< Mark 1 >

1 Ìbẹ̀rẹ̀ ìyìnrere nípa Jesu Kristi, Ọmọ Ọlọ́run.
The beginning of the gospel of Jesus Christ, the Son of God.
2 Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé wòlíì Isaiah pé, “Èmi yóò ran oníṣẹ́ mi síwájú rẹ, Ẹni tí yóò tún ọ̀nà rẹ ṣe.”
As has been written in the prophets; Behold, I send my messenger before thy face, who will prepare thy way before thee;
3 “Ohùn ẹni tí ń kígbe ní ijù, ‘Ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe, ẹ ṣe ojú ọ̀nà rẹ̀ kí ó tọ́.’”
the voice of one roaring in the wilderness; Prepare ye the way of the Lord; make His paths straight.
4 Johanu dé, ẹni tí ó ń tẹnibọmi ní aginjù, tí ó sì ń wàásù ìtẹ̀bọmi ìrònúpìwàdà fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀.
John the Baptist came preaching in the wilderness the baptism of repentance unto the remission of sins.
5 Gbogbo àwọn tí ń gbé ní agbègbè Judea, àti gbogbo ènìyàn Jerusalẹmu jáde tọ̀ ọ́ lọ, a sì ti ọwọ́ rẹ̀ tẹ gbogbo wọn bọ omi ni odò Jordani, wọ́n ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
And all the Judean country and the Jerusalemites were going out unto him, and were being baptized by him in the river Jordan, confessing their sins.
6 Johanu sì wọ aṣọ irun ìbákasẹ. Ó sì di àmùrè awọ mọ́ ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Eṣú àti oyin ìgàn sì ni oúnjẹ rẹ̀.
And John was clothed with camel's hair and a leathern girdle about his loins, and eating locusts and wild honey;
7 Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù wí pé, “Ẹnìkan tí ó tóbi jù mí lọ ń bọ̀ lẹ́yìn mi, okùn bàtà ẹsẹ̀ ẹni tí èmi kò tó ẹni tí ń tú.
And he proclaimed, saying, I indeed baptized you with water; but One cometh after me more powerful than I; the latchet of His sandals I am not worthy, having stooped down, to loose,
8 Èmi ń fi omi ṣe ìtẹ̀bọmi yín, ṣùgbọ́n Òun yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe ìtẹ̀bọmi yín.”
and He shall baptize you with the Holy Ghost.
9 Ó sì ṣe ní ọjọ́ kan Jesu ti Nasareti ti Galili jáde wá, a sì ti ọwọ́ Johanu ṣe ìtẹ̀bọmi fún ní odò Jordani.
And it came to pass in those days, Jesus came from Nazareth of Galilee, and was baptized by John in the Jordan.
10 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tí Jesu ń ti inú omi jáde wá, ó rí ọ̀run tí ó ṣí sílẹ̀, Ẹ̀mí Mímọ́ bí àdàbà sọ̀kalẹ̀ lé e lórí.
And coming up straightway from the water, He saw the heavens open and the Spirit like a dove descending on Him.
11 Ohùn kan sì ti ọ̀run wá wí pé, “Ìwọ ni àyànfẹ́ Ọmọ mi, ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi.”
And there was a voice from the heavens: Thou art my beloved Son, in whom I delight.
12 Lẹ́sẹ̀kan náà, Ẹ̀mí Mímọ́ sì darí Jesu sí ijù,
And immediately the Spirit casts Him out into the wilderness.
13 Ó sì wà ní ogójì ọjọ́ ní aginjù. A sì ti ọwọ́ Satani dán an wò, ó sì wà pẹ̀lú àwọn ẹranko ìgbẹ́. Àwọn angẹli sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún un.
And he was in the wilderness forty days being tempted by Satan, and was with the wild beasts; and the angels continued to minister unto Him.
14 Lẹ́yìn ìgbà tí ọba Herodu ti fi Johanu sínú ẹ̀wọ̀n tan, Jesu lọ sí Galili, ó ń wàásù ìyìnrere ti ìjọba Ọlọ́run.
After that John was cast into prison, Jesus came into Galilee preaching the gospel of the kingdom of God,
15 Ó sì kéde wí pé, “Àkókò náà dé wàyí, ìjọba Ọlọ́run kù sí dẹ̀dẹ̀. Ẹ yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ sì gba ìyìnrere yìí gbọ́.”
and saying, That the time is fulfilled: the kingdom of God is at hand: repent, and believe the gospel.
16 Ní ọjọ́ kan, bí Jesu ti ń rìn létí Òkun Galili, Ó rí Simoni àti Anderu arákùnrin rẹ̀, wọ́n ń fi àwọ̀n wọn pẹja torí pé apẹja ni wọ́n.
And walking by the sea of Galilee, He saw Simon and Andrew his brother casting their net in the sea: for they were fishers.
17 Jesu sì ké sí wọn wí pé, “Ẹ máa tọ̀ mí lẹ́yìn. Èmi yóò sì sọ yín di apẹja ènìyàn.”
Jesus said to them, Come after me, and I will make you to be fishers of men.
18 Ní kánkán wọ́n fi àwọ̀n wọn sílẹ̀, wọ́n sì tọ̀ Ọ́ lẹ́yìn.
And immediately, having left their nets, they followed Him.
19 Bí Ó sì ti rìn síwájú díẹ̀, ní etí Òkun, Ó rí Jakọbu ọmọ Sebede àti Johanu arákùnrin rẹ̀ nínú ọkọ̀, wọ́n ń tún àwọ̀n wọn ṣe.
And going forth thence a little, He saw James, the son of Zebedee, and John his brother, themselves also in a ship mending their nets,
20 Ó sì ké sí àwọn náà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n fi Sebede baba wọn sílẹ̀ nínú ọkọ̀ pẹ̀lú àwọn alágbàṣe, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.
and immediately He called them. And having left their father Zebedee in the ship with the hired hands, they departed after Him.
21 Lẹ́yìn náà, Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wọ ìlú Kapernaumu, nígbà tí ó di òwúrọ̀ ọjọ́ ìsinmi, ó lọ sínú Sinagọgu, ó sì ń kọ́ni.
And they come into Capernaum; and immediately on the Sabbath, He was teaching in the synagogue.
22 Ẹnu sì ya ìjọ ènìyàn nítorí ìkọ́ni rẹ̀, nítorí pé ó ń kọ́ni bí ẹni tí ó ní àṣẹ, kì í ṣe bí àwọn olùkọ́ òfin ṣe ń kọ́ àwọn ènìyàn.
And they were astonished at His teaching; for Ile was teaching them as one having authority, and not as the scribes.
23 Ní àsìkò náà gan an ni ọkùnrin kan tí ó wà nínú Sinagọgu wọn, tí ó ní ẹ̀mí àìmọ́, bẹ̀rẹ̀ sí í kígbe wí pé,
And there was a man in their synagogue with an unclean spirit; and he cried out,
24 “Kí ni ìwọ ń wá lọ́dọ̀ wa, Jesu ti Nasareti? Ṣé ìwọ wá láti pa wá run ni? Èmí mọ ẹni tí ìwọ í ṣe; Ìwọ ní ẹni Mímọ́ Ọlọ́run!”
saying, Let me alone; what is there to us and thee, thou Jesus, the Nazarene? You have come to destroy us; I know thee who thou art, the Holy One of God.
25 Jesu si bá a wí, ó wí pé, “Pa ẹnu rẹ mọ́, kí ó sì jáde kúrò lára rẹ̀.”
And Jesus rebuked him, saying, Be silent, and come out from him.
26 Ẹ̀mí àìmọ́ náà sì gbé e ṣánlẹ̀ lógèdèǹgbé, ó ké ní ohùn rara, ó sì jáde kúrò lára ọkùnrin náà.
And the unclean spirit, convulsing him and crying with a great voice, came out from him.
27 Ẹnu sì ya àwọn ènìyàn, tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi ń sọ láàrín ara wọn ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀. Wọ́n béèrè pẹ̀lú ìgbóná ara, pé, “Kí ni èyí? Irú ẹ̀kọ́ tuntun wo ni èyí? Ó ń fi agbára pàṣẹ fún àwọn ẹ̀mí àìmọ́ pàápàá wọ́n sì gbọ́ tirẹ̀.”
And they were all astonished, so that they were inquiring one to another, saying, What is this? what new teaching is this? Because according to authority He commands the unclean spirits, and they obey Him;
28 Ìròyìn nípa rẹ̀ tàn ká gbogbo agbègbè Galili.
and His fame went out immediately into all the surrounding country of Galilee.
29 Nígbà tí wọn sì jáde kúrò nínú Sinagọgu, wọ́n lọ pẹ̀lú Jakọbu àti Johanu sí ilé Simoni àti Anderu.
And immediately, having come out from the synagogue, they came into the house of Simon and Andrew, with James and John.
30 Ìyá ìyàwó Simoni tí ó dùbúlẹ̀ àìsàn ibà, wọ́n sì sọ fún Jesu nípa rẹ̀.
And the mother-in-law of Simon was lying down burning with fever; and immediately they speak to Him concerning her:
31 Ó sì tọ̀ ọ́ lọ, ó fà á lọ́wọ́, ó sì gbé e dìde; lójúkan náà ibà náà fi sílẹ̀, ó sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún wọn.
And having come to her, taking her by the hand, He raised her up; and immediately the fever left her, and she continued to minister unto them.
32 Nígbà tí ó di àṣálẹ́, tí oòrùn wọ̀, wọ́n gbé gbogbo àwọn aláìsàn àti àwọn tó ni ẹ̀mí àìmọ́ tọ̀ ọ́ wá.
And it being evening, when the sun went down, they were carrying to Him all the sick and demonized;
33 Gbogbo ìlú si péjọ ni ẹnu-ọ̀nà.
and the whole city was gathered to the door.
34 Jesu sì wo ọ̀pọ̀ tí wọ́n ní onírúurú ààrùn sàn. Bákan náà ni ó lé ọ̀pọ̀ ẹ̀mí àìmọ́ jáde. Ṣùgbọ́n kò sì jẹ́ kí àwọn ẹ̀mí àìmọ́ náà kí ó sọ̀rọ̀, nítorí tí wọ́n mọ ẹni tí òun í ṣe.
And He healed many who were afflicted with various diseases, and He cast out many demons; and did not suffer the demons to speak, because they knew Him.
35 Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, kí ilẹ̀ tó mọ́, Jesu nìkan jáde lọ sí aginjù kan, láti lọ gbàdúrà.
And in the morning, exceedingly early, while it was yet night, having arisen up He came out, and went away into a desert place, and was praying there.
36 Simoni àti àwọn ènìyàn rẹ̀ yòókù lọ láti wá a.
And Simon and those who were with him followed Him.
37 Nígbà tí wọ́n sì rí I, wọ́n sọ fún wí pé, “Gbogbo ènìyàn ń wá ọ!”
And they found Him, and say to Him, All are seeking after thee.
38 Jesu sì dáhùn wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a lọ sí àwọn ìlú mìíràn, kí ń lè wàásù níbẹ̀ pẹ̀lú. Nítorí èyí ni èmi sá à ṣe wá.”
And He says to them, Let us go into the surrounding villages and cities, that I may preach there; for unto this I have come out.
39 Nítorí náà, ó ń kiri gbogbo agbègbè Galili, ó ń wàásù nínú Sinagọgu. Ó sì ń lé àwọn ẹ̀mí àìmọ́ jáde.
And He was preaching in their synagogues in all Galilee, and casting out the demons.
40 Ọkùnrin adẹ́tẹ̀ kan tọ̀ ọ́ wá, ó sì kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀. Ó sì bẹ̀bẹ̀ fún ìmúláradá. Ó wí pé, “Bí ìwọ bá fẹ́, ìwọ lè mú mi láradá.”
And a leper comes to Him, entreating Him, and bowing the knee to Him, and saying to Him, That if thou mayest be willing, thou art able to cleanse me.
41 Jesu kún fún àánú, ó na ọwọ́ rẹ̀, ó fi ọwọ́ rẹ̀ bà a, ó wí pé, “Èmí fẹ́. Di mímọ́.”
And Jesus being moved with compassion, reaching forth His hand, touched him, and says to him, I will; be thou cleansed.
42 Lójúkan náà ẹ̀tẹ̀ náà fi sílẹ̀ lọ, ọkùnrin náà sì rí ìwòsàn.
And He speaking, immediately the leprosy departed from him, and he was cleansed.
43 Jesu sì kìlọ̀ fún un gidigidi
And charging him, He immediately sent him away,
44 Ó wí pé, “Lọ fi ara rẹ̀ hàn àlùfáà Júù fún àyẹ̀wò. Ṣùgbọ́n má ṣe dúró sọ ohunkóhun fún ẹnikẹ́ni ní ọ̀nà. Mú ẹ̀bùn lọ́wọ́, èyí tí Mose pàṣẹ fún adẹ́tẹ̀ tí a mú láradá. Èyí tí í ṣe ẹ̀rí pé, ó ti rí ìwòsàn.”
and says to him, See that you may speak nothing to any one: but go, show thyself unto the priest, and offer for thy cleansing those things which Moses commanded, for a testimony unto them.
45 Ṣùgbọ́n ó jáde lọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí í pòkìkí, ó ń tan ìròyìn kálẹ̀. Nítorí èyí, Jesu kò sì le wọ ìlú ní gbangba mọ́, ṣùgbọ́n ó wà lẹ́yìn odi ìlú ní aginjù. Síbẹ̀, àwọn ènìyàn tọ̀ ọ́ wá láti ibi gbogbo.
And he having gone out, began to proclaim many things, and to publish abroad the word, so that He was no longer able openly to come into the city, but was out in desert places: and they continued to come to Him from all directions.

< Mark 1 >