< Matthew 24 >
1 Bí Jesu ti ń kúrò ni tẹmpili, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọ́n fẹ́ fi ẹwà tẹmpili náà hàn án.
και εξελθων ο ιησους επορευετο απο του ιερου και προσηλθον οι μαθηται αυτου επιδειξαι αυτω τας οικοδομας του ιερου
2 Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin kò ha rí gbogbo nǹkan wọ̀nyí? Lóòótọ́ ni mo wí fún yín gbogbo ilé yìí ni a yóò wó lulẹ̀, kò ní sí òkúta kan tí a ó fi sílẹ̀ lórí òmíràn, tí a kì yóò wó lulẹ̀.”
ο δε ιησους ειπεν αυτοις ου βλεπετε ταυτα παντα αμην λεγω υμιν ου μη αφεθη ωδε λιθος επι λιθον ος ου καταλυθησεται
3 Bí ó ti jókòó ní orí òkè Olifi, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tọ̀ ọ́ wá ní ìkọ̀kọ̀, wọ́n wí pé, “Sọ fún wa nígbà wo ni èyí yóò ṣẹlẹ̀? Kí ni yóò jẹ́ àmì ìpadà wá rẹ, àti ti òpin ayé?” (aiōn )
καθημενου δε αυτου επι του ορους των ελαιων προσηλθον αυτω οι μαθηται κατ ιδιαν λεγοντες ειπε ημιν ποτε ταυτα εσται και τι το σημειον της σης παρουσιας και της συντελειας του αιωνος (aiōn )
4 Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàn yín jẹ.
και αποκριθεις ο ιησους ειπεν αυτοις βλεπετε μη τις υμας πλανηση
5 Nítorí ọ̀pọ̀ yóò wá ní orúkọ mi tí wọn yóò máa pe ara wọn ní Kristi náà. Wọn yóò ṣi ọ̀pọ̀lọpọ̀ lọ́nà.
πολλοι γαρ ελευσονται επι τω ονοματι μου λεγοντες εγω ειμι ο χριστος και πολλους πλανησουσιν
6 Ẹ ó máa gbọ́ ìró ogun àti ìdágìrì ogun, kí ẹ̀yin má ṣe jáyà nítorí nǹkan wọ̀nyí kò lè ṣe kí ó ma ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n òpin kì í ṣe àkókò náà.
μελλησετε δε ακουειν πολεμους και ακοας πολεμων ορατε μη θροεισθε δει γαρ παντα γενεσθαι αλλ ουπω εστιν το τελος
7 Orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè, àti ìjọba sí ìjọba. Ìyàn àti ilẹ̀ mímì yóò wà ní ibi púpọ̀.
εγερθησεται γαρ εθνος επι εθνος και βασιλεια επι βασιλειαν και εσονται λιμοι και λοιμοι και σεισμοι κατα τοπους
8 Ṣùgbọ́n gbogbo nǹkan wọ̀nyí sì jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ìpọ́njú tí ó ń bọ̀.
παντα δε ταυτα αρχη ωδινων
9 “Nígbà náà ni a ó sì dá a yín lóró. A ó pa yín, a ó sì kórìíra yín ni gbogbo orílẹ̀-èdè, nítorí pé ẹ̀yin jẹ́ tèmi.
τοτε παραδωσουσιν υμας εις θλιψιν και αποκτενουσιν υμας και εσεσθε μισουμενοι υπο παντων των εθνων δια το ονομα μου
10 Àti pé, ọ̀pọ̀ nínú yín yóò kọsẹ̀, ẹ̀yin yóò ṣòfófó ara yín, ẹ̀yin yóò kórìíra ara yín pẹ̀lú,
και τοτε σκανδαλισθησονται πολλοι και αλληλους παραδωσουσιν και μισησουσιν αλληλους
11 ọ̀pọ̀ àwọn èké wòlíì yóò farahàn, wọn yóò tan ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn jẹ.
και πολλοι ψευδοπροφηται εγερθησονται και πλανησουσιν πολλους
12 Ẹ̀ṣẹ̀ yóò wà níbi gbogbo, yóò sì sọ ìfẹ́ ọ̀pọ̀ di tútù,
και δια το πληθυνθηναι την ανομιαν ψυγησεται η αγαπη των πολλων
13 ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá forítì í dópin ni a ó gbàlà.
ο δε υπομεινας εις τελος ουτος σωθησεται
14 A ó sì wàásù ìyìnrere nípa ìjọba náà yìí ní gbogbo ayé ká, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo orílẹ̀-èdè, nígbà náà ni òpin yóò dé.
και κηρυχθησεται τουτο το ευαγγελιον της βασιλειας εν ολη τη οικουμενη εις μαρτυριον πασιν τοις εθνεσιν και τοτε ηξει το τελος
15 “Nítorí náà, nígbà tí ẹ̀yin bá rí ìríra ‘ìsọdahoro, tí a ti ẹnu wòlíì Daniẹli sọ,’ tí ó bá dúró ní ibi mímọ́ (ẹnikẹ́ni tí ó bá kà á kí ó yé e),
οταν ουν ιδητε το βδελυγμα της ερημωσεως το ρηθεν δια δανιηλ του προφητου εστως εν τοπω αγιω ο αναγινωσκων νοειτω
16 nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ni Judea sálọ sí orí òkè.
τοτε οι εν τη ιουδαια φευγετωσαν επι τα ορη
17 Kí ẹni tí ó wà lórí ilé rẹ̀ má ṣe sọ̀kalẹ̀ wá mú ohunkóhun jáde nínú ilé rẹ̀.
ο επι του δωματος μη καταβαινετω αραι τα εκ της οικιας αυτου
18 Kí àwọn tí ó sì wà lóko má ṣe darí wá sí ilé láti mú àwọn aṣọ wọn.
και ο εν τω αγρω μη επιστρεψατω οπισω αραι τα ιματια αυτου
19 Ṣùgbọ́n àánú ṣe mí fún àwọn obìnrin ti ó lóyún, àti fún àwọn tí ó ń fún ọmọ loyan ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì!
ουαι δε ταις εν γαστρι εχουσαις και ταις θηλαζουσαις εν εκειναις ταις ημεραις
20 Ẹ sì máa gbàdúrà kí sísá yín má ṣe jẹ́ ìgbà òtútù, tàbí ọjọ́ ìsinmi.
προσευχεσθε δε ινα μη γενηται η φυγη υμων χειμωνος μηδε σαββατω
21 Nítorí ìpọ́njú ńlá yóò wà, irú èyí tí kò tí ì ṣẹlẹ̀ láti ìgbà ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ ayé wá títí di ìsinsin yìí irú rẹ̀ kì yóò sì ṣí.
εσται γαρ τοτε θλιψις μεγαλη οια ου γεγονεν απ αρχης κοσμου εως του νυν ουδ ου μη γενηται
22 “Lóòótọ́, àfi bí a ké ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì kúrú, gbogbo ẹ̀dá alààyè yóò ṣègbé. Ṣùgbọ́n nítorí ti àwọn àyànfẹ́ ni a ó fi ké ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì kúrú.
και ει μη εκολοβωθησαν αι ημεραι εκειναι ουκ αν εσωθη πασα σαρξ δια δε τους εκλεκτους κολοβωθησονται αι ημεραι εκειναι
23 Nígbà náà, bí ẹnikẹ́ni bá sọ fún yín pé, ‘Wo Kristi náà,’ tàbí pé ó ti farahàn níhìn-ín tàbí lọ́hùn ún, ẹ má ṣe gbà á gbọ́.
τοτε εαν τις υμιν ειπη ιδου ωδε ο χριστος η ωδε μη πιστευσητε
24 Nítorí àwọn èké Kristi àti àwọn èké wòlíì yóò dìde. Wọn yóò sì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àmì àti ìyanu. Bí ó bá lè ṣe é ṣe wọn yóò tan àwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run pàápàá jẹ.
εγερθησονται γαρ ψευδοχριστοι και ψευδοπροφηται και δωσουσιν σημεια μεγαλα και τερατα ωστε πλανησαι ει δυνατον και τους εκλεκτους
25 Wò ó, mo ti kìlọ̀ fún yín tẹ́lẹ̀.
ιδου προειρηκα υμιν
26 “Nítorí náà, bí ẹnìkan bá sọ fún yín pé, ‘Olùgbàlà ti dé,’ àti pé, ‘Ó wà ní aginjù,’ ẹ má ṣe wàhálà láti lọ wò ó, tàbí tí wọ́n bá ní, ó ń fi ara pamọ́ sí iyàrá,” ẹ má ṣe gbà wọn gbọ́.
εαν ουν ειπωσιν υμιν ιδου εν τη ερημω εστιν μη εξελθητε ιδου εν τοις ταμειοις μη πιστευσητε
27 Nítorí bí mọ̀nàmọ́ná ti ń tàn láti ìlà-oòrùn títí dé ìwọ̀-oòrùn, bẹ́ẹ̀ ni wíwá Ọmọ Ènìyàn yóò jẹ́.
ωσπερ γαρ η αστραπη εξερχεται απο ανατολων και φαινεται εως δυσμων ουτως εσται και η παρουσια του υιου του ανθρωπου
28 Nítorí ibikíbi tí òkú bá gbé wà, ibẹ̀ ni àwọn ẹyẹ igún ń kójọpọ̀ sí.
οπου γαρ εαν η το πτωμα εκει συναχθησονται οι αετοι
29 “Lójúkan náà, lẹ́yìn ìpọ́njú ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, “‘ni oòrùn yóò ṣókùnkùn, òṣùpá kì yóò sì fi ìmọ́lẹ̀ rẹ hàn; àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run yóò já sílẹ̀, agbára ojú ọ̀run ni a ó mì tìtì.’
ευθεως δε μετα την θλιψιν των ημερων εκεινων ο ηλιος σκοτισθησεται και η σεληνη ου δωσει το φεγγος αυτης και οι αστερες πεσουνται απο του ουρανου και αι δυναμεις των ουρανων σαλευθησονται
30 “Nígbà náà ni àmì Ọmọ Ènìyàn yóò sì fi ara hàn ní ọ̀run, nígbà náà ni gbogbo ẹ̀yà ayé yóò káàánú, wọn yóò sì rí Ọmọ Ènìyàn tí yóò máa ti ojú ọ̀run bọ̀ ti òun ti ògo àti agbára ńlá.
και τοτε φανησεται το σημειον του υιου του ανθρωπου εν τω ουρανω και τοτε κοψονται πασαι αι φυλαι της γης και οψονται τον υιον του ανθρωπου ερχομενον επι των νεφελων του ουρανου μετα δυναμεως και δοξης πολλης
31 Yóò sì rán àwọn angẹli rẹ̀ jáde pẹ̀lú ohùn ìpè ńlá, wọn yóò sì kó gbogbo àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ láti orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé àti ọ̀run jọ.
και αποστελει τους αγγελους αυτου μετα σαλπιγγος φωνης μεγαλης και επισυναξουσιν τους εκλεκτους αυτου εκ των τεσσαρων ανεμων απ ακρων ουρανων εως ακρων αυτων
32 “Nísinsin yìí, ẹ kọ́ òwe lára igi ọ̀pọ̀tọ́. Nígbà tí ẹ̀ka rẹ̀ bá ti ń yọ tuntun tí ó bá sì ń ru ewé, ẹ̀yin mọ̀ pé ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn súnmọ́ tòsí.
απο δε της συκης μαθετε την παραβολην οταν ηδη ο κλαδος αυτης γενηται απαλος και τα φυλλα εκφυη γινωσκετε οτι εγγυς το θερος
33 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, nígbà tí ẹ̀yin bá sì rí i tí gbogbo nǹkan wọ̀nyí bá ń ṣẹlẹ̀, kí ẹ mọ̀ pé ìpadàbọ̀ mi dé tán lẹ́yìn ìlẹ̀kùn.
ουτως και υμεις οταν ιδητε ταυτα παντα γινωσκετε οτι εγγυς εστιν επι θυραις
34 Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ìran yìí kì yóò kọjá títí tí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹ.
αμην λεγω υμιν ου μη παρελθη η γενεα αυτη εως αν παντα ταυτα γενηται
35 Ọ̀run àti ayé yóò rékọjá, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ mi kì yóò rékọjá.
ο ουρανος και η γη παρελευσονται οι δε λογοι μου ου μη παρελθωσιν
36 “Ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan ti ó mọ ọjọ́ àti wákàtí tí òpin náà yóò dé, àwọn angẹli ọ̀run pàápàá kò mọ̀ ọ́n. Àní, ọmọ kò mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe Baba mi nìkan ṣoṣo ló mọ̀ ọ́n.
περι δε της ημερας εκεινης και ωρας ουδεις οιδεν ουδε οι αγγελοι των ουρανων ει μη ο πατηρ μου μονος
37 Bí ó ṣe rí ní ìgbà ayé Noa, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni wíwá Ọmọ Ènìyàn yóò sì rí.
ωσπερ δε αι ημεραι του νωε ουτως εσται και η παρουσια του υιου του ανθρωπου
38 Nítorí bí àwọn ọjọ́ náà ti wà ṣáájú ìkún omi, tí wọ́n ń jẹ́ tí wọ́n ń mu, tí wọ́n ń gbéyàwó, tí wọ́n sì ń fa ìyàwó fún ni, títí tí ó fi di ọjọ́ tí Noa fi bọ́ sínú ọkọ̀.
ωσπερ γαρ ησαν εν ταις ημεραις ταις προ του κατακλυσμου τρωγοντες και πινοντες γαμουντες και εκγαμιζοντες αχρι ης ημερας εισηλθεν νωε εις την κιβωτον
39 Ènìyàn kò gbàgbọ́ nípa ohun tí o ṣẹlẹ̀ títí tí ìkún omi fi dé nítòótọ́, tí ó sì kó wọn lọ. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni wíwá Ọmọ Ènìyàn.
και ουκ εγνωσαν εως ηλθεν ο κατακλυσμος και ηρεν απαντας ουτως εσται και η παρουσια του υιου του ανθρωπου
40 Àwọn ọkùnrin méjì yóò máa ṣiṣẹ́ nínú oko, a o mú ẹnìkan, a ó sì fi ẹni kejì sílẹ̀.
τοτε δυο εσονται εν τω αγρω ο εις παραλαμβανεται και ο εις αφιεται
41 Àwọn obìnrin méjì yóò jùmọ̀ máa lọ ọlọ pọ̀, a yóò mú ọ̀kan, a ó fi ẹni kejì sílẹ̀.
δυο αληθουσαι εν τω μυλωνι μια παραλαμβανεται και μια αφιεται
42 “Nítorí náà, ẹ múra sílẹ̀, nítorí ẹ kò mọ ọjọ́ tí Olúwa yín yóò dé.
γρηγορειτε ουν οτι ουκ οιδατε ποια ωρα ο κυριος υμων ερχεται
43 Ṣùgbọ́n, kí ẹ mọ èyí pé, baálé ilé ìbá mọ wákàtí náà tí olè yóò wá, ìbá máa ṣọ́nà, òun kì bá ti jẹ́ kí a já wọ ilé rẹ̀.
εκεινο δε γινωσκετε οτι ει ηδει ο οικοδεσποτης ποια φυλακη ο κλεπτης ερχεται εγρηγορησεν αν και ουκ αν ειασεν διορυγηναι την οικιαν αυτου
44 Nítorí náà, ẹ gbọdọ̀ wà ní ìmúrasílẹ̀, nítorí ní wákàtí àìròtẹ́lẹ̀ ni dídé Ọmọ Ènìyàn yóò jẹ́.
δια τουτο και υμεις γινεσθε ετοιμοι οτι η ωρα ου δοκειτε ο υιος του ανθρωπου ερχεται
45 “Ǹjẹ́ olóòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n ọmọ ọ̀dọ̀ wo ni olúwa rẹ̀ lè fi ṣe olùbojútó ilé rẹ̀ láti bọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ lójoojúmọ́?
τις αρα εστιν ο πιστος δουλος και φρονιμος ον κατεστησεν ο κυριος αυτου επι της θεραπειας αυτου του διδοναι αυτοις την τροφην εν καιρω
46 Alábùkún fún ni ọmọ ọ̀dọ̀ ti olúwa rẹ̀ dé tí ó sì bá a lórí iṣẹ́ ṣíṣe.
μακαριος ο δουλος εκεινος ον ελθων ο κυριος αυτου ευρησει ποιουντα ουτως
47 Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, èmi yóò sì fi irú ẹni bẹ́ẹ̀ ṣe alákòóso gbogbo ohun tí mo ní.
αμην λεγω υμιν οτι επι πασιν τοις υπαρχουσιν αυτου καταστησει αυτον
48 Ṣùgbọ́n bí ọmọ ọ̀dọ̀ náà bá jẹ́ ènìyàn búburú náà bá wí ní ọkàn rẹ̀ pé, ‘Olúwa mi kì yóò tètè dé.’
εαν δε ειπη ο κακος δουλος εκεινος εν τη καρδια αυτου χρονιζει ο κυριος μου ελθειν
49 Tí ó sì bẹ̀rẹ̀ si í fi ìyà jẹ́ àwọn ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, tí ó ń jẹ, tí ó sì ń mu àmupara.
και αρξηται τυπτειν τους συνδουλους αυτου εσθιη δε και πινη μετα των μεθυοντων
50 Nígbà náà ni olúwa ọmọ ọ̀dọ̀ yóò wá ní ọjọ́ àti wákàtí tí kò retí.
ηξει ο κυριος του δουλου εκεινου εν ημερα η ου προσδοκα και εν ωρα η ου γινωσκει
51 Yóò sì jẹ ẹ́ ní ìyà gidigidi, yóò sì rán an sí ibùgbé àwọn àgàbàgebè, níbẹ̀ ni ẹkún àti ìpayínkeke yóò wà.
και διχοτομησει αυτον και το μερος αυτου μετα των υποκριτων θησει εκει εσται ο κλαυθμος και ο βρυγμος των οδοντων