< Matthew 1 >
1 Ìwé ìran Jesu Kristi, ẹni tí í ṣe ọmọ Dafidi, ọmọ Abrahamu:
Généalogie de Jésus-Christ, fils de David, fils d'Abraham.
2 Abrahamu ni baba Isaaki; Isaaki ni baba Jakọbu; Jakọbu ni baba Juda àti àwọn arákùnrin rẹ̀,
Abraham engendra Isaac; Isaac, Jacob; Jacob, Juda et ses frères;
3 Juda ni baba Peresi àti Sera, Tamari sì ni ìyá rẹ̀, Peresi ni baba Hesroni: Hesroni ni baba Ramu;
Juda, Phares et Zara, qu'il eut de Thamar; Phares, Esrom; Esrom, Aram;
4 Ramu ni baba Amminadabu; Amminadabu ni baba Nahiṣoni; Nahiṣoni ni baba Salmoni;
Aram, Aminabad; Aminabad, Naasson; Naasson, Salmon;
5 Salmoni ni baba Boasi, Rahabu sí ni ìyá rẹ̀; Boasi ni baba Obedi, Rutu sí ni ìyá rẹ̀; Obedi sì ni baba Jese;
Salmon, Booz, qu'il eut de Rahab; Booz, Jobed, qu'il eut de Ruth;
6 Jese ni baba Dafidi ọba. Dafidi ni baba Solomoni, ẹni tí ìyá rẹ̀ jẹ́ aya Uriah tẹ́lẹ̀ rí.
Jobed, Issaï; Issaï, le roi David. David engendra Salomon qu'il eut de la femme d'Urie;
7 Solomoni ni baba Rehoboamu, Rehoboamu ni baba Abijah, Abijah ni baba Asa,
Salomon, Roboam; Roboam, Abia; Abia, Asa;
8 Asa ni baba Jehoṣafati; Jehoṣafati ni baba Jehoramu; Jehoramu ni baba Ussiah;
Asa, Josaphat; - Josaphat, Joram; Joram, Ozias;
9 Ussiah ni baba Jotamu; Jotamu ni baba Ahaṣi; Ahaṣi ni baba Hesekiah;
Ozias, Joatham; Joatham, Achez; Achez, Ezéchias;
10 Hesekiah ni baba Manase; Manase ni baba Amoni; Amoni ni baba Josiah;
Ezéchias, Manassé; Manassé, Amos; Amos, Josias;
11 Josiah sì ni baba Jekoniah àti àwọn arákùnrin rẹ̀ ní àkókò ìkólọ sí Babeli.
Josias, Jéchonias et ses frères, lors de l'émigration à Babylone.
12 Lẹ́yìn ìkólọ sí Babeli: Jekoniah ni baba Ṣealitieli; Ṣealitieli ni baba Serubbabeli;
Après l'émigration à Babylone, Jéchonias engendra Salathiel; Salathiél, Zorobabel;
13 Serubbabeli ni baba Abihudi; Abihudi ni baba Eliakimu; Eliakimu ni baba Asori;
Zorobabel, Abioud; Abioud, Eliacim; Eliacim, Azor;
14 Asori ni baba Sadoku; Sadoku ni baba Akimu; Akimu ni baba Elihudi;
Azor, Sadoc; Sadoc, Achim; Achim, Elioud;
15 Elihudi ni baba Eleasari; Eleasari ni baba Mattani; Mattani ni baba Jakọbu;
Elioud, Eléazar; Eléazar, Matthan; Matthan, Jacob;
16 Jakọbu ni baba Josẹfu, ẹni tí ń ṣe ọkọ Maria, ìyá Jesu, ẹni tí í ṣe Kristi.
Jacob, Joseph, le mari de Marie, de laquelle naquit Jésus, qu'on appelle Christ.
17 Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo wọ́n jẹ́ ìran mẹ́rìnlá láti orí Abrahamu dé orí Dafidi, ìran mẹ́rìnlá á láti orí Dafidi títí dé ìkólọ sí Babeli, àti ìran mẹ́rìnlá láti ìkólọ títí dé orí Kristi.
Il y a donc, en tout, quatorze générations d'Abraham à David; quatorze, de David à l'émigration à Babylone, et quatorze, de l'émigration jusqu’à Christ.
18 Bí a ṣe bí Jesu Kristi nìyí, ní àkókò ti àdéhùn ìgbéyàwó ti parí láàrín Maria ìyá rẹ̀ àti Josẹfu, ṣùgbọ́n kí wọn tó pàdé, a rí i ó lóyún láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́.
Or, voici de quelle manière Jésus-Christ vint au monde. Marie, sa mère, ayant été fiancée à Joseph, se trouva enceinte par l'effet du Saint-Esprit, avant qu'ils eussent habité ensemble.
19 Nítorí Josẹfu ọkọ rẹ̀ tí í ṣe olóòtítọ́ ènìyàn kò fẹ́ dójútì í ní gbangba, ó ní èrò láti kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀.
Joseph, son mari, étant un homme de bien, et ne voulant pas l'exposer à la honte, résolut de la répudier secrètement.
20 Ṣùgbọ́n nígbà tí ó ro èrò yìí tán, angẹli Olúwa yọ sí i ní ojú àlá, ó wí pé, “Josẹfu, ọmọ Dafidi, má fòyà láti fi Maria ṣe aya rẹ, nítorí oyún tí ó wà nínú rẹ̀ láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ ni.
Il y pensait, lorsqu'un ange du Seigneur lui apparut en songe, et lui dit: «Joseph, fils de David, ne crains point de prendre chez toi Marie, ta femme; car l'enfant qu'elle a conçu est du Saint-Esprit.
21 Òun yóò sì bí ọmọkùnrin, ìwọ yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jesu, nítorí òun ni yóò gba àwọn ènìyàn rẹ̀ là kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”
Elle mettra au monde un fils, et tu lui donneras le nom de Jésus, parce que c'est lui qui sauvera son peuple de ses péchés.»
22 Gbogbo nǹkan wọ̀nyí sì ṣẹ láti mú ọ̀rọ̀ Olúwa ṣẹ èyí tí a sọ láti ẹnu wòlíì rẹ̀ wá pé:
Tout cela arriva, afin que s'accomplît ce qu'avait dit le Seigneur par le prophète:
23 “Wúńdíá kan yóò lóyún, yóò sì bí ọmọkùnrin kan, yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Emmanueli,” (èyí tí ó túmọ̀ sí “Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa”).
«Voici, la vierge sera enceinte; elle mettra au monde un fils à qui l’on donnera le nom d'Emmanuel, » ce qui signifie «Dieu avec nous.»
24 Nígbà tí Josẹfu jí lójú oorun rẹ̀, òun ṣe gẹ́gẹ́ bí angẹli Olúwa ti pàṣẹ fún un. Ó mú Maria wá sílé rẹ̀ ní aya.
A son réveil, Joseph fit comme l'ange du Seigneur le lui avait commandé: il prit sa femme chez lui.
25 Ṣùgbọ́n òun kò mọ̀ ọ́n títí tí ó fi bí ọmọkùnrin, òun sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Jesu.
Et il ne la connut point, jusqu’à ce qu'elle eût mis au monde un fils, et il lui donna le nom de Jésus.