< Mark 9 >

1 Ó sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín àwọn mìíràn wa nínú àwọn tó dúró níhìn-ín yìí, tí kì yóò tọ́ ikú wò, títí yóò fi rí ìjọba Ọlọ́run tí yóò fi dé pẹ̀lú agbára.”
και ελεγεν αυτοις αμην λεγω υμιν οτι εισιν τινες των ωδε εστηκοτων οιτινες ου μη γευσωνται θανατου εως αν ιδωσιν την βασιλειαν του θεου εληλυθυιαν εν δυναμει
2 Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́fà tí Jesu sọ̀rọ̀ yìí, Jesu mú Peteru, Jakọbu àti Johanu lọ sí orí òkè gíga ní apá kan. Kò sí ẹlòmíràn pẹ̀lú wọn, ara rẹ̀ sì yípadà níwájú wọn.
και μεθ ημερας εξ παραλαμβανει ο ιησους τον πετρον και τον ιακωβον και [τον] ιωαννην και αναφερει αυτους εις ορος υψηλον κατ ιδιαν μονους και μετεμορφωθη εμπροσθεν αυτων
3 Aṣọ rẹ̀ sì di dídán, ó sì funfun gbòò, tí alágbàfọ̀ kan ní ayé kò lè sọ di funfun bẹ́ẹ̀.
και τα ιματια αυτου εγενοντο στιλβοντα λευκα λιαν ως χιων οια γναφευς επι της γης ου δυναται λευκαναι
4 Nígbà náà ni Elijah àti Mose farahàn fún wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ pẹ̀lú Jesu.
και ωφθη αυτοις ηλιας συν μωσει και ησαν συλλαλουντες τω ιησου
5 Peteru sì wí fún Jesu pé, “Rabbi, ó dára fún wa láti máa gbé níhìn-ín, si jẹ́ kí a pa àgọ́ mẹ́ta, ọ̀kan fun ọ, ọ̀kan fún Mose, àti ọ̀kan fún Elijah.”
και αποκριθεις ο πετρος λεγει τω ιησου ραββι καλον εστιν ημας ωδε ειναι και ποιησωμεν σκηνας τρεις σοι μιαν και μωσει μιαν και ηλια μιαν
6 Nítorí òun kò mọ ohun tí òun ìbá sọ, nítorí ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi.
ου γαρ ηδει τι λαλησει ησαν γαρ εκφοβοι
7 Ìkùùkuu kan sì bò wọ́n, ohùn kan sì ti inú ìkùùkuu náà wá wí pé, “Èyí ni àyànfẹ́ ọmọ mi. Ẹ máa gbọ́ ti rẹ̀!”
και εγενετο νεφελη επισκιαζουσα αυτοις και ηλθεν φωνη εκ της νεφελης ουτος εστιν ο υιος μου ο αγαπητος αυτου ακουετε
8 Lójijì, wọ́n wo àyíká wọn, wọn kò sì rí ẹnìkankan mọ́, bí kò ṣe Jesu nìkan ṣoṣo ni ó sì wà pẹ̀lú wọn.
και εξαπινα περιβλεψαμενοι ουκετι ουδενα ειδον αλλα τον ιησουν μονον μεθ εαυτων
9 Bí wọ́n ti ń sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, Jesu kìlọ̀ fún wọn kí wọ́n má ṣe sọ ohun tí wọ́n ti rí fún ẹnikẹ́ni títí Ọmọ Ènìyàn yóò fi jíǹde kúrò nínú òkú.
καταβαινοντων δε αυτων απο του ορους διεστειλατο αυτοις ινα μηδενι διηγησωνται α ειδον ει μη οταν ο υιος του ανθρωπου εκ νεκρων αναστη
10 Nítorí náà, wọ́n pa nǹkan náà mọ́ ní ọkàn wọn. Ṣùgbọ́n wọ́n ń béèrè lọ́wọ́ ara wọn ohun tí àjíǹde kúrò nínú òkú túmọ̀ sí.
και τον λογον εκρατησαν προς εαυτους συζητουντες τι εστιν το εκ νεκρων αναστηναι
11 Nísinsin yìí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, èéṣe tí àwọn olùkọ́ òfin ń sọ wí pé, “Elijah ní yóò kọ́kọ́ dé.”
και επηρωτων αυτον λεγοντες οτι λεγουσιν οι γραμματεις οτι ηλιαν δει ελθειν πρωτον
12 Ó sì dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni Elijah yóò kọ́kọ́ dé yóò sì mú nǹkan gbogbo padà bọ̀ sípò. Àní gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ nípa ti Ọmọ Ènìyàn pé kò le ṣàìmá jìyà ohun púpọ̀ àti pé a ó sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀.
ο δε αποκριθεις ειπεν αυτοις ηλιας μεν ελθων πρωτον αποκαθιστα παντα και πως γεγραπται επι τον υιον του ανθρωπου ινα πολλα παθη και εξουδενωθη
13 Ṣùgbọ́n mo wí fún yín pé, Elijah ti wa ná, wọ́n sì ti ṣe ohunkóhun tí ó wù wọ́n sí i, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé nípa rẹ̀.”
αλλα λεγω υμιν οτι και ηλιας εληλυθεν και εποιησαν αυτω οσα ηθελησαν καθως γεγραπται επ αυτον
14 Nígbà tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ pátápátá sí ẹsẹ̀ òkè náà, wọ́n bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tí wọ́n yí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mẹ́sàn-án ìyókù ká. Àwọn olùkọ́ òfin díẹ̀ sì ń bá wọn jiyàn.
και ελθων προς τους μαθητας ειδεν οχλον πολυν περι αυτους και γραμματεις συζητουντας αυτοις
15 Bí Jesu ti ń súnmọ́ ọ̀pọ̀ ènìyàn wọ̀nyí ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í wò ó pẹ̀lú ìbẹ̀rù, nígbà náà ni wọ́n sáré lọ kí i.
και ευθεως πας ο οχλος ιδων αυτον εξεθαμβηθη και προστρεχοντες ησπαζοντο αυτον
16 Jesu béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Kí ló fa àríyànjiyàn?”
και επηρωτησεν τους γραμματεις τι συζητειτε προς αυτους
17 Ọkùnrin kan láàrín ọ̀pọ̀ ènìyàn dáhùn pé, “Olùkọ́, èmi ni mo mú ọmọ yìí wá fún ọ láti wò ó sàn. Kò lè sọ̀rọ̀ rárá, nítorí tí ó ní ẹ̀mí àìmọ́.
και αποκριθεις εις εκ του οχλου ειπεν διδασκαλε ηνεγκα τον υιον μου προς σε εχοντα πνευμα αλαλον
18 Àti pé, nígbàkígbà tí ó bá mú un, á gbé e ṣánlẹ̀, a sì máa hó itọ́ lẹ́nu, a sì máa lọ́ eyín rẹ̀. Òun pàápàá a wá le gbagidi. Mo sì bẹ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ kí wọn lé ẹ̀mí àìmọ́ náà jáde, ṣùgbọ́n wọ́n kò lè ṣe é.”
και οπου αν αυτον καταλαβη ρησσει αυτον και αφριζει και τριζει τους οδοντας αυτου και ξηραινεται και ειπον τοις μαθηταις σου ινα αυτο εκβαλωσιν και ουκ ισχυσαν
19 Ó sì dá wọn lóhùn, ó wí pé, “Ẹ̀yin ìran aláìgbàgbọ́ yìí, èmi yóò ti bá a yín gbé pẹ́ tó? Èmi yóò sì ti mú sùúrù fún un yín pẹ́ tó? Ẹ mú ọmọ náà wá sọ́dọ̀ mi.”
ο δε αποκριθεις αυτω λεγει ω γενεα απιστος εως ποτε προς υμας εσομαι εως ποτε ανεξομαι υμων φερετε αυτον προς με
20 Wọ́n sì mú un wá sọ́dọ̀ rẹ̀: nígbà tí ó sì rí i, lójúkan náà ẹ̀mí náà nà án tàntàn ó sì ṣubú lu ilẹ̀, ó sì ń fi ara yílẹ̀, ó sì ń yọ ìfófó lẹ́nu.
και ηνεγκαν αυτον προς αυτον και ιδων αυτον ευθεως το πνευμα εσπαραξεν αυτον και πεσων επι της γης εκυλιετο αφριζων
21 Jesu béèrè lọ́wọ́ baba ọmọ náà pé, “Ó tó ìgbà wo tí ọmọ rẹ̀ ti wà nínú irú ipò báyìí?” Baba ọmọ náà dáhùn pé, “Láti kékeré ni.”
και επηρωτησεν τον πατερα αυτου ποσος χρονος εστιν ως τουτο γεγονεν αυτω ο δε ειπεν παιδιοθεν
22 Nígbàkígbà ni ó sì máa ń gbé e sínú iná àti sínú omi, láti pa á run, ṣùgbọ́n bí ìwọ bá lè ṣe ohunkóhun, ṣàánú fún wa, kí o sì ràn wá lọ́wọ́.
και πολλακις αυτον και εις το πυρ εβαλεν και εις υδατα ινα απολεση αυτον αλλ ει τι δυνασαι βοηθησον ημιν σπλαγχνισθεις εφ ημας
23 “Jesu sì wí fún un pé, ‘Bí ìwọ bá le gbàgbọ́: ohun gbogbo ni ó ṣe é ṣe fún ẹni tí ó bá gbàgbọ́.’”
ο δε ιησους ειπεν αυτω το ει δυνασαι πιστευσαι παντα δυνατα τω πιστευοντι
24 Lójúkan náà baba ọmọ náà kígbe ní ohùn rara, ó sì wí pé, “Olúwa, mo gbàgbọ́, ran àìgbàgbọ́ mi lọ́wọ́.”
και ευθεως κραξας ο πατηρ του παιδιου μετα δακρυων ελεγεν πιστευω κυριε βοηθει μου τη απιστια
25 Nígbà tí Jesu rí i pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ń péjọ sọ́dọ̀ wọn, ó bá ẹ̀mí àìmọ́ náà wí pé, “Ìwọ ẹ̀mí àìmọ́, adití àti odi, mo pàṣẹ fún ọ, kí ó jáde kúrò lára ọmọ yìí, kí ó má ṣe padà sí ibẹ̀ mọ́.”
ιδων δε ο ιησους οτι επισυντρεχει οχλος επετιμησεν τω πνευματι τω ακαθαρτω λεγων αυτω το πνευμα το αλαλον και κωφον εγω σοι επιτασσω εξελθε εξ αυτου και μηκετι εισελθης εις αυτον
26 Òun sì kígbe ńlá, ó sì nà án tàntàn, ó sì jáde kúrò lára rẹ̀, ọmọ náà sì dàbí ẹni tí ó kú tó bẹ́ẹ̀ tí ọ̀pọ̀ ènìyàn ké wí pé, “Hé è, ọmọ náà ti kú.”
και κραξαν και πολλα σπαραξαν αυτον εξηλθεν και εγενετο ωσει νεκρος ωστε πολλους λεγειν οτι απεθανεν
27 Ṣùgbọ́n Jesu fà á lọ́wọ́, ó sì ràn án lọ́wọ́ láti dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ̀. Ó dìde dúró.
ο δε ιησους κρατησας αυτον της χειρος ηγειρεν αυτον και ανεστη
28 Nígbà tí ó sì wọ ilé, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bi í léèrè níkọ̀kọ̀ wí pé, “Èéṣe tí àwa kò fi lè lé e jáde?”
και εισελθοντα αυτον εις οικον οι μαθηται αυτου επηρωτων αυτον κατ ιδιαν οτι ημεις ουκ ηδυνηθημεν εκβαλειν αυτο
29 Ó sì wí fún wọn pé, “Irú èyí kò le ti ipa ohun kan jáde, bí kò ṣe nípa àdúrà.”
και ειπεν αυτοις τουτο το γενος εν ουδενι δυναται εξελθειν ει μη εν προσευχη και νηστεια
30 Wọ́n sì kúrò níbẹ̀, wọ́n gba Galili kọjá. Níbẹ̀ ni Jesu ti gbìyànjú láti yẹra kí ó bá à lè wà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, kí ó lè ráàyè kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ sí i.
και εκειθεν εξελθοντες παρεπορευοντο δια της γαλιλαιας και ουκ ηθελεν ινα τις γνω
31 Nítorí ó kọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì wí fun wọn pe, “A ó fi Ọmọ Ènìyàn lé àwọn ènìyàn lọ́wọ́, wọn ó sì pa á, lẹ́yìn ìgbà tí a bá sì pa á tan yóò jíǹde ní ọjọ́ kẹta.”
εδιδασκεν γαρ τους μαθητας αυτου και ελεγεν αυτοις οτι ο υιος του ανθρωπου παραδιδοται εις χειρας ανθρωπων και αποκτενουσιν αυτον και αποκτανθεις τη τριτη ημερα αναστησεται
32 Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ náà kò yé wọn, ẹ̀rù sì bà wọ́n láti béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, ìtumọ̀ ohun tí ó sọ náà.
οι δε ηγνοουν το ρημα και εφοβουντο αυτον επερωτησαι
33 Wọ́n dé sí Kapernaumu. Lẹ́yìn tí wọ́n sinmi tán nínú ilé tí wọ́n wọ̀, Jesu béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Kí ni ohun tí ẹ́ ń bá ara yín jiyàn lé lórí?”
και ηλθεν εις καπερναουμ και εν τη οικια γενομενος επηρωτα αυτους τι εν τη οδω προς εαυτους διελογιζεσθε
34 Ṣùgbọ́n wọ́n dákẹ́; nítorí wọn ti ń bá ara wọn jiyàn pé, ta ni ẹni tí ó pọ̀jù?
οι δε εσιωπων προς αλληλους γαρ διελεχθησαν εν τη οδω τις μειζων
35 Ó jókòó, ó sì pè àwọn méjìlá náà, ó sọ fún wọn pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ ṣe ẹni ìṣáájú, òun ni yóò ṣe ẹni ìkẹyìn gbogbo wọn. Ó ní láti jẹ́ ìránṣẹ́ gbogbo ènìyàn.”
και καθισας εφωνησεν τους δωδεκα και λεγει αυτοις ει τις θελει πρωτος ειναι εσται παντων εσχατος και παντων διακονος
36 Ó sì mú ọmọ kékeré kan, ó fi sáàárín wọn, nígbà tí ó sì gbé e sí apá rẹ̀, ó wí fún wọn pé,
και λαβων παιδιον εστησεν αυτο εν μεσω αυτων και εναγκαλισαμενος αυτο ειπεν αυτοις
37 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ́wọ́gbà ọmọ kékeré bí èyí ní orúkọ mi, òun gbà mí. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbà mi, ó gba Baba mi, tí ó rán mi.”
ος εαν εν των τοιουτων παιδιων δεξηται επι τω ονοματι μου εμε δεχεται και ος εαν εμε δεξηται ουκ εμε δεχεται αλλα τον αποστειλαντα με
38 Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Johanu sọ fún un ní ọjọ́ kan pé, “Olùkọ́, àwa rí ọkùnrin kan, tí ń fi orúkọ rẹ̀ lé àwọn ẹ̀mí àìmọ́ jáde, ṣùgbọ́n a sọ fún un pé kò gbọdọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́, nítorí kì í ṣe ọ̀kan nínú wa.”
απεκριθη δε αυτω [ο] ιωαννης λεγων διδασκαλε ειδομεν τινα τω ονοματι σου εκβαλλοντα δαιμονια ος ουκ ακολουθει ημιν και εκωλυσαμεν αυτον οτι ουκ ακολουθει ημιν
39 Jesu sì sọ fún un pé, “Má ṣe dá irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ dúró, nítorí kò sí ẹnìkan ti ó fi orúkọ mi ṣe iṣẹ́ ìyanu tí yóò tún lè máa sọ ohun búburú nípa mi.
ο δε ιησους ειπεν μη κωλυετε αυτον ουδεις γαρ εστιν ος ποιησει δυναμιν επι τω ονοματι μου και δυνησεται ταχυ κακολογησαι με
40 Nítorí ẹni tí kò bá kọ ojú ìjà sí wa, ó wà ní ìhà tiwa.
ος γαρ ουκ εστιν καθ υμων υπερ υμων εστιν
41 Lóòótọ́ ni mo sọ fún ún yín bí ẹnikẹ́ni bá fún un yín ní ife omi kan nítorí pé ẹ jẹ́ ti Kristi, dájúdájú ẹni náà kì yóò sọ èrè rẹ̀ nù bí ó ti wù kí ó rí.
ος γαρ αν ποτιση υμας ποτηριον υδατος εν ονοματι μου οτι χριστου εστε αμην λεγω υμιν ου μη απολεση τον μισθον αυτου
42 “Ṣùgbọ́n ti ẹnikẹ́ni bá mú ọ̀kan nínú àwọn ọmọ kékeré wọ̀nyí tí ó gbà mí gbọ́ ṣìnà nínú ìgbàgbọ́ rẹ́, ó sàn fún un kí a so òkúta ńlá mọ́ ọn ni ọ̀run, kí a sì sọ ọ́ sínú òkun.
και ος εαν σκανδαλιση ενα των μικρων των πιστευοντων εις εμε καλον εστιν αυτω μαλλον ει περικειται λιθος μυλικος περι τον τραχηλον αυτου και βεβληται εις την θαλασσαν
43 Bí ọwọ́ rẹ bá sì mú ọ kọsẹ̀, gé e sọnù, ó sàn fún ọ kí o ṣe akéwọ́ lọ sí ibi ìyè, ju kí o ní ọwọ́ méjèèjì, kí o lọ sí ọ̀run àpáàdì, sínú iná àjóòkú. (Geenna g1067)
και εαν σκανδαλιζη σε η χειρ σου αποκοψον αυτην καλον σοι εστιν κυλλον εις την ζωην εισελθειν η τας δυο χειρας εχοντα απελθειν εις την γεενναν εις το πυρ το ασβεστον (Geenna g1067)
οπου ο σκωληξ αυτων ου τελευτα και το πυρ ου σβεννυται
45 Bí ẹsẹ̀ rẹ bá sì mú ọ kọsẹ̀, gé é sọnù, ó sàn kí ó di akesẹ̀, kí o sì gbé títí ayé àìnípẹ̀kun ju kí o ní ẹsẹ̀ méjì tí ó gbé ọ lọ sí ọ̀run àpáàdì. (Geenna g1067)
και εαν ο πους σου σκανδαλιζη σε αποκοψον αυτον καλον εστιν σοι εισελθειν εις την ζωην χωλον η τους δυο ποδας εχοντα βληθηναι εις την γεενναν εις το πυρ το ασβεστον (Geenna g1067)
οπου ο σκωληξ αυτων ου τελευτα και το πυρ ου σβεννυται
47 Bí ojú rẹ bá sì mú ọ kọsẹ̀, yọ ọ́ sọnù, ó sàn kí o wọ ìjọba Ọlọ́run pẹ̀lú ojú kan ju kí ó ní ojú méjì kí ó sì lọ sínú iná ọ̀run àpáàdì. (Geenna g1067)
και εαν ο οφθαλμος σου σκανδαλιζη σε εκβαλε αυτον καλον σοι εστιν μονοφθαλμον εισελθειν εις την βασιλειαν του θεου η δυο οφθαλμους εχοντα βληθηναι εις την γεενναν του πυρος (Geenna g1067)
48 Níbi ti “‘kòkòrò wọn kì í kú, tí iná kì í sì í kú.’
οπου ο σκωληξ αυτων ου τελευτα και το πυρ ου σβεννυται
49 Níbẹ̀ ni a ó ti fi iná dán ẹnìkọ̀ọ̀kan wò.
πας γαρ πυρι αλισθησεται και πασα θυσια αλι αλισθησεται
50 “Iyọ̀ dára, ṣùgbọ́n tí ó bá sọ adùn rẹ̀ nù, báwo ni ẹ ṣè lè padà mú un dùn? Ẹ ni iyọ̀ nínú ara yín, ki ẹ sì máa gbé ní àlàáfíà pẹ̀lú ara yín.”
καλον το αλας εαν δε το αλας αναλον γενηται εν τινι αυτο αρτυσετε εχετε εν εαυτοις αλας και ειρηνευετε εν αλληλοις

< Mark 9 >