< Micah 3 >

1 Nígbà náà, ni mo wí pé, “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin olórí Jakọbu, ẹ̀yin alákòóso ilé Israẹli. Ǹjẹ́ ẹ̀yin kò ha ni í gba òdodo bí.
I said, “Now listen, you leaders of Jacob and rulers of the house of Israel: Is it not right for you to understand justice?
2 Ẹ̀yin tí ó kórìíra ìre, tí ẹ sì fẹ́ràn ibi; ẹ̀yin tí ẹ fa awọ ẹran-ara àwọn ènìyàn mi ya kúrò lára wọn àti ẹran-ara wọn kúrò ní egungun wọn;
You who hate good and love evil, you who tear off their skin, their flesh from their bones—
3 àwọn tí ó jẹ ẹran-ara àwọn ènìyàn mi, wọn sì bọ́ awọ ara wọn kúrò lára wọn. Wọ́n sì fọ́ egungun wọn sí wẹ́wẹ́; wọn sì gé e sí wẹ́wẹ́ bí ẹran inú ìkòkò, bí ẹran inú agbada?”
you who also eat the flesh of my people, and tear their skin off, break their bones, and chop them in pieces, just like meat for a pot, just like meat in a cauldron.
4 Nígbà náà ni wọn yóò kígbe sí Olúwa, ṣùgbọ́n òun kì yóò dá wọn lóhùn. Ní àkókò náà ni òun yóò fi ojú rẹ̀ pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn, nítorí ibi tí wọ́n ti ṣe.
Then you rulers will cry out to Yahweh, but he will not answer you. He will hide his face from you at that time, because you have done evil deeds.”
5 Báyìí ni Olúwa wí, “Ní ti àwọn Wòlíì tí ń ṣi àwọn ènìyàn mi lọ́nà, tí ẹnìkan bá fún wọn ní oúnjẹ, wọn yóò kéde àlàáfíà; ṣùgbọ́n tí kò bá fi nǹkan sí wọn ní ẹnu, wọn yóò múra ogun sí i.
Yahweh says this, “As for the prophets who lead my people astray, if one gives them something to eat, they proclaim, 'Peace.' But if he puts nothing in their mouths, they dedicate themselves to wage war on him.
6 Nítorí náà òru yóò wá sórí yín, tí ẹ̀yin kì yóò sì rí ìran kankan, òkùnkùn yóò sì kùn fún yín, tí ẹ̀yin kì yóò sì lè sọtẹ́lẹ̀. Oòrùn yóò sì wọ lórí àwọn wòlíì ọjọ́ yóò sì ṣókùnkùn lórí wọn.
Therefore, it will be night for you with no vision for you; it will be dark so that you will do no divination. The sun will go down on the prophets, and the day will be dark on them.
7 Ojú yóò sì ti àwọn wòlíì àwọn alásọtẹ́lẹ̀ pẹ̀lú yóò sì gba ìtìjú. Gbogbo wọn ni yóò bo ojú wọn, nítorí kò sí ìdáhùn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.”
The seers will be put to shame, and the diviners will be confused. All of them will cover their lips, for there is no answer from me.”
8 Ṣùgbọ́n ní tèmi, èmi kún fún agbára pẹ̀lú ẹ̀mí Olúwa, láti sọ ìré-òfin-kọjá Jakọbu fún un, àti láti sọ ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli fún un.
But as for me, I am full of power by the Spirit of Yahweh, and am full of justice and might, to declare to Jacob his transgression, and to Israel his sin.
9 Gbọ́ ẹ̀yin olórí ilé Jakọbu, àti ẹ̀yin alákòóso ilé Israẹli, tí ó kórìíra òdodo tí ó sì yí òtítọ́ padà;
Now listen to this, you leaders of the house of Jacob, and rulers of the house of Israel, you who detest justice, and pervert everything right.
10 tí ó kọ́ Sioni pẹ̀lú ìtàjẹ̀ sílẹ̀, àti Jerusalẹmu pẹ̀lú ìwà búburú.
You build Zion with blood and Jerusalem with iniquity.
11 Àwọn olórí rẹ̀ ń ṣe ìdájọ́ nítorí àbẹ̀tẹ́lẹ̀, àwọn àlùfáà rẹ̀ sì ń kọ́ni nítorí owó ọ̀yà àwọn wòlíì rẹ̀ pẹ̀lú sì ń sọtẹ́lẹ̀ nítorí owó. Síbẹ̀, wọn gbẹ́kẹ̀lé Olúwa, wọ́n sì wí pé, “Nítòótọ́, Olúwa wà pẹ̀lú wa! Ibi kan kì yóò bá wa.”
Your leaders judge for a bribe, your priests teach for a price, and your prophets do divination for money. Yet you rely on Yahweh and say, “Is not Yahweh with us? No evil will come on us.”
12 Nítorí náà, nítorí tiyín, ni a ó ṣe ro Sioni bí oko, Jerusalẹmu yóò sì di ebè àti òkè tẹmpili bí i ibi gíga igbó.
Therefore, because of you, Zion will become a plowed field, Jerusalem will become a heap of rubble, and the hill of the temple will become a thicket.

< Micah 3 >