< Mark 8 >

1 Ní ọjọ́ kan, bí ọ̀pọ̀ ènìyàn ti péjọ, kò sí oúnjẹ fún wọn mọ́ láti jẹ. Jesu pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.
εν εκειναις ταις ημεραις παλιν πολλου οχλου οντος και μη εχοντων τι φαγωσιν προσκαλεσαμενος ο ιησους τους μαθητας αυτου λεγει αυτοις
2 Ó wí fún wọn pé, “Àánú ọ̀pọ̀ ènìyàn wọ̀nyí ṣe mí nítorí pé ó tó ọjọ́ mẹ́ta tí wọ́n ti wà níhìn-ín, kò sì sí ohun kan tí ó kù sílẹ̀ fún wọn láti jẹ.
σπλαγχνιζομαι επι τον οχλον οτι ηδη ημεραι τρεις προσμενουσιν μοι και ουκ εχουσιν τι φαγωσιν
3 Bí mo bá sọ fún wọn láti máa lọ sí ilé wọn bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ebi, wọn yóò dákú lójú ọ̀nà, nítorí pé àwọn mìíràn nínú wọn ti ọ̀nà jíjìn wá.”
και εαν απολυσω αυτους νηστεις εις οικον αυτων εκλυθησονται εν τη οδω τινες γαρ αυτων απο μακροθεν ηκασιν
4 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ béèrè pé, “Níbo ni a ó ti rí àkàrà tí ó tó láti fi bọ́ wọn nínú aṣálẹ̀ yìí?”
και απεκριθησαν αυτω οι μαθηται αυτου ποθεν τουτους δυνησεται τις ωδε χορτασαι αρτων επ ερημιας
5 Jesu béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ìṣù àkàrà mélòó lẹ ní lọ́wọ́?” Wọ́n fèsì pé, “Ìṣù àkàrà méje.”
και επηρωτα αυτους ποσους εχετε αρτους οι δε ειπον επτα
6 Nítorí náà, ó pàṣẹ fún àwọn ènìyàn náà láti jókòó lórí ilẹ̀. Ó sì mú odindi àkàrà méje náà, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ó sì bù wọ́n sí wẹ́wẹ́, ó pín wọn fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti gbé ka iwájú àwọn ènìyàn, wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀.
και παρηγγειλεν τω οχλω αναπεσειν επι της γης και λαβων τους επτα αρτους ευχαριστησας εκλασεν και εδιδου τοις μαθηταις αυτου ινα παρατιθωσιν και παρεθηκαν τω οχλω
7 Wọ́n rí àwọn ẹja wẹ́wẹ́ díẹ̀ pẹ̀lú. Jesu tún dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún ìpèsè náà, ó sì pàṣẹ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti pín wọn fún àwọn ènìyàn náà.
και ειχον ιχθυδια ολιγα και αυτα ευλογησας ειπεν παρατιθεναι και αυτα
8 Gbogbo ọ̀pọ̀ ènìyàn náà ló jẹ àjẹyó àti àjẹtẹ́rùn. Lẹ́yìn èyí wọ́n kó àjẹkù ti ó kù jọ, agbọ̀n méje sì kún.
εφαγον δε και εχορτασθησαν και ηραν περισσευματα κλασματων επτα σπυριδας
9 Àwọn tí ó jẹ ẹ́ tó ìwọ̀n ẹgbàajì ènìyàn, ó sì rán wọn lọ.
ησαν δε ως τετρακισχιλιοι και απελυσεν αυτους
10 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, lẹ́yìn èyí, Jesu wọ inú ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, wọ́n sì gúnlẹ̀ sí agbègbè Dalmanuta.
και εμβας ευθυς εις το πλοιον μετα των μαθητων αυτου ηλθεν εις τα μερη δαλμανουθα
11 Àwọn Farisi tọ Jesu wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí béèrè ìbéèrè lọ́wọ́ rẹ̀. Láti dán an wò, wọ́n béèrè fún àmì láti ọ̀run.
και εξηλθον οι φαρισαιοι και ηρξαντο συζητειν αυτω ζητουντες παρ αυτου σημειον απο του ουρανου πειραζοντες αυτον
12 Jesu mí kanlẹ̀, nígbà tí ó gbọ́ ìbéèrè wọn. Ó sì dáhùn wí pé, “Èéṣe tí ìran yìí fi ń wá àmì? Lóòótọ́ ni mo sọ fún un yín kò si àmì tí a ó fi fún ìran yín.”
και αναστεναξας τω πνευματι αυτου λεγει τι η γενεα αυτη σημειον επιζητει αμην λεγω υμιν ει δοθησεται τη γενεα ταυτη σημειον
13 Nígbà náà ni ó padà sínú ọkọ̀ ojú omi ó fi àwọn ènìyàn sílẹ̀, ó sì rékọjá sí apá kejì Òkun náà.
και αφεις αυτους εις το πλοιον απηλθεν παλιν
14 Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ti gbàgbé láti mú àkàrà tí yóò tó wọn ọ́n jẹ lọ́wọ́. Ẹyọ ìṣù àkàrà kan ṣoṣo ni ó wà nínú ọkọ̀ wọn.
και επελαθοντο λαβειν αρτους και ει μη ενα αρτον ουκ ειχον μεθ εαυτων εν τω πλοιω
15 Bí wọ́n sì ti ń rékọjá, Jesu kìlọ̀ fún wọn pé, “Ẹ máa ṣọ́ra nítorí ìwúkàrà àwọn Farisi àti ìwúkàrà Herodu.”
και διεστελλετο αυτοις λεγων ορατε βλεπετε απο της ζυμης των φαρισαιων και της ζυμης ηρωδου
16 Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ronú èyí láàrín ara wọn wí pé, “Torí pé a kò mú àkàrà lọ́wọ́ ni?”
και διελογιζοντο προς αλληλους λεγοντες οτι αρτους ουκ εχομεν
17 Jesu mọ ohun tí wọ́n sọ láàrín ara wọn, ó sì dá wọn lóhùn pé, “Èéṣe ti ẹ̀yin fi ń ṣe àròyé pé ẹ̀yin kò mú àkàrà lọ́wọ́? Ẹ̀yin kò kíyèsi i títí di ìsinsin yìí, ẹ kò sì ti mòye, àbí ọkàn yín le ni.
και γνους ο ιησους λεγει αυτοις τι διαλογιζεσθε οτι αρτους ουκ εχετε ουπω νοειτε ουδε συνιετε ετι πεπωρωμενην εχετε την καρδιαν υμων
18 Ẹ̀yin ní ojú, ẹ kò fi ríran? Ẹ̀yin ni etí ẹ kò sí gbọ́ran? Ẹ̀yin kò sì rántí?
οφθαλμους εχοντες ου βλεπετε και ωτα εχοντες ουκ ακουετε και ου μνημονευετε
19 Nígbà ti mo bu ìṣù àkàrà márùn-ún fún ẹgbẹ̀rún márùn-ún ènìyàn, agbọ̀n mélòó ni ó kún fún àjẹkù tí ẹ ṣàjọ?” Wọ́n wí pé, “Méjìlá.”
οτε τους πεντε αρτους εκλασα εις τους πεντακισχιλιους και ποσους κοφινους κλασματων πληρεις ηρατε λεγουσιν αυτω δωδεκα
20 “Bákan náà, nígbà tí mo bọ́ ẹgbàajì pẹ̀lú ìṣù àkàrà méje, agbọ̀n mélòó ló kù sílẹ̀ lẹ́yìn àjẹyó àti àjẹtẹ́rùn wọn?” Wọ́n dáhùn pé, “Ó ku ẹ̀kún agbọ̀n méje.”
οτε δε τους επτα εις τους τετρακισχιλιους ποσων σπυριδων πληρωματα κλασματων ηρατε οι δε ειπον επτα
21 Ó sì wí fún wọn pé, “Èéha ti ṣe tí kò fi yé yin?”
και ελεγεν αυτοις ουπω συνιετε
22 Nígbà tí wọ́n dé Betisaida, àwọn ènìyàn kan mú afọ́jú kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Wọ́n bẹ̀ ẹ́ kí ó fi ọwọ́ kàn án, kí ó sì wò ó sàn.
και ερχεται εις βηθσαιδα και φερουσιν αυτω τυφλον και παρακαλουσιν αυτον ινα αυτου αψηται
23 Jesu fa ọkùnrin náà lọ́wọ́, ó sì mú un jáde lọ sí ẹ̀yìn ìlú. Ó tu itọ́ sí i lójú. Ó sì gbé ọwọ́ rẹ̀ lé ojú náà. Ó sì bi í léèrè pé, “Ǹjẹ́ ìwọ lè rí ohunkóhun nísinsin yìí?”
και επιλαβομενος της χειρος του τυφλου εξηγαγεν αυτον εξω της κωμης και πτυσας εις τα ομματα αυτου επιθεις τας χειρας αυτω επηρωτα αυτον ει τι βλεπει
24 Ọkùnrin náà wo àyíká rẹ̀, ó sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa, mo rí àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n n kò rí wọn kedere, wọ́n n rìn kiri bí àgékù igi.”
και αναβλεψας ελεγεν βλεπω τους ανθρωπους ως δενδρα περιπατουντας
25 Nígbà náà, Jesu tún gbé ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì lé àwọn ojú ọkùnrin náà, bí ọkùnrin náà sì ti ranjú mọ́ ọn, a dá ìran rẹ̀ padà, ó sì rí gbogbo nǹkan kedere.
ειτα παλιν επεθηκεν τας χειρας επι τους οφθαλμους αυτου και εποιησεν αυτον αναβλεψαι και αποκατεσταθη και ενεβλεψεν τηλαυγως απαντας
26 Jesu sì rán an sí àwọn ẹbí rẹ̀. Ó kìlọ̀ fún un pé, “Má ṣe lọ sí ìlú, kí o má sì sọ fún ẹnikẹ́ni ní ìlú.”
και απεστειλεν αυτον εις τον οικον αυτου λεγων μηδε εις την κωμην εισελθης μηδε ειπης τινι εν τη κωμη
27 Nísinsin yìí, Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kúrò ní Galili. Wọ́n sì jáde lọ sí àwọn abúlé ní agbègbè Kesarea-Filipi. Bí wọ́n ti ń lọ lọ́nà, ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ta ni àwọn ènìyàn ń fi mí pè?”
και εξηλθεν ο ιησους και οι μαθηται αυτου εις τας κωμας καισαρειας της φιλιππου και εν τη οδω επηρωτα τους μαθητας αυτου λεγων αυτοις τινα με λεγουσιν οι ανθρωποι ειναι
28 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà dáhùn pé, “Àwọn kan rò pé ìwọ ni Johanu Onítẹ̀bọmi, àwọn mìíràn sọ pé, ìwọ ni Elijah tàbí àwọn wòlíì mìíràn ni ó tún padà wá sáyé.”
οι δε απεκριθησαν ιωαννην τον βαπτιστην και αλλοι ηλιαν αλλοι δε ενα των προφητων
29 Ó sì bi wọ́n pé, “Ta ni ẹ̀yin ń fi mí pè?” Peteru dáhùn pé, “Ìwọ ni Kristi náà.”
και αυτος λεγει αυτοις υμεις δε τινα με λεγετε ειναι αποκριθεις δε ο πετρος λεγει αυτω συ ει ο χριστος
30 Ṣùgbọ́n Jesu kìlọ̀ fún wọn, kí wọn má sọ èyí fún ẹnikẹ́ni.
και επετιμησεν αυτοις ινα μηδενι λεγωσιν περι αυτου
31 Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn, pé, Ọmọ Ènìyàn kò le ṣàìmá jìyà ohun púpọ̀, a ó sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀ láti ọwọ́ àwọn àgbàgbà, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin, a ó sì pa á, lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta yóò sì jíǹde.
και ηρξατο διδασκειν αυτους οτι δει τον υιον του ανθρωπου πολλα παθειν και αποδοκιμασθηναι απο των πρεσβυτερων και των αρχιερεων και των γραμματεων και αποκτανθηναι και μετα τρεις ημερας αναστηναι
32 Jesu bá wọn sọ̀rọ̀ yìí, láìfi ohunkóhun pamọ́ fún wọn, ṣùgbọ́n Peteru pe Jesu sẹ́yìn, ó sì bẹ̀rẹ̀ si bá a wí.
και παρρησια τον λογον ελαλει και προσλαβομενος αυτον ο πετρος ηρξατο επιτιμαν αυτω
33 Jesu yípadà, ó wo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Ó sì wí fún Peteru pẹ̀lú ìtara pé, “Kúrò lẹ́yìn mi Satani, nítorí ìwọ kò ro ohun tí Ọlọ́run bí kò ṣe ohun tí ènìyàn.”
ο δε επιστραφεις και ιδων τους μαθητας αυτου επετιμησεν τω πετρω λεγων υπαγε οπισω μου σατανα οτι ου φρονεις τα του θεου αλλα τα των ανθρωπων
34 Nígbà náà ni Jesu pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ àti ọ̀pọ̀ ènìyàn láti bá wọn sọ̀rọ̀, ó wí fún wọn pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ ara rẹ̀, kí ó si gbé àgbélébùú rẹ̀, kí ó si máa tọ̀ mi lẹ́yìn.
και προσκαλεσαμενος τον οχλον συν τοις μαθηταις αυτου ειπεν αυτοις οστις θελει οπισω μου ακολουθειν απαρνησασθω εαυτον και αρατω τον σταυρον αυτου και ακολουθειτω μοι
35 Nítorí ẹni tó bá gbìyànjú láti gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là, yóò sọ ọ́ nù. Iye àwọn tí ó sọ ẹ̀mí wọn nù nìkan nítorí í tèmi àti nítorí ìyìnrere, òun náà ni yóò gbà á là.
ος γαρ αν θελη την ψυχην αυτου σωσαι απολεσει αυτην ος δ αν απολεση την εαυτου ψυχην ενεκεν εμου και του ευαγγελιου ουτος σωσει αυτην
36 Nítorí èrè kí ni ó jẹ́ fún ẹni tí ó jèrè gbogbo ayé, tí ó sọ ẹ̀mí rẹ̀ nù?
τι γαρ ωφελησει ανθρωπον εαν κερδηση τον κοσμον ολον και ζημιωθη την ψυχην αυτου
37 Tàbí kí ni ènìyàn yóò fi ṣe pàṣípàrọ̀ ẹ̀mí rẹ̀?
η τι δωσει ανθρωπος ανταλλαγμα της ψυχης αυτου
38 Nítorí náà, bí ẹnikẹ́ni bá tijú àti gbà mí tàbí ọ̀rọ̀ mi nínú ìran panṣágà àti ẹlẹ́ṣẹ̀ yìí, tí ó kún fún àìgbàgbọ́ àti ẹ̀ṣẹ̀ báyìí, Ọmọ Ènìyàn yóò tijú rẹ̀ nígbà tí ó bá padà dé nínú ògo Baba rẹ̀, pẹ̀lú àwọn angẹli mímọ́.”
ος γαρ εαν επαισχυνθη με και τους εμους λογους εν τη γενεα ταυτη τη μοιχαλιδι και αμαρτωλω και ο υιος του ανθρωπου επαισχυνθησεται αυτον οταν ελθη εν τη δοξη του πατρος αυτου μετα των αγγελων των αγιων

< Mark 8 >