékélì ní ọdọọdún fún iṣẹ́ ilé Ọlọ́run wa:
我らまた自ら例を設けて年々にシケルの三分の一を出して我らの神の室の用となし
33 nítorí oúnjẹ tí ó wà lórí tábìlì; nítorí ọrẹ ohun jíjẹ àti ẹbọ sísun ìgbà gbogbo; nítorí ọrẹ ọjọ́ ìsinmi, ti àyajọ́ oṣù tuntun àti àjọ̀dún tí a yàn; nítorí ọrẹ mímọ́; nítorí ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù fún Israẹli; àti fún gbogbo iṣẹ́ ilé Ọlọ́run wa.
供物のパン常素祭常燔祭のため安息日月朔および節會の祭物のため聖物のためイスラエルの贖をなす罪祭および我らの神の家の諸の工のために之を用ゐることを定む
34 “Àwa, àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Lefi àti àwọn ènìyàn náà ti dìbò láti pinnu ìgbà tí olúkúlùkù àwọn ìdílé yóò mú ọrẹ igi wá láti sun lọ́ríi pẹpẹ Olúwa Ọlọ́run wa sí ilé Ọlọ́run wa, ní àkókò tí a yàn ní ọdọọdún. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sínú ìwé òfin.
また我ら祭司レビ人および民籤を掣き律法に記されたるごとく我らの神ヱホバの壇の上に焚べき薪木の禮物を年々定まれる時にわれらの宗家にしたがひて我らの神の室に納むる者を定め
35 “Àwa tún gbà ojúṣe láti mú àkọ́so àwọn èso wa wá àti gbogbo èso igi wá ní ilé Olúwa.
かつ誓ひて云ふ我らの產物の初および各種の樹の果の初を年々ヱホバの室に携へきたらん
36 “Gẹ́gẹ́ bí a sì ti kọ ọ́ sínú ìwé òfin, àwa yóò mú àkọ́bí àwọn ọmọkùnrin wa, ti ohun ọ̀sìn wa, ti àwọn abo màlúù àti ti àwọn àgùntàn wa, wá sí ilé Ọlọ́run wa, fún àwọn àlùfáà tí ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀.
また我らの子等および我らの獣畜の首出および我らの牛羊の首出を律法に記されたるごとく我らの神の室に携へ來りて我らの神の室に事ふる祭司に交し
37 “Síwájú sí i, àwa yóò mú àkọ́so oúnjẹ ilẹ̀ wa ti ọrẹ oúnjẹ, ti gbogbo èso àwọn igi àti ti wáìnì tuntun wa àti ti òróró wá sí yàrá ìkó nǹkan pamọ́ sí ilé Ọlọ́run wa àti fún àwọn àlùfáà. Àwa yóò sì mú ìdámẹ́wàá ohun ọ̀gbìn wá fún àwọn ọmọ Lefi, nítorí àwọn ọmọ Lefi ni ó ń gba ìdámẹ́wàá ní gbogbo àwọn ìlú tí a ti ń ṣiṣẹ́.
我らの麥粉の初われらの擧祭の物各種の樹の果および洒油を祭司の許に携へ到りて我らの神の家の室に納め我らの產物の什一をレビ人に與へんレビ人は我らの一切の農作の邑においてその什一を受べき者なればなり
38 Àlùfáà tí o ti ìdílé Aaroni wá ni yóò wá pẹ̀lú àwọn ọmọ Lefi nígbà tí wọ́n bá ń gba ìdámẹ́wàá, àwọn ọmọ Lefi yóò sì mú ìdámẹ́wàá ti ìdámẹ́wàá náà wá sí ilé Ọlọ́run, sí yàrá ìkó nǹkan pamọ́ sí inú ilé ìṣúra.
レビ人什一を受る時にはアロンの子孫たる祭司一人そのレビ人と偕にあるべし而してまたレビ人はその什一の十分の一を我らの神の家に携へ上りて府庫の諸室に納むべし
39 Àwọn ènìyàn Israẹli, àti àwọn ọmọ Lefi gbọdọ̀ mú ọrẹ oúnjẹ, wáìnì tuntun àti òróró wá sí yàrá ìkó nǹkan pamọ́ sí níbi tí a pa ohun èlò ibi mímọ́ mọ́ sí àti ibi tí àwọn àlùfáà tí ń ṣe ìránṣẹ́ lọ́wọ́, àwọn aṣọ́nà àti àwọn akọrin máa ń dúró sí. “Àwa kì yóò gbàgbé tàbí ṣe àìbìkítà nípa ilé Ọlọ́run wa.”
即ちイスラエルの子孫およびレビの子孫は穀物および酒油の擧祭を携さへいたり聖所の器皿および奉事をする祭司門を守る者謳歌者などが在るところの室に之を納むべし我らは我らの神の家を棄じ