< Nahum 2 >

1 Àwọn apanirun ti dìde sí ọ, ìwọ Ninefe. Pa ilé ìṣọ́ mọ́, ṣọ́ ọ̀nà náà, di àmùrè, ẹ̀gbẹ́ rẹ kí ó le múra gírí.
עָלָ֥ה מֵפִ֛יץ עַל־פָּנַ֖יִךְ נָצ֣וֹר מְצֻרָ֑ה צַפֵּה־דֶ֙רֶךְ֙ חַזֵּ֣ק מָתְנַ֔יִם אַמֵּ֥ץ כֹּ֖חַ מְאֹֽד׃
2 Olúwa yóò mú ọláńlá Jakọbu padà sípò gẹ́gẹ́ bí ọláńlá Israẹli bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn apanirun ti pa ibẹ̀ run, tí wọ́n sì ba ẹ̀ka àjàrà wọn jẹ́.
כִּ֣י שָׁ֤ב יְהוָה֙ אֶת־גְּא֣וֹן יַעֲקֹ֔ב כִּגְא֖וֹן יִשְׂרָאֵ֑ל כִּ֤י בְקָקוּם֙ בֹּֽקְקִ֔ים וּזְמֹרֵיהֶ֖ם שִׁחֵֽתוּ׃
3 Asà àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ sì di pupa; àwọn ológun wọn sì wọ aṣọ òdòdó. Idẹ tí ó wà lórí kẹ̀kẹ́ ogun ń kọ mọ̀nàmọ́ná ní ọjọ́ tí a bá pèsè wọn sílẹ̀ tán; igi firi ni a ó sì mì tìtì.
מָגֵ֨ן גִּבֹּרֵ֜יהוּ מְאָדָּ֗ם אַנְשֵׁי־חַ֙יִל֙ מְתֻלָּעִ֔ים בְּאֵשׁ־פְּלָד֥וֹת הָרֶ֖כֶב בְּי֣וֹם הֲכִינ֑וֹ וְהַבְּרֹשִׁ֖ים הָרְעָֽלוּ׃
4 Àwọn kẹ̀kẹ́ ogun yóò ya bo àwọn pópónà, wọn yóò sì máa sáré síwá àti sẹ́yìn ní àárín ìgboro. Wọn sì dàbí ètùfù iná; tí ó sì kọ bí i mọ̀nàmọ́ná.
בַּֽחוּצוֹת֙ יִתְהוֹלְל֣וּ הָרֶ֔כֶב יִֽשְׁתַּקְשְׁק֖וּן בָּרְחֹב֑וֹת מַרְאֵיהֶן֙ כַּלַּפִּידִ֔ם כַּבְּרָקִ֖ים יְרוֹצֵֽצוּ׃
5 Ninefe yóò ṣe àṣàrò àwọn ọlọ́lá rẹ̀; síbẹ̀ wọ́n ń kọsẹ̀ ní ojú ọ̀nà wọn; wọn sáré lọ sí ibi odi rẹ̀, a ó sì pèsè ààbò rẹ̀.
יִזְכֹּר֙ אַדִּירָ֔יו יִכָּשְׁל֖וּ בַּהֲלִֽיכָתָ֑ם יְמַֽהֲרוּ֙ חֽוֹמָתָ֔הּ וְהֻכַ֖ן הַסֹּכֵֽךְ׃
6 A ó ṣí ìlẹ̀kùn àwọn odò wọ̀n-ọn-nì sílẹ̀, a ó sì mú ààfin náà di wíwó palẹ̀.
שַׁעֲרֵ֥י הַנְּהָר֖וֹת נִפְתָּ֑חוּ וְהַֽהֵיכָ֖ל נָמֽוֹג׃
7 A pa á láṣẹ pé ìlú náà, èyí tí a ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ ni a ó sì kó ní ìgbèkùn lọ. A ó sì mú un gòkè wá àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ yóò kérora bí ti ẹyẹ àdàbà, wọn a sì máa lu àyà wọn.
וְהֻצַּ֖ב גֻּלְּתָ֣ה הֹֽעֲלָ֑תָה וְאַמְהֹתֶ֗יהָ מְנַֽהֲגוֹת֙ כְּק֣וֹל יוֹנִ֔ים מְתֹפְפֹ֖ת עַל־לִבְבֵהֶֽן׃
8 Ninefe dàbí adágún omi, tí omi rẹ̀ sì ń gbẹ́ ẹ lọ. “Dúró! Dúró!” ni wọ́n ó máa kígbe, ṣùgbọ́n ẹnìkankan kì yóò wo ẹ̀yìn.
וְנִינְוֵ֥ה כִבְרֵֽכַת־מַ֖יִם מִ֣ימֵי הִ֑יא וְהֵ֣מָּה נָסִ֔ים עִמְד֥וּ עֲמֹ֖דוּ וְאֵ֥ין מַפְנֶֽה׃
9 “Ẹ kó ìkógun fàdákà! Ẹ kó ìkógun wúrà! Ìṣúra wọn ti kò lópin náà, àti ọrọ̀ kúrò nínú gbogbo ohun èlò ti a fẹ́!”
בֹּ֥זּוּ כֶ֖סֶף בֹּ֣זּוּ זָהָ֑ב וְאֵ֥ין קֵ֙צֶה֙ לַתְּכוּנָ֔ה כָּבֹ֕ד מִכֹּ֖ל כְּלִ֥י חֶמְדָּֽה׃
10 Òun ti ṣòfò, ó si di asán, ó sì di ahoro: ọkàn pami, eékún ń lu ara wọn, ìrora púpọ̀ sì wà nínú gbogbo ẹgbẹ́ àti ojú gbogbo wọ́n sì rẹ̀wẹ̀sì.
בּוּקָ֥ה וּמְבוּקָ֖ה וּמְבֻלָּקָ֑ה וְלֵ֨ב נָמֵ֜ס וּפִ֣ק בִּרְכַּ֗יִם וְחַלְחָלָה֙ בְּכָל־מָתְנַ֔יִם וּפְנֵ֥י כֻלָּ֖ם קִבְּצ֥וּ פָארֽוּר׃
11 Níbo ni ihò àwọn kìnnìún wà àti ibi ìjẹun àwọn ọmọ kìnnìún, níbi tí kìnnìún, àní abo kìnnìún tí ń rìn, àti ọmọ kìnnìún, láìsí ohun ìbẹ̀rù.
אַיֵּה֙ מְע֣וֹן אֲרָי֔וֹת וּמִרְעֶ֥ה ה֖וּא לַכְּפִרִ֑ים אֲשֶׁ֣ר הָלַךְ֩ אַרְיֵ֨ה לָבִ֥יא שָׁ֛ם גּ֥וּר אַרְיֵ֖ה וְאֵ֥ין מַחֲרִֽיד׃
12 Kìnnìún tipa ọ̀pọ̀lọpọ̀ fún àwọn ọmọ rẹ̀, ó sì fún un ẹran ọdẹ ní ọrùn pa fún àwọn abo kìnnìún rẹ̀, ó sì fi ohun pípa kún ibùgbé rẹ̀ àti ihò rẹ̀ fún ohun ọdẹ.
אַרְיֵ֤ה טֹרֵף֙ בְּדֵ֣י גֹֽרוֹתָ֔יו וּמְחַנֵּ֖ק לְלִבְאֹתָ֑יו וַיְמַלֵּא־טֶ֣רֶף חֹרָ֔יו וּמְעֹֽנֹתָ֖יו טְרֵפָֽה׃
13 “Kíyèsi i èmi dojúkọ ọ́,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. “Èmi yóò sì fi kẹ̀kẹ́ rẹ̀ wọ̀n-ọn-nì jóná nínú èéfín, idà yóò sì jẹ ọmọ kìnnìún rẹ̀ wọ̀n-ọn-nì run. Èmi yóò sì ké ohun ọdẹ rẹ kúrò lórí ilẹ̀ ayé. Ohùn àwọn ìránṣẹ́ rẹ ni a kì yóò sì tún gbọ́ mọ́.”
הִנְנִ֣י אֵלַ֗יִךְ נְאֻם֙ יְהוָ֣ה צְבָא֔וֹת וְהִבְעַרְתִּ֤י בֶֽעָשָׁן֙ רִכְבָּ֔הּ וּכְפִירַ֖יִךְ תֹּ֣אכַל חָ֑רֶב וְהִכְרַתִּ֤י מֵאֶ֙רֶץ֙ טַרְפֵּ֔ךְ וְלֹֽא־יִשָּׁמַ֥ע ע֖וֹד ק֥וֹל מַלְאָכֵֽכֵה׃ ס

< Nahum 2 >